ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 16
“Arákùnrin Rẹ Máa Dìde”!
“Jésù sọ fún [Màtá] pé: ‘Arákùnrin rẹ máa dìde.’” —JÒH. 11:23.
ORIN 151 Òun Yóò Pè
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ a
1. Báwo ni ọmọdékùnrin kan ṣe fi hàn pé òun nírètí pé àwọn òkú máa jíǹde?
ỌMỌDÉKÙNRIN kan tó ń jẹ́ Matthew ní àìsàn tó le gan-an, ó sì gba pé kí wọ́n ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ abẹ fún un. Nígbà tó wà lọ́mọ ọdún méje, òun àti ìdílé ẹ̀ ń wo ètò Tẹlifíṣọ̀n JW olóṣooṣù. Nígbà tó kù díẹ̀ kí wọ́n wo ètò náà parí, wọ́n gbádùn fídíò orin tó jẹ́ ká rí bá a ṣe máa kí àwọn èèyàn wa káàbọ̀ nígbà tí wọ́n bá jíǹde. b Nígbà tí wọ́n wo ètò náà tán, Matthew lọ bá àwọn òbí ẹ̀, ó di àwọn méjèèjì lọ́wọ́ mú, ó sì sọ pé: “Dádì àti mọ́mì mi, ṣé ẹ rí i pé tí mo bá tiẹ̀ kú, màá jíǹde? Ẹ kàn máa dúró dè mí ni, ẹ má bẹ̀rù rárá.” Ẹ wo bí inú àwọn òbí yẹn ṣe máa dùn tó nígbà tí wọ́n rí ìgbàgbọ́ tó lágbára tí ọmọ wọn ní pé àwọn òkú máa jíǹde.
2-3. Kí nìdí tó fi dáa ká máa ronú nípa àjíǹde àwọn òkú tí Ọlọ́run ṣèlérí?
2 Látìgbàdégbà, ó yẹ kí gbogbo wa máa ronú nípa àjíǹde àwọn òkú tí Bíbélì sọ pé ó máa wáyé lọ́jọ́ iwájú. (Jòh. 5:28, 29) Kí nìdí? Ìdí ni pé a ò mọ ìgbà tí àìsàn tó le gan-an lè ṣe wá tàbí ìgbà tí èèyàn wa kan lè kú lójijì. (Oníw. 9:11; Jém. 4:13, 14) Ìrètí tá a ní pé àwọn òkú máa jíǹde máa jẹ́ ká fara da irú àwọn ìṣòro bẹ́ẹ̀. (1 Tẹs. 4:13) Ìwé Mímọ́ fi dá wa lójú pé Bàbá wa ọ̀run mọ̀ wá dáadáa, ó sì nífẹ̀ẹ́ wa gan-an. (Lúùkù 12:7) Jèhófà Ọlọ́run mọ̀ wá dáadáa débi pé tó bá máa jí àwọn tó kú dìde, irú ẹni tí wọ́n jẹ́ ò ní yí pa dà, wọ́n á sì rántí gbogbo ohun tí wọ́n mọ̀ kí wọ́n tó kú. Ẹ ò rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an torí ó fún wa láǹfààní láti wà láàyè títí láé. Kódà tá a bá kú, ó máa jí wa dìde!
3 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa ìdí tó fi yẹ ká gbà pé àjíǹde tí Ọlọ́run ṣèlérí máa wáyé. Lẹ́yìn náà, a máa sọ̀rọ̀ nípa ìtàn Bíbélì kan tó máa jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára pé àwọn òkú máa jíǹde. Ó dá lórí àkòrí àpilẹ̀kọ yìí, ó ní: “Arákùnrin rẹ máa dìde.” (Jòh. 11:23) A tún máa sọ̀rọ̀ nípa bá a ṣe lè jẹ́ kí àjíǹde ọjọ́ iwájú túbọ̀ dá wa lójú.
