Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 17

O Ṣeyebíye Gan-an Lójú Jèhófà!

O Ṣeyebíye Gan-an Lójú Jèhófà!

“Inú Jèhófà ń dùn sí àwọn èèyàn rẹ̀.”​—SM. 149:4.

ORIN 108 Ìfẹ́ Ọlọ́run Tí Kì Í Yẹ̀

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

Inú Baba wa ọ̀run “ń dùn” sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa (Wo ìpínrọ̀ 1)

1. Kí ni Jèhófà ń kíyè sí lára àwọn èèyàn rẹ̀?

BÍBÉLÌ sọ pé: “Inú Jèhófà ń dùn sí àwọn èèyàn rẹ̀.” (Sm. 149:4) Ìyẹn mà fini lọ́kàn balẹ̀ o! Jèhófà máa ń kíyè sí àwọn ànímọ́ rere tá a ní, ó mọ̀ pé ó máa ń wù wá láti ṣe ohun tó dáa, ó sì máa ń mú ká sún mọ́ òun. Torí náà, tá a bá jẹ́ olóòótọ́ sí i, kò ní fi wá sílẹ̀ láé àti láéláé!​—Jòh. 6:44.

2. Kí nìdí tó fi máa ń ṣòro fáwọn kan láti gbà pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wọn?

2 Àwọn kan lè sọ pé, ‘Mo mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn rẹ̀ lápapọ̀, àmọ́ kò dá mi lójú pé ó rí tèmi rò.’ Kí ló lè mú kẹ́nì kan nírú èrò bẹ́ẹ̀? Arábìnrin Oksana * tójú ẹ̀ rí màbo nígbà tó wà ní kékeré sọ pé: “Inú mi dùn gan-an nígbà tí mo ṣèrìbọmi, kò sì pẹ́ tí mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Àmọ́ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) lẹ́yìn náà, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ro ara mi pin tí mo bá ti ń rántí ohun tójú mi rí ní kékeré. Ìyẹn mú kí n gbà pé mi ò yẹ lẹ́ni tí Jèhófà ń nífẹ̀ẹ́, mi ò sì lè rí ojúure ẹ̀ mọ́.” Arábìnrin Yua tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà rántí ìyà tóun náà jẹ ní kékeré, ó ní: “Mo ya ara mi sí mímọ́ fún Jèhófà torí pé mo fẹ́ mú inú rẹ̀ dùn. Àmọ́ nínú mi lọ́hùn-ún, mo gbà pé kò lè nífẹ̀ẹ́ mi láéláé.”

3. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

3 Bíi tàwọn arábìnrin olóòótọ́ tá a sọ̀rọ̀ wọn tán yìí, ó dájú pé ìwọ náà nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an. Àmọ́, o lè máa ṣiyèméjì pé bóyá ni Jèhófà lè nífẹ̀ẹ́ rẹ. Kí nìdí tó fi yẹ kó dá ẹ lójú pé lóòótọ́ ni Jèhófà nífẹ̀ẹ́ rẹ? Yàtọ̀ síyẹn, kí lo lè ṣe tó o bá ń ronú pé Jèhófà ò lè nífẹ̀ẹ́ rẹ? Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká dáhùn àwọn ìbéèrè yìí.

Ó LÉWU TÉÈYÀN BÁ Ń RONÚ PÉ JÈHÓFÀ Ò NÍFẸ̀Ẹ́ ÒUN

4. Kí nìdí tó fi léwu tá a bá ń ronú pé Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ wa?

4 Ìfẹ́ lágbára gan-an. Tó bá dá wa lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì ń tì wá lẹ́yìn, tọkàntara làá fi máa ṣèfẹ́ rẹ̀ láìka ìṣòro yòówù ká kojú sí. Lọ́wọ́ kejì, tá a bá ń ṣiyèméjì pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, “agbára [wa] ò ní tó nǹkan.” (Òwe 24:10) Tá a bá rẹ̀wẹ̀sì, tá a sì ronú pé Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ wa, wẹ́rẹ́ báyìí la máa kó sọ́wọ́ Sátánì.​—Éfé. 6:16.

