Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 15

Fara Wé Jésù Kó O Lè Ní Ìbàlẹ̀ Ọkàn

Fara Wé Jésù Kó O Lè Ní Ìbàlẹ̀ Ọkàn

“Àlàáfíà Ọlọ́run tó kọjá gbogbo òye yóò sì máa ṣọ́ ọkàn yín.”​—FÍLÍ. 4:7.

ORIN 113 Àlàáfíà Tó Wà Láàárín Wa

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1-2. Kí nìdí tí Jésù fi ní ìdààmú ọkàn?

JÉSÙ ní ìdààmú ọkàn lọ́jọ́ tó lò kẹ́yìn láyé. Ó mọ̀ pé àwọn èèyànkéèyàn máa tó pa òun ní ìpa ìkà. Àmọ́ ìyẹn gangan kọ́ ló ń kó ìdààmú ọkàn bá a. Ó nífẹ̀ẹ́ Baba rẹ̀ gan-an, ó sì fẹ́ ṣe ohun táá múnú rẹ̀ dùn. Jésù mọ̀ pé tóun bá jẹ́ olóòótọ́ títí dójú ikú, òun á dá orúkọ Jèhófà láre. Yàtọ̀ síyẹn, ó nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn, ó sì mọ̀ pé tá a bá máa ní ìyè àìnípẹ̀kun lọ́jọ́ iwájú, àfi kóun jẹ́ olóòótọ́ títí dópin.

2 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdààmú bá Jésù gan-an, síbẹ̀ ó ní àlàáfíà ọkàn. Ó sọ fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé: “Mo fún yín ní àlàáfíà mi.” (Jòh. 14:27) Ó hàn gbangba pé Jésù ní “àlàáfíà Ọlọ́run,” ìyẹn ìbàlẹ̀ ọkàn téèyàn máa ń ní torí pé ó ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run. Àlàáfíà Ọlọ́run yìí ló mú kí ọkàn Jésù balẹ̀.​—Fílí. 4:6, 7.

3. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

3 Kò sí ẹnikẹ́ni nínú wa tó lè nírú àwọn ìṣòro tí Jésù ní, àmọ́ gbogbo wa la máa kojú àdánwò. (Mát. 16:24, 25; Jòh. 15:20) Bíi ti Jésù, àwọn ìgbà kan máa wà tá a máa ní ìdààmú ọkàn. Kí la lè ṣe tí ìdààmú ọkàn yìí ò fi ní bò wá mọ́lẹ̀? Ẹ jẹ́ ká jíròrò mẹ́ta lára ohun tí Jésù ṣe nígbà tó ń ṣiṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ láyé, ká sì wo bá a ṣe lè fara wé e nígbà tá a bá ń kojú ìṣòro.

JÉSÙ MÁA Ń GBÀDÚRÀ

A lè ní ìbàlẹ̀ ọkàn tá a bá ń gbàdúrà (Wo ìpínrọ̀ 4-7)

4. Níbàámu pẹ̀lú 1 Tẹsalóníkà 5:17, sọ àpẹẹrẹ mélòó kan tó fi hàn pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jésù gbàdúrà lọ́jọ́ tó lò kẹ́yìn láyé.

4 Ka 1 Tẹsalóníkà 5:17. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jésù gbàdúrà lọ́jọ́ tó lò kẹ́yìn láyé. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó fi ìrántí ikú rẹ̀ lọ́lẹ̀, ó gbàdúrà sórí búrẹ́dì àti wáìnì tó lò. (1 Kọ́r. 11:23-25) Yàtọ̀ síyẹn, kí òun àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tó kúrò nínú yàrá tí wọ́n ti ṣe Ìrékọjá, ó gbàdúrà pẹ̀lú wọn. (Jòh. 17:1-26) Nígbà tóun àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ dé Òkè Ólífì, ó tún gbàdúrà léraléra. (Mát. 26:36-39, 42, 44) Kódà, àdúrà ni gbólóhùn tó kẹ́yìn tí Jésù sọ lórí òpó igi oró. (Lúùkù 23:46) Ó ṣe kedere pé Jésù gbàdúrà sí Jèhófà nípa gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ yẹn.