ÌDÍ TÓ FI YẸ KÁ NÍGBÀGBỌ́ PÉ ÀJÍǸDE MÁA WÁYÉ
4. Ká tó lè gba ìlérí kan gbọ́, kí ló gbọ́dọ̀ dá wa lójú? Sọ àpèjúwe kan.
4 Ká tó lè gba ìlérí kan gbọ́, ó gbọ́dọ̀ dá wa lójú pé ẹni tó ṣèlérí náà ní agbára láti mú ìlérí ẹ̀ ṣẹ, ó sì wù ú láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ẹ wo àpèjúwe yìí náà: Ká sọ pé ìjì kan jà, ó sì wó ilé ẹ. Ni ọ̀rẹ́ ẹ kan bá wá sọ́dọ̀ ẹ, ó sì ṣèlérí fún ẹ pé, ‘Màá bá ẹ tún ilé ẹ kọ́.’ O mọ̀ pé òótọ́ ló sọ, ó sì dájú pé ó fẹ́ ràn ẹ́ lọ́wọ́. Tó bá jẹ́ kọ́lékọ́lé tó mọṣẹ́ ni, tó sì láwọn irinṣẹ́ tó dáa, á dá ẹ lójú pé ó lè tún ilé náà kọ́. Torí náà, wàá gba ìlérí tó ṣe fún ẹ gbọ́. Bí ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé òun máa jí àwọn òkú dìde ṣe rí náà nìyẹn. Àmọ́, ṣé ó wu Ọlọ́run láti mú ìlérí ẹ̀ ṣẹ? Ṣé ó sì lágbára láti ṣe é?
5-6. Kí ló jẹ́ kó dá wa lójú pé ó wu Jèhófà láti jí àwọn òkú dìde?
5 Ṣé ó wu Jèhófà láti jí àwọn òkú dìde? Bẹ́ẹ̀ ni, ó wù ú. Ó fi ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀ darí àwọn kan tó kọ Bíbélì pé kí wọ́n ṣàkọsílẹ̀ ìlérí tí òun ṣe pé òun máa jí àwọn òkú dìde lọ́jọ́ iwájú. (Àìsá. 26:19; Hós. 13:14; Ìfi. 20:11-13) Gbogbo ìgbà tí Jèhófà bá sì ṣèlérí ló máa ń mú un ṣẹ. (Jóṣ. 23:14) Torí náà, ó wu Jèhófà láti jí àwọn òkú dìde. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀?
6 Ẹ jẹ́ ká gbé ohun tí Jóòbù sọ yẹ̀ wò. Ó dá Jóòbù lójú pé tóun bá tiẹ̀ kú, Jèhófà máa jí òun dìde. (Jóòbù 14:14, 15, àlàyé ìsàlẹ̀) Bó ṣe ń wu Jèhófà náà nìyẹn láti jí gbogbo àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ tó ti kú dìde. Ó wù ú kó jí wọn dìde, kí wọ́n ní ìlera tó jí pépé, kí wọ́n sì máa láyọ̀. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí àìmọye èèyàn tí wọn ò láǹfààní láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà kí wọ́n tó kú? Ọlọ́run tó nífẹ̀ẹ́ wa máa jí àwọn náà dìde. (Ìṣe 24:15) Ó fẹ́ káwọn náà di ọ̀rẹ́ òun, kí wọ́n sì máa gbé ayé títí láé. (Jòh. 3:16) Torí náà, ó dájú pé ó wu Jèhófà láti jí àwọn tó ti kú dìde.
7-8. Kí ló jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà lágbára láti jí àwọn òkú dìde?
