Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 17

ORIN 111 Ohun Tó Ń Fún Wa Láyọ̀

Má Kúrò Nínú Párádísè Tẹ̀mí Láé

Má Kúrò Nínú Párádísè Tẹ̀mí Láé

“Ẹ yọ̀, kí inú yín sì máa dùn títí láé torí ohun tí mò ń dá.”ÀÌSÁ. 65:18.

OHUN TÁ A MÁA KỌ́

Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa àǹfààní tá à ń rí torí pé a wà nínú Párádísè tẹ̀mí àti bá a ṣe lè jẹ́ káwọn míì wá dara pọ̀ mọ́ wa.

1. Kí ni Párádísè tẹ̀mí, kí la sì pinnu pé a máa ṣe?

 PÁRÁDÍSÈ kan wà láyé lónìí tí ọ̀pọ̀ èèyàn kún inú ẹ̀, tí ọwọ́ wọn dí, tí wọ́n sì ń ṣe àwọn nǹkan rere. Ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn ló wà níbẹ̀, àlàáfíà tòótọ́ sì wà láàárín wọn. Àwọn tó ti wà nínú Párádísè yìí ti pinnu pé àwọn ò ní kúrò níbẹ̀ láé. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n fẹ́ kí ọ̀pọ̀ èèyàn wá dara pọ̀ mọ́ wọn torí Párádísè náà ṣàrà ọ̀tọ̀. Párádísè wo là ń sọ? Párádísè tẹ̀mí a ni!

2. Kí ló mú kí Párádísè tẹ̀mí ṣàrà ọ̀tọ̀?

2 Ohun àgbàyanu ló jẹ́ pé nínú ayé burúkú tí Sátánì ti mú káwọn èèyàn kórìíra ara wọn, tí wọ́n sì burú gan-an, Jèhófà fi Párádísè tẹ̀mí jíǹkí àwa èèyàn ẹ̀ níbi tá a ti ní àlàáfíà, tá a sì wà níṣọ̀kan. (1 Jòh. 5:19; Ìfi. 12:12) Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ ti rí ohun tí ayé burúkú yìí ń fojú àwọn èèyàn rí, torí náà ó ṣe nǹkan tó fọkàn àwa èèyàn ẹ̀ balẹ̀ ká lè máa fayọ̀ sìn ín nìṣó. Bíbélì ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ pé Párádísè tẹ̀mí náà jẹ́ “ibi ààbò” àti “ọgbà tí wọ́n ń bomi rin dáadáa.” (Àìsá. 4:6; 58:11) Àwọn tó ń gbé inú Párádísè tẹ̀mí náà láwọn ọjọ́ ìkẹyìn tí nǹkan nira yìí ń láyọ̀, ọkàn wọn sì balẹ̀.—Àìsá. 54:14; 2 Tím. 3:1.

3. Báwo ni Àìsáyà orí 65 ṣe ṣẹ ní Ísírẹ́lì àtijọ́?

3 Jèhófà ṣàlàyé fún wòlíì Àìsáyà nípa bí nǹkan ṣe máa rí fáwọn táá máa gbé inú Párádísè tẹ̀mí. Ohun tí Jèhófà sọ fún un wà nínú Àìsáyà orí 65, ọdún 537 Ṣ.S.K. lọ̀rọ̀ náà sì kọ́kọ́ ṣẹ. Lọ́dún yẹn, a dá àwọn Júù tó ronú pìwà dà sílẹ̀ nígbèkùn Bábílónì, wọ́n sì pa dà sí Jérúsálẹ́mù ìlú ìbílẹ̀ wọn. Jèhófà bù kún àwọn èèyàn ẹ̀, ó sì ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè tún Jérúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì tó ti pa run kọ́, kí wọ́n sì lè pa dà máa jọ́sìn ẹ̀ nínú tẹ́ńpìlì náà ní Ísírẹ́lì.—Àìsá. 51:11; Sek. 8:3.

