ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 14
ORIN 56 Sọ Òtítọ́ Di Tìrẹ
“Ẹ Jẹ́ Ká Tẹ̀ Síwájú, Ká Dàgbà Nípa Tẹ̀mí”
“Ẹ jẹ́ ká tẹ̀ síwájú, ká dàgbà nípa tẹ̀mí.”—HÉB. 6:1.
OHUN TÁ A MÁA KỌ́
A máa rí bó ṣe yẹ kí Kristẹni kan tó ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà máa ronú, kó sì máa hùwà tó ń múnú Jèhófà dùn.
1. Kí ni Jèhófà fẹ́ ká ṣe?
Ọ̀KAN lára ìgbà tínú tọkọtaya máa ń dùn jù ni ìgbà tí wọ́n bá bímọ tuntun. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ ọmọ wọn jòjòló, wọ́n máa ń fẹ́ kó dàgbà, kó sì kúrò ní ọmọ ọwọ́. Kódà, ìdààmú máa ń bá wọn tọ́mọ náà ò bá dàgbà bó ṣe yẹ. Lọ́nà kan náà, inú Jèhófà máa ń dùn sí wa tá a bá bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ nípa ẹ̀, àmọ́ kò fẹ́ ká dúró sójú kan, ó fẹ́ ká ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ. (1 Kọ́r. 3:1) Ohun tó fẹ́ ni pé ká di Kristẹni tó “dàgbà di géńdé.”—1 Kọ́r. 14:20.
2. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
2 Kí ló túmọ̀ sí láti di Kristẹni tó dàgbà di géńdé? Báwo la ṣe lè di Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀? Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ àwọn òtítọ́ Bíbélì tó jinlẹ̀, báwo nìyẹn ṣe máa jẹ́ ká ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà? Tá a bá tiẹ̀ ti di Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀, kí nìdí tí ò fi yẹ ká dára wa lójú jù? A máa rí ìdáhùn àwọn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ yìí.
BÁWO NI KRISTẸNI TÍ ÒTÍTỌ́ JINLẸ̀ NÍNÚ Ẹ̀ ṢE MÁA Ń HÙWÀ?
3. Báwo la ṣe lè di Kristẹni tó dàgbà di géńdé?
3 Nínú Bíbélì, ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n tú sí “dàgbà di géńdé” lè túmọ̀ sí “dàgbà nípa tẹ̀mí” àti “di pípé.” a (1 Kọ́r. 2:6) Bí ọmọ kékeré kan ṣe máa ń dàgbà títí tá á fi di géńdé, báwo la ṣe lè di Kristẹni tó dàgbà di géńdé tàbí tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀? Bá a ṣe lè ṣe é ni pé ká túbọ̀ máa ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. Kódà tá a bá ti di Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀, ó ṣì yẹ ká máa ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti sunwọ̀n sí i. (1 Tím. 4:15) Gbogbo wa, títí kan àwọn ọmọdé tó wà láàárín wa ló lè di Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀. Àmọ́, báwo la ṣe lè mọ̀ pé òtítọ́ jinlẹ̀ nínú Kristẹni kan?
4. Báwo la ṣe lè mọ Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀?
4 Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀ kì í yan èyí tó máa pa mọ́ nínú àwọn òfin Ọlọ́run, gbogbo ẹ̀ ló máa ń pa mọ́. Àmọ́ torí pé aláìpé ni, á ṣì máa ṣàṣìṣe. Síbẹ̀, ojoojúmọ́ lá máa ronú, táá sì máa hùwà tó máa múnú Jèhófà dùn. Ó ti gbé ìwà tuntun wọ̀, ó sì máa ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti ronú bí Jèhófà ṣe ń ronú. (Éfé. 4:22-24) Ó ti kọ́ bó ṣe máa ṣe ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu torí pé ó máa ń ronú lórí àwọn òfin àti ìlànà Jèhófà. Torí náà, kò nílò òfin jàǹrànjanran kó tó mọ ohun tó yẹ kó ṣe. Tó bá sì ṣèpinnu, ó máa ń sapá láti ṣe ohun tó pinnu.—1 Kọ́r. 9:26, 27.
