Bá A Ṣe Lè Bọ́ Àwọn Ìwà Àtijọ́ Sílẹ̀, Ká Má sì Gbé E Wọ̀ Mọ́
“Ẹ bọ́ ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn àṣà rẹ̀.”—KÓL. 3:9.
ORIN: 83, 129
1, 2. Kí làwọn èèyàn ti sọ nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà?
ÀWỌN èèyàn máa ń sọ̀rọ̀ nípa ìwà dáadáa táwa èèyàn Jèhófà ń hù. Bí àpẹẹrẹ, òǹkọ̀wé kan tó ń jẹ́ Anton Gill sọ nípa ìwà àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa nígbà ìjọba Násì lórílẹ̀-èdè Jámánì, ó ní: “Àwọn aláṣẹ ìjọba Násì gbógun ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gan-an. . . . Nígbà tó fi máa dọdún 1939, ẹgbẹ̀rún mẹ́fà [6,000] àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló wà ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́.” Òǹkọ̀wé náà tún sọ pé láìka bí wọ́n ṣe fìyà jẹ àwọn Ẹlẹ́rìí tó, wọ́n jẹ́ olóòótọ́, ọkàn wọn balẹ̀, wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run wọn, wọ́n sì wà níṣọ̀kan.
2 Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àwọn èèyàn ní orílẹ̀-èdè South Africa náà kíyè sí ìwà dáadáa táwa èèyàn Ọlọ́run ní. Ìgbà kan wà tí àwọn Ẹlẹ́rìí tó jẹ́ aláwọ̀ funfun ò lè péjọ pẹ̀lú àwọn tó jẹ́ aláwọ̀ dúdú lórílẹ̀-èdè yẹn. Síbẹ̀, lọ́jọ́ Sunday, December 18, 2011, àwọn Ẹlẹ́rìí tó ju ẹgbẹ̀rún lọ́nà méjìdínlọ́gọ́rin [78,000] lọ péjọ pọ̀ láti gbádùn àpéjọ kan. Orílẹ̀-èdè South Africa àtàwọn orílẹ̀-èdè míì tó wà nítòsí ni awọn tó pé jọ ti wá. Pápá ìṣeré tó tóbi jù nílùú Johannesburg ni wọ́n sì lò fún àpéjọ náà. Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ torí pé àti aláwọ̀ funfun àti aláwọ̀ dúdú ló péjọ síbẹ̀. Nígbà tí ọ̀kan lára àwọn tó ń bójú tó pápá ìṣeré náà
ń sọ̀rọ̀ nípa àpéjọ yẹn, ó ní: “Mi ò rí àwọn èèyàn tó níwà tó dáa bíi tiyín rí ní pápá ìṣeré yìí. Gbogbo yín lẹ múra dáadáa. Ẹ tún mú kí pápá ìṣeré yìí mọ́ tónítóní nígbà tẹ́ ẹ ṣe tán. Àmọ́ ohun tó wú mi lórí jù ni pé ẹ wà níṣọ̀kan bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọ̀ yín yàtọ̀ síra.”3. Kí ló mú kí ẹgbẹ́ ará wa ṣàrà ọ̀tọ̀?
3 Ohun táwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ yìí fi hàn pé ẹgbẹ́ ará wa ṣàrà ọ̀tọ̀ lóòótọ́. (1 Pét. 5:9) Àmọ́ kí ló mú ká yàtọ̀ sáwọn míì? Ohun tó mú ká yàtọ̀ ni pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ẹ̀mí mímọ́ ń mú ká “bọ́ ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà sílẹ̀,” ká sì fi “àkópọ̀ ìwà tuntun wọ ara [wa] láṣọ.”—Kól. 3:9, 10.
4. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí, kí sì nìdí?
