Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 16

ORIN 64 À Ń Fayọ̀ Ṣe Iṣẹ́ Ìkórè Náà

Bí Iṣẹ́ Ìwàásù Ṣe Lè Túbọ̀ Máa Fún Ẹ Láyọ̀

Bí Iṣẹ́ Ìwàásù Ṣe Lè Túbọ̀ Máa Fún Ẹ Láyọ̀

“Ẹ fi ayọ̀ sin Jèhófà.”SM. 100:2.

OHUN TÁ A MÁA KỌ́

Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tá a lè ṣe táá jẹ́ ká túbọ̀ máa láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.

1. Kí ni kì í jẹ́ kó yá àwọn ará wa kan lára láti wàásù? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

 ÀWA Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń wàásù fáwọn èèyàn torí pé a nífẹ̀ẹ́ Baba wa ọ̀run, a sì fẹ́ kí wọ́n mọ̀ ọ́n. Ọ̀pọ̀ lára wa máa ń gbádùn iṣẹ́ ìwàásù, àmọ́ àwọn kan kì í fi bẹ́ẹ̀ gbádùn ẹ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé àwọn kan lára wa máa ń tijú gan-an, ẹ̀rù sì lè máa bà wọ́n láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀. Kì í yá àwọn míì lára láti lọ sílé àwọn èèyàn, láìjẹ́ pé àwọn ló ní kí wọ́n wá. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ará wa kan lè máa bẹ̀rù pé àwọn èèyàn lè má gbọ́rọ̀ wọn. Ohun tí wọ́n sì fi kọ́ àwọn míì ni pé kí wọ́n máa yẹra fún ohunkóhun tó lè dá wàhálà sílẹ̀. Àwọn ará wa yìí nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an, àmọ́ kì í rọrùn fún wọn láti wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fáwọn tí wọn ò mọ̀ rí. Síbẹ̀, wọ́n mọ̀ pé iṣẹ́ ìwàásù ṣe pàtàkì gan-an, wọ́n sì máa ń sapá láti wàásù ní gbogbo ìgbà. Ẹ ò rí i pé inú Jèhófà máa dùn sí wọn gan-an!

Ṣé inú ẹ máa ń dùn tó o bá ń wàásù? (Wo ìpínrọ̀ 1)


2. Kí nìdí tí kò fi yẹ kó sú wa tá ò bá tiẹ̀ fi bẹ́ẹ̀ láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?

2 Ṣé àwọn ohun tá a sọ yẹn máa ń ṣe ìwọ náà, tíyẹn ò sì jẹ́ kó o fi bẹ́ẹ̀ láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, má jẹ́ kó sú ẹ. Tẹ́rù bá ń bà ẹ́ láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀, ìyẹn lè fi hàn pé o nírẹ̀lẹ̀, o ò fẹ́ máa ṣe ṣekárími, o ò sì fẹ́ máa bá àwọn èèyàn jiyàn. Òótọ́ kan ni pé kò sẹ́ni tó máa fẹ́ káwọn èèyàn fojú tí ò dáa wo òun, pàápàá tó bá jẹ́ pé oore ló fẹ́ ṣe fún wọn. Torí náà, mọ̀ dájú pé Baba wa ọ̀run mọ bí nǹkan ṣe rí lára ẹ, ó sì ṣe tán láti ràn ẹ́ lọ́wọ́. (Àìsá. 41:13) Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa ohun márùn-ún tá a lè ṣe tírú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ń ṣe wá. A tún máa sọ̀rọ̀ nípa bá a ṣe lè túbọ̀ máa láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.

JẸ́ KÍ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN FÚN Ẹ LÓKUN

3. Kí ló jẹ́ kí wòlíì Jeremáyà lè wàásù fáwọn èèyàn?

3 Ọjọ́ pẹ́ tí Jèhófà ti ń fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ fún àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ lókun nígbàkigbà tó bá gbé iṣẹ́ tó le fún wọn. Lára àwọn tó ṣe bẹ́ẹ̀ fún ni wòlíì Jeremáyà. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jèhófà ní kó lọ wàásù, kò kọ́kọ́ fẹ́ lọ. Jeremáyà tiẹ̀ sọ pé: “Mi ò mọ ọ̀rọ̀ sọ, ọmọdé lásán ni mí.” (Jer. 1:6) Àmọ́, kí ló jẹ́ kó nígboyà láti ṣiṣẹ́ tí Jèhófà gbé fún un? Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà bá a sọ ni. Jeremáyà sọ pé: “Ńṣe ló dà bí iná tó ń jó, tí wọ́n sé mọ́ inú egungun mi, mi ò lè pa á mọ́ra mọ́.” (Jer. 20:8, 9) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn tí Jeremáyà wàásù fún ò fẹ́ gbọ́rọ̀ ẹ̀, ohun tí Jèhófà ní kó bá wọn sọ fún un lókun láti ṣe iṣẹ́ náà.

4. Àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń ka Bíbélì, tá a sì ronú lórí ohun tá a kà? (Kólósè 1:9, 10)

4 Bíi ti Jeremáyà, ohun tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa ń fún àwa Kristẹni lókun gan-an. Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń kọ lẹ́tà sáwọn ará tó wà ní Kólósè, ó jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé tí wọ́n bá ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tí Jèhófà fẹ́, wọ́n á máa “rìn lọ́nà tó yẹ Jèhófà,” wọ́n á sì máa “so èso nínú gbogbo iṣẹ́ rere.” (Ka Kólósè 1:9, 10.) Iṣẹ́ ìwàásù wà lára iṣẹ́ rere tí Pọ́ọ̀lù ń sọ. Torí náà, tá a bá ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tá a sì ń ronú lórí ohun tá a kà, ìgbàgbọ́ tá a ní nínú Jèhófà á túbọ̀ lágbára, àá sì rídìí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa wàásù ìhìn rere Ìjọba náà.

5. Kí lá jẹ́ kó o túbọ̀ jàǹfààní tó o bá ń ka Bíbélì?

5 Tá a bá fẹ́ túbọ̀ jàǹfààní nígbà tá a bá ń ka Bíbélì, tá à ń kẹ́kọ̀ọ́ tàbí tá à ń ṣàṣàrò lórí ohun tá a kà níbẹ̀, kò yẹ ká máa kánjú ṣe é. Bí àpẹẹrẹ, tó o bá ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan, àmọ́ tí kò yé ẹ, má kàn gbójú fò ó. Dípò ìyẹn, ṣe ló yẹ kó o lo Ìwé Ìwádìí fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tàbí àwọn ìwé ètò Ọlọ́run míì tá a fi ń ṣèwádìí kó o lè rí àlàyé lórí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yẹn. Tó o bá ń fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, á túbọ̀ dá ẹ lójú pé òótọ́ lohun tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (1 Tẹs. 5:21) Bí ohun tó o kọ́ nínú Bíbélì bá ṣe dá ẹ lójú tó lá túbọ̀ máa wù ẹ́ láti sọ ohun tó ò ń kọ́ fáwọn míì.

MÚRA SÍLẸ̀ DÁADÁA KÓ O TÓ LỌ WÀÁSÙ

6. Kí nìdí tó fi yẹ ká múra sílẹ̀ dáadáa ká tó lọ wàásù?

6 Tá a bá múra sílẹ̀ dáadáa ká tó lọ wàásù, ọkàn wa á balẹ̀ tá a bá ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀. Bí àpẹẹrẹ, Jésù sọ àwọn nǹkan táwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ máa ṣe kó tó rán wọn jáde lọ wàásù. (Lúùkù 10:1-11) Torí pé wọ́n tẹ̀ lé ohun tí Jésù kọ́ wọn yìí, ọ̀pọ̀ nǹkan ni wọ́n ṣe láṣeyọrí, ìyẹn sì múnú wọn dùn gan-an.—Lúùkù 10:17.

7. Báwo la ṣe lè múra sílẹ̀ ká tó lọ wàásù? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

7 Báwo la ṣe lè múra sílẹ̀ ká tó lọ wàásù? Àkọ́kọ́ ni pé ká ronú lórí ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ, ká sì ṣàlàyé ẹ̀ lọ́nà táá rọrùn. Ohun míì ni pé ká ronú nǹkan méjì sí mẹ́ta táwọn èèyàn sábà máa ń sọ ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa tí wọn ò bá fẹ́ gbọ́rọ̀ wa àti bá a ṣe máa dá wọn lóhùn. Tá a bá wá dé ọ̀dọ̀ wọn, ká túra ká, ká rẹ́rìn-ín músẹ́, ká sì jẹ́ kára wa yá mọ́ wọn.

