Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Tí Kristẹni kan bá kọ ìyàwó ẹ̀ sílẹ̀ lọ́nà tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu, tó sì fẹ́ ẹlòmíì, irú ojú wo ló yẹ kí ìjọ fi wo ìgbéyàwó tó kọ́kọ́ ṣe àti ìgbéyàwó tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe?
Nírú ipò bẹ́ẹ̀, ìjọ máa gbà pé ìgbéyàwó tó kọ́kọ́ ṣe ti dópin torí ó ti fẹ́ ẹlòmíì báyìí, ìjọ á sì tún gbà pé ìgbéyàwó tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe náà bá òfin mu. Ká lè lóye ìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Jésù sọ lórí kéèyàn kọ ẹni tó bá ṣègbéyàwó sílẹ̀, kó sì fẹ́ ẹlòmíì.
Ní Mátíù 19:9, Jésù jẹ́ ká mọ ohun kan ṣoṣo tó bá Ìwé Mímọ́ mu tó lè mú kéèyàn fòpin sí ìgbéyàwó. Ó sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tó bá kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀, àfi tó bá jẹ́ torí ìṣekúṣe, tó sì fẹ́ ẹlòmíì ti ṣe àgbèrè.” Ohun tí Jésù sọ yìí jẹ́ ká mọ ohun méjì, (1) Bíbélì sọ pé ìṣekúṣe nìkan ló lè mú kéèyàn kọ ẹni tó bá ṣègbéyàwó sílẹ̀ àti pé (2) ọkùnrin tó bá kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ lọ́nà tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu, tó sì fẹ́ ẹlòmíì ti ṣe àgbèrè. *
Ṣé ohun tí Jésù ń sọ ni pé ọkùnrin tó ṣèṣekúṣe tó sì kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ ní òmìnira láti fẹ́ ẹlòmíì láì ta ko ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ? Ohun tó ń sọ kọ́ nìyẹn. Tí ọkùnrin kan bá ṣàgbèrè, ìyàwó ẹ̀ tí kò ṣàgbèrè ló máa pinnu bóyá òun á dárí ji ọkọ òun tàbí òun ò ní dárí jì í. Tí obìnrin náà ò bá dárí jì í, tó sì kọ ọkọ ẹ̀ sílẹ̀ lọ́nà tó bá òfin mu, àwọn méjèèjì á lómìnira láti fẹ́ ẹlòmíì lẹ́yìn tí wọ́n bá ti buwọ́ lu ìwé ìkọ̀sílẹ̀ lọ́dọ̀ ìjọba.
Àmọ́ tó bá ṣẹlẹ̀ pé obìnrin tí kò ṣàgbèrè náà sọ pé òun ò fẹ́ kọ ọkọ òun sílẹ̀ àti pé òun ṣe tán láti dárí jì í ńkọ́? Tí ọkùnrin tó ṣàgbèrè náà bá sọ pé kí ìyàwó òun má dárí ji òun ńkọ́, tó sì dá lọ sọ́dọ̀ ìjọba láti já ìwé ìkọ̀sílẹ̀ fún un? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, Ìwé Mímọ́ sọ pé ọkùnrin náà ò lómìnira láti fẹ́ ẹlòmíì torí pé ìyàwó ẹ̀ ṣe tán láti dárí jì í, ó sì fẹ́ káwọn ṣì jẹ́ tọkọtaya. Tí wọn ò bá yọ ọkùnrin náà kúrò nínú ìjọ àmọ́ tí wọ́n bá a wí, ṣùgbọ́n tó pinnu pé òun máa fẹ́ ẹlòmíì bó tiẹ̀ jẹ́ pé Ìwé Mímọ́ sọ pé kò lómìnira láti ṣe bẹ́ẹ̀, ó tún ṣàgbèrè nìyẹn. Torí náà, ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́ á tún bójú tó ọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i.—1 Kọ́r. 5:1, 2; 6:9, 10.
Tí ọkùnrin kan bá fẹ́ ìyàwó míì bó tiẹ̀ jẹ́ pé Ìwé Mímọ́ sọ pé kò lómìnira láti ṣe bẹ́ẹ̀, ojú wo ló yẹ kí ìjọ máa fi wo ìgbéyàwó tó kọ́kọ́ ṣe àti èyí tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe? Ṣé ìgbéyàwó tó kọ́kọ́ ṣe yẹn ṣì lẹ́sẹ̀ nílẹ̀, tó sì bá Bíbélì mu? Ṣé ìyàwó ẹ̀ tí ò ṣàgbèrè ṣì lè dárí jì í tàbí kó pinnu pé kì í ṣe ọkọ òun mọ́? Ṣé ó yẹ kí ìjọ ka ìgbéyàwó tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe sí ìgbéyàwó alágbèrè?
Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, ìjọ máa ń ka ìgbéyàwó tí ọkùnrin náà ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe sí ìgbéyàwó alágbèrè torí pé ìyàwó àkọ́kọ́ ṣì wà láàyè, kò tíì lọ́kọ míì, bẹ́ẹ̀ sì ni kò ṣe ìṣekúṣe. Àmọ́ nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa ìkọ̀sílẹ̀ àti fífẹ́ ẹlòmíì, kò sọ̀rọ̀ nípa obìnrin tí ọkọ ẹ̀ ṣàgbèrè. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló ṣàlàyé pé tí ọkùnrin kan bá kọ ìyàwó ẹ̀ sílẹ̀ lọ́nà tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu tó sì fẹ́ ẹlòmíì, àgbèrè ló ṣe yẹn. Torí náà bí Jésù ṣe sọ, ọkùnrin tó kọ aya ẹ̀ sílẹ̀ tó sì fẹ́ obìnrin míì ti ṣe àgbèrè, ìyẹn ló sì fòpin sí ìgbéyàwó tó kọ́kọ́ ṣe.
