Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

‘Onídàájọ́ Ilẹ̀ Ayé’ Máa Ń Ṣe Ohun Tó Tọ́ Nígbà Gbogbo

‘Onídàájọ́ Ilẹ̀ Ayé’ Máa Ń Ṣe Ohun Tó Tọ́ Nígbà Gbogbo

“Àpáta náà, pípé ni ìgbòkègbodò rẹ̀, nítorí gbogbo ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ ìdájọ́ òdodo.”​DIU. 32:4.

ORIN: 112, 89

1. Báwo ni Ábúráhámù ṣe fi hàn pé ó dá òun lójú pé Jèhófà jẹ́ onídàájọ́ òdodo? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

Ó DÁ Ábúráhámù lójú pé Jèhófà máa ṣèdájọ́ tó tọ́ fáwọn èèyàn Sódómù àti Gòmórà. Ìdí nìyẹn tó fi béèrè pé: “Onídàájọ́ gbogbo ilẹ̀ ayé kì yóò ha ṣe ohun tí ó tọ́ bí?” (Jẹ́n. 18:25) Ábúráhámù mọ̀ dájú pé Jèhófà kò ní ṣe ohun tí kò tọ́ láé, kò ní “fi ikú pa olódodo pẹ̀lú ẹni burúkú.” Lójú Ábúráhámù, irú nǹkan bẹ́ẹ̀ “kò ṣeé ronú kàn.” Nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́rin [400] ọdún lẹ́yìn náà, Jèhófà sọ nípa ara rẹ̀ pé: “Àpáta náà, pípé ni ìgbòkègbodò rẹ̀, nítorí gbogbo ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ ìdájọ́ òdodo. Ọlọ́run ìṣòtítọ́, ẹni tí kò sí àìṣèdájọ́ òdodo lọ́dọ̀ rẹ̀; Olódodo àti adúróṣánṣán ni.”​—Diu. 31:19; 32:4.

2. Kí ló jẹ́ kó dá wa lójú pé gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń ṣèdájọ́ òdodo?

2 Kí ló mú kó dá Ábúráhámù lójú pé gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń ṣèdájọ́ òdodo? Ìdí ni pé tó bá di pé ká ṣe ìdájọ́ òdodo, kò sẹ́ni tá a lè fi wé Jèhófà. Kódà, ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n lò fún “ìdájọ́ òdodo” àti “òdodo” sábà máa ń wà pa pọ̀ nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. Ohun kan ni pé kò fi bẹ́ẹ̀ síyàtọ̀ láàárín ọ̀rọ̀ méjèèjì. Torí pé Jèhófà ló fún wa ní ìlànà òdodo, ó dájú pé gbogbo ìgbà ni ìdájọ́ rẹ̀ máa ń tọ̀nà. Bákan náà, Bíbélì sọ fún wa pé Jèhófà “jẹ́ olùfẹ́ òdodo àti ìdájọ́ òdodo.”​—Sm. 33:5.

3. Àwọn ìwà àìṣòdodo wo ló kúnnú ayé lónìí?

3 Ọkàn àwọn tó bẹ̀rù Ọlọ́run máa ń balẹ̀ bí wọ́n ṣe mọ̀ pé gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń ṣe ìdájọ́ òdodo torí pé ìwà àìṣòdodo ló kúnnú ayé. Látàrí ìwà àìṣòdodo yìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ni wọ́n ti fìyà jẹ. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n ti fẹ̀sùn èké kan àwọn kan, wọ́n sì ti fi wọ́n sẹ́wọ̀n láìmọwọ́ mẹsẹ̀. Àmọ́ ìtẹ̀síwájú tó bá ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ti mú kí wọ́n ṣàyẹ̀wò ẹjọ́ àwọn kan, wọ́n sì rí i pé wọn ò jẹ̀bi. Wọ́n wá dá wọn sílẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ti lo ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́wọ̀n láìṣẹ̀ láìrò. Ká sòótọ́, irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ máa ń tojú súni, ó sì máa ń múnú bíni gan-an, àmọ́ àwọn àìṣe ìdájọ́ òdodo kan wà tó lè ṣòro fáwa Kristẹni láti pa mọ́ra.

NÍNÚ ÌJỌ

4. Kí ló lè fẹ́ mú Kristẹni kan kọsẹ̀?

4 Àwa Kristẹni mọ̀ pé kò sí káwọn èèyàn inú ayé má hùwà àìṣòdodo sí wa. Àmọ́ tá a bá kíyè sí ohun tó jọ àìṣe ìdájọ́ òdodo nínú ìjọ tàbí pé ohun tó jọ bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí wa, ó lè ṣòro fún wa láti fara dà á. Tí irú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀ sí ẹ, kí lo máa ṣe? Ṣé wàá jẹ́ kíyẹn mú ẹ kọsẹ̀?