4. Báwo ni Àìsáyà orí 65 ṣe ṣẹ lásìkò wa yìí?

4 Ọdún 1919 S.K. ni ìgbà kejì tí àsọtẹ́lẹ̀ Àìsáyà ṣẹ, ọdún yẹn sì ni Jèhófà dá àwa èèyàn ẹ̀ sílẹ̀ nígbèkùn Bábílónì Ńlá. Látọdún yẹn ni Párádísè tẹ̀mí ti bẹ̀rẹ̀, tó sì wà nínú ìjọ àwa èèyàn Jèhófà kárí ayé. Àwọn èèyàn Jèhófà tó ń fìtara wàásù nígbà yẹn dá ọ̀pọ̀ ìjọ sílẹ̀, wọ́n sì ń hùwà tí ẹ̀mí Ọlọ́run máa ń jẹ́ ká ní. Àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n ń hùwà ipá, tí wọ́n ń hùwà bí ẹranko pa ìwà náà tì, wọ́n sì “gbé ìwà tuntun wọ̀, èyí tí a dá gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọ́run.” (Éfé. 4:24) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Párádísè tẹ̀mí là ń gbádùn báyìí, ọjọ́ iwájú nínú ayé tuntun la ti máa gbádùn àwọn ohun rere tí Àìsáyà sọ yẹn. Àmọ́ ní báyìí, à ń jàǹfààní tó pọ̀ gan-an torí pé a wà nínú Párádísè tẹ̀mí. Torí náà, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àwọn àǹfààní tá à ń rí àti ìdí tí kò fi yẹ ká kúrò níbẹ̀ láé.

NǸKAN TÁWỌN TÓ WÀ NÍNÚ PÁRÁDÍSÈ TẸ̀MÍ Ń GBÁDÙN

5. Kí ni Àìsáyà 65:13 sọ pé à ń gbádùn nínú Párádísè tẹ̀mí?

5 Jèhófà ń bọ́ wa, ara sì tù wá. Àsọtẹ́lẹ̀ Àìsáyà jẹ́ ká mọ̀ pé ìyàtọ̀ gbọ̀ọ̀rọ̀-gbọọrọ máa wà láàárín àwọn tó wà nínú Párádísè tẹ̀mí àtàwọn tí kò sí níbẹ̀. (Ka Àìsáyà 65:13.) Jèhófà ti fún wa ní gbogbo nǹkan táá jẹ́ káwa èèyàn ẹ̀ lè máa sìn ín nìṣó. Ó fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀, Bíbélì ọ̀rọ̀ ẹ̀ àtàwọn ìwé àti fídíò tó dá lórí ọ̀rọ̀ rẹ̀, ká lè ‘máa jẹun, ká máa mu, ká sì máa yọ̀.’ (Fi wé Ìfihàn 22:17.) Àmọ́, ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ fáwọn tí kò sí nínú Párádísè tẹ̀mí, ‘ebi ń pa wọ́n, òùngbẹ ń gbẹ wọ́n, ojú sì ń tì wọ́n.’ Ìdí ni pé wọn ò ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà.—Émọ́sì 8:11.

6. Àwọn nǹkan wo ni Jóẹ́lì 2:21-24 sọ pé Jèhófà pèsè fún wa, àǹfààní wo la sì ń rí?

6 Nínú àsọtẹ́lẹ̀ kan tí wòlíì Jóẹ́lì sọ, ó sọ̀rọ̀ nípa àwọn oúnjẹ tó ṣe pàtàkì, irú bí ọkà, wáìnì àti òróró ólífì láti fi hàn pé Jèhófà máa ń pèsè àwọn nǹkan táwa èèyàn ẹ̀ nílò, títí kan àwọn nǹkan tó ń jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa lágbára. (Jóẹ́lì 2:21-24) Lára àwọn nǹkan náà ni Bíbélì tó fi ń tọ́ wa sọ́nà, àwọn ìwé tó dá lórí Bíbélì, ìkànnì wa, àwọn ìpàdé ìjọ, àpéjọ àyíká àti àpéjọ agbègbè. Tá a bá ń lo àwọn nǹkan tí Jèhófà pèsè fún wa yìí déédéé, a máa jàǹfààní tó pọ̀ gan-an, ìgbàgbọ́ wa máa túbọ̀ lágbára, ọkàn wa sí máa balẹ̀.

7. Kí ló ń jẹ́ kí “ayọ̀ kún inú ọkàn” wa? (Àìsáyà 65:14)

7 À ń láyọ̀, a sì nítẹ̀ẹ́lọ́rùn. Àwa èèyàn Jèhófà ń “kígbe ayọ̀” torí pé a mọyì àwọn nǹkan tí Jèhófà ń ṣe fún wa. (Ka Àìsáyà 65:14.) Àwọn ìlérí Jèhófà tó wà nínú Bíbélì ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó ń tù wá nínú àti ìrètí tó dájú tá a ní, tí ẹbọ ìràpadà Kristi mú kó ṣeé ṣe ń fi “ayọ̀ kún inú ọkàn” wa. Kò sí àní-àní pé gbogbo ìgbà tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìlérí yìí pẹ̀lú àwọn ará wa máa ń mú inú wa dùn gan-an!—Sm. 34:8; 133:1-3.