4 Ohun kan ni pé kéèyàn bọ́ ìwà àtijọ́ sílẹ̀, ohun míì ni pé kéèyàn má dé ìdí rẹ̀ mọ́. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa rí bá a ṣe lè bọ́ àwọn ìwà àtijọ́ sílẹ̀, a tún máa rí ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká tètè ṣe bẹ́ẹ̀. Bákan náà, àá rí bá a ṣe lè ṣàtúnṣe kódà ká ti jingíri sínú àwọn ìwà burúkú kan. A tún máa wo bí àwọn tó ti pẹ́ nínú òtítọ́ ṣe lè yẹra fún àwọn ìwà àtijọ́ tí wọ́n ti pa tì. Kí nìdí tá a fi nílò àwọn ìránnilétí yìí? Ìdí ni pé àwọn kan lára wa ti dẹra nù, wọ́n sì ti pa dà sídìí àwọn ìwà burúkú tí wọ́n fi sílẹ̀. Torí náà, ó yẹ kí gbogbo wa fi ìkìlọ̀ Bíbélì yìí sọ́kàn pé: “Kí ẹni tí ó bá rò pé òun dúró kíyè sára kí ó má bàa ṣubú.”—1 Kọ́r. 10:12.
‘Ẹ SỌ ÀWỌN Ẹ̀YÀ ARA YÍN DI ÒKÚ NÍ TI ÀGBÈRÈ’
5. (a) Sọ àpèjúwe kan tó jẹ́ ká rí ìdí tó fi yẹ ká tètè bọ́ àkópọ̀ ìwà àtijọ́ sílẹ̀. (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.) (b) Bó ṣe wà nínú Kólósè 3:5-9, àwọn ìwà wo ni ìwà àtijọ́?
5 Ká sọ pé aṣọ rẹ dọ̀tí, ó sì ń rùn, kí lo máa ṣe? Ó dájú pé wàá tètè bọ́ ọ kúrò lọ́rùn. Lọ́nà kan náà, ó yẹ ká tètè gbé ìgbésẹ̀ láti ṣe ohun tí Bíbélì sọ, pé ká jáwọ́ nínú àwọn ìwà tí kò bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu. Ó ṣe pàtàkì ká fi ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù fún àwa Kristẹni sílò pé: “Ẹ mú gbogbo [ìwà burúkú] kúrò lọ́dọ̀ yín.” Ẹ jẹ́ ká gbé méjì yẹ̀wò lára wọn, ìyẹn àgbèrè àti ìwà àìmọ́.—Ka Kólósè 3:5-9.
6, 7. (a) Báwo ni ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé ó gba ìsapá kéèyàn tó lè bọ́ àwọn ìwà àtijọ́ sílẹ̀? (b) Irú ìgbésí ayé wo ni Sakura ń gbé tẹ́lẹ̀, kí ló ràn án lọ́wọ́ láti jáwọ́ nínú ìṣekúṣe?
6 Àgbèrè. Ọ̀rọ̀ Bíbélì tá a tú sí “àgbèrè” túmọ̀ sí ìbálòpọ̀ láàárín àwọn tí kì í ṣe tọkọtaya àti ìbẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀. Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn Kristẹni pé kí wọ́n “sọ àwọn ẹ̀yà” wọn “di òkú ní ti àgbèrè,” ìyẹn ni pé kí wọ́n má ṣe fàyè gba èrò tàbí ìfẹ́ ọkàn èyíkéyìí tó lè mú kí wọ́n ṣe àgbèrè. Èdè ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù lò fi hàn pé èèyàn gbọ́dọ̀ sapá gan-an láti gbé irú àwọn èrò bẹ́ẹ̀ kúrò lọ́kàn. Síbẹ̀, ó dájú pé tá a bá sapá, a lè borí irú ìfẹ́ ọkàn bẹ́ẹ̀.
