Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kí nìdí tí Jésù fi sọ ohun tó wà nínú Sáàmù 22:1 ṣáájú ikú rẹ̀?

Kí Jésù tó kú, ó sọ ohun tó wà nínú Mátíù 27:46 tó ní: “Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, kí ló dé tí o fi kọ̀ mí sílẹ̀?” Ọ̀rọ̀ Dáfídì tó wà nínú Sáàmù 22:1 ni Jésù fà yọ. (Máàkù 15:34) Ṣé torí pé ìgbàgbọ́ Jésù jó rẹ̀yìn fúngbà díẹ̀ tàbí ó ronú pé Jèhófà já òun kulẹ̀ ló mú kó sọ̀rọ̀ yìí? Rárá, ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀. Ká má gbàgbé pé Jésù mọ ìdí tó fi yẹ kóun kú, ó sì ṣe tán láti fẹ̀mí ẹ̀ lélẹ̀. (Mát. 16:21; 20:28) Ó tún mọ̀ pé lásìkò tóun máa kú, Jèhófà ò ní ṣe “ọgbà yí [òun] ká láti dáàbò bo òun.” (Jóòbù 1:10) Jèhófà ò dáàbò bo Jésù kí Jésù lè fi hàn pé, òun máa jẹ́ olóòótọ́ délẹ̀délẹ̀ láìka irú ikú tóun máa kú sí.​—Máàkù 14:​35, 36.

Kí wá nìdí tí Jésù fi sọ ọ̀rọ̀ tó wà nínú Sáàmù yìí? Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ò lè sọ ní pàtó, ẹ jẹ́ ká wo àwọn nǹkan tó ṣeé ṣe kó mú kí Jésù sọ bẹ́ẹ̀. *

Ṣé ohun tí Jésù ń sọ ni pé Jèhófà ò ní dá sọ́rọ̀ ikú òun? Ó di dandan kí Jésù san ìràpadà náà láìsí pé Jèhófà dá sí i. Èèyàn ẹlẹ́ran ara bíi tiwa ni, ó sì gbọ́dọ̀ kú “kó lè tọ́ ikú wò fún gbogbo èèyàn.”​—Héb. 2:9.

Bí Jésù ṣe fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Sáàmù yẹn, ṣé ó fẹ́ káwọn èèyàn rántí Sáàmù náà látòkèdélẹ̀ ni? Láyé ìgbà yẹn, àwọn Júù sábà máa ń há ọ̀pọ̀ Sáàmù sórí. Bí àpẹẹrẹ, tẹ́nì kan bá rán wọn létí ẹsẹ kan nínú Sáàmù kan, ìyẹn máa ń mú kí wọ́n ronú lórí Sáàmù náà látòkèdélẹ̀. Tó bá jẹ́ pé ohun tí Jésù ní lọ́kàn nìyẹn, ìyẹn á jẹ́ káwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tó jẹ́ Júù rántí ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ikú rẹ̀ bó ṣe wà nínú Sáàmù yìí. (Sm. 22:​7, 8, 15, 16, 18, 24) Bákan náà, lọ́wọ́ ìparí Sáàmù yẹn, onísáàmù yẹn yin Jèhófà, ó sì jẹ́ kó hàn gbangba pé òun ni Ọba Aláṣẹ lórí gbogbo ayé.​—Sm. 22:​27-31.

Ṣé Jésù fẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé òun ò jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan òun ló fi fa ọ̀rọ̀ Dáfídì yọ? Kí Jésù tó kú, ìgbìmọ̀ Sàhẹ́ndìrìn gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀ lọ́nà tí kò bófin mu, wọ́n sì dá a lẹ́jọ́ pé ó sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run. (Mát. 26:​65, 66) Bí àpẹẹrẹ, òru ni ìgbìmọ̀ náà sáré kóra jọ láti gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀, ìyẹn ò sì bófin mu. (Mát. 26:59; Máàkù 14:​56-59) Torí náà, bí Jésù ṣe béèrè pé “Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, kí ló dé tí o fi kọ̀ mí sílẹ̀?” ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ló fẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé òun ò jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan òun.