5. Kí nìdí tí kò fi yẹ kó yà wá lẹ́nu tí ẹnì kan bá hùwà àìdáa sí wa tàbí sí ẹlòmíì nínú ìjọ?

5 Torí pé aláìpé ni gbogbo wa, a sì máa ń dẹ́ṣẹ̀, ó ṣeé ṣe kẹ́nì kan hùwà àìdáa sí wa nínú ìjọ, ó sì lè jẹ́ àwa la máa hùwà àìdáa sáwọn míì. (1 Jòh. 1:8) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ kò wọ́pọ̀, àwọn Kristẹni tòótọ́ mọ̀ pé ó lè ṣẹlẹ̀, torí náà kì í yà wọ́n lẹ́nu tó bá ṣẹlẹ̀, wọn kì í sì í jẹ́ kó mú wọn kọsẹ̀. Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi fún wa ní àwọn ìmọ̀ràn tó máa ràn wá lọ́wọ́ nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Tá a bá fi wọ́n sílò, a ò ní kọsẹ̀ kódà táwọn ará bá hùwà àìdáa sí wa.​—Sm. 55:​12-14.

6, 7. Ìwà àìdáa wo ni wọ́n hù sí arákùnrin kan nínú ìjọ, kí ló ràn án lọ́wọ́ láti fara dà á?

6 Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Arákùnrin Willi Diehl. Látọdún 1931 ni Arákùnrin Diehl ti ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì tó wà nílùú Bern, lórílẹ̀-èdè Switzerland. Nígbà tó di ọdún 1946, ó lọ sí kíláàsì kẹjọ ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì nílùú New York lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Lẹ́yìn tó kẹ́kọ̀ọ́ yege, wọ́n ní kó máa ṣe iṣẹ́ alábòójútó àyíká lórílẹ̀-èdè Switzerland. Nígbà tó ń sọ ìtàn ìgbésí ayé rẹ̀, ó sọ pé: “Ní May 1949, mo sọ fún ẹ̀ka ọ́fíìsì wa nílùú Bern pé mo fẹ́ gbéyàwó.” Èsì wo ni ẹ̀ka ọ́fíìsì fún un? Wọ́n sọ fún un pé: “Kò síṣẹ́ míì fún yín lẹ́yìn kẹ́ ẹ máa ṣe aṣáájú-ọ̀nà déédéé.” Arákùnrin Diehl tún sọ pé: “Wọn ò jẹ́ kí n sọ àsọyé mọ́ . . . Ọ̀pọ̀ ni kì í kí wa mọ́, ṣe ni wọ́n ń ṣe wá bí ẹni tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́.”

7 Kí ni Arákùnrin Diehl ṣe sóhun tó ṣẹlẹ̀ yìí? Ó sọ pé: “Ohun kan tá a mọ̀ ni pé a ò dẹ́ṣẹ̀ torí pé a ṣègbéyàwó. Torí náà, a fọ̀rọ̀ náà sádùúrà, a sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.” Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ètò Ọlọ́run ṣàtúnṣe sí èrò òdì táwọn kan ní nípa ìgbéyàwó, wọ́n sì dá gbogbo àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tí Arákùnrin Diehl ní tẹ́lẹ̀ pa dà fún un. Jèhófà san án lẹ́san torí pé kò jẹ́ kí ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn mú kó ṣìwà hù. * Á dáa ká bi ara wa pé, ‘Ṣé ohun tí arákùnrin yẹn ṣe lèmi náà á ṣe tírú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀ sí mi? Ṣé màá mú sùúrù kí Jèhófà dá sọ́rọ̀ náà, àbí màá gbèjà ara mi?’​—Òwe 11:2; ka Míkà 7:7.

8. Kí ló lè mú kó o ronú pé ẹnì kan nínú ìjọ ṣàìdáa sí ẹ tàbí sí ẹlòmíì, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ lè má rí bẹ́ẹ̀?