7 Ṣé Jèhófà lágbára láti jí àwọn òkú dìde? Bẹ́ẹ̀ ni! Ó lágbára láti ṣe bẹ́ẹ̀ torí òun ni “Olódùmarè.” (Ìfi. 1:8) Ó lágbára láti ṣẹ́gun ọ̀tá èyíkéyìí títí kan ikú. (1 Kọ́r. 15:26) Ìyẹn ń fún wa lókun, ó sì ń jẹ́ kọ́kàn wa balẹ̀. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Arábìnrin Emma Arnold. Àwọn nǹkan kan dán ìgbàgbọ́ òun àti ìdílé ẹ̀ wò nígbà Ogun Àgbáyé Kejì. Nígbà tó ń tu ọmọbìnrin ẹ̀ nínú torí àwọn èèyàn wọn tó kú ní àgọ́ Násì tí wọ́n ti ń fìyà jẹ wọ́n, ó sọ pé: “Tí àwọn èèyàn tó ti kú ò bá lè jí dìde mọ́, á jẹ́ pé ikú lágbára ju Ọlọ́run lọ nìyẹn.” Àmọ́ ikú ò lágbára rárá lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Ó dá wa lójú pé kò sóhun tó lágbára ju Jèhófà lọ! Torí náà, Ọlọ́run tó dá wa lágbára láti jí àwọn tó ti kú dìde.
8 Ìdí míì tó jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run lágbára láti jí àwọn òkú dìde ni pé kì í gbàgbé nǹkan. Bí àpẹẹrẹ, ó mọ orúkọ gbogbo àwọn ìràwọ̀. (Àìsá. 40:26) Bákan náà, Jèhófà ò gbàgbé àwọn tó ti kú. (Jóòbù 14:13; Lúùkù 20:37, 38) Ó máa rántí kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa àwọn tó fẹ́ jí dìde títí kan bí wọ́n ṣe rí, ìwà wọn àtàwọn nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ sí wọn.
9. Kí nìdí tó o fi gba ìlérí tí Jèhófà ṣe gbọ́ pé òun máa jí àwọn òkú dìde lọ́jọ́ iwájú?
9 A lè gba ìlérí tí Jèhófà ṣe gbọ́ pé òun máa jí àwọn òkú dìde lọ́jọ́ iwájú torí ó dá wa lójú pé ó wù ú, ó sì lágbára láti mú ìlérí ẹ̀ ṣẹ. Ìdí míì tá a fi gbà pé Jèhófà máa mú ìlérí ẹ̀ ṣẹ ni pé ó ti jí àwọn èèyàn dìde láwọn ìgbà kan. Lákòókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì, Jèhófà fún àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ ẹ̀ kan lágbára láti jí òkú dìde, Jésù sì wà lára àwọn tó fún lágbára yìí. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ọ̀kan lára àwọn tí Jésù jí dìde bó ṣe wà nínú Jòhánù orí kọkànlá.
Ọ̀RẸ́ JÉSÙ TÍMỌ́TÍMỌ́ KÚ
10. Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jésù ń wàásù ní Bẹ́tánì ní òdìkejì Jọ́dánì, kí ló sì ṣe? (Jòhánù 11:1-3)
10 Ka Jòhánù 11:1-3. Fojú inú wo nǹkan tó ṣẹlẹ̀ ní Bẹ́tánì nígbà tí ọdún 32 S.K. ń parí lọ. Jésù láwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ ní abúlé yìí. Àwọn ni Lásárù pẹ̀lú àwọn ẹ̀gbọ́n ẹ̀ méjì, ìyẹn Màríà àti Màtá. (Lúùkù 10:38-42) Àmọ́, ara Lásárù ò yá, ọkàn àwọn ẹ̀gbọ́n ẹ̀ ò sì balẹ̀. Àwọn ẹ̀gbọ́n ẹ̀ wá ránṣẹ́ sí Jésù nígbà tó wà ní òdìkejì Jọ́dánì, ìyẹn sì máa gba ìrìn ọjọ́ méjì láti Bẹ́tánì. (Jòh. 10:40) Àmọ́, ó ṣeni láàánú pé Lásárù kú kí ẹni tí wọ́n rán níṣẹ́ tó dé ọ̀dọ̀ Jésù. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jésù mọ̀ pé ọ̀rẹ́ òun ṣẹ̀ṣẹ̀ kú, ó ṣì lo ọjọ́ méjì ní òdìkejì Jọ́dánì kó tó wá sí Bẹ́tánì. Nígbà tí Jésù máa dé, ó ti pé ọjọ́ mẹ́rin tí Lásárù ti kú. Torí náà, ó wu Jésù kó ṣe nǹkan tó máa ṣe àwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ láǹfààní, táá sì jẹ́ káwọn èèyàn yin Ọlọ́run lógo.—Jòh. 11:4, 6, 11, 17.
