Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bá A Ṣe Lè Ní Òmìnira Tòótọ́

Bá A Ṣe Lè Ní Òmìnira Tòótọ́

“Bí Ọmọ bá dá yín sílẹ̀ lómìnira, ẹ ó di òmìnira ní ti gidi.”—JÒH. 8:36.

ORIN: 54, 36

1, 2. (a) Kí làwọn èèyàn sábà máa ń ṣe kí wọ́n lè ní òmìnira? (b) Kí ló máa ń jẹ́ àbájáde rẹ̀?

LÓNÌÍ, ọ̀pọ̀ ló ń fẹ́ òmìnira, wọ́n sì fẹ́ kí gbogbo èèyàn wà lọ́gbọọgba. Kárí ayé, ọ̀pọ̀ ló ń wá bí wọ́n á ṣe fòpin sí ipò òṣì, kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà àti ìnilára. Àwọn míì máa ń fẹ́ ní òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ àti òmìnira láti yan ohun tó wù wọ́n. Ká sòótọ́, ọ̀pọ̀ èèyàn kárí ayé ló máa ń fẹ́ ṣe ohun tó wù wọ́n, kí wọ́n sì gbé ìgbésí ayé bí wọ́n ṣe fẹ́.

2 Onírúurú ọ̀nà làwọn èèyàn máa ń gbà wá òmìnira yìí. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan máa ń wọ́de kiri láti jà fún ẹ̀tọ́ wọn, àwọn míì sì máa ń jìjàgbara tàbí kí wọ́n dá rògbòdìyàn sílẹ̀ kí wọ́n lè rí ohun tí wọ́n fẹ́. Àmọ́ ṣé àwọn nǹkan yìí máa ń jẹ́ kọ́wọ́ àwọn èèyàn tẹ òmìnira tí wọ́n ń wá? Rárá o, lọ́pọ̀ ìgbà ṣe ni nǹkan túbọ̀ máa ń nira sí i, ọ̀pọ̀ ẹ̀mí ló sì máa ń ṣòfò. Èyí jẹ́ ká rí i pé òótọ́ pọ́ńbélé ni ọ̀rọ̀ tí Ọba Sólómọ́nì sọ, pé: “Ènìyàn ti jọba lórí ènìyàn sí ìṣeléṣe rẹ̀.”​—Oníw. 8:9.

3. Tá a bá fẹ́ láyọ̀, kọ́kàn wa sì balẹ̀, kí ló yẹ ká ṣe?

3 Ọmọ ẹ̀yìn náà Jákọ́bù sọ ohun tó máa jẹ́ ká ní ayọ̀ tòótọ́, kọ́kàn wa sì balẹ̀. Ó ní: “Ẹni tí ó bá ń wo inú òfin pípé tí í ṣe ti òmìnira ní àwòfín, tí ó sì tẹpẹlẹ mọ́ ọn . . . yóò láyọ̀ nínú ṣíṣe é.” (Ják. 1:25) Jèhófà tó fún wa ní òfin pípé yẹn mọ ohun tó máa jẹ́ ká láyọ̀, ká sì ní ìbàlẹ̀ ọkàn. Ó fún àwọn òbí wa àkọ́kọ́ ní gbogbo nǹkan tó máa jẹ́ kí wọ́n láyọ̀, lára ẹ̀ ni pé wọ́n ní òmìnira tòótọ́.

ÌGBÀ TÍ ÁDÁMÙ ÀTI ÉFÀ NÍ ÒMÌNIRA TÒÓTỌ́

4. Òmìnira wo ni Ádámù àti Éfà gbádùn? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

4 Tá a bá ka orí méjì àkọ́kọ́ nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì, a máa rí i pé Ádámù àti Éfà gbádùn òmìnira táwa ò ní lónìí. Bí àpẹẹrẹ, gbogbo nǹkan tí wọ́n fẹ́ ni wọ́n ní, kò sóhun tó ń kó wọn láyà sókè, kò sì sẹ́ni tó ń ni wọ́n lára. Wọn kì í ṣàníyàn rárá nípa oúnjẹ tàbí iṣẹ́ tí wọ́n á ṣe, wọn ò ṣàìsàn, wọn ò sì bẹ̀rù pé àwọn máa kú. (Jẹ́n. 1:​27-29; 2:​8, 9, 15) Àmọ́ ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé Ádámù àti Éfà lè ṣe bó ṣe wù wọ́n láìsí pé Ọlọ́run ń yẹ̀ wọ́n lọ́wọ́ wò? Ẹ jẹ́ ká gbé ọ̀rọ̀ náà yẹ̀ wò.

