ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 19
Báwo La Ṣe Lè Jẹ́ Kí Ìgbàgbọ́ Wa Túbọ̀ Lágbára Pé Ayé Tuntun Máa Dé?
‘Tí Jèhófà bá sọ ohun kan, ṣé kò ní ṣe é?’ —NỌ́Ń. 23:19.
ORIN 142 Ká Jẹ́ Kí Ìrètí Wa Lágbára
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ a
1-2. Kí ló yẹ ká máa ṣe bá a ṣe ń retí kí ayé tuntun dé?
INÚ wa dùn pé Jèhófà ṣèlérí pé òun máa sọ ayé burúkú yìí di Párádísè táwọn olódodo á máa gbé. (2 Pét. 3:13) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ò mọ ọjọ́ tí ayé tuntun máa dé, àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé báyìí fi hàn pé ayé tuntun ti dé tán.—Mát. 24:32-34, 36; Ìṣe 1:7.
2 Torí náà, bó ti wù kó pẹ́ tó tá a ti ń sin Jèhófà, ó yẹ kí gbogbo wa túbọ̀ nígbàgbọ́ pé ìlérí rẹ̀ máa ṣẹ. Kí nìdí? Ìdí ni pé tá ò bá ṣọ́ra, ìgbàgbọ́ wa lè má lágbára mọ́. Kódà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pe àìnígbàgbọ́ ní “ẹ̀ṣẹ̀ tó máa ń wé mọ́ wa tìrọ̀rùn-tìrọ̀rùn.” (Héb. 12:1) Torí náà, tá a bá fẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ máa lágbára, ó yẹ ká máa ronú jinlẹ̀ lórí àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé ayé tuntun ò ní pẹ́ dé.—Héb. 11:1.
3. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
3 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa nǹkan mẹ́ta táá jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára pé ayé tuntun tí Jèhófà ṣèlérí máa dé. Àwọn nǹkan náà ni: (1) ká máa ronú nípa bí Jèhófà ṣe fi Ọmọ ẹ̀ rà wá pa dà, (2) ká máa ronú nípa bí agbára Jèhófà ṣe pọ̀ tó àti (3) ká máa ṣe àwọn nǹkan táá jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. A tún máa sọ̀rọ̀ nípa bí ohun tí Jèhófà sọ fún Hábákúkù ṣe jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára lónìí. Àmọ́, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìṣòro tá a ní báyìí tó gba pé ká túbọ̀ nígbàgbọ́ tó lágbára pé ayé tuntun tí Jèhófà ṣèlérí máa dé.
ÀWỌN NǸKAN TÓ GBA PÉ KÁ NÍGBÀGBỌ́ TÓ LÁGBÁRA
4. Àwọn ìpinnu wo la máa ń ṣe tó gba pé ká nígbàgbọ́ tó lágbára?
4 Lójoojúmọ́, a máa ń ṣe àwọn ìpinnu tó gba pé ká nígbàgbọ́ tó lágbára. Bí àpẹẹrẹ, a máa ń ṣe ìpinnu lórí irú ẹni tá a máa bá ṣọ̀rẹ́, irú eré ìnàjú tá a máa ṣe, ilé ẹ̀kọ́ gíga, ìgbéyàwó, bóyá a máa bímọ àti irú iṣẹ́ tá a máa ṣe. Torí náà, á dáa ká bi ara wa pé: ‘Ṣé àwọn nǹkan tí mò ń ṣe fi hàn pé mo gbà pé ayé burúkú yìí ò ní pẹ́ pa run, tí ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí sì máa rọ́pò ẹ̀? Àbí àwọn nǹkan tí mò ń ṣe fi hàn pé mo dà bí àwọn tó ń jayé orí wọn, tí wọ́n sì ń sọ pé táwọn bá ti kú, ó parí nìyẹn?’ (Mát. 6:19, 20; Lúùkù 12:16-21) Torí náà, ìpinnu tó dáa là á máa ṣe, tá a bá gbà pé ayé tuntun ti dé tán.
5-6. Kí nìdí tó fi yẹ ká nígbàgbọ́ tó lágbára tí ìṣòro bá dé? Ṣàpèjúwe.