11. Ẹ̀kọ́ wo làwa àtàwọn ọ̀rẹ́ wa kọ́ nínú ìtàn yìí?
11 Àwa àtàwọn ọ̀rẹ́ wa lè kọ́ ẹ̀kọ́ pàtàkì nínú ìtàn yìí. Ẹ kíyè sí i pé nígbà tí Màríà àti Màtá ránṣẹ́ sí Jésù, wọn ò sọ pé kó wá sí Bẹ́tánì. Wọ́n kàn ránṣẹ́ sí i pé ọ̀rẹ́ ẹ̀ tímọ́tímọ́ ń ṣàìsàn. (Jòh. 11:3) Lóòótọ́, nígbà tí Jésù wà ní òdìkejì Jọ́dánì, ó lè jí Lásárù tó ti kú ní Bẹ́tánì dìde, àmọ́ kò ṣe bẹ́ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló gbéra lọ sí Bẹ́tánì níbi tí Màríà àti Màtá tó jẹ́ ọ̀rẹ́ ẹ̀ ń gbé. Ṣé ìwọ náà ní ọ̀rẹ́ kan tó ṣe tán láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ nígbà ìṣòro tó ò bá tiẹ̀ sọ fún un? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, o lẹ́ni tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ ní “ìgbà wàhálà” nìyẹn. (Òwe 17:17) Bíi ti Jésù, ó yẹ káwa náà jẹ́ ọ̀rẹ́ àtàtà. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká tún wo ohun míì tó ṣẹlẹ̀ nínú ìtàn yẹn.
12. Ìlérí wo ni Jésù ṣe fún Màtá, kí sì nìdí tó fi yẹ kó gba ìlérí náà gbọ́? (Jòhánù 11:23-26)
12 Ka Jòhánù 11:23-26. Nígbà tí Màtá gbọ́ pé Jésù ti sún mọ́ Bẹ́tánì, ó jáde lọ pàdé ẹ̀, ó sì sọ pé: “Olúwa, ká ní o wà níbí ni, arákùnrin mi ì bá má kú.” (Jòh. 11:21) Ká sòótọ́, nígbà tí Lásárù ń ṣàìsàn, Jésù lè wò ó sàn. Àmọ́ ohun àrà kan wà lọ́kàn Jésù tó fẹ́ ṣe. Jésù wá ṣèlérí fún Màtá pé: “Arákùnrin rẹ máa dìde.” Ó tún sọ nǹkan míì tó fi yẹ kí Màtá gba ìlérí òun gbọ́, ó ní: “Èmi ni àjíǹde àti ìyè.” Bẹ́ẹ̀ ni, Ọlọ́run ti fún Jésù lágbára láti jí àwọn òkú dìde. Ṣáájú ìgbà yẹn, ọmọdébìnrin kan kú, kò sì pẹ́ lẹ́yìn tó kú tí Jésù jí i dìde. Yàtọ̀ síyẹn, Jésù jí ọ̀dọ́kùnrin kan dìde lọ́jọ́ tó kú. (Lúùkù 7:11-15; 8:49-55) Àmọ́, ṣé ó lè jí ẹni tó ti pé ọjọ́ mẹ́rin tó ti kú dìde, tí òkú ẹ̀ á sì ti máa jẹrà?
“LÁSÁRÙ, JÁDE WÁ!”
