Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 17

Jèhófà Máa Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́ Láti Fara Da Ìṣòro Tó Dé Bá Ẹ

Jèhófà Máa Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́ Láti Fara Da Ìṣòro Tó Dé Bá Ẹ

“Ìṣòro olódodo máa ń pọ̀, àmọ́ Jèhófà ń gbà á sílẹ̀ nínú gbogbo rẹ̀.”​—SM. 34:19.

ORIN 44 Àdúrà Ẹni Tó Ní Ẹ̀dùn Ọkàn

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ a

1. Kí ló dá wa lójú?

 Ó DÁ àwa ìránṣẹ́ Jèhófà lójú pé ó nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì fẹ́ ká gbádùn ayé wa dáadáa. (Róòmù 8:35-39) Ó tún dá wa lójú pé àwọn ìlànà Bíbélì máa ń ṣe wá láǹfààní tá a bá ń tẹ̀ lé wọn. (Àìsá. 48:17, 18) Àmọ́ tí ìṣòro bá dé bá wa ńkọ́, kí la máa ṣe?

2. Àwọn ìṣòro wo ló lè dé bá wa, àwọn ìbéèrè wo ni wọ́n sì lè mú ká bi ara wa?

2 Gbogbo àwa ìránṣẹ́ Jèhófà la máa ń níṣòro. Bí àpẹẹrẹ, ẹnì kan nínú ìdílé wa lè ṣe ohun tó dùn wá. A lè ní àìsàn kan tó lè má jẹ́ ká ṣe tó bá a ṣe fẹ́ nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Àjálù lè ṣẹlẹ̀ sí wa, irú bí omíyalé àti ìmìtìtì ilẹ̀, wọ́n sì lè ṣenúnibíni sí wa torí ohun tá a gbà gbọ́. Táwọn ìṣòro yìí bá dé bá wa, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í bi ara wa pé: ‘Kí ló dé tírú èyí fi ṣẹlẹ̀ sí mi? Àbí mo ti ṣe ohun tí ò dáa ni? Àbí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí mi yìí fi hàn pé inú Jèhófà ò dùn sí mi mọ́ ni?’ Ṣé o ti nírú èrò yìí rí? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, má rẹ̀wẹ̀sì. Ọ̀pọ̀ àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà ló ti nírú èrò tó o ní yìí rí.​—Sm. 22:1, 2; Háb. 1:2, 3.

3. Kí la kọ́ nínú Sáàmù 34:19?

3 Ka Sáàmù 34:19. Ẹ kíyè sí kókó pàtàkì méjì tó wà nínú sáàmù yìí: (1) Àwọn olóòótọ́ èèyàn máa ń níṣòro. (2) Jèhófà máa ń gbà wá tá a bá níṣòro. Báwo ni Jèhófà ṣe ń gbà wá? Ọ̀nà kan ni pé ó jẹ́ ká mọ̀ pé ìgbàkigbà ni ìṣòro lè dé bá wa nínú ayé burúkú yìí. Jèhófà ṣèlérí pé a máa láyọ̀ bá a ṣe ń sin òun, àmọ́ kò ṣèlérí fún wa pé a ò ní níṣòro kankan. (Àìsá. 66:14) Jèhófà rọ̀ wá pé ká máa ronú nípa ọjọ́ iwájú níbi tó ti fẹ́ ká gbádùn ayé wa títí láé. (2 Kọ́r. 4:16-18) Àmọ́ ní báyìí, Jèhófà ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa sìn ín nìṣó.​—Ìdárò 3:22-24.

4. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

4 Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ohun tá a lè kọ́ lára àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà ìgbà àtijọ́ àti tòde òní. Àpẹẹrẹ wọn máa jẹ́ ká rí i pé ìṣòro lè dé bá wa nígbàkigbà, àmọ́ tá a bá gbára lé Jèhófà, ó máa bójú tó wa. (Sm. 55:22) Bá a ṣe ń gbé àpẹẹrẹ àwọn olóòótọ́ náà yẹ̀ wò, bi ara ẹ pé: ‘Tí ohun tó ṣe wọ́n bá ṣẹlẹ̀ sí mi, kí ni màá ṣe? Báwo ni àpẹẹrẹ wọn ṣe máa jẹ́ kí n túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà? Kí ni mo lè rí kọ́ lára wọn tó máa ràn mí lọ́wọ́?’

