Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ÀWỌN Ọ̀DỌ́

Bí Ìwọ àti Àfẹ́sọ́nà Rẹ Bá Fi Ara Yín Sílẹ̀

Bí Ìwọ àti Àfẹ́sọ́nà Rẹ Bá Fi Ara Yín Sílẹ̀

OHUN TÓ JẸ́ ÌṢÒRO

“Mo rò pé mo ti rí ẹni tó máa bá mi kalẹ́. Lọ́kàn mi, ńṣe ló dà bí pé kò sóhun tó lè yà wá. Àmọ́ á túká lẹ́yìn oṣù méjì péré. Ó jọ mí lójú pé iná ìfẹ́ wa tó ń jó lala kú pii lójijì!”​—Anna. *

“A ti lọ mọwọ́ ara wa jù, lọ́kàn mi, àfi bí ìgbà tá a ti ṣègbéyàwó. Àmọ́, bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, mo bẹ̀rẹ̀ sí í rí i pé ìwà rẹ̀ kò bá tèmi mu. Nígbà tí mo rí i pé àṣìṣe ló máa jẹ́ tí mo bá ń bá ìfẹ́sọ́nà yìí lọ, mo sọ fún un pé mi ò ṣe mọ́.”​—Elaine.

Ṣé irú nǹkan báyìí ti ṣẹlẹ̀ sí ẹ rí? Àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ kó o mọ bó o ṣe lè fara dà á.

OHUN TÓ YẸ KÓ O MỌ̀

Tí ẹ bá fi ara yín sílẹ̀, ó máa dun ẹ̀yin méjèèjì, títí kan ẹni tó sọ pé òun ò ṣe mọ́. Lẹ́yìn oṣù mẹ́fà tí ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Sarah fi ẹni tó ń fẹ́ sílẹ̀, ó sọ pé: “Ó dùn mí wọra. Torí mo ti gbà lọ́kàn mi pé òun ni màá bá kalẹ́, àmọ́ ká tó ṣẹ́jú pẹ́ẹ́, a ti túká. Tí mo bá ń gbọ́ àwọn orin tí àwa méjèèjì nífẹ̀ẹ́ sí, mo máa ń rántí àwọn ìgbà tá a jọ wà papọ̀. Ó tún máa ń dùn mí tí mo bá lọ sí àwọn ibi tá a ti jọ máa ń ṣeré, tí mi ò sì rí i lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi. Ọkàn mi máa ń gbọgbẹ́ tí mo bá rántí àjọṣe wa bó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi ni mo sọ pé mi ò ṣe mọ́!”

Tí ẹ bá fi ara yín sílẹ̀, ó máa dùn yín, ṣùgbọ́n ó lè ṣe yín láǹfààní. Elaine sọ pé: “Kò wù ẹ́ kínú ẹni tí ò ń fẹ́ bà jẹ́. Ṣùgbọ́n, tí ọ̀rọ̀ yín ò bá wọ̀, tí o kò sì fòpin sí i, inú ẹ̀yin méjèèjì ló máa pàpà bà jẹ́, torí pé àjọgbé yín lè má tura.” Sarah náà sọ pé: “Tí o kò bá láyọ̀ pẹ̀lú ẹni tó ò ń fẹ́ sọ́nà, ó ṣeé ṣe kó o má láyọ̀ nígbà tẹ́ ẹ bá fẹ́ ara yín sílé tán, torí náà ó máa dáa kẹ́ ẹ fi ara yín sílẹ̀.”

Tó o bá fi ẹni tó ò ń fẹ́ sílẹ̀, ìyẹn kò sọ ẹ́ di aláṣetì. Kì í ṣe gbogbo àwọn tó ń fẹ́ ara wọn sọ́nà ló máa fẹ́ ara wọn sílé. Torí náà, tó o bá rí i pé àjọgbé yín kò ní wọ̀, ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé kẹ́ ẹ fi ara yín sílẹ̀. Ti pé ẹ kò fẹ́ ara yín mọ́ kò sọ ẹ́ di aláṣetì. Kí lo lè ṣe tí ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn kò fi ní mú kó o kárísọ?

