Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 15

Kí La Rí Kọ́ Nínú Àwọn Iṣẹ́ Ìyanu Tí Jésù Ṣe?

Kí La Rí Kọ́ Nínú Àwọn Iṣẹ́ Ìyanu Tí Jésù Ṣe?

‘Ó lọ káàkiri ilẹ̀ náà, ó ń ṣe rere, ó sì ń wo àwọn èèyàn sàn.’​—ÌṢE 10:38.

ORIN 13 Kristi, Àwòkọ́ṣe Wa

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ a

1. Ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jésù ṣiṣẹ́ ìyanu àkọ́kọ́.

 FOJÚ inú wo bí nǹkan ṣe rí nígbà tí Jésù bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ bí ọdún 29 S.K. ṣe ń parí lọ. Wọ́n pe Jésù àti Màríà ìyá rẹ̀ àtàwọn kan lára àpọ́sítélì rẹ̀ wá síbi ìgbéyàwó kan ní abúlé kan tó ń jẹ́ Kánà. Abúlé náà wà ní Násárẹ́tì, ìyẹn ìlú ìbílẹ̀ Jésù. Ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ ni Màríà àtàwọn ìdílé tí ọmọ wọn ń ṣègbéyàwó, ó sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti bójú tó àwọn àlejò. Àmọ́ nígbà tí wọ́n ń jẹun lọ́wọ́ níbi ìgbéyàwó náà, ohun kan ṣẹlẹ̀ tó lè kó ìtìjú bá tọkọtaya náà àti ìdílé wọn. Wáìnì tí wọ́n ń mu tán, ìyẹn sì lè jẹ́ torí pé iye àwọn tó wá ti pọ̀ jù. b Ni Màríà bá tètè lọ bá Jésù, ó sì sọ pé: “Wọn ò ní wáìnì kankan.” (Jòh. 2:1-3) Kí ni Jésù ṣe? Ó ṣiṣẹ́ ìyanu kan tó jọni lójú gan-an, ó sọ omi di “wáìnì tó dáa.”​—Jòh. 2:9, 10.

2-3. (a) Àwọn iṣẹ́ ìyanu wo ni Jésù ṣe? (b) Àǹfààní wo la máa rí tá a bá ronú nípa àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe?

2 Nígbà tí Jésù ń ṣiṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ó ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu míì. c Ó ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu láti ran ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, méjì lára iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe ni pé ó bọ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ọkùnrin, lẹ́yìn ìgbà yẹn ó bọ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rin (4,000) ọkùnrin. Ó sì ṣeé ṣe kí gbogbo àwọn tí Jésù bọ́ ju ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n (27,000) lọ tá a bá ka àwọn obìnrin àtàwọn ọmọdé tó wà níbẹ̀ mọ́ wọn. (Mát. 14:15-21; 15:32-38) Láwọn ìgbà tó ṣiṣẹ́ ìyanu yẹn, ó tún wo ọ̀pọ̀ èèyàn sàn. (Mát. 14:14; 15:30, 31) Ẹ wo bó ṣe máa ya àwọn èèyàn yẹn lẹ́nu gan-an pé Jésù wò wọ́n sàn, ó sì tún bọ́ wọn lọ́nà ìyanu!

3 Lónìí, àwa náà lè kọ́ ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ nínú àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa bí àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe yẹn ṣe lè jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára. Lẹ́yìn náà, a máa sọ̀rọ̀ nípa bá a ṣe lè jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ àti aláàánú bíi ti Jésù nígbà tó ń ṣiṣẹ́ ìyanu.

ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ TÁ A RÍ KỌ́ LÁRA JÈHÓFÀ ÀTI JÉSÙ

4. Àwọn ohun tá a rí kọ́ nínú àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe jẹ́ ká túbọ̀ nígbàgbọ́ nínú àwọn wo?

4 Àwọn ohun tá a rí kọ́ nínú àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe jẹ́ ká túbọ̀ nígbàgbọ́ nínú Jésù àti Bàbá ẹ̀. Ìdí ni pé Jèhófà ló fún Jésù lágbára láti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu yẹn. Ìṣe 10:38 sọ pé: ‘Ọlọ́run fi ẹ̀mí mímọ́ àti agbára yan [Jésù], ó sì lọ káàkiri ilẹ̀ náà, ó ń ṣe rere, ó sì ń wo gbogbo àwọn tí Èṣù ń ni lára sàn, torí pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀.’ Rántí pé gbogbo ohun tí Jésù sọ àtohun tó ṣe, títí kan àwọn iṣẹ́ ìyanu ẹ̀ fi hàn pé ó ń ronú bíi ti Bàbá ẹ̀, ó sì máa ń mọ nǹkan lára bíi ti Bàbá ẹ̀. (Jòh. 14:9) Ẹ jẹ́ ká wo ẹ̀kọ́ mẹ́ta tá a lè rí kọ́ lára àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe.