ÀPẸẸRẸ ÀTIJỌ́

Ogún ọdún (20) ni Jékọ́bù fi ṣiṣẹ́ kára fún Lábánì ẹ̀gbọ́n ìyá ẹ̀, síbẹ̀ ó rẹ́ ẹ jẹ. Àmọ́ Jèhófà bù kún Jékọ́bù (Wo ìpínrọ̀ 5)

5. Àwọn ìṣòro wo ló dé bá Jékọ́bù torí ohun tí Lábánì ṣe fún un? (Wo àwòrán iwájú ìwé.)

5 Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà nígbà àtijọ́ láwọn ìṣòro tí wọn ò rò pé ó lè dé bá wọn. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Jékọ́bù. Bàbá ẹ̀ ní kó lọ fẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọbìnrin Lábánì tó jẹ́ mọ̀lẹ́bí wọn tí wọ́n jọ ń sin Jèhófà, bàbá ẹ̀ sì fi dá a lójú pé Jèhófà máa bù kún ẹ̀. (Jẹ́n. 28:1-4) Jékọ́bù sì ṣe ohun tí bàbá ẹ̀ sọ. Ó fi ilẹ̀ Kénáánì sílẹ̀, ó sì rìnrìn àjò lọ sọ́dọ̀ Lábánì tó lọ́mọ obìnrin méjì tórúkọ wọn ń jẹ́ Líà àti Réṣẹ́lì. Nígbà tí Jékọ́bù débẹ̀, ìfẹ́ Réṣẹ́lì tó jẹ́ àbúrò wọ̀ ọ́ lọ́kàn débi pé ó gbà láti ṣiṣẹ́ ọdún méje fún Lábánì kó lè fẹ́ ọmọ ẹ̀. (Jẹ́n. 29:18) Àmọ́, ọ̀rọ̀ ò rí bí Jékọ́bù ṣe rò, ṣe ni Lábánì tàn án jẹ kó lè fẹ́ Líà tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n. Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ kan, Lábánì gbà kí Jékọ́bù fẹ́ Réṣẹ́lì, àmọ́ ó sọ pé àfi kó tún ṣiṣẹ́ ọdún méje míì fún òun. (Jẹ́n. 29:25-27) Yàtọ̀ síyẹn, nígbà tí Lábánì àti Jékọ́bù jọ dòwò pọ̀, ó tún rẹ́ ẹ jẹ. Torí náà, odindi ogún (20) ọdún ni Lábánì fi ṣe ohun tí ò dáa sí Jékọ́bù!​—Jẹ́n. 31:41, 42.

6. Àwọn ìṣòro míì wo ni Jékọ́bù fara dà?

6 Àwọn ìṣòro míì wà tí Jékọ́bù fara dà. Àwọn ìyàwó ẹ̀ bímọ tó pọ̀, èdèkòyédè sì máa ń wáyé láàárín àwọn ọmọ náà. Kódà, wọ́n ta Jósẹ́fù àbúrò wọn sóko ẹrú. Ohun míì ni pé àwọn ọmọkùnrin Jékọ́bù tó ń jẹ́ Síméónì àti Léfì dójú ti ilé bàbá wọn, wọ́n sì kó ẹ̀gàn bá orúkọ Jèhófà. Yàtọ̀ síyẹn, Réṣẹ́lì tí Jékọ́bù fẹ́ràn gan-an kú nígbà tó fẹ́ bímọ kejì. Nítorí ìyàn tó mú ní ilẹ̀ náà, ó di dandan kí Jékọ́bù àti ìdílé ẹ̀ ṣí lọ sí Íjíbítì nígbà tó darúgbó.​—Jẹ́n. 34:30; 35:16-19; 37:28; 45:9-11, 28.