7 Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Sakura * tó wá láti orílẹ̀-èdè Japan. Nígbà tó ń dàgbà, kò rẹ́ni fojú jọ, ó sì máa ń ṣe é bíi pé kò já mọ́ nǹkan kan. Àtìgbà tó ti wà lọ́mọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] ló ti bẹ̀rẹ̀ sí í ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú oríṣiríṣi ọkùnrin kóun náà lè rẹ́ni fojú jọ. Sakura fìtìjú sọ pé: “Ẹ̀ẹ̀mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni mo ti ṣẹ́yún.” Ó wá fi kún un pé: “Nígbà tí mo kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìṣekúṣe, ó máa ń ṣe mí bíi pé èèyàn pàtàkì lèmi náà, pé mo wúlò, àwọn èèyàn sì nífẹ̀ẹ́ mi. Àmọ́ nígbà tó yá, ó ń ṣe mí bíi pé mi ò já mọ́ nǹkan kan.” Bí Sakura ṣe ń gbé ìgbésí ayé rẹ̀ nìyẹn títí tó fi pé ọmọ ọdún mẹ́tàlélógún [23]. Ìgbà yẹn làwon Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Sakura nífẹ̀ẹ́ ohun tó ń kọ́, Jèhófà sì ràn án lọ́wọ́ láti borí ẹ̀dùn ọkàn tó ní, kò sì ro ara rẹ̀ pin mọ́. Èyí mú kó jáwọ́ nínú ìṣekúṣe tó ń ṣe. Ní báyìí, Sakura ti di aṣáájú-ọ̀nà déédéé, ó sì ti wá láwọn ọ̀rẹ́. Ó sọ pé, “Inú mi dùn pé Jèhófà ń fìfẹ́ hàn sí mi lójoojúmọ́.”
BÁ A ṢE LÈ JÁWỌ́ NÍNÚ ÌWÀ ÀÌMỌ́
8. Kí làwọn nǹkan tó lè sọ wá di aláìmọ́ lójú Ọlọ́run?
8 Ìwà Àìmọ́. Ọ̀rọ̀ Bíbélì tá a tú sí “ìwà àìmọ́” kọjá ọ̀rọ̀ ìṣekúṣe nìkan. Ó kan mímu sìgá àti ìṣẹ̀fẹ̀ rírùn. (2 Kọ́r. 7:1; Éfé. 5:3, 4) Yàtọ̀ síyẹn, ó tún ń tọ́ka sí àwọn ìwàkiwà míì tẹ́nì kan lè máa hù ní ìkọ̀kọ̀, irú bíi kó máa ka ìwé tó ń mú kọ́kàn fà sí ìṣekúṣe tàbí kó máa wo ìwòkuwò, èyí sì lè mú kẹ́ni náà máa fọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ rẹ̀.—Kól. 3:5. *
9. Àkóbá wo ni “ìdálọ́rùn fún ìbálòpọ̀ takọtabo” lè ṣe fúnni?
9 Àwọn tí ìwòkuwò ti di bárakú fún máa ń ní “ìdálọ́rùn fún ìbálòpọ̀ takọtabo,” èyí sì lè mú kí wọ́n jingíri sínú ìṣekúṣe. Ìwádìí fi hàn pé bí ọkàn àwọn ọ̀mùtí àtàwọn tó ń lo oògùn olóró ṣe máa ń fà sí ìmukúmu, bẹ́ẹ̀ náà lọkàn àwọn tó ń wo ìwòkuwò ṣe máa ń fà sí àwòrán ìṣekúṣe. Ó ṣe kedere pé ohun tí ìwòkuwò máa ń yọrí sí kò dáa rárá. Bí àpẹẹrẹ, wọn kì í níyì lójú ara wọn, wọn kì í jára mọ́ṣẹ́, ilé wọn kì í sábà tòrò, ìgbéyàwó wọn lè tú ká, kódà wọ́n lè gbẹ̀mí ara wọn. Nígbà tó pé ọdún kan tí ọkùnrin kan jáwọ́ nínú ìwòkuwò, inú rẹ̀ dún gan-an, ó wá sọ pé: “Mo ti wá pa dà níyì lójú ara mi.”