8. Nǹkan pàtàkì méjì wo ló mú kí Párádísè tẹ̀mí ṣàrà ọ̀tọ̀?

8 Ìfẹ́ àti ìṣọ̀kan tó wà láàárín àwa èèyàn Jèhófà ni nǹkan pàtàkì méjì tó mú kí Párádísè tẹ̀mí ṣàrà ọ̀tọ̀. “Ìdè ìrẹ́pọ̀” tó wà láàárín wa yìí ń jẹ́ ká mọ bí nǹkan ṣe máa rí nínú ayé tuntun, níbi táwa èèyàn Jèhófà ti máa túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ ara wa, tí àá sì túbọ̀ wà níṣọ̀kan ju ti báyìí lọ. (Kól. 3:14) Arábìnrin kan sọ ohun tó kíyè sí nípa àwa èèyàn Jèhófà nígbà tó kọ́kọ́ pàdé wa, ó sọ pé: “Mi ò kì í láyọ̀, kódà àwọn tá a jọ wà nínú ìdílé kì í láyọ̀. Ìgbà àkọ́kọ́ láyé mi tí mo rí àwọn èèyàn tó nífẹ̀ẹ́ ara wọn dénú ni ìgbà tí mo pàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.” Torí náà, tó o bá fẹ́ ní ayọ̀ tòótọ́ àti ìtẹ́lọ́rùn, o gbọ́dọ̀ wá sínú Párádísè tẹ̀mí. Ohun yòówù kí ayé yìí máa rò nípa àwa èèyàn Jèhófà, ó dá wa lójú pé a ní orúkọ rere lọ́dọ̀ Jèhófà àtàwọn tá a jọ ń sìn ín.—Àìsá. 65:15.

9. Kí ni Àìsáyà 65:16, 17 sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ sáwọn ìṣòro wa?

9 Ara tù wá, ọkàn wa sì balẹ̀. Àìsáyà 65:14 sọ pé àwọn tí ò wá sínú Párádísè tẹ̀mí máa ‘ké jáde torí ìrora ọkàn, wọ́n sì máa pohùn réré ẹkún torí ìbànújẹ́ ọkàn.’ Àmọ́ kí ló máa ṣẹlẹ̀ sáwọn nǹkan tó ti fa ìrora bá àwa èèyàn Jèhófà, tó sì ti kóyà jẹ wá? Ó dájú pé gbogbo ẹ̀ “máa di ohun ìgbàgbé, [wọ́n sì] máa pa mọ́ kúrò ní ojú [Ọlọ́run].” (Ka Àìsáyà 65:16, 17.) Jèhófà máa mú àwọn ìṣòro wa kúrò, tó bá sì yá, a ò ní rántí àwọn ìṣòro náà mọ́ láé.

10. Kí nìdí tó o fi mọyì àǹfààní tó o ní pé o wà nínú ètò Ọlọ́run pẹ̀lú àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

10 Kódà ní báyìí, ọkàn àwa èèyàn Jèhófà máa ń balẹ̀ láwọn ìpàdé ìjọ wa, ara máa ń tù wá níbẹ̀, a kì í sì í rántí àwọn ìṣòro tó ń bá wa fínra nínú ayé burúkú yìí. Ọkàn àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tún máa balẹ̀ tá a bá ń fi àwọn ìwà tí ẹ̀mí Ọlọ́run máa ń jẹ́ ká ní hàn sí wọn, irú bí ìfẹ́, ayọ̀, àlàáfíà, inú rere àti ìwà tútù. (Gál. 5:22, 23) Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá la ní pé a wà nínú ètò Ọlọ́run! Àwọn tó bá wà nínú Párádísè tẹ̀mí, tí wọn ò sì kúrò níbẹ̀ máa rí ìgbà tí Ọlọ́run máa mú gbogbo ìlérí ẹ̀ ṣẹ pé òun máa dá “ọ̀run tuntun àti ayé tuntun.”

Àǹfààní ńlá ló jẹ́ pé a wà lára àwọn èèyàn tó ń jọ́sìn Jèhófà nínú Párádísè tẹ̀mí (Wo ìpínrọ̀ 10) c


11.Àìsáyà 65:18, 19 ṣe sọ, báwo ló ṣe yẹ kí Párádísè tẹ̀mí tí Jèhófà ṣètò rí lára wa?