7. Báwo ni Jèhófà ṣe jẹ́ kí Jékọ́bù mọ̀ pé òun wà pẹ̀lú ẹ̀?

7 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìṣòro dé bá Jékọ́bù, kò fi Jèhófà sílẹ̀, ó nígbàgbọ́ nínú àwọn ìlérí tó ṣe, Jèhófà náà sì jẹ́ kó mọ̀ pé òun wà pẹ̀lú ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, bó tiẹ̀ jẹ́ pé Lábánì ṣe ohun tí ò dáa sí Jékọ́bù, Jèhófà bù kún Jékọ́bù, ó sì jẹ́ kó lóhun ìní tó pọ̀. Ó dájú pé inú Jékọ́bù máa dùn, ó sì máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà gan-an nígbà tó pa dà rí Jósẹ́fù tó rò pé ó ti kú! Torí pé àjọṣe tó dáa wà láàárín Jékọ́bù àti Jèhófà, ìyẹn jẹ́ kó lè borí àwọn ìṣòro tó ní. (Jẹ́n. 30:43; 32:9, 10; 46:28-30) Táwa náà bá ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, àá borí ìṣòro èyíkéyìí tó bá dé bá wa.

8. Kí ló wu Ọba Dáfídì pé kó ṣe?

8 Ọba Dáfídì ò lè ṣe gbogbo ohun tó fẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, ó wù ú gan-an láti kọ́ tẹ́ńpìlì kan fún Jèhófà. Ó sọ fún wòlíì Nátánì pé ó wu òun gan-an láti kọ́ tẹ́ńpìlì náà. Nátánì wá sọ fún un pé: “Ṣe ohunkóhun tó wà lọ́kàn rẹ, nítorí Ọlọ́run tòótọ́ wà pẹ̀lú rẹ.” (1 Kíró. 17:1, 2) Ẹ ò rí i pé ọ̀rọ̀ tó sọ yìí máa fún Dáfídì lókun. Kódà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Dáfídì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣètò bó ṣe máa kọ́ tẹ́ńpìlì náà.

9. Kí ni Dáfídì ṣe nígbà tó gbọ́ ìròyìn tó bà á nínú jẹ́?

9 Kò pẹ́ sígbà yẹn, wòlíì Nátánì pa dà wá sọ ìròyìn kan fún Dáfídì tó bà á nínú jẹ́. “Lóru ọjọ́ yẹn,” Jèhófà ní kí Nátánì sọ fún Dáfídì pé òun kọ́ ló máa kọ́ tẹ́ńpìlì náà, kàkà bẹ́ẹ̀ ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀ ló máa kọ́ ọ. (1 Kíró. 17:3, 4, 11, 12) Kí ni Dáfídì ṣe nígbà tó gbọ́ ìròyìn yìí? Ó yí èrò ẹ̀ pa dà. Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í kó owó àti ohun èlò jọ tí Sólómọ́nì ọmọ ẹ̀ máa fi kọ́ tẹ́ńpìlì náà.​—1 Kíró. 29:1-5.

10. Nǹkan rere wo ni Jèhófà ṣe fún Dáfídì?

10 Lẹ́yìn tí Jèhófà ní kí wọ́n sọ fún Dáfídì pé òun kọ́ ló máa kọ́ tẹ́ńpìlì náà, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló bá a dá májẹ̀mú kan. Jèhófà ṣèlérí fún Dáfídì pé ọ̀kan lára àtọmọdọ́mọ ẹ̀ ló máa ṣàkóso títí láé. (2 Sám. 7:16) Nínú ayé tuntun, ẹ wo bí inú Dáfídì ṣe máa dùn tó nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi, tó bá mọ̀ pé Jésù àtọmọdọ́mọ òun ni Ọba tó ń ṣàkóso! Ìtàn Bíbélì yìí jẹ́ ká rí i pé tá ò bá tiẹ̀ lè ṣe gbogbo ohun tá a fẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, ó ṣì lè lò wá láwọn apá ibòmíì tá ò lérò.