5. Kí ló lè ṣẹlẹ̀ sí Kristẹni tí òtítọ́ ò jinlẹ̀ nínú ẹ̀? (Éfésù 4:14, 15)
5 Àmọ́ ní ti Kristẹni tí òtítọ́ ò jinlẹ̀ nínú ẹ̀, ó máa ń rọrùn fáwọn apẹ̀yìndà àtàwọn tó ń tan ìròyìn èké kiri láti fi “ẹ̀kọ́ ẹ̀tàn” àti “ọgbọ́nkọ́gbọ́n” ṣì í lọ́nà. b (Ka Éfésù 4:14, 15.) Bí àpẹẹrẹ, ó lè máa jowú àwọn míì, kó máa bá wọn jà, kó sì jẹ́ pé gbogbo èèyàn ló máa ń ṣẹ̀ ẹ́. Yàtọ̀ síyẹn, tí ohun kan bá dẹ ẹ́ wò, ohun tí ò tọ́ ló sábà máa ń ṣe.—1 Kọ́r. 3:3.
6. Ṣàpèjúwe bí ẹnì kan ṣe lè di Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀. (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
6 Bá a ṣe sọ ṣáájú, Bíbélì fi bí ẹnì kan ṣe ń di Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀ wé bí èèyàn ṣe ń dàgbà di géńdé. Ọ̀pọ̀ nǹkan ni ọmọdé ò mọ̀, torí náà ó gba pé kí àgbàlagbà kan máa tọ́ ọ sọ́nà, kó sì máa dáàbò bò ó. Ẹ wo àpèjúwe yìí ná: Ìyá kan lè sọ fún ọmọbìnrin ẹ̀ tó ṣì kéré pé kó di ọwọ́ òun mú dáadáa tí wọ́n bá fẹ́ sọdá títì. Bí ọmọ náà ṣe ń dàgbà, ìyá ẹ̀ lè gbà pé kó máa dá sọdá títì, àmọ́ á ṣì máa rán an létí pé kó wọ̀nà dáadáa kó tó sọdá. Tí ọmọ náà bá wá di àgbàlagbà, òun fúnra ẹ̀ á ti mọ̀ pé ó yẹ kóun máa wọ̀nà dáadáa kóun tó sọdá. Bí àwọn àgbàlagbà ṣe máa ń ran àwọn ọmọdé lọ́wọ́ kí wọ́n má bàa kó sínú ewu, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe yẹ káwọn Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn máa ran àwọn Kristẹni tí òtítọ́ ò jinlẹ̀ nínú wọn lọ́wọ́ kí àjọṣe wọn pẹ̀lú Jèhófà má bàa bà jẹ́, kí wọ́n sì lè ṣe ìpinnu tó tọ́. Àmọ́ tí Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀ bá fẹ́ ṣe ìpinnu, ó máa ń ronú jinlẹ̀ lórí ìlànà Bíbélì kó lè mọ èrò Jèhófà lórí ọ̀rọ̀ náà, á sì ṣèpinnu tó tọ́.
7. Ṣé Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀ lè sọ pé káwọn ẹlòmíì ran òun lọ́wọ́?
7 Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé àwọn míì ò lè ran Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀ lọ́wọ́? Rárá o. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ó yẹ káwọn Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn máa sọ pé káwọn ẹlòmíì ran àwọn lọ́wọ́. Àmọ́ ẹni tí òtítọ́ ò tíì jinlẹ̀ nínú ẹ̀ lè máa retí pé káwọn míì sọ ohun tó yẹ kóun ṣe tàbí ṣèpinnu fún òun, tó sì jẹ́ pé òun fúnra ẹ̀ ló yẹ kó ṣe ìpinnu náà. Àmọ́, tí Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀ bá sọ pé káwọn Kristẹni míì tí wọ́n nírìírí tí wọ́n sì gbọ́n ran òun lọ́wọ́, ó mọ̀ pé òun lòun máa ṣèpinnu, òun sì máa ‘ru ẹrù ara òun.’—Gál. 6:5.