8 Nígbà míì, ó ṣeé ṣe kó o ronú pé ẹnì kan nínú ìjọ ṣàìdáa sí ẹ tàbí sí ẹlòmíì, kọ́rọ̀ má sì rí bẹ́ẹ̀. Torí àìpé wa, ó lè jẹ́ pé ojú tá a fi wo ọ̀rọ̀ náà ló kù díẹ̀ káàtó tàbí ká má mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀rọ̀ náà. Èyí ó wù kó jẹ́, yálà wọ́n hùwà àìdáa sí wa lóòótọ́ tàbí àwa la ṣi ọ̀rọ̀ náà lóye, ẹ jẹ́ ká fọ̀rọ̀ náà sádùúrà, ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ká sì pinnu pé a ò ní jẹ́ kọ́rọ̀ náà mú wa kọsẹ̀. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, a ò ní “kún fún ìhónú sí Jèhófà.”​—Ka Òwe 19:3.

9. Àwọn àpẹẹrẹ wo la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí àtèyí tó tẹ̀ lé e?

9 Ẹ jẹ́ ká jíròrò àpẹẹrẹ ìwà àìdáa mẹ́ta tó ṣẹlẹ̀ sáwọn kan nínú Bíbélì. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò nípa Jósẹ́fù tó jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù àtohun táwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ṣe fún un. Nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e, a máa sọ bí Jèhófà ṣe bá Áhábù ọba Ísírẹ́lì lò àtohun tó ṣẹlẹ̀ sí àpọ́sítélì Pétérù nílùú Áńtíókù ti Síríà. Bá a ṣe ń jíròrò àwọn àpẹẹrẹ yìí, máa fọkàn sáwọn ẹ̀kọ́ táá jẹ́ kó o lè máa fojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan wò ó, táá sì jẹ́ kí àjọṣe rẹ pẹ̀lú Jèhófà túbọ̀ gún régé, pàápàá jù lọ tó o bá gbà pé wọ́n ṣàìdáa sí ẹ.

WỌ́N ṢÀÌDÁA SÍ JÓSẸ́FÙ

10, 11. (a) Ìwà àìdáa wo làwọn èèyàn hù sí Jósẹ́fù? (b) Àǹfààní wo ni Jósẹ́fù ní nígbà tó wà lẹ́wọ̀n?

10 Àwọn èèyàn ṣàìdáa sí Jósẹ́fù tó jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà. Àmọ́ ohun tó dùn ún jù ni pé àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ náà tún ṣàìdáa sí i. Nígbà tí Jósẹ́fù fẹ́rẹ̀ẹ́ pọ́mọ ogún [20] ọdún, àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ mú un, wọ́n tà á sóko ẹrú, àwọn tó rà á sì fipá mú un lọ sí Íjíbítì. (Jẹ́n. 37:​23-28; 42:21) Lẹ́yìn ìyẹn, ẹnì kan tún parọ́ mọ́ ọn pé ó fẹ́ fipá bá òun sùn, ni wọ́n bá jù ú sẹ́wọ̀n láìgbọ́ tẹnu ẹ̀. (Jẹ́n. 39:​17-20) Nǹkan bí ọdún mẹ́tàlá ni Jósẹ́fù fi jẹ gbogbo ìyà yìí. Kí la lè kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jósẹ́fù tẹ́nì kan tá a jọ jẹ́ ará bá ṣàìdáa sí wa?

11 Jósẹ́fù sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún ẹnì kan tí wọ́n jọ wà lẹ́wọ̀n. Ẹlẹ́wọ̀n yìí ni olórí àwọn agbọ́tí ọba tẹ́lẹ̀. Nígbà tí Jósẹ́fù àti agbọ́tí ọba yìí jọ wà lẹ́wọ̀n, agbọ́tí náà lá àlá kan, Jèhófà sì fi ìtumọ̀ àlá náà han Jósẹ́fù. Jósẹ́fù wá sọ fún agbọ́tí náà pé Fáráò máa dá a pa dà sẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀ nínú ààfin. Nígbà tí Jósẹ́fù sọ ìtumọ̀ àlá yìí, òun náà kúkú wá fi àǹfààní yẹn ṣàlàyé ohun tó sọ ọ́ dèrò ẹ̀wọ̀n fún agbọ́tí náà. Àwa náà lè kẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì látinú ohun tí Jósẹ́fù sọ àtohun tí kò sọ.​—Jẹ́n. 40:​5-13.

12, 13. (a) Báwo ni ọ̀rọ̀ tí Jósẹ́fù sọ fún agbọ́tí náà ṣe fi hàn pé kò kàn gba kámú sí ìwà àìdáa tí wọ́n hù sí i? (b) Kí ni Jósẹ́fù kò sọ fún agbọ́tí náà?