11. Báwo ni Jèhófà ṣe ran àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ lọ́wọ́ bó tiẹ̀ jẹ́ pé Ìjọba Ọlọ́run ò dé nígbà tí wọ́n retí pé kó dé? (Ìṣe 6:7)

11 Àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ náà láwọn ìṣòro tó dé bá wọn. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n fẹ́ kí Ìjọba Ọlọ́run tètè dé, àmọ́ wọn ò mọ̀gbà tó máa dé. (Ìṣe 1:6, 7) Kí ni wọ́n wá ṣe? Ṣe ni wọ́n gbájú mọ́ iṣẹ́ ìwàásù. Torí náà, bí wọ́n ṣe ń wàásù láti ibì kan dé ibòmíì, wọ́n ń rí i pé Jèhófà ń ran àwọn lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ náà.​—Ka Ìṣe 6:7.

12. Kí làwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ ṣe nígbà tí ìyàn mú?

12 Nígbà ayé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀, ìyàn ńlá kan mú “ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé.” (Ìṣe 11:28) Àwọn Kristẹni yẹn sì wà lára àwọn tí ìyàn náà mú nígbà yẹn. Ẹ̀yin náà ẹ wo ìyà tó máa jẹ wọ́n nígbà tí ìyàn ńlá yẹn mú. Ó dájú pé ìdààmú máa bá àwọn olórí ìdílé torí wọ́n á máa ronú bí wọ́n á ṣe wá oúnjẹ fún ìdílé wọn. Kí lẹ rò pé ó lè ṣẹlẹ̀ sáwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n ti ń ṣètò bí wọ́n ṣe máa ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù? Ṣé wọ́n lè máa ronú pé káwọn dúró dìgbà tí ìyàn náà máa parí káwọn tó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe púpọ̀ sí i? Láìka ipò tí wọ́n bá ara wọn sí, wọ́n ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe. Wọ́n lo gbogbo àǹfààní tí wọ́n ní láti wàásù, inú wọn sì dùn pé àwọn fi nǹkan ránṣẹ́ sáwọn ará ní Jùdíà.​—Ìṣe 11:29, 30.

13. Báwo ni Jèhófà ṣe ran àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ lọ́wọ́ nígbà tí ìyàn mú?

13 Báwo ni Jèhófà ṣe ran àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ lọ́wọ́ nígbà tí ìyàn mú? Nígbà táwọn Kristẹni yẹn rí oúnjẹ àtàwọn nǹkan míì tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí wọn gbà, wọ́n rí i pé Jèhófà ń ran àwọn lọ́wọ́. (Mát. 6:31-33) Ìrànwọ́ tí wọ́n rí gbà yìí máa jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ mọyì àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó fi nǹkan ránṣẹ́ sí wọn. Àwọn tó mú nǹkan wá àtàwọn tó lọ fi jíṣẹ́ ń láyọ̀ torí wọ́n ran àwọn ará lọ́wọ́. (Ìṣe 20:35) Jèhófà bù kún gbogbo wọn torí wọ́n ran ara wọn lọ́wọ́ nígbà ìṣòro.

14. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Bánábà àti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, àǹfààní wo ni wọ́n sì rí? (Ìṣe 14:21, 22)

14 Nígbà ayé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀, wọ́n máa ń ṣenúnibíni sí wọn nígbà tí wọn ò retí ẹ̀. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Bánábà àti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù nígbà tí wọ́n ń wàásù ní agbègbè Lísírà. Nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ débẹ̀, àwọn èèyàn náà tẹ́wọ́ gbà wọ́n, wọ́n sì gbọ́ ìwàásù. Àmọ́ nígbà tó yá, àwọn alátakò dé, wọ́n sì “yí àwọn èrò náà lọ́kàn pa dà.” Kódà, àwọn kan lára àwọn èèyàn náà sọ Pọ́ọ̀lù lókùúta débi pé wọ́n rò pé ó ti kú. (Ìṣe 14:19) Ṣùgbọ́n Bánábà àti Pọ́ọ̀lù lọ sí ibòmíì láti máa wàásù. Àǹfààní wo ni wọ́n rí? Wọ́n sọ “àwọn díẹ̀ di ọmọ ẹ̀yìn,” wọ́n gba àwọn ará níyànjú, ìyẹn sì jẹ́ kí ìgbàgbọ́ àwọn ará túbọ̀ lágbára. (Ka Ìṣe 14:21, 22.) Ọ̀pọ̀ àwọn ará ló jàǹfààní torí pé Bánábà àti Pọ́ọ̀lù ò dáwọ́ iṣẹ́ ìwàásù dúró nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣenúnibíni sí wọn. Táwa náà ò bá dáwọ́ iṣẹ́ ìwàásù tí Jèhófà ní ká máa ṣe dúró, ó dájú pé ó máa bù kún wa.