8. Báwo làwọn Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn ṣe yàtọ̀ síra?
8 Bó ṣe jẹ́ pé ìrísí àwọn àgbàlagbà máa ń yàtọ̀ síra, bẹ́ẹ̀ náà làwọn Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn ní àwọn ànímọ́ tó yàtọ̀ síra. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n ní ọgbọ́n àti ìgboyà, wọ́n jẹ́ aláàánú, wọ́n sì lawọ́. Yàtọ̀ síyẹn, tí Kristẹni méjì tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn bá fẹ́ ṣe ìpinnu lórí ọ̀rọ̀ kan, wọ́n lè ṣe ìpinnu tó yàtọ̀ síra, síbẹ̀ kí ìpinnu méjèèjì bá Ìwé Mímọ́ mu. Irú nǹkan báyìí sábà máa ń ṣẹlẹ̀ táwa Kristẹni bá fẹ́ ṣèpinnu tó dá lórí ẹ̀rí ọkàn ẹnì kọ̀ọ̀kan wa. Ohun tá a mọ̀ yìí kì í jẹ́ ká dá àwọn míì lẹ́jọ́ tí ìpinnu wọn bá yàtọ̀ sí tiwa. Kàkà bẹ́ẹ̀, bá a ṣe máa wà níṣọ̀kan ló ṣe pàtàkì jù sí wa.—Róòmù 14:10; 1 Kọ́r. 1:10.
BÁWO LA ṢE LÈ DI KRISTẸNI TÍ ÒTÍTỌ́ JINLẸ̀ NÍNÚ Ẹ̀?
9. Ṣé èèyàn lè di Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀ láì sapá kankan? Ṣàlàyé.
9 Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ọmọdé kan máa dàgbà di géńdé torí bí Ọlọ́run ṣe dá wa nìyẹn. Àmọ́ tẹ́nì kan ò bá sapá gan-an, kò lè di Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin ní Kọ́ríńtì gba ìhìn rere gbọ́, wọ́n ṣèrìbọmi, Ọlọ́run fún wọn ní ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀, wọ́n sì jàǹfààní tó pọ̀ látinú ìmọ̀ràn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fún wọn. (Ìṣe 18:8-11) Síbẹ̀, ọdún mélòó kan lẹ́yìn tí wọ́n ṣèrìbọmi, ọ̀pọ̀ nínú wọn ò tíì di Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀. (1 Kọ́r. 3:2) Kí la lè ṣe tírú nǹkan yìí ò fi ní ṣẹlẹ̀ sí wa?
10. Tá a bá fẹ́ di Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀, kí la gbọ́dọ̀ ṣe? (Júùdù 20)
10 Ká tó lè di Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀, ó gbọ́dọ̀ wù wá láti ṣe bẹ́ẹ̀. Àwọn “aláìmọ̀kan” tí wọ́n yàn láti dúró sójú kan bí adágún omi ò ní lè di Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀ láé. (Òwe 1:22) Torí náà, a ò ní fẹ́ dà bí àwọn tó ti dàgbà àmọ́ tó jẹ́ pé àwọn òbí wọn ni wọ́n fẹ́ kó máa ṣèpinnu fún wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ló gbọ́dọ̀ máa ṣe àwọn nǹkan táá jẹ́ kó di Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀. (Ka Júùdù 20.) Torí náà, tó o bá ṣì ń sapá láti di Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀, bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó lè máa ‘wù ẹ́ láti gbé ìgbésẹ̀, kó sì fún ẹ lágbára láti ṣe é.’—Fílí. 2:13.
11. Àwọn nǹkan wo ló máa jẹ́ ká di Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀? (Éfésù 4:11-13)
11 Tá a bá fẹ́ di Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀, agbára wa nìkan ò gbé e, àfi ká jẹ́ kí Jèhófà ràn wá lọ́wọ́. Ó máa ń lo àwọn alábòójútó tí wọ́n tún jẹ́ olùkọ́ nínú ìjọ Kristẹni láti ràn wá lọ́wọ́ ká lè “di géńdé” tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀, ká sì “dàgbà dé ìwọ̀n kíkún ti Kristi.” (Ka Éfésù 4:11-13.) Jèhófà tún máa ń fi ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀ ràn wá lọ́wọ́ ká lè ní “èrò inú Kristi.” (1 Kọ́r. 2:14-16) Yàtọ̀ síyẹn, Ọlọ́run tún jẹ́ kí wọ́n kọ àwọn ìwé ìhìn rere mẹ́rin tó jẹ́ ká mọ bí Jésù ṣe ronú, bó ṣe sọ̀rọ̀ àti bó ṣe hùwà nígbà tó wà láyé. Tó o bá ń ronú bíi ti Jésù, tó o sì ń hùwà bíi tiẹ̀, wàá di Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀.