5. Kí ló ṣẹlẹ̀ sáwọn kan tó ronú pé Ọlọ́run ò nífẹ̀ẹ́ àwọn?

5 Àwọn ará wa kan ti bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ àwọn, ìyẹn sì ti mú kí ìgbàgbọ́ wọn máa jó àjórẹ̀yìn. Alàgbà kan tó ń jẹ́ James sọ pé: “Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Bẹ́tẹ́lì ni mo ti ń ṣiṣẹ́ sìn, tí mo sì tún wà nínú ìjọ tó ń sọ èdè ilẹ̀ òkèèrè, mo ṣì máa ń ronú pé bóyá ni Jèhófà tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ ìsìn mi. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tí mo ronú pé bóyá ni Jèhófà ń tẹ́tí sí àdúrà mi.” Arábìnrin Eva tóun náà jẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún sọ pé: “Mo ti rí i pé ó léwu gan-an téèyàn bá ń ronú pé Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ òun torí pé irú èrò bẹ́ẹ̀ máa ń mú kéèyàn rẹ̀wẹ̀sì. Téèyàn bá sì ti rẹ̀wẹ̀sì, kò ní yá a lára láti lọ́wọ́ nínú ìjọsìn Ọlọ́run mọ́, kò sì ní láyọ̀ mọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.” Michael tó jẹ́ alàgbà àti aṣáájú-ọ̀nà déédéé sọ pé: “Téèyàn bá ronú pé Ọlọ́run ò nífẹ̀ẹ́ òun, díẹ̀díẹ̀ lá fi Jèhófà sílẹ̀.”

6. Kí ló yẹ ká ṣe tó bá ń ṣe wá bíi pé Ọlọ́run ò nífẹ̀ẹ́ wa?

6 Àwọn àpẹẹrẹ tá a gbé yẹ̀ wò yìí jẹ́ ká rí bó ṣe léwu tó pé kéèyàn máa ronú pé Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ òun. Àmọ́ kí ló yẹ ká ṣe tírú èrò bẹ́ẹ̀ bá wá sí wa lọ́kàn? Ṣe ló yẹ ká gbé e kúrò lọ́kàn kíá! Kí lohun míì tẹ́nì kọ̀ọ̀kan wa lè ṣe? O lè bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè gbé ‘àwọn ohun tó ń dà ẹ́ lọ́kàn rú’ kúrò, kó sì jẹ́ kó o ní ‘àlàáfíà Ọlọ́run táá máa ṣọ́ ọkàn rẹ àti agbára ìrònú rẹ.’ (Sm. 139:23; àlàyé ìsàlẹ̀; Fílí. 4:​6, 7) Sì máa rántí pé ìwọ nìkan kọ́ lo nírú èrò yìí. Àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin kan náà wà tí wọ́n nírú èrò tó o ní. Kódà, àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà kan láyé àtijọ́ ní àwọn nǹkan tó ń dà wọ́n lọ́kàn rú. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká wo ohun tá a lè kọ́ látinú àpẹẹrẹ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù.

KÍ LA RÍ KỌ́ LÁTINÚ ÀPẸẸRẸ PỌ́Ọ̀LÙ?

7. Àwọn ìṣòro wo ni Pọ́ọ̀lù ní?

7 Ǹjẹ́ ó máa ń ṣe ẹ́ bíi pé àwọn ohun tó yẹ kó o ṣe ti pọ̀ jù, ṣé ó sì máa ń nira fún ẹ? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, o rẹ́ni fi jọ. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé Pọ́ọ̀lù ń ṣàníyàn, kì í ṣe lórí ìjọ kan ṣoṣo o, àmọ́ “lórí gbogbo ìjọ.” (2 Kọ́r. 11:​23-28) Ṣé àìsàn tó ń ṣe ẹ́ ló ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá ẹ? Ṣe lọ̀rọ̀ ẹ dà bíi ti Pọ́ọ̀lù tí ìnira bá nítorí ‘ẹ̀gún kan tó wà nínú ara ẹ̀,’ tó ṣeé ṣe kó jẹ́ àìlera ara, tó sì tìtorí ẹ̀ gbàdúrà lọ́pọ̀ ìgbà pé kí Jèhófà bá òun mú un kúrò. (2 Kọ́r. 12:​7-10) Ṣé àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ tó o ní ló ń mú kó o rẹ̀wẹ̀sì? Ó ṣe Pọ́ọ̀lù bẹ́ẹ̀ náà rí. Ìgbà kan wà tó pe ara ẹ̀ ní “abòṣì èèyàn” nítorí àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ rẹ̀ tó ń bá fà á.​—Róòmù 7:​21-24.

