Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 18

Ẹ Máa Gba Ara Yín Níyànjú Nípàdé Ìjọ

Ẹ Máa Gba Ara Yín Níyànjú Nípàdé Ìjọ

‘Ẹ jẹ́ ká máa gba ti ara wa rò, ká sì máa gba ara wa níyànjú.’​—HÉB. 10:24, 25.

ORIN 88 Mú Mi Mọ Àwọn Ọ̀nà Rẹ

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ a

1. Kí nìdí tá a fi ń dáhùn nípàdé?

 KÍ NÌDÍ tá a fi máa ń lọ sípàdé ìjọ? Ìdí pàtàkì náà ni pé ká lè máa yin Jèhófà. (Sm. 26:12; 111:1) Ìdí míì tá a fi ń lọ sípàdé ni pé ká lè máa gba ara wa níyànjú lákòókò tí nǹkan le gan-an yìí. (1 Tẹs. 5:11) Torí náà, tá a bá nawọ́ láti dáhùn nípàdé, à ń yin Jèhófà nìyẹn, a sì tún ń gba ara wa níyànjú.

2. Àwọn ìgbà wo la lè dáhùn nípàdé?

2 Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, a máa ń láǹfààní láti dáhùn nípàdé. Bí àpẹẹrẹ, a máa ń láǹfààní lópin ọ̀sẹ̀ láti dáhùn nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́. Nígbà ìpàdé àárín ọ̀sẹ̀, a lè dáhùn táwọn ará bá ń sọ Ẹ̀kọ́ Iyebíye tí wọ́n rí nínú Bíbélì àti nígbà Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ. Bákan náà, a máa ń dáhùn nígbà tá a bá ń jíròrò àwọn apá míì tó ní ìbéèrè.

3. Kí ló lè mú kó nira fún wa láti dáhùn nípàdé, báwo sì ni Hébérù 10:24, 25 ṣe lè ràn wá lọ́wọ́?

3 Gbogbo wa la fẹ́ máa yin Jèhófà ká sì máa gba àwọn ará níyànjú. Ṣùgbọ́n, ohun tó lè mú kó nira láti dáhùn nípàdé ni pé ẹ̀rù lè máa bà wá tàbí kó wù wá gan-an láti dáhùn léraléra, àmọ́ kí wọ́n máa fi bẹ́ẹ̀ pè wá. Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè borí àwọn ìṣòro yìí? Ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn Hébérù ló máa ràn wá lọ́wọ́. Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa ìdí pàtàkì tó fi yẹ ká máa lọ sípàdé, ó sọ pé ìdí náà ni pé ká lè “máa gba ara wa níyànjú.” (Ka Hébérù 10:24, 25.) Tá a bá mọ̀ pé bá a ṣe ń dáhùn nípàdé tá a sì ń sọ ohun tá a gbà gbọ́ máa ń gbé àwọn ará ró, a ò ní máa bẹ̀rù láti dáhùn nípàdé. Tí wọn ò bá sì pè wá léraléra, ó yẹ kínú wa máa dùn pé àwọn míì náà láǹfààní láti dáhùn.​—1 Pét. 3:8.

4. Àwọn kókó mẹ́ta wo la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

4 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa ìjọ kékeré, ìyẹn bí àwọn ará tó ń dáhùn nínú ìjọ tí wọn ò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ ṣe lè gba ara wọn níyànjú. Lẹ́yìn náà, a máa sọ̀rọ̀ nípa bá a ṣe lè gba ara wa níyànjú nínú ìjọ ńlá níbi táwọn ará tó pọ̀ ti máa ń nawọ́ kí wọ́n lè dáhùn. Paríparí ẹ̀, a máa sọ̀rọ̀ nípa bá a ṣe lè jẹ́ kí ìdáhùn wa gbé àwọn ará ró.

