Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀yin Arákùnrin Tá A Yàn Sípò​—Ẹ Kẹ́kọ̀ọ́ Lára Tímótì

Ẹ̀yin Arákùnrin Tá A Yàn Sípò​—Ẹ Kẹ́kọ̀ọ́ Lára Tímótì

LỌ́DÚN tó kọjá, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn arákùnrin ló di alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ nínú ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé. Tíwọ náà bá wà lára àwọn arákùnrin yìí, ó dájú pé inú rẹ máa dùn gan-an torí àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tuntun tó o ní yìí.

Àmọ́ ká sòótọ́, àǹfààní yìí lè kọ́kọ́ kà ẹ́ láyà. Bí àpẹẹrẹ, Jason ìyẹn alàgbà kan tó jẹ́ ọ̀dọ́ sọ pé, “Nígbà tí wọ́n yàn mí sípò, ṣe ló ń ṣe mí bíi pé mi ò ní lè ṣe é.” Bọ́rọ̀ ṣe rí fún Mósè àti Jeremáyà náà nìyẹn, wọ́n rò pé àwọn ò tóótun fún iṣẹ́ tí Jèhófà gbé fún wọn. (Ẹ́kís. 4:10; Jer. 1:6) Tó bá ń ṣe ìwọ náà bẹ́ẹ̀, báwo lo ṣe lè borí èrò yìí kó o lè tẹ̀ síwájú lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ? Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Kristẹni kan nígbà àtijọ́ tó ń jẹ́ Tímótì.​—Ìṣe 16:​1-3.

TẸ̀ LÉ ÀPẸẸRẸ TÍMÓTÌ

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Tímótì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ọmọ ogún ọdún tàbí kó ṣẹ̀ṣẹ̀ lé díẹ̀ lọ́mọ ogún ọdún nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé kó jẹ́ káwọn jọ máa ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì. Torí pé ọ̀dọ́ ni Tímótì nígbà yẹn, ó lè kọ́kọ́ rò pé òun ò tóótun fún iṣẹ́ náà tàbí kó tiẹ̀ máa lọ́ tìkọ̀. (1 Tím. 4:​11, 12; 2 Tím. 1:​1, 2, 7) Àmọ́ ọdún mẹ́wàá lẹ́yìn náà, Pọ́ọ̀lù sọ fún ìjọ tó wà ní Fílípì pé: “Mo ní ìrètí nínú Jésù Olúwa láti rán Tímótì sí yín láìpẹ́ . . . Nítorí èmi kò ní ẹlòmíràn tí ó ní ìtẹ̀sí-ọkàn bí tirẹ̀.”​—Fílí. 2:​19, 20.

Kí ló mú kí Tímótì jẹ́ alàgbà tó mọ iṣẹ́ rẹ̀ dunjú? Ẹ jẹ́ ká wo nǹkan mẹ́fà tá a lè kọ́ lára rẹ̀.

1. Ó nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn dénú. Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn ará ní Fílípì pé: “[Tímótì] yóò fi òótọ́ inú bójú tó àwọn ohun tí ó jẹmọ́ yín.” (Fílí. 2:20) Tímótì nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn dénú. Ọ̀rọ̀ wọn nípa tẹ̀mí jẹ ẹ́ lọ́kàn gan-an, ó sì ṣe tán láti fi ara rẹ̀ jìn fún wọn.

Kò yẹ ká dà bí awakọ̀ bọ́ọ̀sì kan, tó jẹ́ pé bó ṣe máa dé ibi tó ń lọ ló jẹ ẹ́ lógún dípò kó dúró gbé èrò. Bí àpẹẹrẹ, alàgbà tó mọṣẹ́ rẹ̀ dunjú ni Arákùnrin William, ó sì ti lé lógún ọdún tó ti jẹ́ alàgbà. Arákùnrin yìí wá gba àwọn tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn sípò nímọ̀ràn pé: “Ẹ nífẹ̀ẹ́ àwọn ará. Ohun táwọn ará nílò ló yẹ kó jẹ yín lọ́kàn ju àwọn ojúṣe míì tẹ́ ẹ̀ ń ṣe nínú ìjọ lọ.”