MÁA KẸ́KỌ̀Ọ́ ÀWỌN ÒTÍTỌ́ BÍBÉLÌ TÓ JINLẸ̀
12. Kí ni “àwọn ẹ̀kọ́ àkọ́bẹ̀rẹ̀ nípa Kristi”?
12 Ká tó lè di Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀, ohun tá a mọ̀ gbọ́dọ̀ “kọjá àwọn ẹ̀kọ́ àkọ́bẹ̀rẹ̀ nípa Kristi,” ìyẹn àwọn ohun tá a kọ́kọ́ mọ̀ nígbà tá a di Kristẹni. Lára irú àwọn ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ ni ìrònúpìwàdà, ìgbàgbọ́, ìrìbọmi àti àjíǹde. (Héb. 6:1, 2) Díẹ̀ lára àwọn ẹ̀kọ́ táwa Kristẹni tòótọ́ máa ń kọ́kọ́ mọ̀ nìyẹn. Ìdí nìyẹn tí àpọ́sítélì Pétérù fi sọ̀rọ̀ nípa wọn nígbà tó ń bá ọ̀pọ̀ èèyàn sọ̀rọ̀ lọ́jọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì. (Ìṣe 2:32-35, 38) Ó ṣe pàtàkì pé ká gba àwọn ẹ̀kọ́ àkọ́bẹ̀rẹ̀ yìí gbọ́ ká tó lè di ọmọlẹ́yìn Kristi. Bí àpẹẹrẹ, Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ pé ẹnikẹ́ni tí ò bá gba àjíǹde gbọ́ ò lè di ọmọlẹ́yìn Kristi. (1 Kọ́r. 15:12-14) Torí náà, kì í ṣe àwọn ẹ̀kọ́ àkọ́bẹ̀rẹ̀ nìkan ló yẹ ká mọ̀, ó tún yẹ ká máa kẹ́kọ̀ọ́ àwọn òtítọ́ Bíbélì tó jinlẹ̀.
13. Bí Hébérù 5:14 ṣe sọ, kí la gbọ́dọ̀ ṣe tá a bá fẹ́ jàǹfààní ẹ̀kọ́ òtítọ́ Bíbélì tó jinlẹ̀? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
13 Àwọn ẹ̀kọ́ àkọ́bẹ̀rẹ̀ yàtọ̀ sí ẹ̀kọ́ òtítọ́ Bíbélì tó jinlẹ̀ torí pé kì í ṣe àwọn òfin Jèhófà nìkan ló wà nínú ẹ̀, àwọn ìlànà Jèhófà tó máa jẹ́ ká mọ bó ṣe ń ronú náà wà níbẹ̀. Ká tó lè jàǹfààní ẹ̀, a gbọ́dọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì dáadáa, ká ronú jinlẹ̀ lórí ohun tá a kà, ká sì sapá láti fi àwọn ohun tá a kọ́ sílò nígbèésí ayé wa. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àá mọ bá a ṣe lè máa ṣèpinnu táá múnú Jèhófà dùn. c—Ka Hébérù 5:14.
14. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe ran àwọn tó wà ní Kọ́ríńtì lọ́wọ́ kí wọ́n lè di Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn?