5. Kí lọ̀pọ̀ rò nípa òmìnira, kí ló pọn dandan kó wà káwọn èèyàn tó lè gbádùn òmìnira tí wọ́n ní?

5 Ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí rò pé, ó dìgbà táwọn bá lè ṣe ohunkóhun tó wù wọ́n láìka ohun tó máa tẹ̀yìn ẹ̀ yọ káwọn tó ní òmìnira tòótọ́. Ìwé The World Book Encyclopedia sọ pé, òmìnira túmọ̀ sí pé “kéèyàn yan ohun tó bá fẹ́, kó sì ṣe ohun tó yàn.” Síbẹ̀, ó fi kún un pé: “Tá a bá fojú ọ̀rọ̀ òfin wò ó, àwọn èèyàn máa lómìnira tó bá jẹ́ pé òfin tó pọn dandan, tó bọ́gbọ́n mu, tí kò sì le jù ló ń darí àwọn èèyàn.” Èyí jẹ́ ká rí i pé táwọn èèyàn bá máa gbádùn òmìnira tí wọ́n ní, ó pọn dandan káwọn òfin kan wà tí wọ́n á máa tẹ̀ lé. Àmọ́ ìbéèrè náà ni pé, Ta ló lẹ́tọ̀ọ́ láti gbé òfin àti ìlànà tó pọn dandan kalẹ̀?

6. (a) Kí nìdí tó fi jẹ́ pé Jèhófà nìkan ló lè ṣe ohunkóhun tó wù ú láìsí pé ẹnikẹ́ni ń yẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́ wò? (b) Irú òmìnira wo làwa èèyàn ní, kí sì nìdí?

6 Tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa òmìnira, ó yẹ ká fi sọ́kàn pé Jèhófà nìkan ló lè ṣe ohunkóhun tó wù ú láìsí pé ẹnikẹ́ni ń yẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́ wò. Ìdí ni pé òun ló dá ohun gbogbo, òun sì ni Ọba Aláṣẹ láyé àtọ̀run. (1 Tím. 1:17; Ìṣí. 4:11) Ọba Dáfídì tiẹ̀ ṣàlàyé bí ipò tí Jèhófà wà ṣe ga tó. (Ka 1 Kíróníkà 29:​11, 12.) Àmọ́ gbogbo àwa èèyàn títí kan àwọn áńgẹ́lì tó wà lọ́run ló níbi tí òmìnira wa mọ. Gbogbo wa gbọ́dọ̀ gbà pé Jèhófà lẹ́tọ̀ọ́, ó sì láṣẹ láti fún wa láwọn òfin àti ìlànà tó yẹ ká máa tẹ̀ lé. Ohun tí Jèhófà sì ṣe gẹ́lẹ́ nìyẹn nígbà tó dá àwọn òbí wa àkọ́kọ́.

7. Àwọn nǹkan wo là ń ṣe tó máa ń fún wa láyọ̀?

7 Lóòótọ́ Ádámù àti Éfà lómìnira, síbẹ̀ ó níbi tí òmìnira wọn mọ. Bí Ọlọ́run ṣe dá wọn jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé àwọn nǹkan kan wà táwọn gbọ́dọ̀ máa ṣe. Bí àpẹẹrẹ, àwọn òbí wa àkọ́kọ́ mọ̀ pé táwọn bá máa wà láàyè àwọn gbọ́dọ̀ máa mí, káwọn máa jẹun, káwọn máa sùn, káwọn sì máa ṣe àwọn nǹkan míì. Àmọ́ ṣé wọ́n á ka àwọn nǹkan yẹn sí ìnira? Rárá o, torí Jèhófà ti dá wọn lọ́nà táá mú kí wọ́n gbádùn àwọn nǹkan yẹn. (Sm. 104:​14, 15; Oníw. 3:​12, 13) Ìwọ ńkọ́? Báwo ló ṣe máa ń rí lára rẹ tó o bá ń gba atẹ́gùn tútù sára, tó ò ń jẹ oúnjẹ aládùn tàbí tó o sùn dáadáa? Àwọn nǹkan yìí pọn dandan lóòótọ́, síbẹ̀ a máa ń gbádùn wọn, wọn ò sì ni wá lára. Ó dájú pé bó ṣe rí fún Ádámù àti Éfà náà nìyẹn.

8. Àṣẹ wo ni Ọlọ́run pa fún àwọn òbí wa àkọ́kọ́, kí sì nìdí?