5. Kí ló mú kí Jésù ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu tó ṣe? (Mátíù 20:30-34)

5 Àkọ́kọ́, Jésù àti Bàbá ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ wa gan-an. Nígbà tí Jésù wà láyé, ó fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn gan-an torí ó ṣe iṣẹ́ ìyanu kó lè fòpin sí ìyà tó ń jẹ wọ́n. Nígbà kan, àwọn ọkùnrin afọ́jú méjì kan kígbe pé kó ran àwọn lọ́wọ́. (Ka Mátíù 20:30-34.) Kíyè sí pé ẹsẹ Bíbélì yẹn sọ pé “àánú wọn ṣe Jésù,” ó sì mú wọn lára dá. Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n tú sí “àánú wọn ṣe Jésù” jẹ́ ká rí i pé àánú wọn ṣe é gan-an débi pé ó mọ̀ ọ́n lára. Bí àánú àwọn èèyàn yẹn ṣe ṣe Jésù gan-an fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ gbogbo èèyàn, ìyẹn ló jẹ́ kó bọ́ àwọn tí ebi ń pa, kó sì tún wo alárùn ẹ̀tẹ̀ kan sàn. (Mát. 15:32; Máàkù 1:41) Torí náà, ó dá wa lójú pé Jèhófà Ọlọ́run tó ní “ojú àánú” àti Jésù Ọmọ rẹ̀ nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì máa ń dùn wọ́n gan-an tí ìyà bá ń jẹ wá. (Lúùkù 1:78; 1 Pét. 5:7) Ẹ ò rí i pé ó wu Jèhófà àti Ọmọ ẹ̀ láti mú gbogbo ìyà tó ń jẹ aráyé kúrò!

6. Agbára wo ni Ọlọ́run fún Jésù?

6 Ìkejì, Ọlọ́run fún Jésù lágbára láti yanjú ìṣòro aráyé. Àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe fi hàn pé ó lágbára láti yanjú àwọn ìṣòro tá ò lè yanjú fúnra wa. Bí àpẹẹrẹ, ó lágbára láti gbà wá lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tá a jogún àtàwọn nǹkan tí ẹ̀ṣẹ̀ náà fà irú bí àìsàn àti ikú. (Mát. 9:1-6; Róòmù 5:12, 18, 19) Àwọn iṣẹ́ ìyanu tó ṣe fi hàn pé ó lè wo “onírúurú” àìsàn, ó sì lè jí òkú dìde. (Mát. 4:23; Jòh. 11:43, 44) Bákan náà, ó lágbára láti dáwọ́ ìjì líle dúró, ó sì lágbára láti gba àwọn èèyàn sílẹ̀ lọ́wọ́ ẹ̀mí burúkú. (Máàkù 4:37-39; Lúùkù 8:2) Àwọn nǹkan yìí jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà ti fún Ọmọ ẹ̀ lágbára láti yanjú àwọn ìṣòro wa!

7-8. (a) Kí ló dá wa lójú nígbà tá a kà nípa àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe? (b) Iṣẹ́ ìyanu wo ló wù ẹ́ kó o fojú ara ẹ rí nínú ayé tuntun?

7 Ìkẹta, ó dá wa lójú háún-háún pé Ọlọ́run máa ṣe àwọn ohun rere tó ṣèlérí nínú Ìjọba rẹ̀. Àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé tó bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso ayé, ó máa ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ torí pé òun ni Ọba Ìjọba Ọlọ́run. Ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ lára àwọn nǹkan tá a máa gbádùn nígbà tí Jésù bá ń ṣàkóso ayé. A máa ní ìlera pípé, Jésù sì máa mú gbogbo àìsàn àti àìlera tó ń bá aráyé fínra kúrò. (Àìsá. 33:24; 35:5, 6; Ìfi. 21:3, 4) Ebi ò ní pa wá mọ́, àwọn ohun tí àjálù máa ń fà ò sì ní ṣẹlẹ̀ sí wa mọ́. (Àìsá. 25:6; Máàkù 4:41) Inú wa máa dùn gan-an nígbà tí wọ́n bá jí àwọn èèyàn wa tó wà nínú “ibojì ìrántí” dìde, tá a sì ń kí wọn káàbọ̀. (Jòh. 5:28, 29) Iṣẹ́ ìyanu wo ló wù ẹ́ kó o fojú ara ẹ rí nínú ayé tuntun?