8. Kí ló jẹ́ kí Pọ́ọ̀lù lè fara da àwọn ìṣòro tó ní?

8 Láìka àwọn ìṣòro tí Pọ́ọ̀lù ní sí, kò dẹ́kun àtimáa sin Jèhófà. Kí ló jẹ́ kó lè fara dà á? Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó mọ̀ pé òun láwọn kùdìẹ̀-kudiẹ kan, ó nígbàgbọ́ tó lágbára nínú ìràpadà. Ó mọ̀ pé Jésù ti ṣèlérí pé ‘gbogbo ẹni tó bá ń ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù máa ní ìyè àìnípẹ̀kun.’ (Jòh. 3:16; Róòmù 6:23) Ó sì dájú pé Pọ́ọ̀lù wà lára àwọn tó ní ìgbàgbọ́ nínú ìràpadà. Ó dá a lójú pé Jèhófà ṣe tán láti dárí ji àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ títí kan àwọn tó dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì tí wọ́n bá ronú pìwà dà.​—Sm. 86:5.

9. Kí la rí kọ́ nínú ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ ní Gálátíà 2:20?

9 Ó dá Pọ́ọ̀lù lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ òun gan-an. Ó ṣe tán, torí òun ló ṣe rán Kristi wá sáyé kó lè kú fún òun. (Ka Gálátíà 2:20.) Ẹ kíyè sí ọ̀rọ̀ tó ń fini lọ́kàn balẹ̀ tó wà ní ìparí ẹsẹ yẹn. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ọmọ Ọlọ́run . . . nífẹ̀ẹ́ mi, [ó] sì fi ara rẹ̀ lélẹ̀ fún mi.” Pọ́ọ̀lù ò ronú pé òun ò yẹ lẹ́ni tí Jèhófà ń nífẹ̀ẹ́ kó wá máa sọ pé, ‘Mo mọ ìdí tí Jèhófà fi nífẹ̀ẹ́ àwọn ará yòókù, àmọ́ kò sídìí tó fi máa nífẹ̀ẹ́ èmi.’ Pọ́ọ̀lù rán àwọn ará tó wà ní Róòmù létí pé: “Nígbà tí a ṣì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Kristi kú fún wa.” (Róòmù 5:8) Torí náà, gbogbo wa pátá ni Jèhófà nífẹ̀ẹ́!

10. Kí la rí kọ́ nínú Róòmù 8:​38, 39?

10 Ka Róòmù 8:​38, 39. Ó dá Pọ́ọ̀lù lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an. Ó sọ pé kò sóhun náà tó “máa lè yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run.” Pọ́ọ̀lù mọ bí Jèhófà ṣe mú sùúrù gan-an fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kò sì gbàgbé bí Jèhófà ṣe fàánú hàn sí òun. Lédè míì, ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ ni pé, ‘Tí Jèhófà bá lè rán Ọmọ rẹ̀ wá sáyé láti kú fún mi, kò sídìí tó fi yẹ kí n máa ṣiyèméjì pé bóyá ló nífẹ̀ẹ́ mi.’​—Róòmù 8:32.

Kì í ṣe àwọn àṣìṣe tá a ṣe sẹ́yìn ni Jèhófà ń wò, ohun tó ṣe pàtàkì sí i ni ohun tá à ń ṣe báyìí àtèyí tá a máa ṣe lọ́jọ́ iwájú (Wo ìpínrọ̀ 11) *

11. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Pọ́ọ̀lù ti hu àwọn ìwà tó mẹ́nu bà nínú 1 Tímótì 1:​12-15 sẹ́yìn, kí nìdí tó fi dá a lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ òun?

11 Ka 1 Tímótì 1:​12-15. Ó dájú pé àwọn ìgbà kan máa wà táá máa dun Pọ́ọ̀lù tó bá ń rántí àwọn nǹkan tó ti ṣe sẹ́yìn. Ó ka ara ẹ̀ sí “àkọ́kọ́ lára” àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, ìyẹn ò sì yani lẹ́nu. Kí Pọ́ọ̀lù tó di Kristẹni, ó máa ń ṣenúnibíni sáwọn Kristẹni láti ìlú kan sí òmíì. Ó fi àwọn kan sẹ́wọ̀n, ó sì fọwọ́ sí bí wọ́n ṣe pa àwọn míì. (Ìṣe 26:​10, 11) Ẹ wo bó ṣe máa rí lára Pọ́ọ̀lù tó bá pàdé Kristẹni kan tó sì jẹ́ pé òun ló fọwọ́ sí bí wọ́n ṣe pa àwọn òbí ẹ̀. Ó dájú pé Pọ́ọ̀lù kábàámọ̀ àwọn nǹkan tó ṣe sẹ́yìn, àmọ́ ó mọ̀ pé kò sí ohun tóun lè ṣe nípa ẹ̀. Ó gbà pé òun ni Kristi kú fún, ó sì sọ pé: “Nípa inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run, mo jẹ́ ohun tí mo jẹ́.” (1 Kọ́r. 15:​3, 10) Kí lèyí kọ́ wa? Gbà pé torí ni Jésù ṣe kú kó o lè ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà. (Ìṣe 3:19) Kì í ṣe àwọn àṣìṣe tá a ṣe sẹ́yìn ni Jèhófà ń wò, yálà a jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, ohun tó ṣe pàtàkì sí i ni ohun tá à ń ṣe báyìí àtèyí tá a máa ṣe lọ́jọ́ iwájú.​Àìsá. 1:18.