ÀPẸẸRẸ ÒDE ÒNÍ

15. Kí lo kọ́ lára Arákùnrin A. H. Macmillan?

15 Kó tó di ọdún 1914, àwọn èèyàn Jèhófà ń retí pé káwọn nǹkan pàtàkì kan ṣẹlẹ̀. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Arákùnrin A. H. Macmillan. Bíi ti ọ̀pọ̀ àwọn ará nígbà yẹn, Arákùnrin Macmillan náà rò pé òun máa lọ sọ́run láìpẹ́. Nígbà tó ń sọ àsọyé kan ní September 1914, ó sọ pé: “Ó jọ pé àsọyé tí mo máa sọ kẹ́yìn rèé.” Àmọ́, kì í ṣe àsọyé tó sọ kẹ́yìn nìyẹn. Nígbà tó yá, Arákùnrin Macmillan sọ pé: “Ó jọ pé àwọn kan lára wa ti ń kánjú jù torí a rò pé a ò ní pẹ́ lọ sọ́run.” Ó tún sọ pé: “Ohun tó yẹ ká gbájú mọ́ ni iṣẹ́ ìsìn Olúwa.” Ohun tí Arákùnrin Macmillan sì ṣe gan-an nìyẹn. Ó fìtara wàásù, ó láǹfààní láti gba ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin tó wà lẹ́wọ̀n níyànjú torí pé wọn ò dá sọ́rọ̀ ogun. Kódà, nígbà tó darúgbó, ó ṣì ń wá sípàdé ìjọ déédéé. Àǹfààní wo ni Arákùnrin Macmillan rí nígbà tó ń fi àkókò ẹ̀ ṣiṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run bó ṣe ń dúró de ìgbà tó máa lọ sọ́run? Kó tó kú lọ́dún 1966, ó sọ pé: “Látìbẹ̀rẹ̀ títí di báyìí, ìgbàgbọ́ mi ń lágbára sí i.” Ẹ ò rí i pé Arákùnrin Macmillan fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fún wa, pàápàá tá a bá ti ń fara da ìṣòro kan tá a rò pé ó yẹ kó ti lọ àmọ́ tí ò lọ!​—Héb. 13:7.

16. Ìṣòro wo ló dé bá Arákùnrin Herbert Jennings àti ìyàwó ẹ̀? (Jémíìsì 4:14)

16 Ọ̀pọ̀ lára àwa ìránṣẹ́ Jèhófà la máa ń ṣàìsàn tá ò rò pé ó lè dé bá wa. Bí àpẹẹrẹ, nínú ìtàn ìgbésí ayé Arákùnrin Herbert Jennings, b ó sọ pé òun àtìyàwó òun gbádùn iṣẹ́ ìsìn míṣọ́nnárì táwọn ṣe lórílẹ̀-èdè Gánà. Nígbà tó yá, àyẹ̀wò táwọn dókítà ṣe fi hàn pé ó ní àìsàn kan tó máa ń jẹ́ kí ìṣesí ẹ̀ yí pa dà lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Arákùnrin Jennings wá fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Jémíìsì 4:14, ó sì sọ pé “àìsàn táwọn ò retí ló ṣe òun yìí.” (Kà á.) Ó wá sọ pé: “A ti gba kámú, torí náà a kúrò ní Gánà, a sì fi àwọn ọ̀rẹ́ wa sílẹ̀ kí n lè lọ tọ́jú ara mi lórílẹ̀-èdè Kánádà.” Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Arákùnrin Jennings àtìyàwó ẹ̀ níṣòro, Jèhófà ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa fi òótọ́ sìn ín nìṣó.