Múra sílẹ̀ dáadáa kó o tó lọ wàásù (Wo ìpínrọ̀ 7)


8. Nínú ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ, báwo làwa Kristẹni ṣe dà bí ohun èlò tí a fi amọ̀ ṣe?

8 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jẹ́ ká mọ ojúṣe pàtàkì tá a ní lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, ó sọ pé: “A ní ìṣúra yìí nínú àwọn ohun èlò tí a fi amọ̀ ṣe.” (2 Kọ́r. 4:7) Kí ni ìṣúra tí Pọ́ọ̀lù ń sọ? Iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ni, iṣẹ́ náà sì ń gbẹ̀mí àwọn èèyàn là. (2 Kọ́r. 4:1) Kí wá làwọn ohun èlò tí a fi amọ̀ ṣe? Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó ń wàásù ìhìn rere fáwọn èèyàn ni. Nígbà ayé Pọ́ọ̀lù, àwọn oníṣòwò máa ń fi ìkòkò amọ̀ gbé àwọn ohun tó ṣe pàtàkì bí oúnjẹ, wáìnì àti owó. Lọ́nà kan náà, Jèhófà gbé iṣẹ́ tó ṣeyebíye lé àwa náà lọ́wọ́ pé ká wàásù ìhìn rere. Ó dájú pé Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́, á sì fún wa lókun ká lè ṣe iṣẹ́ náà láṣeyọrí.

BẸ JÈHÓFÀ PÉ KÓ FÚN Ẹ NÍ ÌGBOYÀ

9. Kí ni ò ní jẹ́ ká máa bẹ̀rù pé àwọn èèyàn lè ta kò wá tàbí pé wọn ò ní gbọ́ ọ̀rọ̀ wa? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

9 Nígbà míì, a lè máa bẹ̀rù pé àwọn èèyàn lè ta kò wá tàbí pé wọ́n lè má gbọ́ ọ̀rọ̀ wa. Kí la lè ṣe tá ò fi ní máa bẹ̀rù? Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àdúrà táwọn àpọ́sítélì gbà nígbà táwọn aláṣẹ sọ pé wọn ò gbọ́dọ̀ wàásù mọ́. Dípò tí wọ́n á fi máa bẹ̀rù, wọ́n bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ káwọn lè máa “fi ìgboyà sọ̀rọ̀ [rẹ̀].” Ojú ẹsẹ̀ sì ni Jèhófà dáhùn àdúrà wọn. (Ìṣe 4:18, 29, 31) Torí náà, tẹ́rù bá ń bà wá láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, àwa náà lè gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́. Ká bẹ̀ ẹ́ pé kó jẹ́ ká túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, ká lè wàásù ìhìn rere náà fún wọn láìbẹ̀rù.

Gbàdúrà pé kí Jèhófà fún ẹ nígboyà (Wo ìpínrọ̀ 9)


10. Báwo ni Jèhófà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa jẹ́rìí nípa ẹ̀? (Àìsáyà 43:10-12)

10 Jèhófà ti yàn wá pé ká jẹ́ Ẹlẹ́rìí òun, ó sì ṣèlérí pé òun máa jẹ́ ká nígboyà. (Ka Àìsáyà 43:10-12.) Ẹ jẹ́ ká wo ọ̀nà mẹ́rin tó ń gbà ṣe bẹ́ẹ̀. Àkọ́kọ́ ni pé Jésù máa ń wà pẹ̀lú wa nígbàkigbà tá a bá ń wàásù ìhìn rere. (Mát. 28:18-20) Ìkejì, Jèhófà máa ń lo àwọn áńgẹ́lì láti ràn wá lọ́wọ́. (Ìfi. 14:6) Ìkẹta, Jèhófà máa ń fi ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀ ràn wá lọ́wọ́ ká lè rántí àwọn ohun tá a ti kọ́. (Jòh. 14:25, 26) Ìkẹrin, Jèhófà fi àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin kẹ́ wa. Ó dájú pé a máa ṣe iṣẹ́ ìwàásù láṣeyọrí torí pé Jèhófà wà lẹ́yìn wa, àwọn ará wa kárí ayé sì máa dúró tì wá.

MÁA WÀÁSÙ LÁSÌKÒ TÍ WÀÁ RÁWỌN ÈÈYÀN, KÓ O SÌ GBÀ PÉ WỌ́N Á GBỌ́RỌ̀ Ẹ

11. Kí la lè ṣe táá jẹ́ ká túbọ̀ ráwọn èèyàn bá sọ̀rọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

11 Ṣé iṣẹ́ ìwàásù máa ń sú ẹ torí pé o ò fi bẹ́ẹ̀ báwọn èèyàn nílé? Tó bá ń ṣe ẹ́ bẹ́ẹ̀, bi ara ẹ pé: ‘Ibo ló ṣeé ṣe káwọn èèyàn wà báyìí tá ò fi bá wọn nílé?’ (Ìṣe 16:13) ‘Ṣé ibi iṣẹ́ ni wọ́n wà ni àbí wọ́n lọ sọ́jà?’ Tó bá rí bẹ́ẹ̀, o ò ṣe gbìyànjú ìjẹ́rìí òpópónà bóyá wàá túbọ̀ ráwọn èèyàn bá sọ̀rọ̀? Arákùnrin kan tó ń jẹ́ Joshua sọ pé, “Mo máa ń ráwọn èèyàn wàásù fún tí mo bá lọ síbi tí wọ́n ti ń tajà àtàwọn ibòmíì térò máa ń pọ̀ sí.” Arákùnrin Joshua àti Bridget ìyàwó ẹ̀ tún máa ń báwọn èèyàn nílé lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́ àti ọ̀sán Sunday.—Éfé. 5:15, 16.