Ẹ MÁA GBA ARA YÍN NÍYÀNJÚ NÍNÚ ÌJỌ KÉKERÉ

5. Báwo la ṣe lè gba ara wa níyànjú táwọn ará tó wá sípàdé ò bá pọ̀?

5 Nínú ìjọ tàbí àwùjọ táwọn ará tó wà níbẹ̀ ò pọ̀, àwọn díẹ̀ ló máa ń nawọ́ láti dáhùn. Nígbà míì, ẹni tó ń darí ìpàdé máa dúró díẹ̀ kó tó rí àwọn ará tó máa dáhùn. Irú ìpàdé bẹ́ẹ̀ lè sú àwọn ará, kò sì ní gbé wọn ró. Tó o bá wà nírú ìpàdé yẹn, kí lo lè ṣe? Rí i pé ò ń nawọ́ déédéé. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, á jẹ́ káwọn ẹlòmíì náà máa nawọ́ láti dáhùn.

6-7. Tẹ́rù bá ń bà ẹ́ láti dáhùn nípàdé, kí lo lè ṣe?

6 Kí lo lè ṣe tẹ́rù bá ń bà ẹ́ láti dáhùn nípàdé? Ká sòótọ́, ẹ̀rù máa ń ba ọ̀pọ̀ lára wa. Àmọ́, tó o bá fẹ́ kí ìdáhùn ẹ máa gbé àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin ẹ ró, ó yẹ kó o wo ohun tó o lè ṣe kẹ́rù má bà ẹ́ tó o bá fẹ́ dáhùn. Báwo lo ṣe máa ṣe é?

7 O lè rí àwọn ohun tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ nínú àwọn Ilé Ìṣọ́ b tí ètò Ọlọ́run ti ṣe sẹ́yìn. Bí àpẹẹrẹ, múra ìdáhùn ẹ dáadáa. (Òwe 21:5) Bó o bá ṣe múra ohun tẹ́ ẹ fẹ́ kọ́ dáadáa, bẹ́ẹ̀ lọkàn ẹ máa balẹ̀ láti dáhùn. Bákan náà, jẹ́ kí ìdáhùn ẹ ṣe ṣókí. (Òwe 15:23; 17:27) Tí ìdáhùn ẹ bá ṣe ṣókí, ẹ̀rù ò ní bà ẹ́. Ìdáhùn tó ṣe ṣókí tí ò ju gbólóhùn kan tàbí méjì lọ máa ń tètè yé àwọn ará ju ìdáhùn jàn-ànràn jan-anran. Tó o bá dáhùn ṣókí lọ́rọ̀ ara ẹ, ìyẹn fi hàn pé o múra sílẹ̀ dáadáa àti pé ohun tá à ń kọ́ yé ẹ.

8. Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo bá a ṣe ń ṣe gbogbo ohun tágbára wa gbé?

8 Ká sọ pé o tẹ̀ lé gbogbo àwọn àbá tá a sọ yìí, àmọ́ tẹ́rù ṣì ń bà ẹ́ láti dáhùn ju ẹ̀ẹ̀kan lọ ńkọ́? Mọ̀ dájú pé Jèhófà mọyì bó o ṣe ń ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti dáhùn. (Lúùkù 21:1-4) Rántí pé Jèhófà ò retí pé kó o ṣe ju agbára ẹ lọ. (Fílí. 4:5) Ó yẹ kíwọ fúnra ẹ mọ ohun tí agbára ẹ gbé, kó o mọ bó o ṣe máa ṣe é, kó o sì gbàdúrà sí Jèhófà kẹ́rù má bà ẹ́ mọ́. Ohun tó o lè fi bẹ̀rẹ̀ ni pé kó o dáhùn lẹ́ẹ̀kan nípàdé, kó o sì jẹ́ kó ṣe ṣókí.