OHUN TÓ O LÈ ṢE

Gbà pé ọ̀rọ̀ náà dùn ẹ́. Elaine sọ pé: “Kì í ṣe ọ̀rẹ́ kan lásán la jọ fi ara wa sílẹ̀, olólùfẹ́ tí ọkàn mi yàn ni.” Tí ìwọ àti àfẹ́sọ́nà rẹ bá fi ara yin sílẹ̀, ó dájú pé ó máa dùn ẹ́ wọra. Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Adam sọ pé: “Kò sí bí kò ṣe ní dùn ẹ́ tí ìwọ àti àfẹ́sọ́nà rẹ bá fi ara yín sílẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé torí kó lè dáa lẹ ṣe fòpin sí i.” Ó lè máa ṣe ẹ́ bíi ti Dáfídì Ọba tí Bíbélì mẹ́nu kàn. Nígbà tí ìdààmú ọkàn bá a, ó sọ pé: “Omijé mi ni mo fi ń mú kí àga ìnàyìn mi kún àkúnwọ́sílẹ̀.” (Sáàmù 6:6) Torí náà, má ṣe díbọ́n bíi pé ọ̀rọ̀ náà kò dùn ẹ́. Tó o bá gbà pé ọ̀rọ̀ náà dùn ẹ́, tó o tiẹ̀ sunkún, ìyẹn máa jẹ́ kó o tètè gbé e kúrò lọ́kàn.​—Ìlànà Bíbélì: Sáàmù 4:4.

Sún mọ́ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ. Lóòótọ́, ó lè má rọrùn láti ṣe bẹ́ẹ̀. Anna tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lókè sọ pé: “Kò tiẹ̀ wù mí láti ẹnikẹ́ni, ó sì ń ṣe mi bíi pé kí n dá wà, kí n lè ronú lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí mi.” Nígbà tó yá, Anna rí i pé ó bọ́gbọ́n mu pé kí òun sún mọ́ àwọn ọ̀rẹ́ tó máa jẹ́ kí òun gbé ọ̀rọ̀ náà kúrò lọ́kàn. Ó wá sọ pé: “Ní báyìí, mi ò kárí sọ mọ́, ọ̀rọ̀ náà ò sì dùn mí mọ́ bíi ti tẹ́lẹ̀.”​—Ìlànà Bíbélì: Òwe17:17.

Kẹ́kọ̀ọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀. O lè bi ara rẹ pé: ‘Ṣé ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí ti mú kí n rí ibi tí mo kù sí, kí n sì ṣàtúnṣe? Ṣé ohun kan wà tí mò ń ṣe tẹ́lẹ̀, tí mi ò ní ṣe mọ́ tí mo bá ń fẹ́ ẹlòmíì?’ Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Marcia sọ pé: “Lẹ́yìn àkókò díẹ̀, mo fara balẹ̀ ronú lórí ohun tó ṣẹlẹ̀, torí mo ní láti ṣe sùúrù kí n lè gbé ọ̀rọ̀ náà kúrò lọ́kàn, kí n tó lè kẹ́kọ̀ọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ láàárín wa.” Adam tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lókè náà gbà bẹ́ẹ̀, ó ní: “Ó tó ọdún kan kí ọ̀rọ̀ náà tó tán lára mi, ó sì gbà ju bẹ́ẹ̀ lọ kí n tó rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí mi jẹ́ kí n mọ ara mi, ó jẹ́ kí n mọ ìwà àwọn obìnrin, ó sì tún jẹ́ kí n mọ bó ṣe yẹ kí ìfẹ́sọ́nà rí. Èyí ni kò jẹ́ kọ́rọ̀ náà dùn mí bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́.”

Sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ fún Ọlọ́run. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run máa ń “mú àwọn oníròbìnújẹ́-ọkàn lára dá, ó sì ń di àwọn ojú ibi tí ń ro wọ́n.” (Sáàmù 147:3) Àmọ́, Ọlọ́run kọ́ ló máa yan ẹni tó o máa fẹ́ fún ẹ, kì í sì ṣe ẹ̀bi rẹ̀ tí ìwọ àti àfẹ́sọ́nà rẹ bá fi ara yín sílẹ̀. Ṣùgbọ́n, Ọlọ́run fẹ́ ire fún ẹ. Torí náà, sọ gbogbo àníyàn ọkàn rẹ fún un nínú àdúrà.​—Ìlànà Bíbélì: 1 Pétérù 5:7.

^ ìpínrọ̀ 4 A ti yí àwọn orúkọ inú àpilẹ̀kọ yìí pa dà.