5. Kí nìdí táwọn àpọ́sítélì fi sá lọ nígbà tí àdánwò dé?

5 Ohun kan tó mú kí Jésù fara da àwọn àdánwò tó kojú ni pé ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, kò sì dákẹ́ àdúrà. Àmọ́ àwọn àpọ́sítélì ò tẹra mọ́ àdúrà gbígbà lálẹ́ ọjọ́ yẹn. Torí náà, ṣe ni wọ́n sá lọ nígbà tí wọ́n kojú àdánwò. (Mát. 26:40, 41, 43, 45, 56) Táwa náà bá kojú àdánwò, ohun kan ṣoṣo tó lè mú ká borí ni pé ká “máa gbàdúrà nígbà gbogbo” bíi ti Jésù. Àwọn nǹkan wo la lè gbàdúrà fún?

6. Báwo ni ìgbàgbọ́ ṣe lè mú kọ́kàn wa balẹ̀?

6 A lè bẹ Jèhófà pé kó “fún wa ní ìgbàgbọ́ sí i.” (Lúùkù 17:5; Jòh. 14:1) Kò sí àní-àní pé a nílò ìgbàgbọ́ torí pé gbogbo ọmọlẹ́yìn Jésù pátá ni Sátánì máa dán wò. (Lúùkù 22:31) Báwo ni ìgbàgbọ́ ṣe máa jẹ́ kọ́kàn wa balẹ̀ tá a bá tiẹ̀ ń ti inú ìṣòro kan bọ́ sínú òmíì? Tá a bá ti ṣe gbogbo ohun tágbára wa gbé láti yanjú ìṣòro kan, ìgbàgbọ́ tá a ní máa mú ká fọ̀rọ̀ náà sọ́wọ́ Jèhófà. Nípa bẹ́ẹ̀, ọkàn wa máa balẹ̀ torí a mọ̀ pé kò síṣòro tó kọjá agbára Jèhófà.​—1 Pét. 5:6, 7.

7. Kí lo rí kọ́ látinú ohun tí Robert sọ?

7 Láìka àdánwò yòówù ká máa kojú sí, àdúrà máa ń jẹ́ kọ́kàn wa balẹ̀. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ alàgbà kan tó ń jẹ́ Robert tó ti lé lẹ́ni ọgọ́rin (80) ọdún. Ó sọ pé: “Ìmọ̀ràn tó wà nínú Fílípì 4:6, 7 ló mú kí n lè fara da gbogbo ìṣòro tí mo ní. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ìgbà kan wà tí mi ò lówó lọ́wọ́. Ìgbà kan sì wà tí mi ò sí nípò alàgbà mọ́.” Kí ló jẹ́ kọ́kàn Robert balẹ̀ láìka àwọn ìṣòro yìí sí? Ó sọ pé: “Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ tí àníyàn bá ti ń gbà mí lọ́kàn ni mo máa ń gbàdúrà. Mo gbà pé bí mo ṣe ń tẹra mọ́ àdúrà gbígbà, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn mi túbọ̀ ń balẹ̀ sí i.”

JÉSÙ FÌTARA WÀÁSÙ

A lè ní ìbàlẹ̀ ọkàn tá a bá ń wàásù (Wo ìpínrọ̀ 8-10)

8. Bó ṣe wà nínú Jòhánù 8:29, kí nìdí míì tí Jésù fi ní ìbàlẹ̀ ọkàn?

8 Ka Jòhánù 8:29. Jésù ní ìbàlẹ̀ ọkàn láìka inúnibíni tí wọ́n ṣe sí i torí ó mọ̀ pé òun ń múnú Baba òun dùn. Ó jẹ́ onígbọràn kódà nígbà tó ṣòro gan-an láti ṣe bẹ́ẹ̀. Bákan náà, Jésù fi gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀ ṣèfẹ́ Jèhófà torí pé ó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an. Kí Jésù tó wá sáyé, òun ni “àgbà òṣìṣẹ́” fún Ọlọ́run. (Òwe 8:30) Nígbà tó sì wà láyé, ó fìtara wàásù nípa Baba rẹ̀ fáwọn míì. (Mát. 6:9; Jòh. 5:17) Ó dájú pé iṣẹ́ yìí fún Jésù láyọ̀ gan-an.​—Jòh. 4:​34-36.

