Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Tó Ń lọ Láyé

Ohun Tó Ń lọ Láyé

Ecuador

Lọ́dún 2007, ìjọba orílẹ̀-èdè Ecuador ya ohun tí ó tó ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá [10,000] kìlómítà ilẹ̀ kúrò lára igbó kìjikìji tí wọ́n ń pè ní igbó Amazon, wọ́n kéde pé àwọn fẹ́ dáàbò bo apá yìí nítorí àwọn tó fẹ́ máa wa epo níbẹ̀ kó má bàa di aṣálẹ̀. Àmọ́ wọ́n ti pa ètò yìí tì torí pé àwọn orílẹ̀-èdè yòókù ò gbówó sílẹ̀. Apá ibi tí wọ́n yà sọ́tọ̀ nínú igbó Amazon yìí wà lára ibi tí onírúurú ohun alààyè pọ̀ sí jù lọ láyé.

Japan

Lọ́dún 2013, bàbá kan tó ti lé ní ọgọ́ta [60] ọdún kó àrùn HIV nínú ẹ̀jẹ̀ tí wọ́n fà sí i lára. Lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn, ìwé ìròyìn The Japan News sọ pé kò rọrùn láti rí gbogbo àrùn tó wà nínú ẹ̀jẹ̀ tí wọ́n máa ń fà síni lára. Ìdí ni pé kòkòrò àrùn HIV lè fara pa mọ́ sínú ẹ̀jẹ̀ tí wọ́n tọ́jú pa mọ́ tó fi jẹ́ pé kò sí bí wọ́n ṣe yẹ̀ ẹ́ wò fínnífínní tó, wọn ò ní rí i.

Sìǹbábúwè

Nígbà ogun tó wáyé láàárín orílẹ̀-èdè Sìǹbábúwè àti Mòsáńbíìkì ní ohun tó ju ọgbọ̀n ọdún sẹ́yìn, wọ́n ri àwọn bọ́ǹbù kan mọ́lẹ̀ sí àwọn ibodè ìlú náà. Àmọ́ lẹ́yìn ti ogun náà parí, àwọn bọ́ǹbù yẹn ṣì ń pa àwọn èèyàn, ó sì ń sọ àwọn míì di aláàbọ̀ ara. Àjọ International Committee of the Red Cross sọ pé: “Láti ọdún 1980, àwọn bọ́ǹbù náà ti pa èèyàn tó ju ẹgbẹ̀rún kan ààbọ̀ [1,500] àti ọ̀kẹ́ mẹ́fà [120,000] ẹran ọ̀sìn, ó sì ti sọ ẹgbẹ̀rún méjì [2,000] èèyàn di aláàbọ̀ ara.”

Ọsirélíà

Ìwádìí kan fi hàn pé ọ̀pọ̀ àwọn tọkọtaya tó fẹ́ pínyà ló máa ń bá ara wọn fa ọ̀rọ̀ lórí ìkáwọ́ ẹni tí ajá máa wà. Nígbà tí wọ́n mẹ́nu kan àwọn nǹkan tó sábà máa ń fa wàhálà, ọ̀rọ̀ ilé àti ilẹ̀ ló ṣáájú, owó ló tẹ̀ lé. Lẹ́yìn ìyẹn ni wọ́n mẹ́nu ba àwọn nǹkan míì bíi fọ́tò àti ẹran ọ̀sìn.