12. Báwo lọ̀rọ̀ tó wà nínú 1 Jòhánù 3:​19, 20 ṣe lè fi wá lọ́kàn balẹ̀ tó bá ń ṣe wá bíi pé a ò wúlò tàbí pé Jèhófà ò lè nífẹ̀ẹ́ wa?

12 Nígbà tó o bá ń ronú nípa ìràpadà tí Jésù san fún ẹ, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé ‘kì í ṣe irú èèyàn bíi tèmi ni Jésù máa kú fún.’ Kí ló lè mú kó ṣe ẹ́ bẹ́ẹ̀? Torí pé aláìpé ni wá, ọkàn wa lè tàn wá jẹ, ó lè mú ká máa ronú pé a ò wúlò tàbí pé Jèhófà ò lè nífẹ̀ẹ́ wa. (Ka 1 Jòhánù 3:​19, 20.) Nírú àsìkò bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn pé “Ọlọ́run ju ọkàn wa lọ.” Òótọ́ kan tí kò ṣeé já ní koro ni pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ rẹ, ó sì máa dárí jì ẹ́ kódà tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé kò nífẹ̀ẹ́ ẹ tàbí pé kò lè dárí jì ẹ́. Ó ṣe pàtàkì ká máa wo ara wa bí Jèhófà ṣe ń wò wá, pé ó nífẹ̀ẹ́ wa, kò sì ní fi wá sílẹ̀. Èyí gba pé ká máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé, ká máa gbàdúrà nígbà gbogbo, ká sì máa kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn ará. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa ṣe àwọn nǹkan yìí?

BÍ ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ, ÀDÚRÀ ÀTI ÀWỌN ARÁ ṢE LÈ RÀN WÁ LỌ́WỌ́

13. Àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run? (Tún wo àpótí náà “ Bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ṣe Ràn Wọ́n Lọ́wọ́.”)

13 Máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́ torí ìyẹn á jẹ́ kó o túbọ̀ mọ Jèhófà. Á jẹ́ kó túbọ̀ dá ẹ lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ rẹ. Tó o bá ń ṣàṣàrò lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́, á jẹ́ kó o máa ronú lọ́nà tó tọ́. (2 Tím. 3:16) Alàgbà kan tó ń jẹ́ Kevin tó ti fìgbà kan rí ronú pé òun ò wúlò sọ pé: “Nígbà tí mo ka Sáàmù kẹtàlélọ́gọ́rùn-ún (103), tí mo sì ṣàṣàrò lé e lórí, ó jẹ́ kí n tún èrò mi ṣe, ó sì jẹ́ kó dá mi lójú pé mo ṣeyebíye lójú Jèhófà.” Arábìnrin Eva tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Lójoojúmọ́, kí n tó lọ sùn, mo máa ń ronú lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ìyẹn máa ń jẹ́ kọ́kàn mi balẹ̀, kí ìgbàgbọ́ mi sì lágbára.”

14. Báwo ni àdúrà ṣe lè ràn wá lọ́wọ́?

14 Máa gbàdúrà nígbà gbogbo. (1 Tẹs. 5:17) Kí àárín àwọn ọ̀rẹ́ méjì tó lè wọ̀, wọ́n gbọ́dọ̀ máa bára wọn sọ̀rọ̀ déédéé. Bákan náà lọ̀rọ̀ rí tó bá kan àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà. Tá a bá jẹ́ kí Jèhófà mọ bí nǹkan ṣe rí lára wa, èrò wa àtohun tó ń jẹ wá lọ́kàn, ṣe là ń fi hàn pé a fọkàn tán an, a sì gbà pé ó nífẹ̀ẹ́ wa. (Sm. 94:​17-19; 1 Jòh. 5:​14, 15) Yua tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Tí mo bá ń gbàdúrà, kì í ṣe àwọn ohun tí mo ṣe lọ́jọ́ yẹn nìkan ni mo máa ń sọ fún Jèhófà. Ṣe ni mo máa ń tú ọkàn mi jáde sí i, mo sì máa ń jẹ́ kó mọ bí nǹkan ṣe rí lára mi. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó túbọ̀ ṣe kedere sí mi pé Jèhófà kì í ṣe ọ̀gá ilé iṣẹ́ kan tó kàn máa ń pàṣẹ. Kàkà bẹ́ẹ̀, Bàbá tó nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ rẹ̀ ni.”​—Wo àpótí náà “ Ṣé O Ti Kà Á?

