ILÉ ÌṢỌ́—Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ April 2020

Àwọn àpilẹ̀kọ tá a máa kẹ́kọ̀ọ́ láti June 1–July 5, 2020 ló wà nínú Ilé Ìṣọ́ yìí.

Ìgbéjàkò Láti Apá Àríwá!

Àpilẹ̀kọ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ 14: June 1-7, 2020. Kókó mẹ́rin wo ló jẹ́ ká rídìí tó fi yẹ ká ṣàtúnṣe sí òye tá a ní nípa Jóẹ́lì orí 1 àti 2?

Ojú Wo Lo Fi Ń Wo Àwọn Tó Wà ní Ìpínlẹ̀ Ìwàásù Rẹ?

Àpilẹ̀kọ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ 15: June 8-14, 2020. Kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jésù àti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kó o lè máa fojú tó tọ́ wo àwọn tó ò ń wàásù fún, kó o lè mọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́ àtohun tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí, kó o sì tún ní in lọ́kàn pé wọ́n lè di ọmọ ẹ̀yìn.

Túbọ̀ Mọ Àwọn Ará, Kó O sì Máa Gba Tiwọn Rò

Àpilẹ̀kọ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ 16: June 15-21, 2020. Jèhófà fìfẹ́ ran Jónà, Èlíjà, Hágárì àti Lọ́ọ̀tì lọ́wọ́. A máa rí bá a ṣe lè fara wé Jèhófà nínú bá a ṣe ń bá àwọn mí ì lò.

“Mo Pè Yín Ní Ọ̀rẹ́”

Àpilẹ̀kọ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ 17: June 22-28, 2020. Àwọn nǹkan kan wà tó lè mú kó ṣòro fún wa láti dọ̀rẹ́ Jésù. Àmọ́ a lè borí àwọn ìṣòro náà.

“Sá Eré Ìje Náà Dé Ìparí”

Àpilẹ̀kọ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ 18: June 29–July 5, 2020. Bá a tiẹ̀ ń fara da onírúurú ìṣòro bíi hẹ́gẹhẹ̀gẹ ọjọ́ ogbó tàbí àìsàn tó le koko tó sì ń tánni lókun, báwo ni gbogbo wa ṣe lè sá eré ìje ìyè náà dópin?