9. Tá a bá jẹ́ kọ́wọ́ wa dí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, báwo nìyẹn ṣe lè mú kọ́kàn wa balẹ̀?

9 A lè fara wé Jésù tá a bá ń ṣègbọràn sí Jèhófà, tá a sì ń “ní ohun púpọ̀ láti ṣe nínú iṣẹ́ Olúwa nígbà gbogbo.” (1 Kọ́r. 15:58) Tá a bá jẹ́ kí ‘ọwọ́ wa dí gan-an’ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, àwọn ìṣòro wa ò ní gbà wá lọ́kàn ju bó ti yẹ lọ. (Ìṣe 18:5) Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ àwọn tá à ń wàásù fún ló jẹ́ pé ìṣòro wọn ju tiwa lọ. Síbẹ̀, tí wọ́n bá kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí wọ́n ṣe lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tí wọ́n sì ń fi àwọn ìlànà rẹ̀ sílò, ìgbésí ayé wọn máa ń nítumọ̀, wọ́n sì máa ń láyọ̀. Bá a ṣe ń kíyè sí ayọ̀ tí wọ́n ní, bẹ́ẹ̀ ló túbọ̀ ń dá wa lójú pé Jèhófà máa bójú tó wa, èyí á sì mú kọ́kàn wa balẹ̀. Arábìnrin kan tó máa ń ro ara ẹ̀ pin, tó sì máa ń ní ìsoríkọ́ nígbà gbogbo gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí. Ó sọ pé: “Tí mo bá wà lóde ẹ̀rí, ọkàn mi máa ń balẹ̀, inú mi sì máa ń dùn. Ìdí ni pé ìgbà yẹn ni mo sún mọ́ Jèhófà jù lọ.”

10. Kí lo rí kọ́ látinú ohun tí Arábìnrin Brenda sọ?

10 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Arábìnrin Brenda. Òun àti ọmọbìnrin rẹ̀ ní àìsàn multiple sclerosis, ìyẹn àìsàn kan tó ń mú kí iṣan ara le gbagidi. Ó máa ń rẹ Brenda gan-an, kódà kẹ̀kẹ́ arọ ló máa ń lò. Síbẹ̀, ó máa ń wàásù láti ilé dé ilé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà lẹ́tà ló fi máa ń wàásù. Brenda sọ pé: “Lẹ́yìn tí mo ti gba kámú pé àìsàn tó ń ṣe mí ò lè lọ nínú ayé burúkú yìí, ṣe ni mo gbájú mọ́ iṣẹ́ ìwàásù. Iṣẹ́ yìí máa ń jẹ́ kí n gbọ́kàn kúrò lórí ìṣòro mi, ó sì máa ń jẹ́ kí n ronú nípa bí mo ṣe lè ran àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa lọ́wọ́. Yàtọ̀ síyẹn, ó máa ń jẹ́ kí n pọkàn pọ̀ sórí ìrètí ọjọ́ iwájú tí Ọlọ́run ṣèlérí.”

JÉSÙ GBÀ KÁWỌN MÍÌ RAN ÒUN LỌ́WỌ́

A lè ní ìbàlẹ̀ ọkàn tá a bá ń kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ gidi (Wo ìpínrọ̀ 11-15)

11-13. (a) Báwo làwọn àpọ́sítélì ṣe fi hàn pé ọ̀rẹ́ gidi làwọn jẹ́ fún Jésù? (b) Báwo ni ìrànwọ́ tí wọ́n ṣe fún un ṣe rí lára rẹ̀?

11 Nígbà tí Jésù ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, ọ̀rẹ́ gidi làwọn àpọ́sítélì rẹ̀ jẹ́ fún un nígbà dídùn àti nígbà kíkan. Wọ́n jẹ́ ká rí i pé òótọ́ ni òwe Bíbélì tó sọ pé: “Ọ̀rẹ́ kan wà tó ń fà mọ́ni ju ọmọ ìyá lọ.” (Òwe 18:24) Jésù mọyì àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ yìí gan-an. Ó ṣe tán, àwọn àbúrò rẹ̀ ò gbà á gbọ́. (Jòh. 7:3-5) Kódà ìgbà kan wà táwọn mọ̀lẹ́bí Jésù sọ pé orí rẹ̀ ti yí. (Máàkù 3:21) Àmọ́ àwọn àpọ́sítélì ò ronú bẹ́ẹ̀, ìdí nìyẹn tó fi sọ fún wọn lálẹ́ ọjọ́ tó lò kẹ́yìn pé: “Ẹ̀yin lẹ ti dúró tì mí nígbà àdánwò.”​—Lúùkù 22:28.