8 Nígbà tí Jésù ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu tó ṣe, ó fi hàn pé òun nírẹ̀lẹ̀, ó sì tún ṣàánú àwọn èèyàn, torí náà ó yẹ káwa náà fara wé Jésù. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ méjì. Àpẹẹrẹ àkọ́kọ́ tá a máa gbé yẹ̀ wò ni ìgbéyàwó tó wáyé ní Kánà.

JÉSÙ KỌ́ WA NÍRẸ̀LẸ̀

9. Kí ni Jésù ṣe níbi ayẹyẹ ìgbéyàwó tó wáyé ní Kánà? (Jòhánù 2:6-10)

9 Ka Jòhánù 2:6-10. Nígbà tí wáìnì tán níbi ayẹyẹ ìgbéyàwó tó wáyé ní Kánà, ṣé dandan ni kí Jésù ṣe nǹkan nípa ẹ̀? Rárá. Kò sí àsọtẹ́lẹ̀ kankan tó sọ pé Mèsáyà máa sọ omi di wáìnì, àmọ́ tó bá jẹ́ ìwọ lò ń ṣègbéyàwó tí ohun mímu sì tán níbẹ̀, báwo ló ṣe máa rí lára ẹ? Àánú ìdílé tó ń ṣègbéyàwó ṣe Jésù, pàápàá ọkọ àti ìyàwó, kò sì fẹ́ kójú tì wọ́n. Torí náà, bá a ṣe sọ níṣàájú, ó ṣe iṣẹ́ ìyanu kan. Ó sọ omi tó tó ọgọ́rùn-ún mẹ́ta àti àádọ́rùn-ún (390) lítà di wáìnì tó dáa jù. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìdí tí Jésù fi jẹ́ kí wáìnì náà pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ ni pé ó fẹ́ kó ṣẹ́ kù, kí wọ́n lè lò ó nígbà míì. Tàbí ó fẹ́ kí wọ́n ta èyí tó kù, kí tọkọtaya náà lè rówó ná. Ẹ ò rí i pé tọkọtaya yẹn máa mọyì ohun tí Jésù ṣe fún wọn gan-an!

Bíi ti Jésù, má ṣe máa fọ́nnu tó o bá ṣe àwọn àṣeyọrí kan nígbèésí ayé ẹ (Wo ìpínrọ̀ 10-11) e

10. Àwọn kókó pàtàkì wo ló wà nínú Jòhánù orí 2? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

10 Ẹ jẹ́ ká wo àwọn kókó pàtàkì inú ìtàn Jòhánù orí 2. Ṣẹ́ ẹ kíyè sí i pé Jésù fúnra ẹ̀ kọ́ ló pọn omi kún inú àwọn ìṣà omi náà? Dípò kó jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé òun lòun fẹ́ sọ omi di wáìnì, ó sọ pé káwọn tó ń ṣiṣẹ́ níbi àsè náà pọn omi sínú wọn. (Ẹsẹ 6, 7) Yàtọ̀ síyẹn, lẹ́yìn tí Jésù sọ omi di wáìnì, òun fúnra ẹ̀ kọ́ ló bu wáìnì náà lọ fún alága àsè, kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn tó ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀ ló ní kí wọ́n gbé e lọ. (Ẹsẹ 8) Jésù ò fi kọ́ọ̀bù bu wáìnì náà, kó nà án sókè, kó wá máa fọ́nnu níwájú àwọn tó wà níbi àsè náà pé, ‘Wáìnì tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe rèé, ó yá, ẹ tọ́ ọ wò!’