5 Nígbà míì, àwọn ìṣòro máa ń dé bá wa tó gba pé ká nígbàgbọ́ tó lágbára. Ó lè jẹ́ pé à ń fara da inúnibíni, àìsàn kan tó le gan-an tàbí àwọn ìṣòro míì tó ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wa. Tí ìṣòro náà bá kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀, a lè máa rò pé a lè fara dà á. Àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, ìṣòro náà kì í tètè lọ. Tó bá ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀, ó máa gba pé ká nígbàgbọ́ tó lágbára ká lè fara dà á, ká sì lè máa sin Jèhófà nìṣó.—Róòmù 12:12; 1 Pét. 1:6, 7.
6 Tá a bá níṣòro, a lè máa rò pé ayé tuntun tí Jèhófà ṣèlérí ò ní dé láé. Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé a ò nígbàgbọ́ tó lágbára? Ó lè má jẹ́ bẹ́ẹ̀. Wo àpèjúwe yìí ná. Ká sọ pé òjò ti ń rọ̀ láti nǹkan bí ọ̀sẹ̀ mélòó kan, a lè rò pé oòrùn ò ní ràn mọ́. Lọ́nà kan náà, tí ìṣòro bá dorí wa kodò, a lè rò pé ayé tuntun ò ní dé mọ́. Torí náà, tá a bá nígbàgbọ́ tó lágbára, á dá wa lójú pé Ọlọ́run máa mú àwọn ìlérí ẹ̀ ṣẹ. (Sm. 94:3, 14, 15; Héb. 6:17-19) Ohun tó dá wa lójú yìí máa ń jẹ́ ká fi ìjọsìn Jèhófà sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé wa.
7. Èrò tí ò tọ́ wo la ò gbọ́dọ̀ gbà láàyè?
7 Ẹ jẹ́ ká tún wo nǹkan míì tó gba pé ká nígbàgbọ́ tó lágbára, ìyẹn iṣẹ́ ìwàásù. Ọ̀pọ̀ èèyàn tá à ń wàásù “ìhìn rere” fún pé ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí máa dé rò pé àlá tí ò lè ṣẹ ni. (Mát. 24:14; Ìsík. 33:32) Ó yẹ ká ṣọ́ra, ká má ṣiyèméjì bíi tiwọn. Torí náà, tá ò bá fẹ́ kíyẹn ṣẹlẹ̀, a gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa nǹkan mẹ́ta tá a lè ṣe.
MÁA RONÚ NÍPA ÌRÀPADÀ
8-9. Tá a bá ń ronú nípa ìràpadà, báwo ló ṣe máa jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára?
8 Ọ̀nà kan tá a lè gbà mú kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára ni pé ká máa ronú lórí bí Ọlọ́run ṣe fi Ọmọ ẹ̀ rà wá pa dà. Ìràpadà jẹ́ kó dá wa lójú pé Ọlọ́run máa mú àwọn ìlérí ẹ̀ ṣẹ. Tá a bá ronú dáadáa lórí ìdí tí Ọlọ́run fi pèsè ìràpadà àtohun tó ṣe kí ìràpadà náà lè ṣeé ṣe, ìgbàgbọ́ wa máa túbọ̀ lágbára pé ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí máa dé níbi tá ò ti ní kú mọ́. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀?
9 Kí ni Jèhófà ṣe láti rà wá pa dà? Jèhófà rán àkọ́bí ẹ̀ tó nífẹ̀ẹ́ gan-an, tó sún mọ́ ọn jù lọ látọ̀run kí wọ́n lè bí i sáyé ní ẹni pípé. Nígbà tí Jésù wá sáyé, ó fara da onírúurú ìṣòro tó dé bá a. Lẹ́yìn náà, ìyà jẹ ẹ́, ó sì kú ikú oró. Ẹ ò rí i pé nǹkan kékeré kọ́ ni Jèhófà ṣe láti rà wá pa dà! Tó bá jẹ́ pé àkókò díẹ̀ la máa fi gbádùn ìràpadà náà, Ọlọ́run tó nífẹ̀ẹ́ wa ò ní gbà láé kí ìyà jẹ Ọmọ ẹ̀ kó sì kú. (Jòh. 3:16; ) Torí náà, tí Jèhófà bá lè fi Ọmọ ẹ̀ kan ṣoṣo rà wá pa dà, ó dájú pé á jẹ́ kí ayé tuntun tó ṣèlérí dé, níbi tá ò ti ní kú mọ́. 1 Pét. 1:18, 19