11 A mọyì Párádísè tẹ̀mí, inú wa sì ń dùn. Bí Àìsáyà ṣe ń bá ọ̀rọ̀ ẹ̀ lọ, ó ṣàlàyé ìdí tó fi yẹ káwa èèyàn Jèhófà máa “yọ̀, kí inú [wa] sì máa dùn” nínú Párádísè tẹ̀mí. Jèhófà ló dìídì ṣètò Párádísè tẹ̀mí yìí. (Ka Àìsáyà 65:18, 19.) Torí náà, kò yà wá lẹ́nu pé Jèhófà ń lò wá láti ran àwọn èèyàn tí kò mọ òtítọ́ nípa òun lọ́wọ́, kí wọ́n lè kúrò nínú ẹ̀sìn èké, kí wọ́n sì wá sínú Párádísè tẹ̀mí! Torí pé a wà nínú ètò Ọlọ́run, tá a sì láǹfààní láti máa kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, ìdí nìyẹn tínú wa fi ń dùn.—Jer. 31:12.

12. Báwo ni ìlérí tí Jèhófà ṣe nínú Àìsáyà 65:20-24 ṣe rí lára ẹ, kí sì nìdí?

12 A tún mọyì àǹfààní tá a ní pé a wà nínú Párádísè tẹ̀mí, inú wa sì ń dùn torí pé a nírètí pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa. Ronú nípa bí nǹkan ṣe máa rí nínú ayé tuntun, ìyẹn gbogbo àwọn nǹkan tá a máa rí àtàwọn nǹkan tá a máa ṣe! Ọlọ́run ṣèlérí nínú Bíbélì pé: “Kò ní sí ọmọ ọwọ́ kankan . . . tó máa lo ọjọ́ díẹ̀ mọ́, kò sì ní sí àgbàlagbà kankan tí kò ní lo ọjọ́ rẹ̀ dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.” A máa ‘kọ́ ilé, a sì máa gbé inú wọn, a máa gbin ọgbà àjàrà, a sì máa jẹ èso wọn.’ A “ò ní ṣiṣẹ́ kára lásán” torí pé “Jèhófà [máa] bù kún” wa. Jèhófà ṣèlérí fún wa pé òun máa dáàbò bò wá, òun sì máa fún wa láwọn nǹkan tá a fẹ́, ó sọ pé: ‘Kódà ká tó pè,’ òun ti mọ ohun tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa fẹ́, òun sì máa “fún gbogbo ohun alààyè ní ohun tí wọ́n ń fẹ́.”—Àìsá. 65:20-24; Sm. 145:16.

13. Àwọn àyípadà wo ni Àìsáyà 65:25 sọ pé àwọn èèyàn ṣe nígbèésí ayé wọn nígbà tí wọ́n fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í jọ́sìn Jèhófà?

13 Àlàáfíà tòótọ́ wà láàárín wa, ọkàn wa sì balẹ̀. Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ti ran ọ̀pọ̀ èèyàn tí wọ́n ń hùwà bí ẹranko tẹ́lẹ̀ lọ́wọ́, wọ́n sì ti ṣe àwọn àyípadà tó yẹ nígbèésí ayé wọn. (Ka Àìsáyà 65:25.) Wọ́n ti ṣiṣẹ́ kára kí wọ́n lè jáwọ́ nínú àwọn ìwà tí ò dáa yẹn. (Róòmù 12:2; Éfé. 4:22-24) Òótọ́ ni pé aláìpé ṣì làwa èèyàn Ọlọ́run, torí náà kò sí bá ò ṣe ní máa ṣàṣìṣe. Àmọ́ Jèhófà ti kó “onírúurú èèyàn” tó nífẹ̀ẹ́ ẹ̀ jọ, tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn, ìyẹn sì jẹ́ kí àlàáfíà tòótọ́ àti ìṣọ̀kan wà láàárín wa. (Títù 2:11) Jèhófà Ọlọ́run Olódùmarè nìkan ló lè mú kíyẹn ṣeé ṣe!