12 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìgbà kan wà táwọn àpọ́sítélì ṣe ohun tó dun Jésù, síbẹ̀ àwọn nǹkan rere tí wọ́n ṣe ló gbájú mọ́, ó sì mọyì bí wọ́n ṣe nígbàgbọ́ nínú òun. (Mát. 26:40; Máàkù 10:13, 14; Jòh. 6:66-69) Lálẹ́ ọjọ́ tí Jésù lò kẹ́yìn kí wọ́n tó pa á, ó sọ fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ olóòótọ́ pé: “Mo pè yín ní ọ̀rẹ́, torí pé mo ti jẹ́ kí ẹ mọ gbogbo ohun tí mo gbọ́ látọ̀dọ̀ Baba mi.” (Jòh. 15:15) Kò sí àní-àní pé àwọn ọ̀rẹ́ Jésù fún un níṣìírí. Bí wọ́n ṣe ràn án lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ mú kí inú rẹ̀ dùn gan-an.​—Lúùkù 10:17, 21.

13 Yàtọ̀ sáwọn àpọ́sítélì, Jésù tún ní àwọn ọ̀rẹ́ míì lọ́kùnrin àti lóbìnrin tó ràn án lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù àti láwọn ọ̀nà míì. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan máa ń gbà á lálejò kó lè wá jẹun nílé wọn. (Lúùkù 10:38-42; Jòh. 12:1, 2) Àwọn míì máa ń bá a rìnrìn àjò, wọ́n sì máa ń ṣàjọpín ohun tí wọ́n ní pẹ̀lú rẹ̀. (Lúùkù 8:3) Jésù láwọn ọ̀rẹ́ gidi torí pé ọ̀rẹ́ gidi lòun náà jẹ́ sí wọn. Ó máa ń ṣe àwọn nǹkan rere fún wọn, kò sì retí pé kí wọ́n ṣe ju agbára wọn lọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni pípé ni Jésù, síbẹ̀ ó mọyì ìrànwọ́ táwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tó jẹ́ aláìpé ṣe fún un. Ó dájú pé àwọn ọ̀rẹ́ Jésù mú kọ́kàn ẹ̀ balẹ̀.

14-15. Báwo la ṣe lè ní àwọn ọ̀rẹ́ gidi, báwo sì ni wọ́n ṣe lè ràn wá lọ́wọ́?

14 Àwọn ọ̀rẹ́ gidi máa ń mú kó rọrùn fún wa láti jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. Ọ̀nà kan tá a sì lè gbà ní ọ̀rẹ́ gidi ni pé káwa náà jẹ́ ọ̀rẹ́ gidi sáwọn míì. (Mát. 7:12) Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì rọ̀ wá pé ká lo ara wa fáwọn míì, pàápàá jù lọ fáwọn aláìní. (Éfé. 4:28) Ṣé o lè ronú kan ẹnì kan nínú ìjọ rẹ tó o lè ràn lọ́wọ́? Ṣé o lè bá akéde tí kò lè jáde nílé ra àwọn nǹkan tó nílò? Ṣé o lè pèsè oúnjẹ fún ìdílé kan tí kò fi bẹ́ẹ̀ ní lọ́wọ́? Tó o bá mọ bí wọ́n ṣe ń lo ìkànnì jw.org® àti ètò ìṣiṣẹ́ JW Library® ṣé o lè ran àwọn míì nínú ìjọ rẹ lọ́wọ́ káwọn náà lè mọ̀ ọ́n lò? Tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti ran àwọn míì lọ́wọ́, ó dájú pé a máa láyọ̀.​—Ìṣe 20:35.