MÁA RONÚ NÍPA BÍ AGBÁRA JÈHÓFÀ ṢE PỌ̀ TÓ
10. Bí Éfésù 3:20 ṣe sọ, kí ni Jèhófà lágbára láti ṣe?
10 Ọ̀nà kejì tá a lè gbà mú kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára ni pé ká máa ronú lórí bí agbára Jèhófà ṣe pọ̀ tó. Ó lágbára láti mú gbogbo ìlérí ẹ̀ ṣẹ. Ká sòótọ́, ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí ló rò pé ìlérí tí Jèhófà ṣe pé a ò ní kú mọ́ nínú ayé tuntun ò lè ṣẹ. Gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń ṣèlérí tó sì máa ń mú un ṣẹ, àmọ́ àwa èèyàn ò lè ṣe bẹ́ẹ̀. Ó máa ń mú ìlérí ẹ̀ ṣẹ torí òun ni Ọlọ́run Olódùmarè. (Jóòbù 42:2; Máàkù 10:27) Torí náà, tí Ọlọ́run bá ṣèlérí tó ṣàrà ọ̀tọ̀, a mọ̀ pé ó máa mú un ṣẹ.—Ka Éfésù 3:20.
11. Sọ ìlérí àrà ọ̀tọ̀ kan tí Ọlọ́run ṣe. (Wo àpótí náà, “ Àwọn Ìlérí Àrà Ọ̀tọ̀ Tó Ti Ṣẹ.”)
11 Ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ lára àwọn ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fáwọn èèyàn ẹ̀ nígbà àtijọ́ tó dà bíi pé kò lè ṣẹ. Ọlọ́run fi dá Ábúráhámù àti Sérà lójú pé wọ́n máa bí ọmọkùnrin kan, bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti darúgbó. (Jẹ́n. 17:15-17) Ó tún sọ fún Ábúráhámù pé òun máa fún àwọn àtọmọdọ́mọ ẹ̀ ní ilẹ̀ Kénáánì. Ọ̀pọ̀ ọdún làwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù fi ṣẹrú nílẹ̀ Íjíbítì, lásìkò yẹn, ó lè dà bíi pé ìlérí tí Jèhófà ṣe ò ní ṣẹ láé. Àmọ́ ìlérí náà ṣẹ. Lẹ́yìn ìyẹn, Jèhófà sọ fún Èlísábẹ́tì pé òun náà máa bí ọmọkùnrin kan, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ti darúgbó. Ó tún sọ fún Màríà wúńdíá pé ó máa bí Ọmọ òun, ìyẹn ọmọ tí Jèhófà ṣèlérí ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn nínú ọgbà Édẹ́nì pé wọ́n máa bí. Àsọtẹ́lẹ̀ náà sì ṣẹ!—Jẹ́n. 3:15.
12. Kí ni Jóṣúà 23:14 àti Àìsáyà 55:10, 11 sọ tó jẹ́ kó dá wa lójú pé alágbára ni Jèhófà?
12 Tá a bá ń ronú nípa àwọn ìlérí tí Jèhófà ṣe tó mú ṣẹ, á jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára, á sì jẹ́ kó dá wa lójú pé ayé tuntun máa dé. (Ka Jóṣúà 23:14; Àìsáyà 55:10, 11.) Ìgbàgbọ́ tó lágbára tá a ní yìí ló ń jẹ́ ká máa sọ fáwọn èèyàn pé ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé ayé máa di tuntun kì í ṣe àlá tí ò lè ṣẹ. Kódà, nígbà tí Jèhófà ń sọ̀rọ̀ nípa ọ̀run tuntun àti ayé tuntun, ó ní: “Àwọn ọ̀rọ̀ yìí ṣeé gbára lé, òótọ́ sì ni.”—Ìfi. 21:1, 5.
MÁA ṢE ÀWỌN NǸKAN TÁÁ JẸ́ KÓ O TÚBỌ̀ SÚN MỌ́ JÈHÓFÀ
13. Tá a bá ń lọ sípàdé, báwo nìyẹn ṣe máa jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára? Ṣàlàyé.
13 Ọ̀nà kẹta tá a lè gbà mú kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára ni pé ká máa ṣe ohun táá jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kan tó fi hàn pé a máa ń jàǹfààní láwọn ìpàdé wa. Arábìnrin Anna tó ti lo ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn àkànṣe sọ pé: “Bí mo ṣe ń lọ sípàdé máa ń jẹ́ kí ìgbàgbọ́ mi túbọ̀ lágbára. Kódà, tí arákùnrin tó ń sọ̀rọ̀ ò bá tiẹ̀ mọ̀ọ̀yàn kọ́ dáadáa tàbí tí ò sọ ohun tuntun kan nígbà tó ń sọ̀rọ̀, mo ṣì máa ń gbọ́ ohun tó máa jẹ́ kí Bíbélì túbọ̀ yé mi, táá sì jẹ́ kí ìgbàgbọ́ mi túbọ̀ lágbára.” b Ó dájú pé a tún máa ń mọyì ìdáhùn àwọn ará tó ń fún ìgbàgbọ́ wa lókun.—Róòmù 1:11, 12; 10:17.
