Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

TA LÓ ṢIṢẸ́ ÀRÀ YÌÍ?

Párì Ọ̀nì

Párì Ọ̀nì

KÒ SÍ ẹranko mí ì láyé yìí tó lè fagbára deyín mọ́ nǹkan tó ọ̀nì. Bí àpẹẹrẹ, agbára tí àwọn ọ̀nì tó wà lágbègbè Ọsirélíà fi ń deyín mọ́ nǹkan fi ìlọ́po mẹ́ta ju agbára tí kìnnìún àti ẹkùn fi ń deyín mọ́ nǹkan lọ. Síbẹ̀, ọ̀nì máa ń tètè nímọ̀lára tí nǹkan bá kan párì rẹ̀, kódà, ó máa ń yára mọ nǹkan lára ju àwa èèyàn lọ. Báwo ni ọ̀nì tí awọ ara rẹ̀ yi bí irin ṣe lè tètè máa mọ nǹkan lára?

Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn sẹ́ẹ̀lì tíntìntín tó ń gbé ìsọfúnni lọ sínú ọpọlọ ló wà ní párì ọ̀nì. Olùṣèwádìí kan tó ń jẹ́ Duncan Leitch sọ pé: “Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn fọ́nrán iṣan tó so kọ́ àwọn sẹ́ẹ̀lì yìí ló gba inú àwọn ihò ­tíntìntín tó wà nínú agbárí ọ̀nì.” Ihò agbárí yìí máa ń dáàbò bo àwọn fọ́nrán iṣan yẹn, lẹ́sẹ̀ kan náà, ó máa ń jẹ́ kó yára gba ìsọfúnni, èyí ló fà á tí ọ̀nì fi máa ń tètè mọ nǹkan lára. Fún ìdí yìí, ọ̀nì tètè máa ń mọ̀ ìyàtọ̀ láàárín oúnjẹ àti ohun tí kì í ṣe oúnjẹ tó bá wà ní ẹnu rẹ̀. Bákan náà, ọ̀nì tún lè kó àwọn ọmọ rẹ̀ sí ẹnu láìjẹ́ pé ó máa ṣèèṣì deyín mọ́ wọn. Ká sòótọ́, ohun àrà gbáà ni páárì ọ̀nì jẹ́ torí pé, bó ṣe lágbára tó, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe tètè máa ń mọ̀ nǹkan lára.

Kí lèrò rẹ? Ṣé párì ọ̀nì kàn ṣàdédé wà bẹ́ẹ̀ ni, àbí ẹnì kan ló ṣiṣẹ́ àrà yìí?