ILÉ ÌṢỌ́—Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ August 2018

Àwọn àpilẹ̀kọ tá a máa kẹ́kọ̀ọ́ láti October 1 sí 28, 2018 ló wà nínú Ilé Ìṣọ́ yìí.

Máa Rí Àrídájú Ọ̀rọ̀

Àwọn ìlànà Bíbélì mẹ́ta wo la lè ronú lé tá a bá fẹ́ mọ béèyàn ṣe ń gbé ọ̀rọ̀ yẹ̀ wò dáadáa?

Má Ṣe Máa Fi Ìrísí Dáni Lẹ́jọ́

Wàá rí àwọn ìdí tí kò fi bọ́gbọ́n mu láti fi ẹ̀yà, bẹ́nì kan ṣe lówó tó àti ọjọ́ orí pinnu irú ẹni tó jẹ́.

ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

Mo Pinnu Pé Mi Ò Ní Juwọ́ Sílẹ̀

Ka àwọn ìrírí tí Maxim Danyleyko ti ní ní gbogbo ọdún méjìdínláàádọ́rin [68] tó fi ṣe míṣọ́nnárì.

A Máa Láyọ̀ Tá A Bá Jẹ́ Ọ̀làwọ́

Kí nìdí tá a fi máa láyọ̀ tá a bá jẹ́ ọ̀làwọ́?

Máa Bá Jèhófà Ṣiṣẹ́ Lójoojúmọ́

Àwọn ọ̀nà márùn-ún wo la lè gbà di alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Jèhófà?

Ìpamọ́ra—Fífaradà Á Pẹ̀lú Ìrètí

Wàá mọ ohun tí sùúrù túmọ̀ sí, bó o ṣe lè ní in àti àǹfààní tó o máa rí tó o bá ń mú sùúrù.

LÁTINÚ ÀPAMỌ́ WA

Bí Iṣẹ́ Fífúnrúgbìn Ìjọba Náà Ṣe Bẹ̀rẹ̀ Lórílẹ̀-Èdè Pọ́túgà

Àwọn ìṣòro wo làwọn tó kọ́kọ́ wàásù níbẹ̀ borí?