11. Kí la rí kọ́ nínú bí Jésù ṣe sọ omi di wáìnì?

11 Kí la rí kọ́ nínú bí Jésù ṣe sọ omi di wáìnì? Ó kọ́ wa pé ó yẹ ká nírẹ̀lẹ̀. Jésù ò fọ́nnu nítorí iṣẹ́ ìyanu yẹn. Kódà, kò sígbà kankan tí Jésù fọ́nnu nípa àwọn nǹkan tó ṣe. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìrẹ̀lẹ̀ tí Jésù ní máa ń jẹ́ kó gbé gbogbo ògo fún Bàbá rẹ̀. (Jòh. 5:19, 30; 8:28) Táwa náà bá nírẹ̀lẹ̀ bíi ti Jésù, a ò ní máa fọ́nnu nítorí àwọn nǹkan tá à ń gbé ṣe. Ohun yòówù ká máa ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, kò yẹ ká gbé ògo fún ara wa. Kàkà bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run tá à ń sìn ló yẹ ká máa yìn torí òun lògo tọ́ sí. (Jer. 9:23, 24) Ká sòótọ́, kò sí àṣeyọrí tá a lè ṣe láìjẹ́ pé Jèhófà ràn wá lọ́wọ́.​—1 Kọ́r. 1:26-31.

12. Ọ̀nà míì wo la lè gbà fi hàn pé a nírẹ̀lẹ̀ bíi ti Jésù? Ṣàpèjúwe.

12 Ọ̀nà míì wà tá a lè gbà fi hàn pé a nírẹ̀lẹ̀ bíi ti Jésù. Ẹ jẹ́ ká sọ pé alàgbà kan ran ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan lọ́wọ́ láti múra àsọyé tó kọ́kọ́ fẹ́ sọ. Torí pé alàgbà yẹn ràn án lọ́wọ́, ó sọ àsọyé náà dáadáa, àwọn ará sì gbádùn ẹ̀. Lẹ́yìn ìpàdé, ẹnì kan wá bá alàgbà náà, ó sì sọ pé: ‘A gbádùn àsọyé Arákùnrin lágbájá, ó sì wọ̀ wá lọ́kàn.’ Ṣé ó yẹ kí alàgbà yẹn sọ pé: ‘Bẹ́ẹ̀ ni, òótọ́ lo sọ, àmọ́ èmi ni mo ràn án lọ́wọ́?’ Àbí ṣe ló yẹ kó fìrẹ̀lẹ̀ sọ pé: ‘Bẹ́ẹ̀ ni, òótọ́ lo sọ, iṣẹ́ ńlá ló ṣe’? Tá a bá nírẹ̀lẹ̀, a ò ní fọ́nnu tá a bá ṣe ohun kan láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Ọkàn wa máa balẹ̀ torí a mọ̀ pé Jèhófà rí ohun tá a ṣe, ó sì mọyì ẹ̀. (Fi wé Mátíù 6:2-4; Héb. 13:16) Torí náà, tá a bá fi hàn pé a nírẹ̀lẹ̀ bíi ti Jésù, ó dájú pé inú Jèhófà máa dùn sí wa.​—1 Pét. 5:6.

JÉSÙ KỌ́ WA PÉ KÁ MÁA ṢÀÁNÚ

13. Kí ni Jésù rí nítòsí ìlú Náínì, kí ló sì ṣe nípa ẹ̀? (Lúùkù 7:11-15)

13 Ka Lúùkù 7:11-15. Fojú inú wo ohun tó ṣẹlẹ̀ ní nǹkan bí ọdún méjì lẹ́yìn tí Jésù bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. Ó rìnrìn àjò lọ sí Náínì, ìyẹn ìlú kan tó wà lágbègbè Gálílì tí kò jìnnà sí Ṣúnémù níbi tí wòlíì Èlíṣà ti jí ọmọ obìnrin kan dìde ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án (900) ọdún sẹ́yìn. (2 Ọba 4:32-37) Bí Jésù ṣe ń sún mọ́ ẹnubodè ìlú náà, ó rí àwọn tó ń jáde bọ̀ nínú ìlú tí wọ́n fẹ́ lọ sin ẹnì kan. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn ba àwọn èèyàn nínú jẹ́ gan-an torí ọmọ kan ṣoṣo tí opó kan bí ló kú. Àmọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn látinú ìlú ló tẹ̀ lé ìyá ọmọ náà nígbà tí wọ́n fẹ́ lọ sin ín. Jésù dá wọn dúró nígbà tó rí wọn, ó ṣe ohun kan tó jọ ìyá ọmọ náà lójú, ó jí ọmọkùnrin ẹ̀ dìde! Ẹni àkọ́kọ́ rèé nínú àwọn mẹ́ta tí Ìwé Ìhìn Rere sọ pé Jésù jí dìde.