13. Bó ṣe wà nínú Jòhánù 11:32-35, kí ni Jésù ṣe nígbà tó rí Màríà àtàwọn èèyàn tó ń sunkún? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
13 Ka Jòhánù 11:32-35. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí Màtá bá Jésù sọ̀rọ̀. Màríà náà jáde lọ pàdé Jésù. Ohun tí Màtá sọ lòun náà sọ, ó ní: “Olúwa, ká ní o wà níbí ni, arákùnrin mi ì bá má kú.” Ẹ̀dùn ọkàn bá Màríà àtàwọn èèyàn tó wà lọ́dọ̀ ẹ̀. Nígbà tí Jésù rí wọn tí wọ́n ń sunkún, inú ẹ̀ bà jẹ́ gan-an. Àánú àwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ ṣe é, òun náà sì bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún. Jésù mọ̀ pé ó máa ń dun èèyàn gan-an tí èèyàn ẹni bá kú. Ó dájú pé ó wu Jésù gan-an kó ṣe ohun tí ò ní jẹ́ kí wọ́n sunkún mọ́!
14. Kí la rí kọ́ lára Jèhófà nínú ohun tí Jésù ṣe nígbà tí Màríà ń sunkún?
14 Ohun tí Jésù ṣe nígbà tí Màríà ń sunkún kọ́ wa pé Ọlọ́run tó lójú àánú ni Jèhófà. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, ohun tá a kọ́ ni pé Jésù máa ń ronú, ó sì máa ń mọ nǹkan lára bíi ti Bàbá ẹ̀. (Jòh. 12:45) Torí náà, nígbà tá a kà nípa Jésù pé àánú àwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ tó ń ṣọ̀fọ̀ ṣe é débi pé ó sunkún, ìyẹn jẹ́ ká rí i pé àánú àwa náà máa ń ṣe Jèhófà tí ìbànújẹ́ bá dorí wa kodò. (Sm. 56:8) Ṣé kò wù ẹ́ kó o túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run tó lójú àánú yìí?
15. Bó ṣe wà nínú Jòhánù 11:41-44, sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jésù dé ibojì Lásárù. (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
15 Ka Jòhánù 11:41-44. Nígbà tí Jésù dé ibojì Lásárù, ó ní kí wọ́n yí òkúta ẹnu ibojì náà kúrò. Ni Màtá bá sọ pé kí wọ́n má ṣe bẹ́ẹ̀ torí òkú Lásárù á ti máa rùn. Jésù wá sọ pé: “Ṣebí mo sọ fún ọ pé tí o bá gbà gbọ́, o máa rí ògo Ọlọ́run?” (Jòh. 11:39, 40) Ni Jésù bá gbé ojú ẹ̀ sókè, ó sì gbàdúrà níṣojú gbogbo èèyàn. Ìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ó fẹ́ káwọn èèyàn yin Ọlọ́run lógo lẹ́yìn tóun bá jí Lásárù dìde. Jésù wá kígbe pé: “Lásárù, jáde wá!” Lásárù sì jáde látinú ibojì! Ohun tí Jésù ṣe yìí ya àwọn èèyàn lẹ́nu torí wọ́n rò pé kò lè ṣeé ṣe.—Wo àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Jòh. 11:17, nwtsty-E.
