Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìrànlọ́wọ́ Fún Ìdílé | Ọmọ Títọ́

Bi O Se Le Salaye Ohun Ti Iku Je fun Omo Re

Bi O Se Le Salaye Ohun Ti Iku Je fun Omo Re

OHUN TÓ JẸ́ ÌṢÒRO

Ọmọ rẹ tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́fà wò ṣùnṣùn lọ́jọ́ kan, ó bi ẹ́ pé, “Ṣé ẹ̀yìn náà ṣì máa kú lọ́jọ́ kan?” Ìbéèrè yẹn kà ẹ́ láyà, ó sì yà ẹ́ lẹ́nu, o bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé: ‘Ṣé ọmọ mi ti gbọ́n tóyẹn ni? Báwo ni mo ṣe lè ṣàlàyé ohun tí ikú jẹ́ fún un?’

OHUN TÓ YẸ KÓ O MỌ̀

Àwọn ọmọdé náà máa ń ronú nípa ikú. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé tí wọ́n bá ń ṣeré, ọ̀kan nínú wọn lè díbọ́n bí ẹni tó ti kú. Torí náà, kì í ṣe èèwọ̀ láti ṣàlàyé ohun tí ikú jẹ́ fún ọmọ rẹ, ó sì yẹ kó o múra tán láti dáhùn àwọn ìbéèrè tó bá ní nípa rẹ̀. Bó o bá ń fọgbọ́n ṣàlàyé ọ̀rọ̀ náà fún un lóòrèkóòrè, ó máa rọrùn fún un láti fara dà á bí ẹnì kan tó fẹ́ràn bá kú.

Má ṣe rò pé ò ń dẹ́rù ba ọmọ rẹ tó o bá ń sọ̀rọ̀ nípa ikú, kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe lò ń mú ìbẹ̀rù kúrò lọ́kàn rẹ̀. Àwọn ohun kan wà táwọn ọmọdé máa ń ṣì lóye nípa ikú. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ọ̀mọ̀ràn sọ pé ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ tí kò tíì tó ọmọ ọdún mẹ́fà kò mọ̀ pé ẹni tó bá ti kú ti lọ ráúráú nìyẹn. Tí wọ́n bá ń bára wọn ṣeré, ọ̀kan lè díbọ́n bí ẹni tó ti kú, kó sì tún dìde lẹ́yìn ìṣẹ́jú díẹ̀.

Bí wọ́n ṣe ń dàgbà, wọ́n á bẹ̀rẹ̀ sí í rí i pé ikú kì í ṣe ọ̀rọ̀ eré rárá. Èyí lè mú kí ọkàn wọn má balẹ̀ tàbí kí wọ́n tiẹ̀ máa bẹ̀rù, pàápàá bí ẹnì kan tí wọ́n mọ̀ bá kú. Ìdí nìyẹn tó fi ṣe pàtàkì pé kó o jíròrò ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú wọn. Dókítà kan tó ń jẹ́ Marion Haza sọ pé: “Ẹ̀rù lè bẹ̀rẹ̀ sí í ba ọmọ kan tó bá jẹ́ pé ńṣe ni ẹ sọ ọ̀rọ̀ ikú di ọ̀rọ̀ má-jẹ̀ẹ́-á-gbọ́ nínú ilé.”

Má ṣe yọ ara rẹ lẹ́nu nípa ọ̀nà tó yẹ kó o gbà ṣàlàyé ọ̀rọ̀ náà fún un. Ìwádìí kan sọ pé, ohun táwọn ọmọdé fẹ́ ni pé “kó o sọ òótọ́ fún wọn lọ́nà pẹ̀lẹ́.” Ohun kan ni pé àwọn ọmọdé kì í déédéé béèrè ọ̀rọ̀ láìjẹ́ pé ó ń jẹ wọ́n lọ́kàn, wọ́n sì fẹ́ ìdáhùn.