14 Ó máa ń nira fáwọn Kristẹni tí òtítọ́ ò jinlẹ̀ nínú wọn láti ṣèpinnu tó tọ́, pàápàá tí kò bá sí òfin kankan nínú Bíbélì tó sọ̀rọ̀ nípa ìpinnu tí wọ́n fẹ́ ṣe. Tí kò bá sí òfin kankan nínú Bíbélì tó sọ nípa nǹkan tá a fẹ́ ṣe, àwọn kan lè ronú pé àwọn lè ṣe ohun tó wu àwọn. Àwọn míì sì lè máa rin kinkin pé òfin wo ló ti ọ̀rọ̀ kan lẹ́yìn, tó sì jẹ́ pé kò sírú òfin bẹ́ẹ̀ nínú Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, àwọn Kristẹni tó wà ní Kọ́ríńtì bi Pọ́ọ̀lù pé ṣé òfin kankan wà tó sọ bóyá káwọn jẹ ẹran tí wọ́n fi rúbọ sí òrìṣà tàbí káwọn má jẹ ẹ́? Dípò tí Pọ́ọ̀lù ì bá fi sọ ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe, ó jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ọ̀rọ̀ ẹ̀rí ọkàn ni àti pé kálukú wọn ló ní ‘ẹ̀tọ́ láti yan ohun tó wù ú.’ Ó wá mẹ́nu kan àwọn ìlànà Bíbélì kan tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣèpinnu tí kò ní da ẹ̀rí ọkàn wọn láàmú, tí kò sì ní mú àwọn míì kọsẹ̀. (1 Kọ́r. 8:4, 7-9) Torí náà, Pọ́ọ̀lù ran àwọn tó wà ní Kọ́ríńtì lọ́wọ́ kí wọ́n lè di Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn, kí wọ́n sì máa lo agbára ìfòyemọ̀ wọn dípò kí wọ́n jẹ́ káwọn ẹlòmíì ṣèpinnu fún wọn tàbí kí wọ́n máa wá òfin tí kò sí nínú Bíbélì.
15. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe ran àwọn Hébérù lọ́wọ́ láti di Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn?
15 A rí ẹ̀kọ́ pàtàkì kọ́ nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù. Àwọn kan ò jẹ́ kí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn, wọ́n sì ti ‘pa dà di ẹni tó nílò wàrà, dípò oúnjẹ líle nípa tẹ̀mí.’ (Héb. 5:12) Wọn ò kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn nǹkan tuntun tí Jèhófà ń kọ́ wọn nínú ìjọ, wọn ò sì gba àwọn ẹ̀kọ́ náà. (Òwe 4:18) Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ àwọn Júù tó di Kristẹni ṣì ń rin kinkin mọ́ Òfin Mósè, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọgbọ̀n (30) ọdún ṣáájú ìgbà yẹn ni wọn ò ti tẹ̀ lé Òfin náà mọ́ torí pé ẹbọ ìràpadà Kristi ti fòpin sí i. (Róòmù 10:4; Títù 1:10) Ó yẹ káwọn Júù tó di Kristẹni yẹn ti yí èrò wọn pa dà láti ọgbọ̀n (30) ọdún sẹ́yìn! Ẹni tó bá ka lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn Hébérù máa rí i pé ńṣe ló fẹ́ ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè gba ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó jinlẹ̀ tó ń kọ́ wọn. Lẹ́tà tó kọ sí wọn yẹn jẹ́ kó túbọ̀ dá wọn lójú pé ọ̀nà tuntun tí Jésù ní kí wọ́n máa gbà jọ́sìn Jèhófà báyìí dáa ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, ó sì tún jẹ́ kí wọ́n máa fìgboyà wàásù láìka àtakò látọ̀dọ̀ àwọn Júù sí.—Héb. 10:19-23.
MÁ DÁRA Ẹ LÓJÚ JÙ
16. Yàtọ̀ sí pé ká jẹ́ kí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wa, kí ló tún yẹ ká ṣe?
16 A gbọ́dọ̀ ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti di Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀, ká sì máa tẹ̀ síwájú. Kò yẹ ká dára wa lójú jù, ká wá máa rò pé òtítọ́ ti jinlẹ̀ nínú wa. (1 Kọ́r. ) Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló yẹ ká “máa dán ara [wa] wò,” ká sì rí i pé à ń tẹ̀ síwájú.— 10:122 Kọ́r. 13:5.
17. Báwo ni lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará Kólósè ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé ó yẹ kí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wa?