Ẹ MÁA GBA ARA YÍN NÍYÀNJÚ NÍNÚ ÌJỌ ŃLÁ

9. Kí ló lè mú kó nira fáwọn ará láti dáhùn nínú ìjọ ńlá?

9 Táwọn ará tó wà nínú ìjọ tó o wà bá pọ̀, ó lè má rọrùn fún ẹ láti dáhùn. Ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin lè nawọ́ láti dáhùn, ìyẹn sì lè má jẹ́ kí wọ́n pè ẹ́. Bí àpẹẹrẹ, Arábìnrin Danielle máa ń dáhùn déédéé nípàdé, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kínú ẹ̀ dùn. c Ó mọ̀ pé ọ̀kan lára ọ̀nà tóun ń gbà jọ́sìn Jèhófà nìyẹn, tó jẹ́ kóun lè máa gbé àwọn ará ró, tó sì tún ń jẹ́ kí ìgbàgbọ́ òun túbọ̀ lágbára. Àmọ́ nígbà tó ṣí lọ sí ìjọ táwọn ará ti pọ̀, wọn kì í fi bẹ́ẹ̀ pè é tó bá nawọ́ láti dáhùn. Nígbà míì wọn kì í pè é rárá títí ìpàdé á fi parí. Ó sọ pé: “Ńṣe ló dà bí ìgbà tí àǹfààní ńlá kan bọ́ mọ́ mi lọ́wọ́, nǹkan sì tojú sú mi. Kò sí béèyàn ò ṣe ní rò pé wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ má pe òun ni torí ó ti ń di lemọ́lemọ́.”

10. Kí la lè ṣe ká lè máa dáhùn dáadáa nípàdé?

10 Ṣé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Arábìnrin Danielle ti ṣẹlẹ̀ sí ìwọ náà rí? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé kó o má nawọ́ láti dáhùn mọ́, àmọ́ kó o kàn máa gbọ́ ìdáhùn àwọn ẹlòmíì. Torí náà, má jẹ́ kó sú ẹ láti nawọ́ kó o lè dáhùn. Kí lo lè ṣe? Á dáa kó o múra ìdáhùn tó pọ̀. Tí wọn ò bá pè ẹ́ níbẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ náà, wọ́n ṣì lè pè ẹ́ bẹ́ ẹ ṣe ń bá ẹ̀kọ́ náà lọ. Tó o bá ń múra ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́, ronú nípa bí ìpínrọ̀ kọ̀ọ̀kan ṣe ṣàlàyé àkòrí ẹ̀kọ́ náà. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá lè dáhùn lọ́nà tó máa gbé àwọn ará ró nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Yàtọ̀ síyẹn, o lè múra láti dáhùn àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tó jinlẹ̀ tó lè nira fáwọn ará láti ṣàlàyé. (1 Kọ́r. 2:10) Kí nìdí tó fi yẹ kó o ṣe bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé àwọn tó máa nawọ́ láti dáhùn apá yìí kì í pọ̀. Ká sọ pé o ṣe gbogbo nǹkan yìí, àmọ́ tó o ṣì rí i pé wọn kì í pè ẹ́ ńkọ́? O lè lọ bá ẹni tó ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà kí ìpàdé tó bẹ̀rẹ̀, kó o sì sọ ìpínrọ̀ tó o fẹ́ dáhùn fún un.

11. Kí ni Fílípì 2:4 gbà wá níyànjú pé ká ṣe?

11 Ka Fílípì 2:4. Ẹ̀mí Ọlọ́run darí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti gba àwọn Kristẹni níyànjú pé kí wọ́n máa ṣe ohun tó máa ṣe àwọn èèyàn láǹfààní. Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yìí tá a bá wà nípàdé? Bá a ṣe lè tẹ̀ lé e ni pé ká máa rántí pé àwa nìkan kọ́ ló máa dáhùn nípàdé, ká jẹ́ káwọn ẹlòmíì náà dáhùn.

Tí àwa àtẹnì kan bá jọ ń sọ̀rọ̀, a ò ní máa dá gbogbo ọ̀rọ̀ náà sọ. Bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe yẹ ká máa fún àwọn ará láǹfààní láti dáhùn nípàdé (Wo ìpínrọ̀ 12)

12. Sọ ohun kan tó dáa tá a lè ṣe láti gbé àwọn ará ró nípàdé. (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

12 Rò ó wò ná. Tí ìwọ àti ọ̀rẹ́ ẹ kan bá jọ ń sọ̀rọ̀, ṣé ìwọ nìkan ni wàá máa sọ̀rọ̀ ṣáá àbí wàá fún òun náà láǹfààní láti sọ̀rọ̀? Rárá o, wàá jẹ́ kóun náà sọ̀rọ̀! Lọ́nà kan náà, tá a bá wà nípàdé, dípò ká máa nawọ́ ṣáá, á dáa ká jẹ́ káwọn ẹlòmíì náà dáhùn. Kódà, ọ̀kan lára ohun tá a lè ṣe láti gba àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa níyànjú ni pé, ká fún wọn láǹfààní láti dáhùn kí wọ́n lè sọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́. (1 Kọ́r. 10:24) Ẹ jẹ́ ká wo bá a ṣe lè ṣe é.