17. Báwo làwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa ṣe jàǹfààní látinú ìrírí Arákùnrin Jennings?

17 Ohun tí Arákùnrin Jennings sọ nínú ìtàn ìgbésí ayé wọn ti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ gan-an. Bí àpẹẹrẹ, arábìnrin kan sọ pé: “Mi ò tíì ka irú ìtàn ìgbésí ayé tó wọ̀ mí lọ́kàn tó báyìí rí. . . . Nígbà tí mo ka ìtàn ìgbésí ayé Arákùnrin Jennings, tí mo sì rí bí wọ́n ṣe fi iṣẹ́ ìsìn tí wọ́n ń ṣe sílẹ̀ kí wọ́n lè lọ tọ́jú àìsàn tó ń ṣe wọ́n, mo rí i pé bí mo ṣe fi iṣẹ́ ìsìn tèmi náà sílẹ̀ nígbà tí àìsàn ṣe mí ò burú.” Bákan náà, arákùnrin kan sọ pé: “Lẹ́yìn tí mo ti ṣiṣẹ́ alàgbà fún odindi ọdún mẹ́wàá, mo ní láti fi iṣẹ́ náà sílẹ̀ torí àìsàn ọpọlọ tó ń ṣe mí. Mo máa ń ro ara mi pin, mo sì máa ń soríkọ́ débi pé mi ò fẹ́ ka àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí ìtàn ìgbésí ayé àwọn ará wa. . . . Àmọ́ nígbà tí mo ka ìtàn ìgbésí ayé Arákùnrin Jennings, tí mo sì rí bí wọ́n ṣe fara dà á tù mí nínú gan-an.” Àwọn ìrírí yìí jẹ́ ká rí i pé tá a bá fara da àwọn ìṣòro tó dé bá wa, ó lè fún àwọn míì níṣìírí láti fara da ìṣòro tiwọn. Kódà, tí nǹkan ò bá lọ dáadáa fún wa bá a ṣe rò, síbẹ̀ tá a fara dà á, tá a sì fi hàn pé a nígbàgbọ́, a máa jẹ́ àpẹẹrẹ rere fáwọn ará.​—1 Pét. 5:9.

Tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà láwọn ìgbà tá a níṣòro, ìyẹn á jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ ọn (Wo ìpínrọ̀ 18)

18. Bó ṣe wà nínú àwòrán yẹn, kí la rí kọ́ lára opó kan lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà?

18 Àwọn àjálù irú bí àjàkálẹ̀ àrùn Kòrónà ti ṣọṣẹ́ fún ọ̀pọ̀ lára àwa èèyàn Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, arábìnrin opó kan lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà ò fi bẹ́ẹ̀ lówó lọ́wọ́, oúnjẹ díẹ̀ ló sì ní nílé. Láàárọ̀ ọjọ́ kan, ọmọ ẹ̀ obìnrin bi í pé lẹ́yìn táwọn bá se agolo ìrẹsì kan tó ṣẹ́ kù nílé, kí làwọn á máa jẹ? Arábìnrin náà wá sọ fún ọmọbìnrin ẹ̀ pé bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò sówó lọ́wọ́ àwọn, tí kò sì sí oúnjẹ kankan nílé mọ́, kó jẹ́ káwọn se oúnjẹ tó ṣẹ́ kù, káwọn sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá bíi ti opó Sáréfátì. (1 Ọba 17:8-16) Kó tó di pé wọ́n ronú ohun tí wọ́n máa jẹ lọ́sàn-án ọjọ́ yẹn, àwọn ará fi oúnjẹ ìrànwọ́ ránṣẹ́, wọ́n sì rí i gbà. Oúnjẹ náà pọ̀ débi pé ó máa gbé wọn ju ọ̀sẹ̀ méjì lọ. Arábìnrin náà sọ pé òun ò mọ̀ pé Jèhófà gbọ́ ohun tóun sọ fún ọmọbìnrin òun. Ká sòótọ́, tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà láwọn ìgbà tí ìṣòro bá dé bá wa, ó máa jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ ọn.​—1 Pét. 5:6, 7.