Máa wàásù lásìkò tó o máa bá àwọn èèyàn (Wo ìpínrọ̀ 11)


12. Báwo la ṣe lè mọ ohun táwọn èèyàn gbà gbọ́ tàbí tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí?

12 Tí ọ̀pọ̀ lára àwọn tá a lọ wàásù fún ò bá fẹ́ gbọ́rọ̀ wa, ó yẹ ká gbìyànjú láti mọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́ tàbí ohun tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí. Joshua àti Bridget tá a sọ̀rọ̀ wọn nínú ìpínrọ̀ tó ṣáájú máa ń lo ìbéèrè tó wà níwájú àṣàrò kúkúrú láti bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ wọn. Bí àpẹẹrẹ, tí wọ́n bá fẹ́ lo àṣàrò kúkúrú náà Irú Ìwé Wo Ni Bíbélì?, wọ́n á sọ pé: “Àwọn kan gbà pé Ọlọ́run ló ni Bíbélì, àwọn míì ò sì gbà bẹ́ẹ̀. Kí lèrò yín?” Kí wọ́n tó mọ̀, wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò pẹ̀lú ẹni náà.

13. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé a ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù báwọn èèyàn ò tiẹ̀ gbọ́rọ̀ wa? (Òwe 27:11)

13 Kì í ṣe báwọn èèyàn ṣe gbọ́rọ̀ wa tó ló ń pinnu àṣeyọrí tá a ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé a ti ṣe ohun tí Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ fẹ́ ká ṣe, ìyẹn sì ni pé ká wàásù. (Ìṣe 10:42) Torí náà, tá ò bá tiẹ̀ rẹ́ni bá sọ̀rọ̀ tàbí táwọn èèyàn ò gbọ́rọ̀ wa, a ṣì lè máa láyọ̀ torí a mọ̀ pé ohun tí Baba wa ọ̀run fẹ́ là ń ṣe.—Ka Òwe 27:11.

14. Kí nìdí tó fi yẹ kínú wa dùn tí arákùnrin tàbí arábìnrin kan bá rẹ́ni tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ ní ìpínlẹ̀ tá a ti ń wàásù?

14 Inú wa tún máa ń dùn tí arákùnrin tàbí arábìnrin kan bá rẹ́ni tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ ní ìpínlẹ̀ tá a ti ń wàásù. Nínú àpilẹ̀kọ Ilé Ìṣọ́ kan, a fi iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe wé àwọn tó ń wá ọmọ kan tó sọ nù. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń wá ọmọ náà kiri, kò síbi tí wọn ò wá a dé. Nígbà tí wọ́n rí ọmọ náà, inú àwọn tó rí i dùn, yàtọ̀ síyẹn, inú gbogbo àwọn tó ń wá a ló dùn. Lọ́nà kan náà, iṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn kì í ṣe iṣẹ́ ẹnì kan, iṣẹ́ gbogbo wa ni. Òótọ́ ni pé gbogbo wa là ń ṣiṣẹ́ kára ká lè wàásù fún gbogbo èèyàn ní ìpínlẹ̀ wa, àmọ́ tí arákùnrin tàbí arábìnrin kan bá rí ẹni tó máa kọ́ lẹ́kọ̀ọ́, tónítọ̀hún sì bẹ̀rẹ̀ sí í wá sípàdé, ó yẹ kínú gbogbo wa dùn.

JẸ́ KÍ ÌFẸ́ TÓ O NÍ FÚN JÈHÓFÀ ÀTÀWỌN ÈÈYÀN MÚ KÓ O TÚBỌ̀ MÁA WÀÁSÙ

15. Tá a bá ń ṣe ohun tí Mátíù 22:37-39 sọ, báwo nìyẹn ṣe máa jẹ́ ká túbọ̀ nítara lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù? (Tún wo iwájú ìwé.)