8 Jèhófà dìídì pàṣẹ fún Ádámù àti Éfà pé kí wọ́n fi àwọn ọmọ wọn kún ayé kí wọ́n sì máa bójú tó ilẹ̀ ayé. (Jẹ́n. 1:28) Ṣé àṣẹ yìí ká wọn lọ́wọ́ kò ni? Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Ìdí tí Ọlọ́run fi pàṣẹ yìí ni pé ó fẹ́ káwa èèyàn náà lọ́wọ́ nínú mímú ohun tó ní lọ́kàn fáráyé ṣẹ, ìyẹn sì ni pé kí ilẹ̀ ayé di Párádísè níbi tí àwọn èèyàn pípé á máa gbé títí láé. (Aísá. 45:18) Lónìí, àwọn kan lè pinnu pé àwọn ò ní ṣègbéyàwó, àwọn tọkọtaya kan sì lè pinnu pé àwọn ò ní bímọ, gbogbo ìyẹn ò sì lòdì sí ìfẹ́ Ọlọ́run. Síbẹ̀, àwọn èèyàn ń ṣègbéyàwó wọ́n sì ń bímọ láìka àwọn nǹkan tí wọ́n máa kojú sí. (1 Kọ́r. 7:​36-38) Kí nìdí tí wọ́n fi ń ṣe bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé tí kì í bá ṣe bí nǹkan ṣe rí ni, ayọ̀ wà nínú kéèyàn ṣègbéyàwó kó sì bímọ. (Sm. 127:3) Èyí fi hàn pé títí láé ni Ádámù àti Éfà ì bá fi máa gbádùn ìgbéyàwó wọn.

BÍ ARÁYÉ ṢE PÀDÁNÙ ÒMÌNIRA TÒÓTỌ́

9. Báwo la ṣe mọ̀ pé àṣẹ tó wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 2:17 pọn dandan, ó bọ́gbọ́n mu, kò sì le jù?

9 Jèhófà tún pàṣẹ míì fún Ádámù àti Éfà, ó sì jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tó máa tẹ̀yìn ẹ̀ yọ tí wọn ò bá pa àṣẹ náà mọ́. Ó sọ pé: “Ní ti igi ìmọ̀ rere àti búburú, ìwọ kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú rẹ̀, nítorí ọjọ́ tí ìwọ bá jẹ nínú rẹ̀, dájúdájú, ìwọ yóò kú.” (Jẹ́n. 2:17) Ṣé a lè sọ pé àṣẹ yìí kò pọn dandan, kò bọ́gbọ́n mu tàbí pé ó le jù? Ṣé ìyẹn ní kí Ádámù àti Éfà má ní òmìnira? Rárá, kò rí bẹ́ẹ̀. Kódà, àwọn ọ̀mọ̀wé Bíbélì kan sọ̀rọ̀ nípa bí àṣẹ yẹn ṣe bọ́gbọ́n mu tó. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀mọ̀wé kan sọ pé: ‘Ohun tí Jẹ́nẹ́sísì 2:​16, 17 sọ jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run nìkan ló mọ ohun rere, ìyẹn ohun tó dáa fáwa èèyàn àtohun tí kò dáa. Táwa èèyàn bá fẹ́ gbádùn àwọn nǹkan ‘rere’ yẹn, a gbọ́dọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run ká sì máa ṣègbọràn sí i. Tá a bá ṣàìgbọràn, á jẹ́ pé àwa fúnra wa là ń pinnu ohun tó dáa àtohun tí kò dáa.’ Ó ṣe kedere pé ìyẹn ju agbára àwa èèyàn lọ torí a ò ní ọgbọ́n láti pinnu ohun tó dáa àtohun tí kò dáa.

Àjálù ni ìpinnu Ádámù àti Éfà yọrí sí (Wo ìpínrọ̀ 9 sí 12)

10. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ìyàtọ̀ wà láàárín kéèyàn lómìnira àti kéèyàn pinnu ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́?