14. Báwo ni ìrírí arákùnrin kan ṣe fi hàn pé òótọ́ lohun tó wà nínú Àìsáyà 65:25?

14 Ṣé ó ṣeé ṣe káwọn èèyàn yí ìwà wọn pa dà? Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kan. Nígbà tí ọ̀dọ́kùnrin kan fi máa pé ogún ọdún, ọ̀pọ̀ ìgbà ló ti lọ sẹ́wọ̀n, ó máa ń ṣèṣekúṣe, ó sì máa ń hùwà ipá. Wọ́n jù ú sẹ́wọ̀n torí pé ó jí mọ́tò, ó fọ́lé àti nítorí àwọn ìwà ọ̀daràn míì tó burú jáì. Ìgbà gbogbo ló máa ń fẹ́ bá àwọn èèyàn jà. Àmọ́ nígbà tó kọ́kọ́ gbọ́ nípa ẹ̀kọ́ òtítọ́ inú Bíbélì tó sì bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sípàdé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó wá dá a lójú pé òun ti rí ẹ̀sìn tòótọ́, òun á sì máa sin Jèhófà nínú Párádísè tẹ̀mí. Lẹ́yìn tó ṣèrìbọmi tó sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, gbogbo ìgbà ló máa ń ronú lórí bí àwọn àyípadà tóun ti ṣe ṣe bá Àìsáyà 65:25 mu. Ní báyìí, kò hùwà ẹhànnà mọ́, ó ti wá dẹni jẹ́jẹ́ tó wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn èèyàn.

15. Kí nìdí tó fi ń wù wá pé káwọn èèyàn wá dara pọ̀ mọ́ wa nínú Párádísè tẹ̀mí, báwo la sì ṣe lè ṣe é?

15 Ọ̀rọ̀ tó bẹ̀rẹ̀ Àìsáyà 65:13 sọ pé “ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí,” nígbà tí ọ̀rọ̀ tó parí ẹsẹ kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) sọ pé, “ni Jèhófà wí.” Kò sí àní-àní pé gbogbo ìgbà ni àwọn ìlérí Jèhófà máa ń ṣẹ. (Àìsá. 55:10, 11) Torí náà, ó dá wa lójú pé a ti ń gbádùn Párádísè tẹ̀mí báyìí. Jèhófà ti kó àwọn èèyàn tó ń jọ́sìn ẹ̀ jọ, wọ́n sì ṣàrà ọ̀tọ̀. Torí pé a wà lára àwọn tó ń jọ́sìn Jèhófà, a ní àlàáfíà, ọkàn wa sì balẹ̀ bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìwà ipá pọ̀ láyé yìí. (Sm. 72:7) Ìdí nìyẹn tó fi ń wù wá pé ká ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè wá dara pọ̀ mọ́ wa, ká lè jọ máa jọ́sìn Jèhófà nínú Párádísè tẹ̀mí. Torí náà, tá a bá gbájú mọ́ iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn, a máa ṣàṣeyọrí.—Mát. 28:19, 20.

BÁ A ṢE LÈ MÚ KÁWỌN ÈÈYÀN WÁ SÍNÚ PÁRÁDÍSÈ TẸ̀MÍ

16. Kí ló ń jẹ́ káwọn èèyàn wá sínú Párádísè tẹ̀mí?

16 Ẹnì kọ̀ọ̀kan wa gbọ́dọ̀ máa ṣe ohun táá jẹ́ káwọn èèyàn wá sínú Párádísè tẹ̀mí. A sì lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń fara wé Jèhófà. Kì í fipá mú àwọn èèyàn kí wọ́n wá sin òun. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló máa ń fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ ‘fa’ àwọn èèyàn sọ́dọ̀ ara rẹ̀. (Jòh. 6:44; Jer. 31:3) Abájọ tó fi jẹ́ pé táwọn èèyàn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ bá kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà àtàwọn ànímọ́ rẹ̀, ó máa ń wù wọ́n kí wọ́n sún mọ́ ọn. Torí náà, báwo la ṣe lè jẹ́ kí ìwà àti ìṣe wa mú kó máa wu àwọn èèyàn láti wá sínú Párádísè tẹ̀mí?

17. Kí la lè ṣe táá jẹ́ kó máa wu àwọn èèyàn láti wá sínú Párádísè tẹ̀mí?

17 Ohun kan tá a lè ṣe táá mú káwọn èèyàn wá sínú Párádísè tẹ̀mí ni pé ká máa fìfẹ́ hàn sáwọn tá a jọ ń sin Jèhófà, ká sì máa ṣe dáadáa sí wọn. Torí náà, a fẹ́ káwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sípàdé wa náà nírú èrò táwọn aláìgbàgbọ́ tó wá sípàdé ní Kọ́ríńtì ìgbà àtijọ́ yẹn ní. Èrò wo ni wọ́n ní? Wọ́n sọ pé: “Ọlọ́run wà láàárín yín lóòótọ́.” (1 Kọ́r. 14:24, 25; Sek. 8:23) Èyí jẹ́ ká rí i pé ó yẹ ká máa tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù gbà wá pé ká “wà ní àlàáfíà pẹ̀lú ara [wa].”—1 Tẹs. 5:13.