16. Báwo ni ìtàn tó wà nínú Jòhánù orí 11 ṣe jẹ́ kí ìgbàgbọ́ tá a ní pé àwọn òkú máa jíǹde túbọ̀ lágbára?
16 Ìtàn tó wà nínú Jòhánù orí 11 jẹ́ kí ìgbàgbọ́ tá a ní pé àwọn òkú máa jíǹde túbọ̀ lágbára. Lọ́nà wo? Ṣẹ́ ẹ rántí ìlérí tí Jésù ṣe fún Màtá. Ó sọ pé: “Arákùnrin rẹ máa dìde.” (Jòh. 11:23) Bíi ti Bàbá ẹ̀, ó wu Jésù pé kó mú ìlérí yìí ṣẹ, ó sì lágbára láti ṣe é. Bí Jésù ṣe sunkún fi hàn pé ó wù ú kó jí àwọn tó ti kú dìde, kó sì mú ìbànújẹ́ tí ikú fà kúrò. Nígbà tí Jésù jí Lásárù dìde, tó sì jáde látinú ibojì, Jésù tún fi hàn lẹ́ẹ̀kan sí i pé òun lágbára láti jí àwọn òkú dìde. Ẹ tún ronú nípa ohun tí Jésù sọ nígbà tó rán Màtá létí pé: “Ṣebí mo sọ fún ọ pé tí o bá gbà gbọ́, o máa rí ògo Ọlọ́run?” (Jòh. 11:40) Àwọn nǹkan tí Jésù ṣe yìí jẹ́ ká gbà pé Ọlọ́run máa mú ìlérí ẹ̀ ṣẹ pé òun máa jí àwọn òkú dìde. Àmọ́ kí ló yẹ ká ṣe kó lè túbọ̀ dá wa lójú pé àwọn òkú máa jíǹde?
BÁ A ṢE LÈ JẸ́ KÍ ÀJÍǸDE ÀWỌN ÒKÚ TÚBỌ̀ DÁ WA LÓJÚ
17. Kí ló yẹ ká máa rántí tá a bá kà nípa àwọn àjíǹde tó wáyé nínú Bíbélì?
17 Máa ka àwọn ìtàn àjíǹde tó wáyé nígbà àtijọ́, kó o sì máa ṣàṣàrò lórí wọn. Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa èèyàn mẹ́jọ tí wọ́n jí dìde nígbà àtijọ́. c O ò ṣe fara balẹ̀ ka ìtàn àjíǹde kọ̀ọ̀kan? Bó o ṣe ń ka àwọn ìtàn náà, máa rántí pé ìtàn àwọn ọkùnrin, obìnrin àtàwọn ọmọdé tó ti gbé ayé rí lò ń kà. Wo àwọn ẹ̀kọ́ tó o lè rí kọ́ níbẹ̀. Ronú nípa bí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn àjíǹde yẹn ṣe fi hàn pé ó wu Ọlọ́run láti jí àwọn òkú dìde, ó sì lágbára láti ṣe é. Àmọ́ ó tún yẹ kó o ronú nípa àjíǹde tó ṣe pàtàkì jù lọ, ìyẹn àjíǹde Jésù. Rántí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ló rí Jésù lẹ́yìn tó jíǹde, ìyẹn sì jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára pé àwọn òkú máa jíǹde.—1 Kọ́r. 15:3-6, 20-22.
18. Báwo lo ṣe lè lo àwọn orin ètò Ọlọ́run tó sọ̀rọ̀ nípa àjíǹde àwọn òkú? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
18 Máa gbọ́ “àwọn orin ẹ̀mí” tó sọ̀rọ̀ nípa àjíǹde àwọn òkú. d (Éfé. 5:19) Àwọn orin ẹ̀mí tí ètò Ọlọ́run ṣe máa ń jẹ́ kí àjíǹde túbọ̀ dá wa lójú, ó sì máa ń jẹ́ kígbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára pé àwọn òkú máa jíǹde. Máa gbọ́ àwọn orin náà, máa kọ wọ́n kó o lè mọ̀ ọ́ kọ dáadáa, kó o sì sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọ̀rọ̀ inú orin náà nígbà ìjọsìn ìdílé yín. Rí i dájú pé o mọ àwọn ọ̀rọ̀ orin náà sórí, kó sì wà lọ́kàn ẹ. Tí ìṣòro kan tó le bá dé bá ẹ tàbí tí èèyàn ẹ kan bá kú, ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè rántí àwọn ọ̀rọ̀ inú orin náà. Wọ́n á tù ẹ́ nínú, wàá sì lókun.
