Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Nínú Bíbélì Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tá a mú jáde lédè Gẹ̀ẹ́sì lọ́dún 2013, a ṣe àtúnṣe sí Sáàmù 144:12-15. Nínú Bíbélì ti tẹ́lẹ̀, àwọn èèyàn búburú tí ẹsẹ kọkànlá mẹ́nu kàn ni ẹsẹ kejìlá sí kẹẹ̀ẹ́dógún ń tọ́ka sí. Àmọ́, nínú Bíbélì tá a mú jáde lọ́dún 2013, àwọn èèyàn Jèhófà làwọn ẹsẹ yẹn tọ́ka sí. Kí nìdí tá a fi ṣàtúnṣe yìí?
Ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n lò nínú ẹsẹ yẹn lè tọ́ka sí àwọn ẹni burúkú tàbí àwọn èèyàn Jèhófà. Torí náà, ẹ jẹ́ ká jíròrò àwọn ìdí tá a fi gbà pé àwọn èèyàn Jèhófà ni àwọn ẹsẹ yẹn ń tọ́ka sí:
Ọ̀rọ̀ tá a lò báyìí mú kí ìtumọ̀ yẹn ṣe kedere. Ọ̀rọ̀ Hébérù àkọ́kọ́ tó wà nínú ẹsẹ kejìlá, ìyẹn asher ló jẹ́ ká mọ bí Sáàmù 144:12-15 ṣe tan mọ́ àwọn ẹsẹ tó ṣáájú. Oríṣiríṣi ọ̀nà la lè gbà tú asher. Bí àpẹẹrẹ, ó lè túmọ̀ sí ọ̀rọ̀ arọ́pò orúkọ bí “àwọn,” ohun tá a sì lò nìyẹn nínú Bíbélì ti tẹ́lẹ̀. Ìyẹn wá mú kó dà bíi pé àwọn ẹni burúkú táwọn ẹsẹ tó ṣáájú mẹ́nu bà ló máa gbádùn àwọn ìbùkún tó wà nínú ẹsẹ kejìlá sí kẹrìnlá. Àmọ́ láwọn ìgbà míì, asher lè túmọ̀ sí ohun tó máa tẹ̀yìn nǹkan yọ bíi “nígbà náà.” Torí náà, “nígbà náà” ló wà nínú Bíbélì Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tá a mú jáde lédè Gẹ̀ẹ́sì lọ́dún 2013 àti nínú àwọn ìtumọ̀ Bíbélì míì.
Àtúnṣe tá a ṣe sí ẹsẹ yìí bá àwọn ẹsẹ yòókù tó wà nínú Sáàmù yẹn mu. Ọ̀rọ̀ náà “nígbà náà” tá a lò nínú ẹsẹ kejìlá túmọ̀ sí pé àwọn olódodo ló máa gbádùn àwọn ìbùkún tó wà nínú ẹsẹ kejìlá sí kẹrìnlá. Ìyẹn àwọn tó ní kí Ọlọ́run ‘dá àwọn sílẹ̀ lómìnira, kí ó sì dá wọn nídè’ lọ́wọ́ àwọn ẹni ibi bó ṣe wà ní ẹsẹ kọkànlá. Bákan náà lọ̀rọ̀ rí tá a bá wo ẹsẹ kẹẹ̀ẹ́dógún níbi tí ọ̀rọ̀ náà “aláyọ̀” ti fara hàn lẹ́ẹ̀mejì, “àwọn ènìyàn tí Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run wọn” náà ló ń tọ́ka sí. Ẹ má sì gbàgbé pé èdè Hébérù ìpilẹ̀ṣẹ̀ ò ní àmì ìpín gbólóhùn bí àmì àyọlọ̀ (“ ” tàbí ‘ ‘). Torí náà, àwọn atúmọ̀ èdè máa ní láti wo àyíká ọ̀rọ̀ kí wọ́n tó lè mọ ohun tí àwọn ẹsẹ kan ń sọ gan-an.
Àtúnṣe tá a ṣe sí ọ̀rọ̀ yẹn mú kí àwọn ẹsẹ yẹn bá àwọn apá míì nínú Bíbélì mu, níbi tí Ọlọ́run ti ṣèlérí pé òun máa bù kún àwọn tó bá jẹ́ olóòótọ́. Àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú sáàmù yẹn jẹ́ ká rí ìrètí tí Dáfídì ní pé, lẹ́yìn tí Ọlọ́run bá dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nídè kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn, wọ́n máa láyọ̀, wọ́n á sì rí ọ̀pọ̀ ìbùkún gbà. (Léf. 26:9, 10; Diu. 7:13; Sm. 128:1-6) Bí àpẹẹrẹ, Diutarónómì 28:4 sọ pé: “Ìbùkún ni fún èso ikùn rẹ àti èso ilẹ̀ rẹ àti èso ẹranko agbéléjẹ̀ rẹ, ọmọ ẹran ọ̀sìn rẹ àti àtọmọdọ́mọ agbo ẹran rẹ.” Abájọ tó fi jẹ́ pé nígbà ìṣàkóso Sólómọ́nì ọmọ Dáfídì, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà ní àlàáfíà, wọ́n sì rí ọ̀pọ̀ ìbùkún. Bákan náà, àlàáfíà táwọn èèyàn Ọlọ́run gbádùn nígbà ìṣàkóso Sólómọ́nì tún ń ṣàpẹẹrẹ bí àlàáfíà ṣe máa gbilẹ̀ nígbà ìṣàkóso Mèsáyà.—1 Ọba 4:20, 21; Sm. 72:1-20.
Ní paríparí ẹ̀, àtúnṣe tá a ṣe sí Sáàmù 144 kò yí òye tá a ní nípa àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì pa dà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló túbọ̀ tànmọ́lẹ̀ sí ìrètí táwa èèyàn Jèhófà ti ń fojú sọ́nà fún tipẹ́tipẹ́, pé láìpẹ́ Jèhófà máa pa àwọn ẹni ibi run, á sì mú káwọn olódodo gbádùn àlàáfíà àti ọ̀pọ̀ ìbùkún nínú ayé tuntun.—Sm. 37:10, 11.