Ṣé ó lè jẹ́ pé ńṣe ni Jésù fẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà fàyè gba pé kí Dáfídì jìyà, kò fi í sílẹ̀? Kì í ṣe pé Dáfídì ò nígbàgbọ́ ló fi béèrè ìbéèrè náà. Ẹ̀yìn tó béèrè ìbéèrè yẹn ló fi hàn pé ó dá òun lójú pé Jèhófà máa ń gba àwọn èèyàn ẹ̀ là, Jèhófà náà sì bù kún un. (Sm. 22:​23, 24, 27) Lọ́nà kan náà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jésù tó jẹ́ “Ọmọ Dáfídì” náà ń jẹ̀rora lórí òpó igi, Jèhófà ò fi í sílẹ̀.​—Mát. 21:9.

Ṣé ohun tó jẹ́ kí ẹ̀dùn ọkàn Jésù pọ̀ gan-an ni pé Jèhófà ò dáàbò bò ó, ó sì jẹ́ kí wọ́n dán an wò dé góńgó kó lè fi hàn pé adúróṣinṣin ni? Ká ní Ádámù àti Éfà ò dẹ́ṣẹ̀ ni, kò sídìí pé kí Jèhófà rán Jésù wá sáyé kó lè jìyà kó sì kú. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jésù ò hùwà àìdáa èyíkéyìí, ó di dandan kó jìyà, kó sì kú kó lè fi hàn pé irọ́ ni ẹ̀sùn tí Sátánì fi kan Jèhófà. Yàtọ̀ síyẹn, ikú rẹ̀ ló mú kó ṣeé ṣe láti san ìràpadà náà kí aráyé lè rí ìyè àìnípẹ̀kun. (Máàkù 8:31; 1 Pét. 2:​21-24) Kíyẹn tó lè ṣeé ṣe, àfi kí Jèhófà fàyè gbà á pé kí wọ́n fìyà jẹ ẹ́, kó sì kú. Ìyẹn sì ni ìgbà àkọ́kọ́ tí Jèhófà máa fàyè gba irú ẹ̀ fún Ọmọ ẹ̀.

Àbí ńṣe ni Jésù fẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ ronú lórí ìdí tí Jèhófà fi jẹ́ kóun kú lórí òpó igi oró? * Jésù mọ̀ pé bí wọ́n ṣe fi ẹ̀sùn ọ̀daràn kan òun, tí wọ́n sì pa òun lórí òpó igi oró máa mú kí ọ̀pọ̀ kọsẹ̀. (1 Kọ́r. 1:23) Àmọ́ tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ bá pọkàn pọ̀ sórí ìdí tó fi kú, wọn ò ní kọsẹ̀. (Gál. 3:​13, 14) Nípa bẹ́ẹ̀, wọn ò ní fojú ọ̀daràn wò ó, kàkà bẹ́ẹ̀ wọ́n á gbà pé ṣe ló gba àwọn là.

Ohun yòówù kó mú kí Jésù fa ọ̀rọ̀ Dáfídì yọ nínú Sáàmù 22, ó mọ̀ pé ohun tí Jèhófà fẹ́ kóun ṣe lòun ń ṣe. Kò pẹ́ lẹ́yìn tí Jésù fa ọ̀rọ̀ inú Sáàmù yẹn yọ ló sọ pé: “A ti ṣe é parí!” (Jòh. 19:30; Lúùkù 22:37) Bí Jèhófà ṣe fàyè gba pé kí Jésù jìyà fúngbà díẹ̀ mú kó lè ṣàṣeparí gbogbo ohun tí Jèhófà ní kó wá ṣe láyé. Bákan náà, ó jẹ́ kí Jésù lè mú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó wà “nínú Òfin Mósè àti nínú ìwé àwọn Wòlíì àti Sáàmù” ṣẹ.​—Lúùkù 24:44.

^ ìpínrọ̀ 2 Wo ìpínrọ̀ 9 àti 10 nínú àpilẹ̀kọ náà “Ohun Tá A Rí Kọ́ Nínú Àwọn Ọ̀rọ̀ Tí Jésù Sọ Kẹ́yìn” nínú Ilé Ìṣọ́ yìí.

^ ìpínrọ̀ 4 Nígbà tí Jésù ń ṣiṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, àwọn ìgbà kan wà tó máa ń sọ̀rọ̀ tàbí béèrè àwọn ìbéèrè kan kó lè mọ ohun tó wà lọ́kàn àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó mọ ohun tí òun fẹ́ ṣe.​—Máàkù 7:​24-27; Jòh. 6:​1-5; wo Ilé Ìṣọ́, October 15, 2010, ojú ìwé 4 àti 5.