19. Inúnibíni wo ni Arákùnrin Aleksey Yershov fara dà?

19 Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa ló ti fara da inúnibíni tí wọn ò retí. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Arákùnrin Aleksey Yershov tó ń gbé ní Rọ́ṣíà. Nígbà tí Arákùnrin Yershov ṣèrìbọmi ní 1994, àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè náà ń jọ́sìn ẹ̀ fàlàlà láìsí inúnibíni. Àmọ́ lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún, nǹkan yí pa dà lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà. Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún 2020, àwọn ọlọ́pàá Rọ́ṣíà ya wọ ilé Arákùnrin Yershov, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í tú u. Wọ́n tún gbẹ́sẹ̀ lé àwọn nǹkan ìní ẹ̀. Ọ̀pọ̀ oṣù lẹ́yìn náà, ìjọba fẹ̀sùn ọ̀daràn kàn án. Èyí tó burú jù níbẹ̀ ni pé ó ju ọdún kan lọ tẹ́ni tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ fi díbọ́n bíi pé òun nífẹ̀ẹ́ sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà, òun ló sì ṣe fídíò tí wọ́n fi fẹ̀sùn kàn án!

20. Báwo ni Arákùnrin Yershov ṣe mú kí àjọṣe ẹ̀ àti Jèhófà túbọ̀ lágbára?

20 Ṣé Arákùnrin Yershov jàǹfààní kankan bí wọ́n ṣe ṣe inúnibíni sí i? Bẹ́ẹ̀ ni. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn ti jẹ́ kí àjọṣe òun àti Jèhófà túbọ̀ lágbára. Ó sọ pé: “Èmi àtìyàwó mi túbọ̀ tẹra mọ́ àdúrà tá a máa ń gbà. Mo mọ̀ pé tí kì í bá ṣe pé Jèhófà ràn mí lọ́wọ́ ni, mi ò ní lè fara da inúnibíni yẹn.” Ó tún sọ pé: “Ìdákẹ́kọ̀ọ́ tí mo máa ń ṣe jẹ́ kí n lè borí ìrẹ̀wẹ̀sì. Mo máa ń ṣàṣàrò lórí àpẹẹrẹ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ìgbà àtijọ́. Ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ ló sì wà nínú Bíbélì tó jẹ́ ká rí bó ti ṣe pàtàkì tó pé kò yẹ ká bẹ̀rù tá a bá níṣòro. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.”

21. Kí la ti kọ́ nínú àpilẹ̀kọ yìí?

21 Kí la ti kọ́ nínú àpilẹ̀kọ yìí? Ìṣòro lè dé bá wa nígbàkigbà nínú ayé burúkú yìí. Síbẹ̀, Jèhófà máa ń ran àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ lọ́wọ́ tó bá rí i pé wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé òun. Bó sì ṣe wà nínú ẹsẹ Bíbélì tí àpilẹ̀kọ yìí dá lé nìyẹn, ó ní: “Ìṣòro olódodo máa ń pọ̀, àmọ́ Jèhófà ń gbà á sílẹ̀ nínú gbogbo rẹ̀.” (Sm. 34:19) Torí náà, ẹ má ṣe jẹ́ ká máa ronú ṣáá nípa àwọn ìṣòro wa, àmọ́ ká máa ronú nípa bí Jèhófà ṣe ń lo agbára ẹ̀ láti gbà wá sílẹ̀. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, àwa náà máa lè sọ bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pé: “Mo ní okun láti ṣe ohun gbogbo nípasẹ̀ ẹni tó ń fún mi lágbára.”​—Fílí. 4:13.

ORIN 38 Yóò Sọ Ọ́ Di Alágbára

a Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìṣòro lè dé bá wa nínú ayé burúkú yìí, ó dá wa lójú pé Jèhófà máa ran àwa olóòótọ́ ìránṣẹ́ ẹ̀ lọ́wọ́. Báwo ni Jèhófà ṣe ran àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ lọ́wọ́ nígbà àtijọ́? Báwo ló ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ lónìí? Tá a bá kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn tó gbára lé Jèhófà nígbà àtijọ́ àti lóde òní, á túbọ̀ dá wa lójú pé Jèhófà máa ran àwa náà lọ́wọ́ tá a bá gbára lé e.