Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Tó o Lè Fi Kẹ́kọ̀ọ́

Ohun Tó o Lè Fi Kẹ́kọ̀ọ́

Ṣé ò ń jàǹfààní àwọn ẹsẹ Bíbélì tá a ṣàlàyé nínú Ìwé Ìwádìí fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

Àwọn àlàyé tá a ṣe lórí àwọn ẹsẹ Bíbélì náà máa jẹ́ kó o túbọ̀ lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Àlàyé náà máa ń sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ẹsẹ Bíbélì kan, ìdí tí wọ́n fi kọ ọ́, ẹni tó ń sọ nípa ẹ̀ àti ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ tàbí gbólóhùn kan.

ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower àti JW Library® máa jẹ́ kó o rí àwọn ìwé tó ṣàlàyé ẹsẹ Bíbélì kan nínú Ìwé Ìwádìí fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Tó o bá lo èyíkéyìí lára Bíbélì tó wà níbẹ̀, wàá rí àwọn ìwé tó o lè fi ṣèwádìí ní abala ìkẹ́kọ̀ọ́ lápá ọ̀tún.

Tó o bá ń lo àwọn ìwé náà, kíyè sí déètì tí wọ́n ṣe wọ́n. Àwọn àpilẹ̀kọ tó dé kẹ́yìn tó sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹsẹ Bíbélì kan máa ń wà lókè pátápátá. Àwọn àpilẹ̀kọ tó ti pẹ́ ló máa ń wà nísàlẹ̀, àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú ẹ̀ sì lè jẹ́ òye tá a ní tẹ́lẹ̀ nípa ọ̀rọ̀ kan àmọ́ tá a ti ṣàtúnṣe ẹ̀.

  • Àwọn ìwé tó ṣàlàyé ẹsẹ Bíbélì tó wà nínú Ìwé Ìwádìí fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń hàn lórí ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ.

  • Kó o tó lè rí àwọn ìwé tó ṣàlàyé ẹsẹ Bíbélì lórí JW Library, wa Ìwé Ìwádìí fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà jáde sórí fóònù tàbí kọ̀ǹpútà ẹ, kó o lè rí àwọn ìwé tuntun tó wà níbẹ̀. Bó o ṣe máa ṣe é ni pé kó o tẹ bọ́tìnì tó wà lókè pátápátá ní abala ìkẹ́kọ̀ọ́ tó wà lápá ọ̀tún orí Bíbélì tó o ṣí.