2. Àwọn nǹkan tẹ̀mí ló gbà á lọ́kàn. Pọ́ọ̀lù sọ ohun tó fi hàn pé Tímótì yàtọ̀ sáwọn míì, ó ní: “Gbogbo àwọn yòókù ń wá ire ara wọn, kì í ṣe ti Kristi Jésù.” (Fílí. 2:21) Ìlú Róòmù ni Pọ́ọ̀lù wà nígbà tó kọ lẹ́tà yìí. Ó kíyè sí i pé àwọn arákùnrin tó wà níbẹ̀ ò fi bẹ́ẹ̀ ráyè fáwọn nǹkan tẹ̀mí, iṣẹ́ tara wọn ni wọ́n gbájú mọ́, wọn ò sì fi taratara lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù. Àmọ́ ọ̀rọ̀ Tímótì ò rí bẹ́ẹ̀, nígbàkigbà tí àǹfààní bá yọ láti wàásù ìhìn rere, ṣe ló máa ń ṣe bíi ti Aísáyà tó sọ pé: “Èmi nìyí! Rán mi.”​—Aísá. 6:8.

Kí lo lè ṣe táwọn nǹkan míì ò fi ní dí àwọn nǹkan tẹ̀mí lọ́wọ́? Lákọ̀ọ́kọ́, mọ ohun tó yẹ kó gbawájú láyé rẹ. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Máa wádìí dájú àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù.” (Fílí. 1:10) Àwọn nǹkan tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu ni kó o jẹ́ kó ṣe pàtàkì jù sí ẹ. Ìkejì, má fàkókò àti okun ẹ ṣòfò lórí àwọn nǹkan tí kò pọn dandan. Pọ́ọ̀lù gba Tímótì níyànjú pé: “Sá fún àwọn ìfẹ́-ọkàn tí ó máa ń bá ìgbà èwe rìn, ṣùgbọ́n máa lépa òdodo, ìgbàgbọ́, ìfẹ́ [àti] àlàáfíà.”​—2 Tím. 2:22.

3. Ó ṣiṣẹ́ kára lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Pọ́ọ̀lù rán àwọn ará Fílípì létí pé: “Ẹ̀yin mọ ẹ̀rí tí [Tímótì] fúnni nípa ara rẹ̀, pé bí ọmọ lọ́dọ̀ baba ni ó sìnrú pẹ̀lú mi fún ìtẹ̀síwájú ìhìn rere.” (Fílí. 2:22) Tímótì kì í ṣe ọ̀lẹ torí pé ó ṣiṣẹ́ kára pẹ̀lú Pọ́ọ̀lù, ìyẹn sì mú káwọn méjèèjì túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ ara wọn.

Iṣẹ́ pọ̀ gan-an nínú ètò Ọlọ́run lónìí, iṣẹ́ náà ò sì lè tán. Iṣẹ́ yìí máa fún ẹ láyọ̀, ó sì máa jẹ́ kó o túbọ̀ sún mọ́ àwọn ará. Torí náà, pinnu pé wàá “máa ní púpọ̀ rẹpẹtẹ láti ṣe nígbà gbogbo nínú iṣẹ́ Olúwa.”​—1 Kọ́r. 15:58.

4. Ó fi àwọn ohun tó kọ́ sílò. Pọ́ọ̀lù sọ fún Tímótì pé: “Ìwọ ti tẹ̀ lé ẹ̀kọ́ mi pẹ́kípẹ́kí, ipa ọ̀nà ìgbésí ayé mi, ète mi, ìgbàgbọ́ mi, ìpamọ́ra mi, ìfẹ́ mi, ìfaradà mi.” (2 Tím. 3:10) Torí pé Tímótì fi àwọn ohun tó kọ́ sílò, ìyẹn mú kó tóótun láti gba àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn míì.​—1 Kọ́r. 4:17.