17 Nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará Kólósè, ó tún jẹ́ ká mọ̀ pé ó yẹ kí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wa, ká sì máa tẹ̀ síwájú. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti di Kristẹni tó dàgbà di géńdé, Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ fún wọn pé kí wọ́n má ṣe máa ronú bí àwọn èèyàn ayé ṣe ń ronú. (Kól. 2:6-10) Épáfírásì tó mọ àwọn ará ìjọ dáadáa máa ń gbàdúrà nígbà gbogbo pé “níkẹyìn, kí [wọ́n] lè dúró ní pípé” tàbí kí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn. (Kól. 4:12) Kí la rí kọ́? Pọ́ọ̀lù àti Épáfírásì mọ̀ pé ká tó lè di Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀, àfi kí Ọlọ́run ràn wá lọ́wọ́, káwa fúnra wa sapá gan-an, ká sì máa tẹ̀ síwájú. Torí náà, ohun tí wọ́n fẹ́ ni pé kí òtítọ́ máa jinlẹ̀ nínú àwọn ará Kólósè, kí wọ́n sì di Kristẹni tó dàgbà nípa tẹ̀mí láìka ìṣòro tí wọ́n ní sí.
18. Kí ló lè ṣẹlẹ̀ sí Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
18 Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ fáwọn Hébérù pé tí Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀ ò bá ṣọ́ra, ó lè má rí ojúure Ọlọ́run mọ́. Lọ́nà wo? Tí ọkàn Kristẹni kan bá le, kò ní lè ronú pìwà dà kí Ọlọ́run lè dárí jì í. A dúpẹ́ pé ọ̀rọ̀ àwọn Hébérù ò tíì burú tóyẹn. (Héb. 6:4-9) Àwọn tí wọ́n di aláìṣiṣẹ́mọ́ tàbí tí wọ́n yọ kúrò nínú ìjọ lásìkò wa yìí ńkọ́, àmọ́ tí wọ́n ronú pìwà dà? Bí wọ́n ṣe ronú pìwà dà fi hàn pé wọ́n nírẹ̀lẹ̀, wọ́n sì yàtọ̀ sáwọn tí Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà rẹ̀ sí. Òótọ́ ni pé wọ́n ti pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà, síbẹ̀ ó ṣì gba pé kí Jèhófà ràn wọ́n lọ́wọ́. (Ìsík. 34:15, 16) Torí náà, àwọn alàgbà lè ṣètò pé kí arákùnrin tàbí arábìnrin kan tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀ ràn wọ́n lọ́wọ́, kí wọ́n lè pa dà ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà.
19. Kí ló yẹ kó o máa ṣe?
19 Tó o bá ń ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti di Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀, ó dájú pé wàá ṣàṣeyọrí! Máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé, kó o sì máa ronú bí Jèhófà ṣe ń ronú. Tó o bá ti di Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀, tó o sì ti dàgbà di géńdé, a rọ̀ ẹ́ pé kó o máa tẹ̀ síwájú.
KÍ NI ÌDÁHÙN RẸ?
-
Kí ló túmọ̀ sí láti di Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀?
-
Báwo la ṣe lè di Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀?
-
Kí nìdí tí ò fi yẹ ká dára wa lójú jù?
ORIN 65 Ẹ Tẹ̀ Síwájú!
a Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù ò lo ọ̀rọ̀ náà “dàgbà nípa tẹ̀mí” àti “ẹni tí ò dàgbà nípa tẹ̀mí,” ó sọ ohun tó jọ ọ́. Bí àpẹẹrẹ, ìwé Òwe sọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín ọ̀dọ́ tó jẹ́ aláìmọ̀kan àti ẹni tó gbọ́n tó sì ní òye.—Òwe 1:4, 5.
b Wo àpilẹ̀kọ náà “Bó O Ṣe Lè Dáàbò Bo Ara Ẹ Lọ́wọ́ Àwọn Ìsọfúnni Tí Kì Í Ṣòótọ́” ní abala “Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò” lórí ìkànnì jw.org àti JW Library.®
c Wo apá tá a pè ní “Ohun Tó O Lè Kẹ́kọ̀ọ́ Nípa Ẹ̀” nínú Ilé Ìṣọ́ yìí.
d ÀLÀYÉ ÀWÒRÁN: Arákùnrin kan ń fi àwọn ìlànà Bíbélì tó kọ́ nínú Bíbélì sílò nígbà tó fẹ́ yan eré ìnàjú tó máa wò.