14. Báwo ni iṣẹ́ ìwàásù ṣe máa ń jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára?
14 Tá a bá ń wàásù, ìgbàgbọ́ wa máa túbọ̀ lágbára. (Héb. 10:23) Barbara tó ti ń sin Jèhófà lóhun tó ju àádọ́rin (70) ọdún lọ sọ pé: “Mo ti rí i pé gbogbo ìgbà tí mo bá lọ sóde ìwàásù ni ìgbàgbọ́ mi túbọ̀ máa ń lágbára. Bí mo ṣe ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ àwọn ìlérí àgbàyanu tí Jèhófà ṣe, bẹ́ẹ̀ náà ni ìgbàgbọ́ mi ń lágbára sí i.”
15. Báwo ni ìdákẹ́kọ̀ọ́ ṣe máa ń jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
15 Ẹ jẹ́ ká wo nǹkan míì tó máa ń jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára. Ohun náà ni ìdákẹ́kọ̀ọ́. Arábìnrin Susan sọ pé bí òun ṣe ṣètò ìgbà tóun á máa dá kẹ́kọ̀ọ́ ti ṣe òun láǹfààní gan-an. Ó sọ pé: “Ọjọ́ Sunday ni mo máa ń múra Ilé Ìṣọ́ ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀ lé e. Tó bá dọjọ́ Monday àti Tuesday, màá wá múra ìpàdé àárín ọ̀sẹ̀. Mo sì máa ń fi àwọn ọjọ́ tó kù dá kẹ́kọ̀ọ́.” Torí pé Arábìnrin Susan ń tẹ̀ lé ètò tó ṣe láti máa dá kẹ́kọ̀ọ́, ìyẹn ń jẹ́ kí ìgbàgbọ́ ẹ̀ túbọ̀ lágbára. Arábìnrin Irene tó fi ọ̀pọ̀ ọdún sìn lóríléeṣẹ́ wa rí i pé bóun ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì ti jẹ́ kí ìgbàgbọ́ òun túbọ̀ lágbára. Ó sọ pé: “Ó wú mi lórí gan-an nígbà tí mo rí i pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ kan tí Jèhófà sọ ti ṣẹ láìkù síbì kan.” c
“YÓÒ ṢẸ LÁÌKÙNÀ”
16. Báwo ni ọ̀rọ̀ tí Jèhófà fi dá Hábákúkù lójú ṣe kan àwa náà lónìí? (Hébérù 10:36, 37)
16 Ọjọ́ pẹ́ tí àwọn kan lára àwa ìránṣẹ́ Jèhófà ti ń dúró de ìgbà tí òpin ayé burúkú yìí máa dé. Àwọn kan rò pé àkókò tí Ọlọ́run dá pé òun máa mú ìlérí òun ṣẹ ti ń pẹ́ jù. Àmọ́ Jèhófà mọ bọ́rọ̀ yìí ṣe rí lára àwa ìránṣẹ́ ẹ̀, ìdí nìyẹn tó fi sọ fún Hábákúkù pé kó má mikàn, ó ní: “Àkókò tí ìran náà máa ṣẹ kò tíì tó, ó ń yára sún mọ́lé, kò sì ní lọ láìṣẹ. Tó bá tiẹ̀ falẹ̀, ṣáà máa retí rẹ̀! Torí yóò ṣẹ láìkùnà. Kò ní pẹ́ rárá!” (Háb. 2:3) Ṣé Hábákúkù nìkan ni Jèhófà sọ̀rọ̀ yìí fún, àbí ọ̀rọ̀ yìí kan àwa náà lónìí? Ẹ̀mí Ọlọ́run darí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti sọ irú ọ̀rọ̀ yìí fún àwọn Kristẹni tó ń retí ayé tuntun. (Ka Hébérù 10:36, 37.) Torí náà, tó bá dà bíi pé àwọn ìlérí Jèhófà ń pẹ́ lójú ẹ, mọ̀ dájú pé “yóò ṣẹ láìkùnà. Kò ní pẹ́ rárá!”
