Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ǸJẸ́ O LÈ PINNU BÍ ÌGBÉSÍ AYÉ RẸ ṢE MÁA RÍ?

Ohun tó jẹ́ ìṣòro: Ìṣòro Tó Kọjá Agbára Wa

Ohun tó jẹ́ ìṣòro: Ìṣòro Tó Kọjá Agbára Wa

ṢÉ ÀÌSÀN kan ló ń bá ẹ fínra? Ṣé ẹnì kejì rẹ ló kọ̀ ẹ́ sílẹ̀, àbí èèyàn rẹ kan ló kú? Nígbà tá a bá kojú ìṣòro tó kọjá agbára wa, ó máa ń ṣe wá bíi pé kí ìṣòro yẹn fò lọ. Àmọ́, kò sóhun tá a lè ṣe láti yí ohun tó ti ṣẹlẹ̀ pa dà. Kí lo lè ṣe tí ìṣòro yìí kò fi ní mu ẹ́ lómi?

ÀPẸẸRẸ INÚ BÍBÉLÌ: PỌ́Ọ̀LÙ

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi ìtara wàásù káàkiri. Àmọ́, wọ́n fàṣẹ ọba mú un láìtọ́, ọdún méjì sì ni àwọn ọmọ ogun fi ṣọ́ ọ kó má baà jáde nílé. Ìyẹn kò jẹ́ kí Pọ́ọ̀lù lè wàásù káàkiri mọ́. Kàkà kí Pọ́ọ̀lù kárí sọ, ńṣe ló gbájú mọ́ ohun tó lè ṣe. Pọ́ọ̀lù máa ń sọ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún àwọn tó bá wá kí i. Àkókò yẹn náà ló kọ àwọn lẹ́tà mélòó kan tó wà nínú Bíbélì.​—Ìṣe 28:​30, 31.

OHUN TÍ ANJA ṢE

Bá a ṣe sọ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, Anja kò lè jáde nílé. Ó sọ pé: “Látìgbà tí mo ti mọ̀ pé mo ní àrùn jẹjẹrẹ ni ìgbésí ayé mi ti yí pa dà. Mi ò lè lọ síbi iṣẹ́ mọ́, mi ò sì lè jáde bó ṣe wù mí kí n má baà dá kún ìṣòro mi.” Kí ni Anja ṣe tí ìṣòro yìí kò fi paná ayọ̀ rẹ̀? Ó sọ pé: “Mo ronú lórí àwọn nǹkan tí mo lè ṣe. Mo fi àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì síwájú, mo sì gbájú mọ́ àwọn nǹkan tágbára mi ká. Èyí ti jẹ́ kí n lè pinnu bí mo ṣe fẹ́ kí ìgbésí ayé mi rí.”

OHUN TÓ O LÈ ṢE

Tó o bá ní ìṣòro kan tó kọjá agbára rẹ, o lè ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí:

  • Máa ṣe ohun tí agbára rẹ gbé. Bí àpẹẹrẹ, o lè má rí nǹkan kan ṣe sí àìlera rẹ, àmọ́ o lè máa jẹ oúnjẹ tó dọ́ṣọ̀, kó o máa ṣe eré ìmárale, kó o sì máa sinmi dáadáa?

  • Pinnu pé wàá gbé nǹkan kan ṣe láyé rẹ. Ronú lórí àwọn nǹkan tó o lè ṣe kí ọwọ́ rẹ lè tẹ ohun tó o pinnu. Kó o sì máa lo àkókò díẹ̀ lójoojúmọ́ láti ṣiṣẹ́ lórí rẹ̀.

  • Máa ṣe àwọn nǹkan pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ bíi kó o gbálẹ̀ tàbí kó o fọ abọ́. Múra lọ́nà tó máa buyì kún ẹ. Àwọn nǹkan tó bá sì ṣe pàtàkì ni kó o máa jí mú ṣe. Èyí á jẹ́ kó o mọ̀ pé ìwọ náà wúlò, wàá sì láyọ̀.

  • Ronú nípa àǹfààní tí ipò rẹ lè ṣe ẹ́. Bí àpẹẹrẹ, ìṣòro rẹ lè jẹ́ kó o mọ béèyàn ṣe ń lẹ́mìí ìfaradà. Wàá sì lè kọ́ àwọn míì nípa bí wọ́n ṣe lè fara da ìṣòro.

Ohun Tó Yẹ Kó O Mọ̀: O lè má rí nǹkan kan ṣe sí ìṣòro rẹ, àmọ́ ọ̀pọ̀ nǹkan lo lè ṣe tí ìṣòro náà kò fi ní pin ẹ́ lẹ́mìí.

“Mo ti kẹ́kọ̀ọ́, nínú àwọn ipò yòówù tí mo bá wà, láti máa ní ẹ̀mí ohun-moní-tómi.”​—Ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù nínú ìwé Fílípì 4:11