“Àmì Ìrántí Kan Tó Ṣe Kedere”
ÀWÓKÙ ilé kan wà ní etíkun Odò Motoyasu ní ìlú Hiroshima, lórílẹ̀-èdè Japan. Àtọdún 1945 ni ilé náà ti wà bẹ́ẹ̀, àmọ́ kí nìdí tí wọn ò fi tún ilé yẹn kọ́ láti nǹkan bí àádọ́rin [70] ọdún báyìí?
Ọdún 1915 ni wọ́n kọ́ ilé alájà mẹ́ta náà parí, wọ́n sì sọ ọ́ di gbọ̀ngàn tí wọ́n fí ń ṣe àfihàn àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé kí wọ́n lè gbé iṣẹ́ ìmọ̀ ẹ̀rọ lárugẹ. Àmọ́ ṣàdédé ni gbogbo ìyẹn yí pa dà ní òwúrọ̀ ọjọ́ kẹfà, oṣù kẹjọ, ọdún 1945 ní déédéé aago mẹ́jọ kọjá ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún. Àkókò yẹn ni bọ́ǹbù runlérùnnà àkọ́kọ́ bú gbàù nítòsí òrùlé ilé náà. Ojú ẹsẹ̀ ni gbogbo àwọn tó wà nínú ilé náà kú pátápátá. Bọ́ǹbù náà ba ilé yẹn jẹ́ gan-an, àmọ́ ìpìlẹ̀ àti ògiri rẹ̀ ṣì dúró digbí.
Àjọ UNESCO * sọ pé wọ́n fi àwókù ilé yẹn sílẹ̀ bẹ́ẹ̀ kó lè jẹ́ “àmì ìrántí kan tó ṣe kedere nípa àjálù tí àwọn bọ́ǹbù runlérùnnà máa ń fà.” Ní ọdún 1996, wọ́n fi àwókù ilé náà kún Àwọn Ibi Àgbàyanu Yíká Ayé Tó Wà Nínú Àkọsílẹ̀ Àjọ UNESCO. Orúkọ tí wọ́n fún un ní Hiroshima Peace Memorial, ìyẹn Àmì Ìrántí Àlàáfíà ní Hiroshima.
Àmọ́ ó bani nínú jẹ́ pé láìka irú àwọn ìrántí tó gba àfiyèsí yìí, àwọn èèyàn ṣì ń jagun. Ohun tó sì sábà máa ń fa ogun ni ìwọra, ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni, àwọ̀ tèmi lọ̀gá, ìsìn àti kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà. Ṣùgbọ́n ṣé bí nǹkan a ṣe máa bá a lọ rèé?
Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ìyípadà máa tó ṣẹlẹ̀. Ìwé Sáàmù 46:9 sọ pé: ‘Ọlọ́run yóò mú kí ogun kásẹ̀ nílẹ̀ títí dé ìkángun ilẹ̀ ayé. Ó ṣẹ́ ọrun sí wẹ́wẹ́, ó sì ké ọ̀kọ̀ sí wẹ́wẹ́; Ó sun àwọn kẹ̀kẹ́ nínú iná.’ Ọlọ́run máa fi ìjọba tirẹ̀ rọ́pò ìjọba èèyàn, Jésù Kristi tí Bíbélì pè ni “Ọba àwọn ọba” ló máa jẹ́ alákòóso nínú Ìjọba Ọlọ́run.—Ìṣípayá 11:15; 19:16.
Tó bá di ìgbà yẹn, a ò ní nílò àwọn àmì ìrántí kankan fún àjálù tí ogun ń fà. Ìdí ni pé ìwé Aísáyà 65:17 sọ pé: “Àwọn ohun àtijọ́” ìyẹn àwọn nǹkan tó ń kọ wá lóminú lónìí “ni a kì yóò sì mú wá sí ìrántí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò wá sí ọkàn-àyà.”
^ ìpínrọ̀ 4 Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Lórí Ètò Ẹ̀kọ́, Ìmọ̀ Ìjìnlẹ̀, àti Àṣà Ìbílẹ̀.