“Ẹnikẹ́ni tó bá kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀, àfi tó bá jẹ́ torí ìṣekúṣe, tó sì fẹ́ ẹlòmíì ti ṣe àgbèrè.”—Mát. 19:9
Nínú àpẹẹrẹ tá a sọ ṣáájú, ọkùnrin kan ṣàgbèrè, òun àti ìyàwó ẹ̀ sì kọ ara wọn sílẹ̀. Ká ní ọkùnrin yẹn ò ṣàgbèrè, àmọ́ tó já ìwé ìkọ̀sílẹ̀ fún ìyàwó ẹ̀, tó sì fẹ́ ẹlòmíì ńkọ́? Tàbí tó bá ṣẹlẹ̀ pé ọkùnrin kan ò ṣèṣekúṣe kó tó kọ ìyàwó ẹ̀ sílẹ̀, àmọ́ lẹ́yìn tó kọ ìyàwó ẹ̀ sílẹ̀ ló wá ṣèṣekúṣe ńkọ́, tó sì fẹ́ obìnrin míì bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìyàwó ẹ̀ sọ pé òun ti dárí jì í? Nínú gbogbo àpẹẹrẹ yìí, ọkùnrin tó kọ ìyàwó ẹ̀ sílẹ̀ tó sì fẹ́ ẹlòmíì ti ṣe àgbèrè, ìyẹn sì ti fòpin sí ìgbéyàwó tó kọ́kọ́ ṣe. Torí náà, ìgbéyàwó tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe yẹn bófin mu. Ilé Ìṣọ́ May 15, 1980, ojú ìwé 32 sọ pé: ‘Ní báyìí, ó ti ṣe ìgbéyàwó míì, torí náà kò lè fòpin sí ìgbéyàwó náà kó sì pa dà sọ́dọ̀ ìyàwó àkọ́kọ́ torí pé ìkọ̀sílẹ̀, àgbèrè àti ìgbéyàwó tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe ti fòpin sí ìgbéyàwó àkọ́kọ́.’
Òye tuntun tá a ní yìí kò túmọ̀ sí pé a ò fọwọ́ pàtàkì mú ìgbéyàwó tó jẹ́ ohun mímọ́ tàbí pé àgbèrè kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì. Ọkùnrin tó kọ ìyàwó ẹ̀ sílẹ̀ lọ́nà tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu tó sì fẹ́ ẹlòmíì bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò lómìnira láti ṣe bẹ́ẹ̀ máa jẹ́jọ́ níwájú ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́ torí pé àgbèrè ló ṣe yẹn. (Tí ìyàwó tuntun tó fẹ́ náà bá jẹ́ Kristẹni, òun náà á jẹ́jọ́ níwájú ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́ torí pé àgbèrè lòun náà ṣe.) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ò ní ka ìgbéyàwó tuntun náà sí ìgbéyàwó alágbèrè, ọkùnrin náà ò ní láǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọ fún ọ̀pọ̀ ọdún títí dìgbà tí ìwà tó hù yẹn ò fi ní kó ẹ̀dùn ọkàn bá àwọn èèyàn mọ́ tàbí títí dìgbà táwọn èèyàn á bẹ̀rẹ̀ sí í bọ̀wọ̀ fún un. Kí àwọn alàgbà tó lè fún ọkùnrin náà láǹfààní iṣẹ́ ìsìn èyíkéyìí, wọ́n á wo bí nǹkan ṣe rí fún obìnrin tó hùwà àìṣòótọ́ sí àti bí nǹkan ṣe rí fún àwọn ọmọ wọn kéékèèké tó ṣeé ṣe kó já jù sílẹ̀ fún obìnrin náà.—Mál. 2:14-16.
Torí náà, tá a bá ronú lórí aburú tí ìkọ̀sílẹ̀ àti fífẹ́ ẹlòmíì lọ́nà tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu máa ń yọrí sí, ó yẹ kí àwa Kristẹni máa fojú tó tọ́ wo ètò ìgbéyàwó bíi ti Jèhófà, ká sì kà á sí ohun mímọ́.—Oníw. 5:4, 5; Héb. 13:4.
^ ìpínrọ̀ 2 Ká lè lóye ọ̀rọ̀ yìí dáadáa, a máa pe ẹni tó ṣàgbèrè ní ọkùnrin, àá sì pe ẹni tí kò ṣàgbèrè ní obìnrin. Àmọ́ ìmọ̀ràn tí Jésù fún wa lórí ọ̀rọ̀ yìí ní Máàkù 10:11, 12 jẹ́ ká mọ̀ pé bí ọ̀rọ̀ náà ṣe kan ọkùnrin, bẹ́ẹ̀ náà ló kan obìnrin.
^ ìpínrọ̀ 1 Òye tuntun lèyí jẹ́. Ó yàtọ̀ sí èrò tá a ní tẹ́lẹ̀ pé ìgbéyàwó alágbèrè nirú ìgbéyàwó bẹ́ẹ̀ torí pé ìyàwó àkọ́kọ́ tí kò ṣàgbèrè ṣì wà láàyè, kò tíì fẹ́ ọkọ míì, bẹ́ẹ̀ sì ni kò ṣèṣekúṣe.