Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

OHUN TÓ O LÈ KẸ́KỌ̀Ọ́ NÍPA Ẹ̀

Àwọn Tó Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Máa Ń Ṣe Ìpinnu Tó Bọ́gbọ́n Mu

Àwọn Tó Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Máa Ń Ṣe Ìpinnu Tó Bọ́gbọ́n Mu

Ka Jẹ́nẹ́sísì 25:29-34 kó o lè mọ̀ bóyá Ísọ̀ àti Jékọ́bù ṣe ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu.

Kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ nípa ohun tó ò ń kà. Kí ló ṣẹlẹ̀ ṣáájú ìgbà yẹn? (Jẹ́n. 25:20-28) Kí ló ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìgbà yẹn?—Jẹ́n. 27: 1-46.

Ṣèwádìí nípa àwọn nǹkan tó o kà. Àwọn ojúṣe àti ẹ̀tọ́ wo ni àkọ́bí ọkùnrin máa ń ní nígbà yẹn?—Jẹ́n. 18:18, 19; w10 5/1 13.

  • Ṣé dandan ni kí ọkùnrin jẹ́ àkọ́bí kó tó lè di baba ńlá Mèsáyà? (w17.12 14-15)

Wá àwọn ẹ̀kọ́ inú ẹ̀, kó o sì fi wọ́n sílò. Kí nìdí tí Jékọ́bù fi fọwọ́ pàtàkì mú ẹ̀tọ́ àkọ́bí ju Ísọ̀ lọ? (Héb. 12:16, 17; w03 10/15 28-29) Ojú wo ni Jèhófà fi wo àwọn méjèèjì, kí sì nìdí? (Mál. 1:2, 3) Kí ni Ísọ̀ ì bá ti ṣe kó lè ṣèpinnu tó bọ́gbọ́n mu?

  • Bi ara ẹ pé, ‘Báwo ni mo ṣe lè fi hàn pé ìjọsìn Jèhófà ṣe pàtàkì sí mi tí mo bá fẹ́ pinnu bí mo ṣe máa lo àkókò mi láàárín ọ̀sẹ̀?’