19. Àwọn nǹkan wo la lè fojú inú wò pé ó máa ṣẹlẹ̀ nígbà táwọn òkú bá ń jíǹde? (Wo àpótí náà “ Kí Lo Máa Bi Wọ́n?”)
19 Máa fojú inú wo nǹkan. Jèhófà ti dá a mọ́ wa pé ká máa fojú inú wo nǹkan. Torí náà, a lè fojú inú wo ara wa pé a wà nínú ayé tuntun. Arábìnrin kan sọ pé: “Mo máa ń lo ọ̀pọ̀ àkókò láti fojú inú wo ara mi pé mo wà nínú ayé tuntun, mo sì máa ń rí ara mi bíi pé mò ń gbóòórùn àwọn òdòdó nínú Párádísè.” Ẹ wo bó ṣe máa rí nígbà yẹn tá a bá rí àwọn olóòótọ́ ọkùnrin àti obìnrin ìgbà àtijọ́. Ta ló ń wù ẹ́ láti bá sọ̀rọ̀ lára wọn? Àwọn ìbéèrè wo ni wàá fẹ́ bi ẹni náà? Tún fojú inú wo bí ìwọ àti àwọn èèyàn ẹ tó ti kú ṣe máa pa dà rí ara yín. Fojú inú wo nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ tẹ́ ẹ bá kọ́kọ́ ríra yín, irú bí àwọn ọ̀rọ̀ tẹ́ ẹ máa kọ́kọ́ sọ, bẹ́ ẹ ṣe máa dì mọ́ ara yín àti omijé ayọ̀ tó máa bọ́ lójú yín.
20. Kí la pinnu pé a máa ṣe?
20 A mà dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà ò torí ìlérí tó ṣe pé òun máa jí àwọn òkú dìde. Ó dá wa lójú pé Jèhófà máa mú ìlérí ẹ̀ ṣẹ torí ó wù ú, ó sì lágbára láti ṣe é. Torí náà, jẹ́ kí ìgbàgbọ́ tó o ní pé àwọn òkú máa jíǹde túbọ̀ máa lágbára. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run tó ṣèlérí fún ẹ pé ‘Àwọn èèyàn ẹ máa jíǹde!’
ORIN 147 Ọlọ́run Ṣèlérí Ìyè Àìnípẹ̀kun
a Tí èèyàn ẹ kan bá ti kú, ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé àwọn òkú máa jíǹde máa tù ẹ́ nínú gan-an. Àmọ́, báwo lo ṣe máa ṣàlàyé ìdí tó o fi gba ìlérí yẹn gbọ́? Báwo lo ṣe máa jẹ́ kí ìgbàgbọ́ tó o ní pé àwọn òkú máa jíǹde túbọ̀ lágbára? Ìdí tá a fi kọ àpilẹ̀kọ yìí ni pé ó máa jẹ́ kí ìgbàgbọ́ tá a ní pé àwọn òkú máa jíǹde túbọ̀ lágbára.
b Àkòrí fídíò orin náà ni Ó Ti Fẹ́rẹ̀ẹ́ Dé Tán, tó wà nínú ètò JW Broadcasting® ti November 2016.
c Wo àpótí náà “Àjíǹde Mẹ́jọ Tí Bíbélì Mẹ́nu Kàn” nínú Ilé Ìṣọ́ August 1, 2015, ojú ìwé 4.
d Wo àwọn orin yìí nínú ìwé orin “Fi Ayọ̀ Kọrin” sí Jèhófà: “Fojú Inú Wo Ìgbà Tí Gbogbo Nǹkan Máa Di Tuntun” (Orin 139), “Tẹjú Mọ́ Èrè Náà!” (Orin 144) àti “Òun Yóò Pè” (Orin 151). Tún wo ìkànnì jw.org kó o lè rí àwọn orin wa míì, irú bí “Ó Ti Fẹ́rẹ̀ẹ́ Dé Tán,” “Ayé Tuntun” àti “Ìlérí Ọlọ́run Máa Ṣẹ.”