12 Ka Jẹ́nẹ́sísì 40:​14, 15Ẹ máa kíyè sí pé Jósẹ́fù sọ pé wọ́n jí òun gbé. Ó ṣe kedere pé ìwà àìdáa gbáà nìyẹn. Jósẹ́fù tún ṣàlàyé pé òun kò ṣe ohun tí wọ́n tìtorí rẹ̀ sọ òun sẹ́wọ̀n. Ó wá sọ fún agbọ́tí náà pé kó sọ nípa òun fún Fáráò. Kí nìdí? Ìdí ni pé ó fẹ́ kó “mú [òun] jáde kúrò” lẹ́wọ̀n.

13 Ǹjẹ́ Jósẹ́fù sọ̀rọ̀ bí ẹni tó ti gba kámú pé kò sí nǹkan tóun lè ṣe sọ́rọ̀ náà? Rárá o. Òun fúnra rẹ̀ mọ̀ dáadáa pé àwọn èèyàn ti ṣe ọ̀pọ̀ àìdáa sóun. Ó ṣàlàyé bọ́rọ̀ ṣe jẹ́ gan-an fún agbọ́tí náà, torí ó mọ̀ pé agbọ́tí náà máa tó wà nípò tó fi lè ran òun lọ́wọ́. Àmọ́ ẹ kíyè sí pé kò síbì kankan tí Bíbélì ti sọ pé Jósẹ́fù sọ fún ẹnikẹ́ni títí kan Fáráò pé àwọn ẹ̀gbọ́n òun ló jí òun gbé. Kódà nígbà tí Jósẹ́fù àtàwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ parí ọ̀rọ̀ wọn ní Íjíbítì, Fáráò gbà wọ́n tọwọ́tẹsẹ̀. Ó tiẹ̀ tún sọ fún wọn pé kí wọ́n wá máa gbé ní Íjíbítì, kí wọ́n sì gbádùn “ohun rere gbogbo ilẹ̀” náà.​—Jẹ́n. 45:​16-20.

Tá a bá ń tan ọ̀rọ̀ kan kálẹ̀, ṣe la máa dá kún ìṣòro tó wà nílẹ̀ (Wo ìpínrọ̀ 14)

14. Tí wọ́n bá tiẹ̀ ṣàìdáa sí wa nínú ìjọ, kí ni kò ní jẹ́ ká máa sọ̀rọ̀ náà kiri?

14 Tí Kristẹni kan bá rò pé ẹnì kan ti hùwà àìdáa sóun, ó yẹ kó ṣọ́ra kó má lọ máa sọ̀rọ̀ náà kiri. A lè lọ bá àwọn alàgbà fún ìrànlọ́wọ́ tá a bá níṣòro, ó sì tún yẹ ká sọ fún wọn tẹ́nì kan nínú ìjọ bá hùwà àìtọ́ tó burú jáì. (Léf. 5:1) Síbẹ̀, tó bá jẹ́ pé ohun tó ṣẹlẹ̀ kì í ṣe ìwà àìtọ́ tó burú jáì, a lè yanjú ọ̀rọ̀ náà láìpe ẹnikẹ́ni sí i títí kan àwọn alàgbà. (Ka Mátíù 5:​23, 24; 18:15.) Tá a bá fẹ́ jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà, ìlànà Bíbélì ló yẹ ká fi yanjú irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀. Láwọn ìgbà míì, a lè wá rí i pé eni náà ò tiẹ̀ ṣàìdáa sí wa. Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ wo bí inú wa ṣe máa dùn tó pé a ò ba ẹni yẹn jẹ́ lójú àwọn míì! Ẹ rántí pé, yálà wọ́n hùwà àìdáa sí wa tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, tá a bá ń sọ̀rọ̀ náà kiri, ìyẹn ò ní yanjú ìṣòro náà. Tá a bá jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà, tá a sì nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin wa, a ò ní ṣe irú àṣìṣe bẹ́ẹ̀. Nígbà tí onísáàmù náà ń sọ̀rọ̀ nípa “ẹni tí ń rìn láìlálèébù,” ó sọ pé, “kò lo ahọ́n rẹ̀ ní fífọ̀rọ̀ èké bani jẹ́, kò ṣe ohun búburú kankan sí alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀, kò sì sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí ojúlùmọ̀ rẹ̀ tímọ́tímọ́.”​—Sm. 15:​2, 3; Ják. 3:5.

MÁA RÁNTÍ ÀJỌṢE TÓ O NÍ PẸ̀LÚ JÈHÓFÀ

15. Ìbùkún wo ni Jósẹ́fù rí torí pé kò fi Jèhófà sílẹ̀?