13. Kí la lè ṣe káwọn ẹlòmíì lè dáhùn nípàdé?

13 Ohun kan tá a lè ṣe ni pé ká jẹ́ kí ìdáhùn wa ṣe ṣókí, káwọn ẹlòmíì lè dáhùn. Ó yẹ káwọn alàgbà àtàwọn tó ti pẹ́ nínú òtítọ́ fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí. Tí ìdáhùn ẹ bá tiẹ̀ ṣe ṣókí, má sọ kókó tó pọ̀. Tó o bá sọ gbogbo kókó tó wà nínú ìpínrọ̀ náà, àwọn ará ò ní rí nǹkan kan sọ mọ́. Bí àpẹẹrẹ, nínú ìpínrọ̀ yìí wọ́n sọ ohun méjì tá a lè ṣe, wọ́n ní ká jẹ́ kí ìdáhùn wa ṣe ṣókí, ká má sì sọ kókó tó pọ̀. Torí náà, tó bá jẹ́ ìwọ ni wọ́n kọ́kọ́ pè láti dáhùn ní ìpínrọ̀ yìí, ẹyọ kan nínú kókó méjì náà ni kó o sọ.

Ìgbà wo la lè pinnu pé a ò ní nawọ́ láti dáhùn nípàdé? (Wo ìpínrọ̀ 14) f

14. Kí ló máa jẹ́ ká mọ iye ìgbà tó yẹ ká nawọ́ láti dáhùn? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

14 Ó yẹ kó o fòye mọ iye ìgbà tó yẹ kó o nawọ́ láti dáhùn. Tá a bá ń nawọ́ ṣáá, á jẹ́ kí ẹni tó ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà máa rò pé dandan ni kóun pè wá léraléra bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn míì ò tíì dáhùn. Ìyẹn sì lè mú káwọn tí ò tíì dáhùn má nawọ́ mọ́.​—Oníw. 3:7.

15. (a) Kí ni ò yẹ ká ṣe tí wọn ò bá pè wá pé ká dáhùn? (b) Báwo lẹni tó ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ ṣe lè gba tàwọn ará tó ń dáhùn rò? (Wo àpótí náà, “ Tó O Bá Ń Darí Ìpàdé.”)

15 Táwọn ará tó ń nawọ́ láti dáhùn bá pọ̀ nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ kan, a lè má láǹfààní láti dáhùn bá a ṣe fẹ́. Nígbà míì, ẹni tó ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lè má pè wá rárá. Ká sòótọ́, ó lè dùn wá, àmọ́ kò yẹ ká bínú tí wọn ò bá pè wá rárá.​—Oníw. 7:9.

16. Báwo la ṣe lè gbé àwọn ará tó dáhùn nípàdé ró?

16 Tó ò bá láǹfààní láti dáhùn bó o ṣe fẹ́, o ò ṣe fetí sílẹ̀ nígbà táwọn ẹlòmíì bá ń dáhùn kó o lè gbóríyìn fún wọn lẹ́yìn tí ìpàdé bá parí. Tá ò bá tiẹ̀ dáhùn nípàdé àmọ́ tá a gbóríyìn fáwọn ará tó dáhùn, àwa náà ti dáhùn nìyẹn, ìyẹn sì máa gbé wọn ró. (Òwe 10:21) Torí náà, ọ̀nà míì tá a lè gbà gbé àwọn ará ró ni pé ká máa gbóríyìn fún wọn.

ÀWỌN NǸKAN MÍÌ TÁ A LÈ ṢE LÁTI GBA ARA WA NÍYÀNJÚ

17. (a) Báwo làwọn òbí ṣe lè bá àwọn ọmọ wọn múra ìdáhùn tó rọrùn? (b) Àwọn nǹkan mẹ́rin wo ló wà nínú fídíò yẹn tó o máa ṣe tó o bá fẹ́ múra ìdáhùn ẹ? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)