Ṣé ẹnì kan wà tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀, tó sì wù ẹ́ pé kó o fara wé? Tí kò bá sí, o ò ṣe wá ẹnì kan? Arákùnrin Tom tó ti jẹ́ alàgbà fún ọ̀pọ̀ ọdún rántí bí alàgbà kan ṣe ràn án lọ́wọ́, ó ní: “Alàgbà kan tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú rẹ̀ fà mí mọ́ra, ó sì dá mi lẹ́kọ̀ọ́. Mo sábà máa ń ní kí wọ́n gbà mí nímọ̀ràn, mo sì máa ń fi ìmọ̀ràn náà sílò. Èyí jẹ́ kọ́kàn mi balẹ̀, kí n sì tètè mú iṣẹ́ mi bí iṣẹ́.”

5. Ó túbọ̀ ń dá ara ẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́. Pọ́ọ̀lù sọ fún Tímótì pé: “Máa kọ́ ara rẹ pẹ̀lú fífọkànsin Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ìfojúsùn rẹ.” (1 Tím. 4:7) Bí àpẹẹrẹ, eléré ìdárayá kan lè ní kóòṣì tó ń dá a lẹ́kọ̀ọ́, síbẹ̀ òun fúnra rẹ̀ ṣì gbọ́dọ̀ máa dánra wò. Pọ́ọ̀lù wá gba Tímótì níyànjú pé: “Máa bá a lọ ní fífi ara rẹ fún ìwé kíkà ní gbangba, fún ìgbani-níyànjú, fún kíkọ́ni. . . . Máa fẹ̀sọ̀ ronú lórí nǹkan wọ̀nyí; fi ara rẹ fún wọn pátápátá, kí ìlọsíwájú rẹ lè fara hàn kedere fún gbogbo ènìyàn.”​—1 Tím. 4:​13-15.

Ìwọ náà gbọ́dọ̀ máa dá ara rẹ lẹ́kọ̀ọ́ sí i kó o lè túbọ̀ jáfáfá. Má ṣe dúró sójú kan, máa tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, kó o sì dojúlùmọ̀ àwọn ìlànà tuntun tá à ń rí gbà lóòrèkóòrè. Bákan náà, má ṣe dá ara rẹ lójú jù tàbí kó o máa ronú pé o ti nírìírí débi pé tó ò bá tiẹ̀ ṣe ìwádìí tó jinlẹ̀, kò sọ́rọ̀ tó ò lè yanjú. Bíi ti Tímótì, ìwọ náà gbọ́dọ̀ “máa fiyè sí ara rẹ nígbà gbogbo àti sí ẹ̀kọ́ rẹ.”​—1 Tím. 4:16.

6. Ó gbára lé ẹ̀mí Jèhófà. Pọ́ọ̀lù sọ fún Tímótì pé: “Ohun ìtọ́júpamọ́ àtàtà yìí ni kí o ṣọ́ nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ tí ń gbé inú wa.” (2 Tím. 1:14) Torí náà, kí Tímótì tó lè ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ó ṣe pàtàkì kó gbára lé ẹ̀mí Ọlọ́run.

Arákùnrin Donald tó ti jẹ́ alàgbà fún ọ̀pọ̀ ọdún sọ pé: “Àwọn arákùnrin tá a yàn sípò gbọ́dọ̀ mọyì àjọṣe tí wọ́n ní pẹ̀lú Ọlọ́run. Àwọn tó bá ṣe bẹ́ẹ̀ máa túbọ̀ lókun sí i. Tí wọ́n bá ń gbàdúrà fún ẹ̀mí Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń fi èso tẹ̀mí ṣèwà hù, ìbùkún ńlá ni wọ́n máa jẹ́ fáwọn ará nínú ìjọ.”​—Sm. 84:7; 1 Pét. 4:11.

MỌYÌ ÀǸFÀÀNÍ IṢẸ́ ÌSÌN RẸ

Ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn sípò bíi tìẹ ló ń tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, ìyẹn sì ń múnú wa dùn gan-an. Jason tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ sọ pé: “Ọ̀pọ̀ nǹkan ni mo ti kọ́ látìgbà tí mo ti di alàgbà, ìyẹn sì ti mú kọ́kàn mi balẹ̀. Ní báyìí, mo gbà pé àǹfààní ńlá ni mo ní, mo sì ń gbádùn rẹ̀ gan-an.”

Ṣé ìwọ náà á túbọ̀ máa tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí? Sapá láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Tímótì. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìbùkún ńlá nìwọ náà máa jẹ́ fáwọn èèyàn Ọlọ́run.