10 Àwọn kan ronú pé àṣẹ tí Jèhófà pa fún Ádámù kò fún un ní òmìnira láti ṣe ohun tó fẹ́. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ò mọ̀ pé ìyàtọ̀ wà láàárín kéèyàn lómìnira àti kéèyàn pinnu ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́. Ádámù àti Éfà ní òmìnira láti pinnu bóyá wọ́n á ṣègbọràn sí Ọlọ́run àbí wọn ò ní ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́, Jèhófà nìkan ló lẹ́tọ̀ọ́ láti pinnu ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́, “igi ìmọ̀ rere àti búburú” tó wà nínú ọgbà Édẹ́nì sì jẹ́ kíyẹn ṣe kedere sí Ádámù àti Éfà. (Jẹ́n. 2:9) Òótọ́ kan ni pé kò sí bá a ṣe gbọ́n tó tá a lè sọ pé gbogbo ìpinnu tá a bá ṣe ló máa yọrí sí rere, ó ṣe tán ó níbi tí òye wa mọ. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé nígbà míì táwọn èèyàn bá ṣèpinnu tí wọ́n tiẹ̀ rò pé ó dáa, ìyà, àjálù àti ìjàǹbá ló máa ń gbẹ̀yìn rẹ̀. (Òwe 14:12) Ìdí sì ni pé ó níbi tágbára àwa èèyàn mọ. Àmọ́, àṣẹ tí Jèhófà pa fún Ádámù àti Éfà jẹ́ kí wọ́n mọ bó ṣe yẹ kí wọ́n lo òmìnira wọn. Lọ́nà wo, kí sì ni tọkọtaya àkọ́kọ́ yìí ṣe?

11, 12. Kí nìdí tí ìpinnu tí Ádámù àti Éfà ṣe fi yọrí sí àjálù? Ṣàpèjúwe.

11 Sátánì ṣèlérí fún Éfà pé: “Ojú yín yóò là, ó sì dájú pé ẹ̀yin yóò dà bí Ọlọ́run, ní mímọ rere àti búburú.” (Jẹ́n. 3:5) Ọ̀rọ̀ yìí wọ Éfà lọ́kàn débi pé kò lè gbé e kúrò lọ́kàn. Bó ṣe di pé àwọn òbí wa àkọ́kọ́ pinnu láti ṣàìgbọràn nìyẹn o. Ṣé ìpinnu tí wọ́n ṣe yìí mú kí wọ́n túbọ̀ ní òmìnira? Rárá. Ibi tí wọ́n fojú sí, ọ̀nà ò gbabẹ̀ torí wọn ò rí òmìnira tí Sátánì sọ pé wọ́n máa rí. Kódà, kò pẹ́ tí wọ́n fi mọ̀ pé téèyàn bá ṣàìgbọràn sí Jèhófà, ó máa kan àgbákò. (Jẹ́n. 3:​16-19) Kò sì yani lẹ́nu torí pé Jèhófà ò fáwa èèyàn láṣẹ láti fúnra wa pinnu ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́.​—Ka Òwe 20:24; Jeremáyà 10:23.

12 A lè ṣàpẹẹrẹ rẹ̀ lọ́nà yìí. Kí ọkọ̀ òfuurufú kan tó lè dé ibi tó ń lọ, ó níbi tó gbọ́dọ̀ gbà. Kíyẹn lè ṣeé ṣe, àwọn ẹ̀rọ kan wà nínú ọkọ̀ òfuurufú tó ń jẹ́ kí awakọ̀ lè máa bá àwọn tó wà nílẹ̀ sọ̀rọ̀, àwọn yẹn ló sì máa ń tọ́ awakọ̀ sọ́nà. Àmọ́ tí awakọ̀ náà bá kọtí ikún sí ìtọ́sọ́nà tí wọ́n ń fún un tó sì gba ibi tó wù ú, ó ṣeé ṣe kó kàgbákò. Bíi ti awakọ̀ òfuurufú yẹn, Ádámù àti Éfà kọ ìtọ́ni tí Jèhófà fún wọn, wọ́n sì yàn láti ṣe tinú wọn. Kí nìyẹn wá yọrí sí? Wọ́n kàgbákò ní ti pé wọ́n mú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú wá sórí ara wọn àtàwọn àtọmọdọ́mọ wọn. (Róòmù 5:12) Torí pé wọ́n kọ Jèhófà sílẹ̀, tí wọ́n sì yàn láti ṣe tinú wọn, wọ́n pàdánù òmìnira tòótọ́ tí Jèhófà fún wọn.

BÁ A ṢE LÈ NÍ ÒMÌNIRA TÒÓTỌ́

13, 14. Báwo la ṣe lè ní òmìnira tòótọ́?

13 Àwọn kan lè ronú pé á dáa téèyàn bá lè ṣe ohun tó wù ú láìsí ẹni tó ń yẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́ wò. Òótọ́ kan ni pé àǹfààní wà nínú kéèyàn lè ṣe ohun tó wù ú, àmọ́ ewu tún wà níbẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ẹ wo bí ayé ṣe máa rí ká sọ pé kò sí òfin kankan, táwọn èèyàn sì ń ṣe ohun tó wù wọ́n láìsí ẹni tó ń yẹ̀ wọ́n lọ́wọ́ wò. Ìwé The World Book Encyclopedia sọ pé: “Ní ọ̀pọ̀ ìlú, wọ́n máa ń ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ òfin. Àwọn òfin yìí máa ń fún àwọn èèyàn lómìnira, ó sì tún máa ń jẹ́ kí wọ́n mọ bí wọ́n ṣe lè lo òmìnira náà.” Ká sòótọ́, ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ òfin làwọn èèyàn ti ṣe, bẹ́ẹ̀ sì làwọn lọ́yà àtàwọn adájọ́ tí wọ́n ń túmọ̀ òfin pọ̀ jáǹtìrẹrẹ.