15 Tá a bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àtàwọn èèyàn, àá túbọ̀ nítara lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. (Ka Mátíù 22:37-39.) Ẹ wo bínú Jèhófà ṣe máa dùn tó bó ṣe ń rí i tá à ń ṣiṣẹ́ kára lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù! Yàtọ̀ síyẹn, inú àwọn tá à ń wàásù fún náà máa dùn tí wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì! Bákan náà, máa rántí pé àwọn tó bá tẹ́tí sọ́rọ̀ wa, tí wọ́n sì pinnu pé àwọn máa sin Jèhófà máa wà láàyè títí láé.—Jòh. 6:40; 1 Tím. 4:16.

Tá a bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àtàwọn èèyàn, àá túbọ̀ láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù (Wo ìpínrọ̀ 15)


16. Tí nǹkan kan bá ṣẹlẹ̀ sí wa tí ò jẹ́ ká lè kúrò nílé, kí lá jẹ́ ká máa láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù? Sọ àpẹẹrẹ kan.

16 Ṣé nǹkan kan ti ṣẹlẹ̀ sí ẹ tí ò jẹ́ kó o lè kúrò nílé? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, máa ṣe àwọn nǹkan tó fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àtàwọn èèyàn. Bí àpẹẹrẹ, nígbà àjàkálẹ̀ àrùn kòrónà, Samuel àti Dania ìyàwó ẹ̀ ò lè kúrò nílé. Ní gbogbo àsìkò tí nǹkan nira fún wọn yẹn, wọ́n máa ń fi fóònù wàásù déédéé, wọ́n máa ń kọ lẹ́tà, wọ́n sì máa ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lórí Zoom. Yàtọ̀ síyẹn, Samuel wàásù fáwọn tó rí nílé ìwòsàn nígbà tó lọ tọ́jú ara ẹ̀ torí pé ó ní àrùn jẹjẹrẹ. Ó sọ pé: “Tá a bá níṣòro tó le gan-an, ó máa ń tán wa lókun, kì í jẹ́ kọ́kàn wa balẹ̀, ó sì lè dán ìgbàgbọ́ wa wò. Àmọ́, ó yẹ kínú wa máa dùn bá a ṣe ń sin Jèhófà.” Àsìkò yẹn náà ni Dania ṣubú, odindi oṣù mẹ́ta ni ò fi lè kúrò lórí bẹ́ẹ̀dì. Lẹ́yìn ìgbà yẹn, wọ́n ní ó máa wà lórí kẹ̀kẹ́ arọ fún oṣù mẹ́fà. Dania sọ pé: “Mo ṣe gbogbo ohun tágbára mi gbé lásìkò yẹn. Bí àpẹẹrẹ, mo wàásù fún nọ́ọ̀sì kan tó wá tọ́jú mi, mo sì tún máa ń wàásù nílé fáwọn tí wọ́n wá gbé ọjà tá a rà fún wa. Yàtọ̀ síyẹn, obìnrin kan wà tó ń ṣojú fún ilé iṣẹ́ tó ń ta àwọn nǹkan tí wọ́n ń lò nílé ìwòsàn, torí náà mo máa ń wàásù fún un lórí fóònù.” Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Samuel àti Dania ò jẹ́ kí wọ́n lè ṣe tó bí wọ́n ṣe fẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, àmọ́ wọ́n ṣe gbogbo ohun tágbára wọn gbé, inú wọn sì ń dùn.

17. Àǹfààní wo lo máa rí tó o bá ṣe àwọn nǹkan márùn-ún tá a sọ nínú àpilẹ̀kọ yìí?

17 Tó o bá fẹ́ ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, a rọ̀ ẹ́ pé kó o ṣe àwọn nǹkan márùn-ún tá a sọ nínú àpilẹ̀kọ yìí. Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn nǹkan tá a ti jíròrò yìí dà bí èròjà tẹ́nì kan fẹ́ fi se oúnjẹ. Tó bá lo gbogbo èròjà náà, ó dájú pé oúnjẹ náà máa dùn. Lọ́nà kan náà, tá a bá ṣe gbogbo nǹkan márùn-ún tá a sọ nínú àpilẹ̀kọ yìí, kò ní jẹ́ ká rẹ̀wẹ̀sì lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe làá máa láyọ̀.

BÁWO LÀWỌN NǸKAN YÌÍ ṢE MÁA JẸ́ KÓ O TÚBỌ̀ LÁYỌ̀ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ?

  • Tó o bá múra sílẹ̀ dáadáa kó o tó lọ wàásù

  • Tó o bá bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ nígboyà

  • Tó o bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àtàwọn èèyàn

ORIN 80 ‘Tọ́ Ọ Wò, Kó O sì Rí I Pé Ẹni Rere Ni Jèhófà’