17. Báwo ni arábìnrin kan ṣe tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tí Jèhófà fún Hábákúkù?
17 Ọ̀pọ̀ àwa ìránṣẹ́ Jèhófà ló ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tó fún Hábákúkù pé ká “máa retí” ìgbà tóun máa gbà wá. Ọ̀pọ̀ ọdún làwọn ará kan sì ti ń ṣe bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, láti ọdún 1939 ni Arábìnrin Louise ti ń sin Jèhófà bọ̀. Ó sọ pé: “Nígbà yẹn, mo rò pé Amágẹ́dọ́nì máa dé kí n tó parí ilé ẹ̀kọ́ girama. Àmọ́, Amágẹ́dọ́nì ò dé. Láti ọ̀pọ̀ ọdún wá, ohun tó ti ràn mí lọ́wọ́ ni àwọn ìtàn Bíbélì tó dá lórí bí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà irú bíi Nóà, Ábúráhámù, Jósẹ́fù àtàwọn míì ṣe fi ọ̀pọ̀ ọdún dúró de Jèhófà kó tó fún wọn lérè tó ṣèlérí. Bí mo ṣe ń dúró de Jèhófà pé ó máa mú àwọn ìlérí ẹ̀ ṣẹ ti jẹ́ kémi àtàwọn míì gbà pé ayé tuntun ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé.” Ọ̀pọ̀ àwọn tó ti ń sin Jèhófà tipẹ́tipẹ́ náà gbà pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí!
18. Tá a bá ń kíyè sí àwọn nǹkan tí Jèhófà dá, báwo ló ṣe máa jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú pé ayé tuntun máa dé?
18 Ká sòótọ́, ayé tuntun ò tíì dé báyìí. Àmọ́ kó tó dé, máa kíyè sí àwọn nǹkan tó wà láyìíká ẹ, irú bí ìràwọ̀, igi, ẹranko àtàwọn èèyàn. Kò sẹ́ni tó lè jiyàn pé àwọn nǹkan yìí ò sí, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìgbà kan wà tí wọn ò sí. Àmọ́ à ń rí àwọn nǹkan yẹn torí pé Jèhófà ló dá wọn. (Jẹ́n. 1:1, 26, 27) Ọlọ́run wa ti ṣèlérí pé òun máa sọ ayé di tuntun, ó sì máa mú ìlérí yẹn ṣẹ. Nínú ayé tuntun, àwọn èèyàn ò ní kú mọ́, wọ́n sì máa ní ìlera tó jí pépé. Torí náà, tó bá tó àkókò lójú Ọlọ́run, ayé tuntun tó ṣèlérí máa dé.—Àìsá. 65:17; Ìfi. 21:3, 4.
19. Àwọn nǹkan wo ló yẹ kó o máa ṣe kí ìgbàgbọ́ ẹ lè túbọ̀ lágbára?
19 Kí ayé tuntun tó dé, máa ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe kí ìgbàgbọ́ ẹ lè túbọ̀ lágbára. Máa dúpẹ́ ní gbogbo ìgbà pé Jèhófà fi Ọmọ ẹ̀ rà wá pa dà. Máa ronú lórí bí agbára Jèhófà ṣe pọ̀ tó. Máa ṣe àwọn ohun táá jẹ́ kó o túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá wà lára “àwọn tí ìgbàgbọ́ àti sùúrù mú kí wọ́n jogún àwọn ìlérí” Ọlọ́run.—Héb. 6:11, 12; Róòmù 5:5.
ORIN 139 Fojú Inú Wo Ìgbà Tí Gbogbo Nǹkan Máa Di Tuntun
a Lónìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ni ò gba ohun tí Ọlọ́run sọ gbọ́ pé òun máa sọ ayé di tuntun. Wọ́n rò pé àlá tí ò lè ṣẹ ni. Àmọ́, ó dá wa lójú pé gbogbo ìlérí tí Jèhófà ṣe ló máa ṣẹ pátápátá. Síbẹ̀, ó yẹ ká ṣì máa ṣiṣẹ́ kára láti mú kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára. Báwo la ṣe máa ṣe é? Ohun tá a máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí nìyẹn.
b A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.
c Wàá rí àwọn àpilẹ̀kọ tó sọ̀rọ̀ nípa àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó o bá wo àkòrí náà “Àsọtẹ́lẹ̀” nínú Ìwé Ìwádìí fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, wo àpilẹ̀kọ náà “Àsọtẹ́lẹ̀ Jèhófà Máa Ń Ṣẹ” nínú Ilé Ìṣọ́ January 1, 2008.