10. Kí ló ran Ribeiro lọ́wọ́ láti jáwọ́ nínú wíwo àwòrán ìṣekúṣe?
10 Kì í rọrùn fún ọ̀pọ̀ láti jáwọ́ nínú ìwòkuwò. Àmọ́, ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Ribeiro tó wá láti orílẹ̀-èdè Brazil jẹ́ ká mọ̀ pé èèyàn lè borí àṣàkaṣà yìí. Ìgbà tí Ribeiro wà lọ́dọ̀ọ́ ló ti filé sílẹ̀, ó sì ń ṣiṣẹ́ ní iléeṣẹ́ kan tí wọ́n ti ń ṣàtúnlò bébà àlòkù, ibẹ̀ ló ti bẹ̀rẹ̀ sí í wo àwòrán ìṣekúṣe. Ó sọ pé: “Díẹ̀díẹ̀ ni àṣàkaṣà yìí mọ́ mi lára. Ó le débi pé ṣe ló máa ń ṣe mí bíi pé kí obìnrin tá a jọ ń gbé pọ̀ bíi tọkọtaya tètè kúrò nílé kí n lè wo fíìmù ìṣekúṣe.” Àmọ́ lọ́jọ́ kan níbiṣẹ́, Ribeiro rí ìwé Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé láàárín àwọn bébà tí wọ́n tò jọ pelemọ, ó sì kà á. Ohun tó kà níbẹ̀ mú kó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àmọ́ ó pẹ́ kó tó lè jáwọ́ nínú wíwo àwòrán ìṣekúṣe. Kí ló wá ràn án lọ́wọ́? Ó sọ pé: “Mo máa ń gbàdúrà, mò ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo sì máa ń ronú lórí àwọn ohun tí mò ń kọ́. Èyí mú kí n túbọ̀ mọ irú ẹni tí Jèhófà jẹ́, mo sì wá nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an débi pé wíwo àwòrán ìṣekúṣe kúrò lọ́kàn mi pátápátá.” Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ẹ̀mí mímọ́ ló ran Ribeiro lọ́wọ́ láti bọ́ ìwà àtijọ́ yìí sílẹ̀. Nígbà tó yá, ó ṣèrìbọmi, ó sì ti di alàgbà báyìí.
11. Kí ló yẹ kẹ́nì kan ṣe tó bá fẹ́ jáwọ́ nínú wíwo àwòrán ìṣekúṣe?
11 Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìkan kọ́ ló mú kí Ribeiro jáwọ́ nínú àṣà burúkú yìí. Ó máa ń ṣàṣàrò kí ohun tó ń kọ́ lè wọ̀ ọ́ lọ́kàn. Ó tún máa ń gbàdúrà pé kí Jèhófà ran òun lọ́wọ́. Àwọn nǹkan yìí ló mú kó túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, kó sì jáwọ́ pátápátá nínú wíwo àwòrán ìṣekúṣe. Torí náà, tá a bá fẹ́ jáwọ́ nínú àṣà yìí, a gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an, ká sì kórìíra ohun tó burú.—Ka Sáàmù 97:10.