14 Àmọ́ o, Jésù Kristi sọ ọ̀nà tá a lè gbà rí òmìnira tòótọ́. Ó ní: “Bí ẹ bá dúró nínú ọ̀rọ̀ mi, ọmọ ẹ̀yìn mi ni ẹ̀yin jẹ́ ní ti tòótọ́, ẹ ó sì mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì dá yín sílẹ̀ lómìnira.” (Jòh. 8:​31, 32) Ohun méjì ni Jésù sọ pé a gbọ́dọ̀ ṣe ká tó lè gbádùn òmìnira tòótọ́: Àkọ́kọ́, a gbọ́dọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ tó fi kọ́ni, ìkejì sì ni pé ká di ọmọlẹ́yìn rẹ̀. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, àá ní òmìnira tòótọ́. Àmọ́ òmìnira kúrò lọ́wọ́ kí ni? Jésù sọ pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ń dá ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ ẹrú ẹ̀ṣẹ̀. . . . Bí Ọmọ bá dá yín sílẹ̀ lómìnira, ẹ ó di òmìnira ní ti gidi.”​—Jòh. 8:​34, 36.

15. Kí nìdí tá a fi gbà pé òmìnira tí Jésù ṣèlérí ló máa jẹ́ ká ní “òmìnira ní ti gidi”?

15 Ó ṣe kedere pé òmìnira tí Jésù ṣèlérí fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ kọjá òmìnira táwọn èèyàn ń jà fún lónìí. Jésù sọ pé: “Bí Ọmọ bá dá yín sílẹ̀ lómìnira, ẹ ó di òmìnira ní ti gidi.” Òmìnira wo ni Jésù ní lọ́kàn? Òmìnira kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ ni. Ìdí sì ni pé ọjọ́ pẹ́ tí ẹ̀ṣẹ̀ ti ń pọ́n aráyé lójú. Ká sòótọ́, àwa èèyàn ti di ẹrú ẹ̀ṣẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ẹ̀ṣẹ̀ ló mú ká máa ṣàṣìṣe, òun sì ni kì í jẹ́ ká ṣe ohun tá a mọ̀ pé ó tọ́. Ìyẹn ló sì fà á tí nǹkan fi ń tojú sú wa, tá à ń jìyà, tá a sì ń kú. (Róòmù 6:23) Bó ṣe rí fún àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà nìyẹn. (Ka Róòmù 7:​21-25.) Ó dìgbà tá a bá bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ ká tó lè gbádùn òmìnira tòótọ́ táwọn òbí wa àkọ́kọ́ gbádùn nígbà yẹn.

16. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe ká tó lè ní òmìnira tòótọ́?

16 Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé “bí ẹ bá dúró nínú ọ̀rọ̀ mi” fi hàn pé àwọn nǹkan kan wà tá a gbọ́dọ̀ ṣe, àwọn nǹkan kan sì wà tá a gbọ́dọ̀ yẹra fún kó tó lè dá wa sílẹ̀ lómìnira. Torí pé ọmọlẹ́yìn Kristi ni wá, a ti sẹ́ ara wa, a sì ti pinnu pé ẹ̀kọ́ Kristi làá jẹ́ kó máa darí wa. (Mát. 16:24) Bí Jésù ti ṣèlérí, a máa ní òmìnira tòótọ́ nígbà tá a bá jàǹfààní ẹbọ ìràpadà Kristi lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́.

17. (a) Kí ló máa jẹ́ káyé wa nítumọ̀, kọ́kàn wa sì balẹ̀? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?

17 Tí àwa Kristẹni bá fẹ́ káyé wa nítumọ̀, a gbọ́dọ̀ máa fi àwọn ohun tí Jésù kọ́ wa sílò. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a máa bọ́ pátápátá lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú lọ́jọ́ iwájú. (Ka Róòmù 8:​1, 2, 20, 21.) Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa jíròrò bá a ṣe lè fi ọgbọ́n lo òmìnira tá a ní báyìí ká lè mú ìyìn àti ògo wá fún Jèhófà Ọlọ́run wa títí láé.