Bíi ti Jésù, ó yẹ ká máa kíyè sí àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀, ká sì fàánú hàn sí wọn (Wo ìpínrọ̀ 14-16)

14. Àwọn kókó pàtàkì wo ló wà nínú ìtàn Lúùkù orí 7? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

14 Ẹ jẹ́ ká wo àwọn kókó pàtàkì inú Lúùkù orí 7. Ṣẹ́ ẹ kíyè sí i pé lẹ́yìn tí Jésù ‘tajú kán rí’ ìyá ọmọ tó kú náà, “àánú rẹ̀ ṣe é”? (Ẹsẹ 13) Ó ṣeé ṣe kí Jésù rí i pé ìyá ọmọ náà ń sunkún bó ṣe ń rìn lọ níwájú òkú ọmọ ẹ̀, ìyẹn sì jẹ́ kí àánú ìyá ọmọ náà ṣe Jésù. Jésù ò kàn káàánú ìyá ọmọ náà, àmọ́ ó ṣe ohun kan tó fi hàn pé àánú ẹ̀ ṣe é. Ó wá sọ ohun tó fi ìyá ọmọ náà lọ́kàn balẹ̀, ó ní: “Má sunkún mọ́.” Lẹ́yìn náà, ó ṣe ohun kan láti ràn án lọ́wọ́. Ó jí ọmọ ẹ̀ dìde, ó sì ‘fà á lé e lọ́wọ́.’​—Ẹsẹ 14, 15.

15. Kí la rí kọ́ nínú bí Jésù ṣe jí ọmọ opó kan dìde?

15 Kí la rí kọ́ nínú bí Jésù ṣe jí ọmọ obìnrin opó kan dìde? Ohun tá a rí kọ́ ni pé ká máa fàánú hàn sáwọn tó ń ṣọ̀fọ̀. Ká sòótọ́, a ò lè jí òkú dìde bí Jésù ti ṣe. Àmọ́ tá a bá lákìíyèsí bíi ti Jésù, àwa náà máa fàánú hàn sáwọn tó ń ṣọ̀fọ̀. Bá a ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká sọ ohun tó máa tù wọ́n nínú tàbí ká ṣe ohun tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́. d (Òwe 17:17; 2 Kọ́r. 1:3, 4; 1 Pét. 3:8) Kódà, tí ohun tá a ṣe fún wọn ò bá tó nǹkan, ó máa tù wọ́n nínú gan-an.

16. Bá a ṣe ń wò ó nínú àwòrán yẹn, kí lo kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ìyá kan tí ọmọ ẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ kú?

16 Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ìyá kan. Lọ́dún mélòó kan sẹ́yìn nígbà táwọn ará ń kọrin nípàdé, arábìnrin kan kíyè sí ìyá kan tó wà nítòsí ẹ̀ tó ń sunkún. Orin náà dá lórí àjíǹde àwọn òkú, ohun tó sì ń pa arábìnrin náà lẹ́kún nìyẹn torí pé ọmọbìnrin ẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ kú ni. Torí pé arábìnrin yẹn mọ ohun tó ṣẹlẹ̀, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló lọ sọ́dọ̀ ìyá náà, ó fọwọ́ kọ́ ọ lọ́rùn, wọ́n sì jọ kọrin náà tán. Nígbà tó yá, ìyá yẹn sọ pé: “Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin fìfẹ́ hàn sí mi gan-an.” Inú ìyá yẹn dùn pé òun lọ sípàdé lọ́jọ́ yẹn. Ó tún sọ pé: “Tá a bá wá sípàdé, a máa ń rí ìṣírí gbà.” Torí náà, mọ̀ dájú pé Jèhófà ń kíyè sí ẹ, ó sì mọyì ohunkóhun tó o bá ṣe bó ti wù kó kéré tó láti mára tu àwọn tí “àárẹ̀ bá ẹ̀mí wọn.”​—Sm. 34:18.

ÀWỌN IṢẸ́ ÌYANU JÉSÙ MÁA JẸ́ KÍ ÌGBÀGBỌ́ Ẹ TÚBỌ̀ LÁGBÁRA

17. Àwọn nǹkan wo la ti kọ́ nínú àpilẹ̀kọ yìí?