Ẹ MÚ ÌBÍNÚ, Ọ̀RỌ̀ ÈÉBÚ ÀTI IRỌ́ KÚRÒ LỌ́DỌ̀ YÍN
12. Kí ló mú kí Stephen kápá ìbínú rẹ̀, tí kì í sì í bú èébú mọ́?
12 Àwọn tó máa ń tètè bínú sábà máa ń bú èébú tí inú bá ń bí wọn. Irú ìwà bẹ́ẹ̀ kì í jẹ́ kí ìdílé tòrò. Bàbá kan tó ń jẹ́ Stephen láti orílẹ̀-èdè Ọsirélíà sọ pé: “Mo máa ń ṣépè gan-an, mo sì máa ń gbaná jẹ lórí ohun tí kò tó nǹkan. Ẹ̀ẹ̀mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni èmi àti ìyàwó mi ti pínyà, kódà a ti fẹ́ kọ ara wa sílẹ̀.” Nígbà tó yá, wọ́n gbà kí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kí ló wá ṣẹlẹ̀ nígbà tí Stephen bẹ̀rẹ̀ sí í fi ìlànà Bíbélì sílò? Ó sọ pé: “Nǹkan ti yàtọ̀ gan-an nínú ìdílé wa. Tẹ́lẹ̀, kí nǹkan kékeré má tíì ṣẹlẹ̀, màá ti fara ya. Àmọ́, Jèhófà ti ràn mí lọ́wọ́ láti jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà, kí n sì túbọ̀ máa ní sùúrù.” Ní báyìí, Stephen ti di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ nínú ìjọ, ìyàwó rẹ̀ sì ti ń ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé fún ọ̀pọ̀ ọdún. Àwọn alàgbà tó wà nínú ìjọ tí Stephen wà sọ pé: “Èèyàn jẹ́jẹ́ ni Stephen, ó máa ń ṣiṣẹ́ kára, ó sì lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀.” Kódà, wọn ò rí i kó bínú rí. Ṣé Stephen náà gbà pé agbára òun ló mú kí èyí ṣeé ṣe? Rárá o, òun fúnra rẹ̀ sọ pé: “Tí kì í bá ṣe pé Jèhófà ràn mí lọ́wọ́, kò sí bí mo ṣe lè fi àwọn ìwà àtijọ́ mi sílẹ̀.”
13. Kí nìdí tí kò fi dáa kéèyàn máa bínú, ìkìlọ̀ wo ni Bíbélì sì fún wa?
13 Bíbélì kìlọ̀ fún wa pé ká yẹra fún ìbínú, ọ̀rọ̀ èébú àti ìlọgun. (Éfé. 4:31) Ìkìlọ̀ yìí bọ́gbọ́n mu torí pé àwọn ìwà yìí sábà máa ń fa wàhálà, wọ́n sì máa ń dá ìjà sílẹ̀. Àwọn èèyàn inú ayé ò rí ohun tó burú nínú kéèyàn máa bínú, àmọ́ irú ìwà bẹ́ẹ̀ kò fi hàn pé a bọ̀wọ̀ fún Ẹlẹ́dàá wa. Ọ̀pọ̀ wa ti sapá gan-an láti bọ́ ìwà àtijọ́ sílẹ̀, a sì ti gbé ìwà tuntun wọ̀.—Ka Sáàmù 37:8-11.
14. Ṣé ó ṣeé ṣe kí ẹni tó ń hùwà jàgídíjàgan yí pa dà di oníwà tútù?
14 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ alàgbà kan tó ń jẹ́ Hans ní orílẹ̀-èdè Austria. Olùṣekòkáárí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà ìjọ tí Hans wà sọ pé: “Hans wà lára àwọn tó níwà tútù jù nínú ìjọ.” Àmọ́ kì í ṣe bí Hans ṣe rí tẹ́lẹ̀ nìyẹn. Nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́, ó máa ń mutí gan-an, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kó hùwà jàgídíjàgan. Lọ́jọ́ kan tó ti mutí yó, ó lu ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ pa, ìjọba sì rán an lọ sẹ́wọ̀n ogún [20] ọdún. Àmọ́ ẹ̀wọ̀n yẹn ò yí ìwà Hans pa dà. Nígbà tó yá, ìyá rẹ̀ ṣètò pé kí alàgbà kan máa kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n, Hans náà sì gbà. Hans sọ pé: “Kò rọrùn fún mi láti fi ìwà mi àtijọ́ sílẹ̀. Lára àwọn ẹsẹ Bíbélì tó ràn mí lọ́wọ́ ni Aísáyà 55:7 tó sọ pé: ‘Kí ènìyàn burúkú fi ọ̀nà rẹ̀ sílẹ̀,’ àti 1 Kọ́ríńtì 6:11 tó sọ nípa àwọn tó fi ìwà àtijọ́ wọn sílẹ̀ pé: ‘Ohun tí àwọn kan lára yín ti jẹ́ rí nìyẹn.’ Ọ̀pọ̀ ọdún ni Jèhófà fi mú sùúrù fún mi, tó sì ń fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ràn mí lọ́wọ́ kí n lè gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀.” Inú ẹ̀wọ̀n ni Hans ti ṣèrìbọmi, lẹ́yìn ọdún mẹ́tàdínlógún àtààbọ̀ tó lò lẹ́wọ̀n, wọ́n dá a sílẹ̀. Hans sọ pé: “Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó fàánú hàn sí mi, ó sì dárí jì mí.”