17 Àwọn nǹkan míì wo la lè ṣe láti gbé ara wa ró tá a bá wà nípàdé? Tó o bá jẹ́ òbí, bá àwọn ọmọ ẹ múra ìdáhùn tó máa rọrùn fún wọn láti sọ. (Mát. 21:16) Nígbà míì, àpilẹ̀kọ kan lè dá lórí ìṣòro táwọn tọkọtaya máa ń ní tàbí kó dá lórí ìwà mímọ́, àmọ́ ìpínrọ̀ kan tàbí méjì máa wà níbẹ̀ táwọn ọmọdé ti lè dáhùn. Bákan náà, jẹ́ káwọn ọmọ ẹ mọ̀ pé gbogbo ìgbà tí wọ́n bá nawọ́ kọ́ ni wọ́n máa pè wọ́n. Tó o bá ti ṣàlàyé fún wọn ṣáájú, inú ò ní bí wọn tí wọn ò bá pè wọ́n àmọ́ tí wọ́n pe àwọn ẹlòmíì.​—1 Tím. 6:18. d

18. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa yin ara wa tá a bá ń dáhùn nípàdé? (Òwe 27:2)

18 Gbogbo wa la lè múra ìdáhùn tó máa bọlá fún Jèhófà, tó sì máa gbé àwọn ará ró. (Òwe 25:11) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, a lè sọ ìrírí ara wa ní ṣókí, ó tún yẹ ká ṣọ́ra ká má máa sọ̀rọ̀ nípa ara wa jù. (Ka Òwe 27:2; 2 Kọ́r. 10:18) Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká fi ìdáhùn wa yin Jèhófà lógo, ká fi ṣàlàyé Bíbélì, ká sì tún fi sọ ìrírí àwọn ará wa. (Ìfi. 4:11) Àmọ́ ṣá o, tí ìbéèrè kan bá sọ pé ká sọ̀rọ̀ nípa ara wa, ó yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀. A máa rí àpẹẹrẹ irú ìbéèrè yìí nínú ìpínrọ̀ tó kàn.

19. (a) Àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń gba tàwọn ará rò nípàdé? (Róòmù 1:11, 12) (b) Kí lo rí kọ́ nínú àpilẹ̀kọ yìí nípa bó ṣe yẹ ká máa dáhùn nípàdé?

19 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò sí òfin kan tá à ń tẹ̀ lé nípa bó ṣe yẹ ká dáhùn nípàdé, ẹ jẹ́ ká rí i dájú pé à ń fi ìdáhùn wa gbé àwọn ará ró. O lè dáhùn lọ́pọ̀ ìgbà, àmọ́ jẹ́ kí ìdáhùn ẹ ṣe ṣókí. Tó bá jẹ́ ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lo láǹfààní láti dáhùn, jẹ́ kó tẹ́ ẹ lọ́rùn. Tó bá sì jẹ́ àwọn ẹlòmíì ni wọ́n pè láti dáhùn, jẹ́ kínú ẹ dùn. Torí náà, tá a bá ń gba tàwọn ará rò nígbà tá a bá ń dáhùn nípàdé, a máa “fún ara wa ní ìṣírí.”​—Ka Róòmù 1:11, 12.

ORIN 93 Bù Kún Ìpàdé Wa

a A máa ń gba ara wa níyànjú tá a bá dáhùn nípàdé ìjọ. Àmọ́ ẹ̀rù máa ń ba àwọn kan láti dáhùn nípàdé. Inú àwọn kan sì máa ń dùn láti dáhùn, torí náà wọ́n máa ń fẹ́ kí wọ́n pè wọ́n léraléra. Bóyá ẹ̀rù máa ń bà wá láti dáhùn tàbí ẹ̀rù kì í bà wá, báwo la ṣe lè fi hàn pé à ń gba ti ara wa rò ká lè fún ara wa níṣìírí? Báwo la ṣe lè fi ìdáhùn wa gbé àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa ró kí wọ́n lè nífẹ̀ẹ́ ara wọn, kí wọ́n sì máa ṣe iṣẹ́ rere? A máa rí ìdáhùn àwọn ìbéèrè yẹn nínú àpilẹ̀kọ yìí.

c A ti yí orúkọ rẹ̀ pa dà.

f ÀWÒRÁN: Nínú ìjọ táwọn ará ti pọ̀, arákùnrin kan tó ti dáhùn fún àwọn tí ò tíì dáhùn láǹfààní láti dáhùn.