17 Tá a bá kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ nípa àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe nínú àwọn Ìwé Ìhìn Rere, ìgbàgbọ́ wa máa túbọ̀ lágbára. Àwọn iṣẹ́ ìyanu yẹn kọ́ wa pé Jèhófà àti Jésù nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, pé Jésù lágbára láti yanjú ìṣòro aráyé, wọ́n sì tún jẹ́ kó dá wa lójú pé àwọn ohun rere tí Jèhófà ṣèlérí nínú Ìjọba Ọlọ́run máa ṣẹ láìpẹ́. Bá a ṣe ń ka àwọn ìtàn Bíbélì yẹn, ó yẹ ká máa ṣàṣàrò lórí bá a ṣe lè ní àwọn ànímọ́ tí Jésù ní. Tó o bá fẹ́ ṣètò àwọn nǹkan tó o máa fi dá kẹ́kọ̀ọ́ tàbí tẹ́ ẹ máa lò nígbà Ìjọsìn Ìdílé yín, ẹ ò ṣe kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn iṣẹ́ ìyanu yòókù tí Jésù ṣe? Tó o bá ti ń ka àwọn ìtàn yẹn, kíyè sí àwọn ẹ̀kọ́ tó o lè rí kọ́ níbẹ̀, kó o sì sọ ohun tó o rí kọ́ fáwọn ẹlòmíì. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ máa fún ara yín níṣìírí, ìgbàgbọ́ yín á sì túbọ̀ lágbára.​—Róòmù 1:11, 12.

18. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?

18 Nígbà tí iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù ń parí lọ, ó tún jí ẹnì kan dìde, èyí sì ni àjíǹde kẹta tó ṣe kẹ́yìn tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀. Àmọ́, irú àjíǹde yìí ò ṣẹlẹ̀ rí torí ọ̀rẹ́ ẹ̀ tímọ́tímọ́ tó ti lo ọjọ́ mẹ́rin nínú ibojì ló jí dìde. Kí làwọn nǹkan tá a rí kọ́ nínú àjíǹde tí Jésù ṣe kẹ́yìn yìí? Báwo la sì ṣe lè jẹ́ kí ìgbàgbọ́ tá a ní pé àwọn òkú máa jíǹde túbọ̀ lágbára? A máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.

ORIN 20 O Fún Wa Ní Ọmọ Rẹ Ọ̀wọ́n

a Ó mú kí ìjì pa rọ́rọ́, ó wo àwọn aláìsàn sàn, ó sì jí òkú dìde. Inú wa máa ń dùn tá a bá ń kà nípa àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe. Wọ́n kọ àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn sínú Bíbélì ká lè kẹ́kọ̀ọ́ lára wọn, kì í ṣe ká kàn máa kà wọ́n bí ẹni ka ìwé ìtàn. Torí náà, bá a ṣe ń gbé díẹ̀ lára àwọn iṣẹ́ ìyanu náà yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ yìí, wọ́n á jẹ́ ká túbọ̀ nígbàgbọ́ nínú Jèhófà àti Jésù, wọ́n á sì tún jẹ́ ká mọ àwọn ànímọ́ tó yẹ ká ní.

b Ọ̀mọ̀wé Bíbélì kan ṣàlàyé pé: “Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtàwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká máa ń gba àwọn èèyàn lálejò gan-an, wọ́n sì kà á sí ojúṣe pàtàkì. Ẹni tó bá gba àwọn èèyàn lálejò máa ń se oúnjẹ tó pọ̀ gan-an débi pé àwọn àlejò máa jẹ àjẹyó àti àjẹṣẹ́kù. Torí náà, tẹ́nì kan bá fẹ́ fi hàn pé lóòótọ́ lòun fẹ́ ṣe àwọn èèyàn lálejò, pàápàá tó bá jẹ́ níbi ìgbéyàwó, á filé pọntí, á sì fọ̀nà rokà.”

c Àkọsílẹ̀ Ìwé Ìhìn Rere jẹ́ ká mọ̀ pé iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe ju ọgbọ̀n (30) lọ. Yàtọ̀ síyẹn, Jésù ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu míì, àmọ́ Bíbélì ò dárúkọ wọn lọ́kọ̀ọ̀kan. Bí àpẹẹrẹ nígbà kan, “gbogbo ìlú” wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ‘ó sì wo ọ̀pọ̀ àwọn tí àìsàn ń yọ lẹ́nu sàn.’​—Máàkù 1:32-34.

d Kó o lè mọ ohun tó o lè sọ tàbí tó o lè ṣe tó o bá fẹ́ tu àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ nínú, wo àpilẹ̀kọ náà “Máa Tu Àwọn Tó Ń Ṣọ̀fọ̀ Nínú Bí Jésù Ti Ṣe” nínú Ilé Ìṣọ́ November 1, 2010.

e ÀWÒRÁN: Jésù là ń wò yẹn tó dúró lẹ́yìn. Ọkọ àti ìyàwó pẹ̀lú àwọn àlejò wọn ń gbádùn wáìnì tó dáa tó ṣe.