15. Ìwà wo ló gbòde kan lónìí, àmọ́ kí ni Bíbélì sọ nípa rẹ̀?
15 Yàtọ̀ sí ọ̀rọ̀ èébú, irọ́ pípa wà lára àwọn ìwà àtijọ́ tó yẹ ká yẹra fún. Bí àpẹẹrẹ, àwọn èèyàn sábà máa ń parọ́ kí wọ́n má bàa san owó orí tàbí kí wọ́n má bàa jìyà ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá. Àmọ́ Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ni “Ọlọ́run òtítọ́.” (Sm. 31:5) Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi fẹ́ kí gbogbo àwa olùjọ́sìn rẹ̀ máa “bá aládùúgbò [wa] sọ òtítọ́,” ká má sì “máa purọ́.” (Éfé. 4:25; Kól. 3:9) Torí náà, a gbọ́dọ̀ máa sọ òtítọ́ kódà tí òtítọ́ náà ò bá bára dé tàbí tó bá máa kó ìtìjú bá wa.—Òwe 6:16-19.
OHUN TÓ JẸ́ KÍ WỌ́N BORÍ ÌWÀ WỌN ÀTIJỌ́
16. Àwọn nǹkan wo ló yẹ ká ṣe ká lè fi àwọn ìwà àtijọ́ sílẹ̀?
16 Ká sòótọ́, àtibọ́ àwọn ìwà àtijọ́ sílẹ̀ kì í ṣe ohun téèyàn lè dá ṣe fúnra rẹ̀. Sakura, Ribeiro, Stephen àti Hans tá a sọ̀rọ̀ wọn nínú àpilẹ̀kọ yìí sapá gan-an kí wọ́n tó lè fi àwọn ìwà àtijọ́ sílẹ̀. Síbẹ̀ wọ́n ṣàṣeyọrí torí pé wọ́n jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ẹ̀mí mímọ́ ràn wọ́n lọ́wọ́. (Lúùkù 11:13; Héb. 4:12) Káwọn nǹkan yìí tó lè ran àwa náà lọ́wọ́, a gbọ́dọ̀ máa ka Bíbélì déédéé, ká máa ronú lé e lórí, ká sì máa gbàdúrà pé kí Jèhófà fún wa ní ọgbọ́n àti okun táá jẹ́ ká lè fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò. (Jóṣ. 1:8; Sm. 119:97; 1 Tẹs. 5:17) Tá a bá fẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ẹ̀mí mímọ́ ràn wá lọ́wọ́, a gbọ́dọ̀ máa múra ìpàdé sílẹ̀, ká sì máa pésẹ̀ síbẹ̀ déédéé. (Héb. 10:24, 25) Láfikún síyẹn, ó yẹ ká máa jadùn oúnjẹ tẹ̀mí tí Jèhófà pèsè fún wa lónírúurú ọ̀nà.—Lúùkù 12:42.
17. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
17 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a ti jíròrò àwọn ìwàkiwà tó yẹ káwa Kristẹni bọ́ sílẹ̀ pátápátá. Àmọ́, ṣé gbogbo nǹkan tí Ọlọ́run ń béèrè lọ́wọ́ wa nìyẹn ká tó lè rí ìtẹ́wọ́gbà rẹ̀? Rárá o. A tún gbọ́dọ̀ gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀. Nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e, a máa jíròrò àwọn ìwà tuntun tá a ní láti gbé wọ̀ kó sì di ara fún wa.
^ ìpínrọ̀ 7 A ti yí àwọn orúkọ kan nínú àpilẹ̀kọ yìí pa dà.