Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

OJÚ ÌWÒYE BÍBÉLÌ

Ìmọ́tótó

Ìmọ́tótó

Ǹjẹ́ ìmọ́tótó ara ṣe pàtàkì lójú Ọlọ́run?

“Ẹ jẹ́ kí a wẹ ara wa mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin ti ẹran ara àti ti ẹ̀mí.” —2 Kọ́ríńtì 7:1.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Ẹlẹ́dàá wa fẹ́ ká gbádùn ayé wa, ká ní ìlera tó dáa, kí ẹ̀mí wa sì gùn. Ọlọ́run sọ fún wa pé: “Kí ọkàn-àyà rẹ sì pa àwọn àṣẹ mi mọ́, nítorí ọjọ́ gígùn àti ọ̀pọ̀ ọdún ìwàláàyè àti àlàáfíà ni a ó fi kún un fún ọ.” (Òwe 3:1, 2) Àwọn òfin tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípa ìmọ́tótó jẹ́ ká mọ̀ pé lóòótọ́ ló nífẹ̀ẹ́ wa. (Diutarónómì 23:12-14) Gbogbo ìgbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì tẹ̀ lé àwọn ìlànà yẹn ni wọ́n gbádùn ìlera tó dáa, wọ́n sì bọ́ lọ́wọ́ àwọn àìsàn burúkú tó dààmú àwọn orílẹ̀-èdè míì bí Íjíbítì tí kò ní irú àwọn òfin yẹn. —Diutarónómì 7:12, 15.

Bẹ́ẹ̀ náà lọ̀rọ̀ rí lónìí, àwọn tó bá “wẹ ara [wọn] mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin ti ẹran ara” máa ń gbádùn ìlera tó dáa, ẹ̀mí wọn sì máa ń gùn. Lára àwọn ẹ̀gbin ti ara náà ni sìgá mímu, ọtí àmujù àti lílo oògùn olóró. Bí a bá ń pa àwọn ìlànà Ọlọ́run mọ́ lórí ọ̀rọ̀ ìmọ́tótó, ńṣe la tún ń fi hàn pé a gba tàwọn tó wà láyìíká wa rò.—Máàkù 12:30, 31.

Ǹjẹ́ Ọlọ́run ka ìwà mímọ́ àti ìjọsìn mímọ́ sí pàtàkì?

“Ẹ sọ àwọn ẹ̀yà ara yín . . . di òkú ní ti àgbèrè, ìwà àìmọ́, ìdálọ́rùn fún ìbálòpọ̀ takọtabo, ìfẹ́-ọkàn tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́, àti ojúkòkòrò, tí í ṣe ìbọ̀rìṣà. Ní tìtorí nǹkan wọnnì ni ìrunú Ọlọ́run fi ń bọ̀.” —Kólósè 3:5, 6.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Gẹ́gẹ́ bí a ṣe sọ ṣáájú, Bíbélì rọ̀ wá pé ká “wẹ ara wa mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin ti ẹran ara àti ti ẹ̀mí.” Nígbà ayé Jésù Kristi, àwọn aṣáájú ìsìn Júù máa ń sapá gan-an láti wẹ ara wọn mọ́, àmọ́ ìwà wọn burú jáì, ojú ayé lásán sì ni ìjọsìn wọn. (Máàkù 7:1-5) Jésù wá bá wọn sọ èyí tó ń jóòótọ́ ọ̀rọ̀, ó ní: ‘Kò sí ohun kan láti òde tí ń kọjá sínú ènìyàn tí ó lè sọ ọ́ di ẹlẹ́gbin, níwọ̀n bí o ti kọjá sínú ikùn rẹ̀, a sì kọjá síta sínú ihò ẹ̀gbin.’ Ó wá fi kún un pé: “Èyíinì tí ń jáde wá láti inú ènìyàn ni ohun tí ń sọ ènìyàn di ẹlẹ́gbin; nítorí láti inú, láti inú ọkàn-àyà àwọn ènìyàn, ni àwọn èrò tí ń ṣeni léṣe ti ń jáde wá: àgbèrè, olè jíjà, ìṣìkàpànìyàn, panṣágà, ojúkòkòrò, àwọn iṣẹ́ ìwà burúkú, ẹ̀tàn, ìwà àìníjàánu, ojú tí ń ṣe ìlara, . . . àìlọ́gbọ́n-nínú. Gbogbo ohun burúkú wọ̀nyí . . . ń sọ ènìyàn di ẹlẹ́gbin.”—Máàkù 7:18-23.

Ohun tí Jésù ń sọ ni pé, tí èèyàn bá jẹ́ afínjú lórí ìmọ́tótó ara nìkan àmọ́ tí kò ka ìlànà Ọlọ́run sí lórí ọ̀rọ̀ ìwà rere àti ìjọsìn, ńṣe ni ẹni náà dà bíi kọ́ọ̀bù tí ara rẹ̀ mọ́ ṣùgbọ́n tí inú rẹ̀ dọ̀tí.—Mátíù 23:25, 26.

Ǹjẹ́ àwọn ìlànà Bíbélì le jù fún wa?

“Èyí ni ohun tí ìfẹ́ fún Ọlọ́run túmọ̀ sí, pé kí a pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́; síbẹ̀ àwọn àṣẹ rẹ̀ kì í ṣe ẹrù ìnira.”—1 Jòhánù 5:3.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Ìwé Míkà 6:8 kà pé: ‘Kí ni ohun tí Jèhófà ń béèrè láti ọ̀dọ̀ rẹ bí kò ṣe pé kí o ṣe ìdájọ́ òdodo, kí o sì nífẹ̀ẹ́ inú rere, kí o sì jẹ́ ẹni tí ó mẹ̀tọ́mọ̀wà ní bíbá Ọlọ́run rẹ rìn?’ Ṣé ohun tí Ọlọ́run béèrè yẹn wá pọ̀ jù? Yàtọ̀ síyẹn, Ẹlẹ́dàá wa fẹ́ ká máa ṣègbọràn sí òun torí pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Tí a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a máa láyọ̀ gan-an. (Sáàmù 40:8) Nígbà tá a bá dẹ́ṣẹ̀ pàápàá, àánú Ọlọ́run máa ń fi wá lọ́kàn balẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Bí baba ti ń fi àánú hàn sí àwọn ọmọ rẹ̀, Bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà ń fi àánú hàn sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀. Nítorí tí òun fúnra rẹ̀ mọ ẹ̀dá wa, Ó rántí pé ekuru ni wá,” ìyẹn ni pé, ó mọ ibi tí agbára wa mọ.—Sáàmù 103:13, 14.

Lákòópọ̀, àwọn ìlànà tí Ọlọ́run fún wa nípa ìmọ́tótó ara, ti ìwà àti ti ìjọsìn fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì ní ire wa lọ́kàn. Tí àwa náà bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà yẹn, ńṣe là ń fi hàn pé a jẹ́ ọlọ́gbọ́n, à sì nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run.