18. Kí ló lè mú káwọn èèyàn wá sin Jèhófà?

18 Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa ṣeyebíye gan-an lójú Jèhófà, torí náà ó yẹ káwa náà sapá láti fara wé e. Bá a ṣe lè ṣe é ni pé ká máa wo ibi táwọn ará wa dáa sí, dípò tí àá fi máa wo àìpé wọn tí ò ní sí mọ́ láìpẹ́. Torí náà tí èdèkòyédè bá wáyé láàárín wa, ó yẹ ká fìfẹ́ yanjú ẹ̀, ká ‘jẹ́ onínúure sí ara wa, ká máa ṣàánú, ká sì máa dárí ji ara wa fàlàlà.’ (Éfé. 4:32) Ó dájú pé táwọn èèyàn bá rí bá a ṣe ń hùwà tó dáa síra wa, á wù wọ́n láti wá sínú Párádísè tẹ̀mí. b

MÁ KÚRÒ NÍNÚ PÁRÁDÍSÈ TẸ̀MÍ

19. (a) Bó ṣe wà nínú àpótí náà “ Wọ́n Pa Dà Sínú Ètò Ọlọ́run,” kí làwọn kan sọ nígbà tí wọ́n pa dà sínú Párádísè tẹ̀mí? (b) Kí la pinnu pé a máa ṣe? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

19 A dúpẹ́, a tọ́pẹ́ dá pé a wà nínú Párádísè tẹ̀mí! A ti túbọ̀ wà níṣọ̀kan, àlàáfíà túbọ̀ wà láàárín wa, àwa tá à ń jọ́sìn Jèhófà sì ti pọ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Títí ayé làá máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó jẹ́ ká wà nínú Párádísè tẹ̀mí. Torí náà, ẹni tó bá fẹ́ kára tu òun, tó fẹ́ nítẹ̀ẹ́lọ́rùn, tó sì fẹ́ kọ́kàn òun balẹ̀ gbọ́dọ̀ wá sínú Párádísè tẹ̀mí, kó má sì kúrò níbẹ̀ láé! Àmọ́, ó yẹ ká ṣọ́ra torí gbogbo ọgbọ́n ni Sátánì ń dá ká lè kúrò nínú Párádísè tẹ̀mí. (1 Pét. 5:8; Ìfi. 12:9) Torí náà, ẹ má ṣe jẹ́ ká gbà fún un o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká máa ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká lè túbọ̀ máa wà ní àlàáfíà, ká sì wà níṣọ̀kan nínú Párádísè tẹ̀mí.

Àwọn tí ò bá kúrò nínú Párádísè tẹ̀mí máa gbádùn Párádísè tí Jèhófà ṣèlérí lọ́jọ́ iwájú (Wo ìpínrọ̀ 19)


KÍ NI ÌDÁHÙN RẸ?

  • Kí ni Párádísè tẹ̀mí?

  • Àwọn nǹkan wo là ń gbádùn nínú Párádísè tẹ̀mí?

  • Kí la lè ṣe táá mú káwọn èèyàn wá sínú Párádísè tẹ̀mí?

ORIN 144 Tẹjú Mọ́ Èrè Náà!

a ÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀: “Párádísè tẹ̀mí” ṣàpẹẹrẹ ibi tá a ti ń jọ́sìn Jèhófà, tí ọkàn wa sì balẹ̀. Nínú Párádísè tẹ̀mí yìí, àjọṣe tó dáa wà láàárín àwa àti Jèhófà, àlàáfíà sì wà láàárín àwa àtàwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin.

b Wo fídíò náà Ibo Ni Wọ́n Wà Báyìí? Alena Žitníková: Mo Rí Ohun Tí Mò Ń Wá lórí jw.org, wàá rí bí arábìnrin kan ṣe jàǹfààní torí pé ó wà nínú Párádísè tẹ̀mí.

c ÀLÀYÉ ÀWÒRÁN: Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ nípàdé, dípò kí arákùnrin kan dara pọ̀ mọ́ wọn, ńṣe ló dá jókòó.