Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bó O Ṣe Lè Máa Fara Dà Á Tó O Bá Ní Ìdààmú Ọkàn

Bó O Ṣe Lè Máa Fara Dà Á Tó O Bá Ní Ìdààmú Ọkàn

TẸ́NÌ kan bá ní ìdààmú ọkàn, ńṣe ló dà bí ìgbà tí ẹrù tó wúwo wà lọ́kàn ẹ̀. (Òwe 12:25) Ǹjẹ́ ohun kan ti ṣẹlẹ̀ sí ẹ rí tó jẹ́ kí àníyàn bò ẹ́ mọ́lẹ̀? Ṣé ó ń ṣe ẹ́ bíi pé o ò lè fara dà á mọ́? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ìwọ nìkan kọ́ nirú ẹ̀ ń ṣe. Ọ̀pọ̀ lára wa ni nǹkan ti tojú sú torí pé à ń bójú tó ẹnì kan tó ń ṣàìsàn tàbí ẹni tó ti dàgbà, èèyàn wa lè ti kú, àjálù lè ti ṣẹlẹ̀ sí wa tàbí ká ní àwọn ìṣòro kan tó ń kó ìdààmú bá wa. Àmọ́ kí ló máa jẹ́ ká lè fara dà á? *

Tá a bá fẹ́ mọ bá a ṣe lè fara dà á tá a bá ní ìdààmú ọkàn, a lè kẹ́kọ̀ọ́ lára Ọba Dáfídì. Ọ̀pọ̀ ìṣòro ló dojú kọ nígbèésí ayé ẹ̀, àwọn ìgbà kan sì wà tí wọ́n fẹ́ pa á. (1 Sám. 17:34, 35; 18:10, 11) Kí ló jẹ́ kí Dáfídì lè fara da ìdààmú ọkàn tó ní? Báwo làwa náà ṣe lè fara dà á bíi tiẹ̀?

BÍ DÁFÍDÌ ṢE FARA DÀ Á NÍGBÀ TÓ NÍ ÌDÀÀMÚ ỌKÀN

Dáfídì dojú kọ ọ̀pọ̀ ìṣòro lẹ́ẹ̀kan náà. Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká wo nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí i nígbà tó ń sá fún Ọba Sọ́ọ̀lù. Nígbà tí Dáfídì àtàwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú ẹ̀ dé láti ibi tí wọ́n ti lọ jagun, ó yà wọ́n lẹ́nu pé àwọn ọ̀tá ti jí ẹrù wọn kó, wọ́n dáná sun ilé wọn, wọ́n sì kó ìyàwó àtàwọn ọmọ wọn lẹ́rú. Kí ni Dáfídì wá ṣe? Bíbélì sọ pé: “Dáfídì àti àwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú rẹ̀ . . . bú sẹ́kún, wọ́n ń ké títí wọn ò fi lókun láti sunkún mọ́.” Ohun tó dá kún ìdààmú ọkàn Dáfídì ni pé àwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú ẹ̀ sọ pé “àwọn máa sọ ọ́ lókùúta.” (1 Sám. 30:1-6) Ìṣòro ńlá mẹ́ta tó dojú kọ Dáfídì lẹ́ẹ̀kan náà ni pé, wọ́n kó ìyàwó àtàwọn ọmọ ẹ̀ lẹ́rú, kò mọ̀ bóyá àwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú ẹ̀ máa pa á, Ọba Sọ́ọ̀lù náà sì ń wá bó ṣe máa pa á. Ẹ wo bí àwọn nǹkan yìí ṣe máa kó ìdààmú bá Dáfídì tó!

Kí ni Dáfídì wá ṣe? Bíbélì sọ pé lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ Dáfídì “fún ara rẹ̀ lókun látọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀.” Báwo ni Dáfídì ṣe ṣe é? Tí Dáfídì bá ti ní ìṣòro, ó máa ń gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ran òun lọ́wọ́, ó sì máa ń ronú nípa bó ṣe ran òun lọ́wọ́ láwọn ìgbà kan sẹ́yìn. (1 Sám. 17:37; Sm. 18:2, 6) Dáfídì rí i pé ó yẹ kóun wádìí lọ́wọ́ Jèhófà, torí náà ó béèrè lọ́wọ́ Jèhófà pé kí ló yẹ kóun ṣe. Lẹ́yìn tí Jèhófà jẹ́ kí Dáfídì mọ ohun tó máa ṣe, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló gbé ìgbésẹ̀. Torí náà, Jèhófà bù kún òun àtàwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú ẹ̀, wọ́n sì rí àwọn èèyàn wọn àtàwọn ẹrù wọn gbà pa dà. (1 Sám. 30:7-9, 18, 19) Ṣé o kíyè sí àwọn nǹkan mẹ́ta tí Dáfídì ṣe? Ó gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ran òun lọ́wọ́, ó ronú nípa àwọn ohun tí Jèhófà ti ṣe fún un sẹ́yìn, ó sì ṣe ohun tí Jèhófà ní kó ṣe. Báwo làwa náà ṣe lè ṣe bíi ti Dáfídì? Ẹ jẹ́ ká wo ọ̀nà mẹ́ta tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀.