OHUN TÓ O LÈ ṢE

Lo àǹfààní tó o bá rí láti bá ọmọ rẹ sọ̀rọ̀. Bí ọmọ rẹ bá rí òkú ẹranko kan lójú títì tàbí tí ajá rẹ̀ kú, o lè rọra fi àwọn ìbéèrè kan wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu rẹ̀. O lè bi í pé: “Ṣé àwọn ẹranko tó ti kú máa ń jìyà? Ṣé òtútù lè mú un tàbí ṣé ebi lè pa á? Báwo lo ṣe lè mọ̀ pé ẹnì kan tàbí ẹranko kan ti kú?”—Ìlànà Bíbélì: Oníwàásù 3:1, 7.

Má fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ. Tí mọ̀lẹ́bí kan bá kú, má ṣe pẹ́ ọ̀rọ̀ sọ tàbí kó o máa sọ̀rọ̀ lówelówe fún ọmọ rẹ. Má ṣe lo àwọn ọ̀rọ̀ bíi “Màmá àgbà ti rìnrìn-àjò.” Irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ lè jẹ́ kí ọmọ rẹ rò pé ẹni náà ṣì ń pa dà bọ̀. Ì bá dáa kó o kúkú sojú abẹ níkòó. Bí àpẹẹrẹ, o lè sọ pé: “Màmá àgbà ti kú, wọn ò sì lè ṣiṣẹ́ kankan mọ́ báyìí. A ò lè bá wọn sọ̀rọ̀, àmọ́, a ò ní gbàgbé wọn.”—Ìlànà Bíbélì: Éfésù 4:25.

Ọ̀pọ̀ ọmọdé ló rò pé ikú máa ń ràn, torí náà fi ọkàn ọmọ rẹ balẹ̀ pé kò sí aburú kankan tó máa ṣẹlẹ̀ sí i

Fi ọmọ rẹ lọ́kàn balẹ̀. Ọmọ rẹ lè máa rò pé èrò òun tàbí ohun kan tóun ṣe ló fa ikú ẹni náà. Kàkà tí wà á fi sọ fún un pé òun kọ́ ló fà á, ì bá sàn kó o bi í pé: “Kí ló mú kó o rò pé ìwọ ló fà á?” Fara balẹ̀ tẹ́tí sí ohun tó bá sọ, má sì ka èrò rẹ̀ sí ọ̀rọ̀ ọmọdé lásán. Bákan náà, ọ̀pọ̀ ọmọdé ló rò pé ikú máa ń ràn, torí náà fi ọmọ rẹ lọ́kàn balẹ̀ pé kò sí aburú kankan tó máa ṣẹlẹ̀ sí i.

Fà á mọ́ra kó lè sọ̀rọ̀. Ẹ jọ máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn mọ̀lẹ́bí yín tó ti kú títí kan àwọn tí kò mọ̀ pàápàá. O lè sọ àwọn nǹkan tó o rántí nípa wọn àtàwọn àwàdà tí wọ́n máa ń ṣe nígbà yẹn lọ́hùn-ún. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe lò ń jẹ́ kí ọmọ rẹ mọ̀ pé kò sóhun tó burú tó bá ń sọ̀rọ̀ tàbí ronú nípa àwọn tó ti kú. Àmọ́ ṣá o, bí kò bá fẹ́ sọ̀rọ̀, má fipá mú un. Bí kò bá sọ̀rọ̀ lọ́jọ́ yẹn, àyè á wà láti sọ ọ́ nígbà míì.—Ìlànà Bíbélì: Òwe 20:5.

Orí 34 àti 35 nínú ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà máa ran ọmọ rẹ lọ́wọ́ láti mọ ohun tí Bíbélì fi kọ́ni nípa ikú. Wo abẹ́ ÀWỌN ÌTẸ̀JÁDE > ÀWỌN ÌWÉ ŃLÁ ÀTÀWỌN ÌWÉ PẸLẸBẸ