15 Àjọṣe tí Jósẹ́fù ní pẹ̀lú Jèhófà tún kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì kan. Jósẹ́fù fi hàn pé ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan lòun náà fi ń wò ó ní gbogbo ọdún mẹ́tàlá tó fi jìyà. (Jẹ́n. 45:​5-8) Kò fìgbà kan dá Jèhófà lẹ́bi fún ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò gbàgbé àìdáa táwọn èèyàn ṣe sí i, kò bẹ̀rẹ̀ sí í fapá jánú. Ní pàtàkì jù, kò jẹ́ kí àìpé àti àṣìṣe àwọn míì mú kó fi Jèhófà sílẹ̀. Bí Jósẹ́fù ṣe jẹ́ adúróṣinṣin jẹ́ kó rí ọwọ́ Jèhófà nínú ọ̀rọ̀ náà. Jèhófà dá a láre, ó sì bù kún òun àti ìdílé rẹ̀.

16. Kí nìdí tó fi yẹ ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà tí wọ́n bá ṣàìdáa sí wa nínú ìjọ?

16 Lọ́nà kan náà, àwa náà gbọ́dọ̀ fọwọ́ pàtàkì mú àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà. Torí pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí àìpé àwọn ará wa mú ká fi í sílẹ̀. (Róòmù 8:​38, 39) Kàkà bẹ́ẹ̀, tẹ́nì kan bá ṣàìdáa sí wa nínú ìjọ, ẹ jẹ́ ká ṣe bíi Jósẹ́fù, ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, ká sì fojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan wò ó. Tá a bá ti ṣe ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ láti yanjú ọ̀rọ̀ náà, ó yẹ ká fọ̀rọ̀ náà lé Jèhófà lọ́wọ́. Ká mọ̀ dájú pé tó bá tásìkò lójú rẹ̀, ó máa yanjú ọ̀rọ̀ náà bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ.

GBẸ́KẸ̀ LÉ “ONÍDÀÁJỌ́ GBOGBO ILẸ̀ AYÉ”

17. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a gbẹ́kẹ̀ lé “Onídàájọ́ gbogbo ilẹ̀ ayé”?

17 A mọ̀ pé kò sí káwọn èèyàn má ṣàìdáa sí wa nínú ayé burúkú yìí. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ó ṣeé ṣe kẹ́nì kan ṣàìdáa sí ẹ nínú ìjọ tàbí sí ẹnì kan tó o mọ̀, ó sì lè jẹ́ pé ṣe lo kàn rò bẹ́ẹ̀. Tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, má ṣe jẹ́ kíyẹn mú ẹ kọsẹ̀. (Sm. 119:165) Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ká jẹ́ adúróṣinṣin sí i, ká sì bẹ̀ ẹ́ pé kó ràn wá lọ́wọ́. Bákan náà, ó yẹ ká rántí pé a lè má mọ bọ́rọ̀ náà ṣe jẹ́ gan-an. Ká máa fi sọ́kàn pé ó lè jẹ́ ojú táwa náà fi ń wo ọ̀rọ̀ náà ni kò tọ́. Bá a ṣe rí i nínú àpẹẹrẹ Jósẹ́fù, a ò gbọ́dọ̀ máa sọ ọ̀rọ̀ náà kiri, tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe la kàn máa dá kún ìṣòro tó wà nílẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, dípò ká máa wá bá a ṣe máa gbèjà ara wa, ẹ jẹ́ ká jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà, ká sì ní sùúrù títí dìgbà tí Jèhófà máa yanjú ọ̀rọ̀ náà. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, inú Jèhófà máa dùn sí wa, á sì bù kún wa bó ṣe bù kún Jósẹ́fù. Ẹ jẹ́ kó dá wa lójú pé gbogbo ìgbà ni Jèhófà, ‘Onídàájọ́ ilẹ̀ ayé,’ máa ń ṣe ohun tó tọ́, “nítorí gbogbo ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ ìdájọ́ òdodo.”​—Jẹ́n. 18:25; Diu. 32:4.

18. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?

18 Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa gbé àpẹẹrẹ méjì míì yẹ̀ wò nípa ìwà àìdáa táwọn kan hù láàárín àwọn èèyàn Jèhófà láyé àtijọ́. Àwọn àpẹẹrẹ náà máa jẹ́ ká rí i pé ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ìdáríjì ṣe pàtàkì táwa náà bá fẹ́ ní èrò tí Jèhófà ní nípa ìdájọ́ òdodo.

^ ìpínrọ̀ 7 Wo ìtàn ìgbésí ayé Willi Diehl nínú Ilé-Ìṣọ́nà ti November 1, 1991, a pe àkòrí rẹ̀ ní, “Jehofa ni Ọlọrun Mi, Ninu Ẹni Ti Emi Yoo Nigbẹkẹle.