Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Kí nìdí táwọn tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì fi wà lára ọmọ ogun Ọba Dáfídì?

SÉLÉKÌ ọmọ Ámónì, Ùráyà ọmọ Hétì àti Ítímà ọmọ Móábù kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì, àmọ́ wọ́n wà lára àwọn ọmọ ogun Dáfídì. a (1 Kíró. 11:39, 41, 46) Kò tán síbẹ̀ o, àwọn kan lára “àwọn Kérétì àti àwọn Pẹ́lẹ́tì àti àwọn ará Gátì” tún wà lára àwọn ọmọ ogun Dáfídì. (2 Sám. 15:18) Àwọn èèyàn gbà pé àwọn Kérétì àtàwọn Pẹ́lẹ́tì tan mọ́ àwọn Filísínì. (Ìsík. 25:16) Àmọ́ ìlú Gátì tó wà ní agbègbè àwọn Filísínì làwọn ará Gátì ti wá.—Jóṣ. 13:2, 3; 1 Sám. 6:17, 18.

Kí nìdí tí Dáfídì fi jẹ́ káwọn tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì wà lára àwọn ọmọ ogun rẹ̀? Ìdí ni pé ó dá a lójú pé wọ́n jẹ́ adúrótini nígbà ìṣòro, wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ òun dénú. Èyí tó ṣe pàtàkì jù ni pé, wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, ìwé The New Interpreter’s Dictionary of the Bible sọ nípa àwọn Kérétì àtàwọn Pẹ́lẹ́tì pé: “Wọ́n dúró ti Dáfídì gbágbáágbá ní gbogbo ìgbà tí nǹkan le gan-an fún un lásìkò tó ń ṣàkóso.” Kí ni wọ́n ṣe? Nígbà tí “gbogbo àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì” fi Ọba Dáfídì sílẹ̀, tí wọ́n tẹ̀ lé ‘ọkùnrin oníwàhálà kan tó ń jẹ́ Ṣébà,’ àwọn Kérétì àtàwọn Pẹ́lẹ́tì ò fi Dáfídì sílẹ̀ rárá, wọ́n ràn án lọ́wọ́ láti paná ọ̀tẹ̀ tí Ṣébà dá sílẹ̀. (2 Sám. 20:1, 2, 7) Yàtọ̀ síyẹn, ìgbà kan wà tí Ádóníjà ọmọ Ọba Dáfídì fẹ́ gbàjọba mọ́ bàbá ẹ̀ lọ́wọ́. Àwọn Kérétì àtàwọn Pẹ́lẹ́tì tún dúró ti Dáfídì, wọ́n sì tì í lẹ́yìn láti fi Sólómọ́nì jọba torí òun ni Jèhófà yàn pé kó di ọba lẹ́yìn bàbá ẹ̀.—1 Ọba 1:24-27, 38, 39.

Ẹlòmíì tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì àmọ́ tó jẹ́ olóòótọ́ délẹ̀délẹ̀ sí Dáfídì ni Ítáì ará Gátì. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Ábúsálómù ọmọ Dáfídì dìtẹ̀ bàbá ẹ̀, tó sì ń dọ́gbọ́n fa ojú àwọn èèyàn Ísírẹ́lì mọ́ra, Ítáì àtàwọn ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) ọmọ ogun ẹ̀ kò fi Ọba Dáfídì sílẹ̀. Dáfídì tiẹ̀ sọ fún Ítáì pé kò yẹ kó jà fáwọn torí pé àjèjì ni. Àmọ́ Ítáì sọ pé: “Bí Jèhófà àti olúwa mi ọba ti wà láàyè, ibikíbi tí olúwa mi ọba bá wà, yálà fún ikú tàbí fún ìyè, ibẹ̀ ni ìránṣẹ́ rẹ yóò wà!”—2 Sám. 15: 6, 18-21.

Ítáì dúró ti Dáfídì torí pé òun ni ọba tí Jèhófà yàn

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn Kérétì, àwọn Pẹ́lẹ́tì àtàwọn ará Gátì kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n gbà pé Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́ àti pé Dáfídì ni ọba tí Jèhófà yàn. Ó dájú pé inú Dáfídì máa dùn gan-an torí pé àwọn ọkùnrin olóòótọ́ yìí dúró tì í gbágbáágbá!

a Òfin tó wà nínú Diutarónómì 23:3-6 jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ò fàyè gba àwọn ọmọ Ámónì àtàwọn ọmọ Móábù pé kí wọ́n wá sínú ìjọ Ísírẹ́lì. Àmọ́, ó jọ pé ohun tí ẹsẹ Bíbélì yìí ń sọ ni pé lábẹ́ òfin, wọn ò ní lè di ọmọ Ísírẹ́lì, wọn ò sì ní lẹ́tọ̀ọ́ sí gbogbo nǹkan tí ọmọ Ísírẹ́lì kan lè ṣe, bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n lè jọ ṣe àwọn nǹkan kan tàbí kí wọ́n gbé pa pọ̀. Wo ìwé Insight on the Scriptures, Ìdìpọ̀ Kìíní, ojú ìwé 95.