FARA WÉ DÁFÍDÌ TÓ O BÁ NÍ ÌDÀÀMÚ ỌKÀN

1. Gbàdúrà. Tó o bá rí i pé o ní ìdààmú ọkàn, o sì ń ṣàníyàn, o lè gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́, kó sì fún ẹ lọ́gbọ́n tó o máa fi yanjú ẹ̀. Tó o bá ń gbàdúrà léraléra, tó o sì sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn ẹ fún un, ara máa tù ẹ́. O tún lè gbàdúrà sínú, kó o sì jẹ́ kó ṣe ṣókí tó bá jẹ́ pé o ò ní lè gbàdúrà síta níbi tó o wà. Gbogbo ìgbà tó o bá ní kí Jèhófà ràn ẹ́ lọ́wọ́, tó o sì gbẹ́kẹ̀ lé e, ńṣe nìwọ náà ń sọ bíi ti Dáfídì pé: “Jèhófà ni àpáta gàǹgà mi àti odi ààbò mi àti Ẹni tó ń gbà mí sílẹ̀. Ọlọ́run mi ni àpáta mi, ẹni tí mo fi ṣe ibi ààbò.” (Sm. 18:2) Ṣé àdúrà lè ràn wá lọ́wọ́ lóòótọ́? Arábìnrin aṣáájú-ọ̀nà kan tó ń jẹ́ Kahlia sọ pé: “Ọkàn mi máa ń balẹ̀ tí mo bá ti gbàdúrà. Àdúrà máa ń jẹ́ kí n ronú lọ́nà tí Jèhófà ń gbà ronú, ìyẹn sì jẹ́ kí n túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé e.” Ká sòótọ́, àdúrà tá à ń gbà sí Jèhófà ń ràn wá lọ́wọ́ gan-an láti fara dà á tá a bá ní ìdààmú ọkàn.

2. Ronú nípa àwọn ohun tí Jèhófà ti ṣe fún ẹ sẹ́yìn. Tó o bá ń ronú nípa àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sí ẹ, ṣé o rántí àwọn ìgbà tó o níṣòro àmọ́ tó jẹ́ pé Jèhófà ló ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti fara dà á? Tá a bá ronú lórí bí Jèhófà ṣe ran àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ lọ́wọ́ nígbà àtijọ́ àti bó ṣe ń ran àwa náà lọ́wọ́ lónìí, ọkàn wa máa balẹ̀, àá sì túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé e. (Sm. 18:17-19) Alàgbà kan tó ń jẹ́ Joshua sọ pé, “Mo máa ń kọ àwọn àdúrà mi tí Jèhófà dáhùn sílẹ̀. Ó máa ń jẹ́ kí n rántí àwọn ìgbà tí mo gbàdúrà pàtó sí Jèhófà tó sì fún mi lóhun tí mo béèrè gẹ́lẹ́.” Ó dájú pé tá a bá ń ronú lórí ohun tí Jèhófà ti ṣe fún wa, àá túbọ̀ lókun láti máa fara dà á.

3. Ṣe ohun tí Jèhófà ní kó o ṣe. Ká tó pinnu ohun tá a máa ṣe tóhun kan bá ṣẹlẹ̀ sí wa, ó yẹ ká wo inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ká lè rí ìtọ́sọ́nà tó dáa jù. (Sm. 19:7, 11) Ọ̀pọ̀ àwọn ará ti rí i pé táwọn bá ṣèwádìí lórí ẹsẹ Bíbélì kan, ó máa ń jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ mọ bí wọ́n ṣe lè fi ẹsẹ Bíbélì náà sílò. Alàgbà kan tó ń jẹ́ Jarrod sọ pé: “Tí mo bá ṣèwádìí dáadáa nípa ẹsẹ Bíbélì kan, ó máa ń jẹ́ kí n lóye gbogbo nǹkan tí Jèhófà ń sọ fún mi nínú ẹsẹ Bíbélì náà. Ó máa ń jẹ́ kí n gba ohun tí mo kà gbọ́ kí n sì ṣiṣẹ́ lórí ẹ̀.” Tá a bá ní ìdààmú ọkàn àmọ́ tá a ka Ìwé Mímọ́ ká lè rí ìtọ́sọ́nà Jèhófà, tá a sì ṣiṣẹ́ lórí ohun tá a kà, ọkàn wa á balẹ̀, àá sì máa láyọ̀.

JÈHÓFÀ MÁA RÀN Ẹ́ LỌ́WỌ́ KÓ O LÈ FARA DÀ Á

Dáfídì mọ̀ pé kóun tó lè borí ìdààmú ọkàn tóun ní, àfi kí Jèhófà ran òun lọ́wọ́. Ó mọyì bí Jèhófà ṣe ti òun lẹ́yìn débi tó fi sọ pé: “Agbára Ọlọ́run ni mo fi lè gun ògiri. Ọlọ́run tòótọ́ ni ẹni tó ń gbé agbára wọ̀ mí.” (Sm. 18:29, 32) Àwọn ìṣòro wa lè dà bí ògiri tí ò ṣeé gùn. Àmọ́ tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ó máa ràn wá lọ́wọ́ láti borí ìṣòro tó dà bíi pé ó ju agbára wa lọ! Tá a bá gbàdúrà pé kí Jèhófà ràn wá lọ́wọ́, tá à ń ronú lórí àwọn nǹkan tó ti ṣe fún wa sẹ́yìn, tá a sì ń ṣe ohun tó ní ká ṣe, ó dájú pé ó máa fún wa lágbára àti ọgbọ́n tó máa jẹ́ ká fara dà á tá a bá ní ìdààmú ọkàn!

^ ìpínrọ̀ 2 Ó yẹ kí ẹni tó ní ìdààmú ọkàn tó le gan-an lọ rí dókítà.