15. Kí ni Jèhófà fún wa tó fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ wa gan-an?

15 Máa kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn ará torí àwọn ni ọ̀rẹ́ tòótọ́ tí Jèhófà fi jíǹkí ẹ. (Jém. 1:17) Ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa ló mú kó fún wa ní àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tí wọ́n “nífẹ̀ẹ́ [wa] nígbà gbogbo.” (Òwe 17:17) Nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará Kólósè, ó dárúkọ àwọn ará kan tí wọ́n tì í lẹ́yìn, ó sì pè wọ́n ní “orísun ìtùnú.” (Kól. 4:​10, 11) Yàtọ̀ sí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tó jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀, Jésù tún láwọn ọ̀rẹ́ tó jẹ́ áńgẹ́lì, ó sì mọyì bí wọ́n ṣe dúró tì í lásìkò tó nílò wọn.​—Lúùkù 22:​28, 43.

16. Báwo làwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ ṣe lè mú ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà?

16 Ṣé o ní àwọn ọ̀rẹ́ gidi nínú ìjọ? Ti pé a sọ ìṣòro wa fún ẹnì kan tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀ kò túmọ̀ sí pé a ò lè dá ìpinnu ṣe. Kàkà bẹ́ẹ̀, á jẹ́ ká lè ṣe ìpinnu tó tọ́. James tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Bí mo ṣe ń bá àwọn tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn ṣọ̀rẹ́ ti ràn mí lọ́wọ́ gan-an. Láwọn ìgbà tí ìrẹ̀wẹ̀sì bá mi, àwọn ọ̀rẹ́ yìí máa ń fetí sí mi, wọ́n sì máa ń rán mi létí pé àwọn wà níbẹ̀ fún mi. Èyí jẹ́ kó túbọ̀ dá mi lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ mi gan-an.” Ẹ ò rí bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká máa kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin, ká má sì jẹ́ kí ohunkóhun da àárín wa rú!

DÚRÓ NÍNÚ ÌFẸ́ JÈHÓFÀ

17-18. Ta ló yẹ ká fetí sí, kí sì nìdí?

17 Sátánì ò fẹ́ ká ṣe ohun tó tọ́. Ṣe ló fẹ́ ká máa ronú pé Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ wa àti pé a ò yẹ lẹ́ni tí Jésù máa kú fún. Àmọ́ bá a ṣe jíròrò ẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ yìí, irọ́ gbuu ni.

18 Jèhófà nífẹ̀ẹ́ rẹ gan-an, o sì ṣeyebíye lójú rẹ̀. Tó o bá ń ṣègbọràn sí i, wàá “dúró nínú ìfẹ́ rẹ̀” títí láé bíi ti Jésù. (Jòh. 15:10) Torí náà, má ṣe tẹ́tí sí Sátánì, má sì jẹ́ kí ọkàn ẹ tàn ẹ́ jẹ. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jèhófà ni kó o máa tẹ́tí sí torí pé ibi tẹ́nì kọ̀ọ̀kan wa dáa sí ló ń wò. Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé “inú Jèhófà ń dùn sí àwọn èèyàn rẹ̀,” títí kan ìwọ náà!

ORIN 141 Ìyanu Ni Ìwàláàyè Jẹ́

^ ìpínrọ̀ 5 Ó ṣòro fáwọn ará wa kan láti gbà pé Jèhófà lè nífẹ̀ẹ́ àwọn. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò ìdí tá a fi gbà pé ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ni Jèhófà nífẹ̀ẹ́. A tún máa sọ̀rọ̀ nípa ohun tá a lè ṣe tá ò fi ní máa ṣiyèméjì pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa.

^ ìpínrọ̀ 2 A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.

^ ìpínrọ̀ 67 ÀWÒRÁN: Kí Pọ́ọ̀lù tó dọmọ ẹ̀yìn Jésù, ó fi ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni sẹ́wọ̀n. Àmọ́ nígbà tó mọ Kristi, ó yí pa dà, ó sì fún àwọn ará níṣìírí títí kan àwọn tó ṣeé ṣe kó jẹ́ mọ̀lẹ́bí àwọn tó ṣenúnibíni sí.