15 Àwọn ọ̀rẹ́ gidi máa ń dúró tini nígbà ìṣòro, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kọ́kàn wa balẹ̀. Bí Élíhù ṣe fara balẹ̀ tẹ́tí sí Jóòbù nígbà tó ń sọ bí nǹkan ṣe rí lára ẹ̀, àwọn ọ̀rẹ́ gidi máa ń fara balẹ̀ tẹ́tí sí wa nígbà tá a bá ń tú àníyàn wa jáde. (Jóòbù 32:4) Òótọ́ ni pé àwọn ọ̀rẹ́ wa ò lè ṣèpinnu fún wa, síbẹ̀ á dáa ká tẹ́tí sí ìmọ̀ràn Bíbélì tí wọ́n bá fún wa. (Òwe 15:22) Bákan náà, bíi ti Ọba Dáfídì tó gbà káwọn ọ̀rẹ́ òun ran òun lọ́wọ́, ó yẹ káwa náà lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, ká sì tẹ́wọ́ gba ìrànlọ́wọ́ èyíkéyìí táwọn ọ̀rẹ́ wa bá ṣe fún wa. (2 Sám. 17:27-29) Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Jèhófà làwọn ọ̀rẹ́ gidi jẹ́.​—Jém. 1:17.

BÁ A ṢE LÈ NÍ ÀLÀÁFÍÀ ỌKÀN

16. Fílípì 4:6, 7 ṣe sọ, kí ni ọ̀nà kan ṣoṣo tá a lè gbà ní àlàáfíà ọkàn? Ṣàlàyé.

16 Ka Fílípì 4:​6, 7Kí nìdí tí Jèhófà fi sọ pé “nípasẹ̀ Kristi Jésù” la lè gbà ní àlàáfíà tóun ń fúnni? Ìdí ni pé ká tó lè ní ìbàlẹ̀ ọkàn tó máa wà pẹ́ títí, a gbọ́dọ̀ nígbàgbọ́ nínú Jésù, ká sì mọ ipa tó ń kó nínú ìfẹ́ Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, ìràpadà tí Jésù ṣe ni Jèhófà ń wò mọ́ wa lára tó fi ń dárí jì wá. (1 Jòh. 2:12) Ìyẹn mà tuni lára o! Torí pé Jésù ni Ọba Ìjọba Ọlọ́run, ó máa mú gbogbo aburú tí Sátánì àti ayé burúkú yìí ti fà fún wa kúrò. (Àìsá. 65:17; 1 Jòh. 3:8; Ìfi. 21:3, 4) Ó dájú pé ìrètí tó ń fọkàn ẹni balẹ̀ nìyẹn! Yàtọ̀ síyẹn, bó tiẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ tí Jésù gbé fún wa ò rọrùn, síbẹ̀ ó wà pẹ̀lú wa, ó sì ń fún wa lókun tá a nílò ká lè ṣiṣẹ́ náà láṣeyanjú nínú ayé burúkú yìí. (Mát. 28:19, 20) Kò sí àní-àní pé ìyẹn ń fún wa nígboyà! Ká sòótọ́, ó ṣe pàtàkì ká ní ìtura, ìrètí àti ìgboyà ká tó lè ní ìbàlẹ̀ ọkàn.

17. (a) Báwo la ṣe lè ní ìbàlẹ̀ ọkàn? (b) Bó ṣe wà nínú Jòhánù 16:33, kí ni Jésù sọ pé àwa náà máa ṣe?

17 Kí lo lè ṣe táá jẹ́ kọ́kàn ẹ balẹ̀ bó o tiẹ̀ ń kojú àwọn ìṣòro tó lékenkà? Máa fara wé Jésù. Lọ́nà wo? Àkọ́kọ́, máa gbàdúrà nígbà gbogbo. Ìkejì, máa ṣègbọràn sí Jèhófà kó o sì máa fìtara wàásù tí kò bá tiẹ̀ rọrùn. Ìkẹta, jẹ́ káwọn ọ̀rẹ́ rẹ ràn ẹ́ lọ́wọ́. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àlàáfíà Ọlọ́run á máa ṣọ́ ọkàn rẹ. Bíi ti Jésù, ìwọ náà á borí ìṣòro èyíkéyìí tó lè dé bá ẹ.​—Ka Jòhánù 16:33.

ORIN 41 Jọ̀ọ́, Gbọ́ Àdúrà Mi

^ ìpínrọ̀ 5 Gbogbo wa la ní àwọn ìṣòro tó ń kó wa lọ́kàn sókè. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò ohun mẹ́ta tí Jésù ṣe táwa náà lè fara wé. Èyí á jẹ́ kọ́kàn wa balẹ̀ kódà tá a bá ń kojú ìṣòro tó le gan-an.