Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìpamọ́ra—Fífaradà Á Pẹ̀lú Ìrètí

Ìpamọ́ra—Fífaradà Á Pẹ̀lú Ìrètí

Ó ṢE pàtàkì gan-an pé káwa èèyàn Jèhófà ní ìpamọ́ra tàbí lédè míì, ká ní sùúrù pàápàá jù lọ nísinsìnyí tá a ti wà “ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” tí nǹkan ti le gan-an. (2 Tím. 3:1-5) Ìdí ni pé àwọn onímọtara-ẹni-nìkan, àwọn tí kò ṣeé bá ṣe àdéhùn kankan àtàwọn tí kò ní ìkóra-ẹni-níjàánu ló kúnnú ayé yìí. Irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ máa ń ṣe wàdùwàdù, wọn kì í ní sùúrù rárá. Torí náà, ó yẹ kí kálukú bi ara rẹ̀ pé: ‘Ṣé kì í ṣe pé èmi náà ti ń di aláìnísùúrù bíi táwọn èèyàn ayé? Kí ló túmọ̀ sí pé kéèyàn ní sùúrù? Kí ni mo lè ṣe kí n lè túbọ̀ máa ní sùúrù?’

OHUN TÍ SÙÚRÙ TÚMỌ̀ SÍ

Nínú Bíbélì, ọ̀rọ̀ náà ìpamọ́ra tàbí sùúrù kọjá pé kéèyàn kàn máa fara da ipò kan tó ṣòro. Ẹni tó bá ní sùúrù máa ń fara da ipò kan tó ṣòro, á sì nírètí pé nǹkan ṣì máa dáa. Ẹni tó bá ní sùúrù kì í ro tara ẹ̀ nìkan, àmọ́ ó tún máa ń ro táwọn míì mọ́ tiẹ̀, títí kan tẹni tó fa ìṣòro náà. Torí náà, tí wọ́n bá ṣẹ ẹnì kan tó ní sùúrù, dípò táá fi bínú, ṣe ló máa mú sùúrù, á sì nírètí pé àárín òun àti ẹni kejì ṣì máa pa dà gún. Abájọ tí Bíbélì fi kọ́kọ́ mẹ́nu kan “ìpamọ́ra” tàbí sùúrù nígbà tó ń sọ àwọn ànímọ́ tí ìfẹ́ máa ń jẹ́ ká ní. * (1 Kọ́r. 13:4) Yàtọ̀ síyẹn, “ìpamọ́ra” wà lára àwọn apá tí Bíbélì sọ pé “èso ti ẹ̀mí” pín sí. (Gál. 5:22, 23) Àmọ́ kí ló yẹ ká ṣe ká lè ní ànímọ́ àtàtà yìí?

BÁ A ṢE LÈ NÍ SÙÚRÙ

Ká tó lè máa ní sùúrù, a gbọ́dọ̀ bẹ Jèhófà pé kó fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. Ó sì dájú pé Jèhófà máa ń fún àwọn tó bá gbẹ́kẹ̀ lé e ní ẹ̀mí mímọ́ yìí. (Lúùkù 11:13) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀mí mímọ́ lágbára láti ràn wá lọ́wọ́, síbẹ̀ àwa náà gbọ́dọ̀ ṣe ipa tiwa ní ti pé ká ṣe ohun tó bá àdúrà wa mu. (Sm. 86:10, 11) Ìyẹn gba pé ká sapá láti máa mú sùúrù nínú gbogbo ohun tá a bá ń ṣe lójoojúmọ́. Àmọ́ nígbà míì, kì í rọrùn láti mú sùúrù. Kí ni nǹkan míì tó lè ràn wá lọ́wọ́?

Ohun míì tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti ní sùúrù ni pé ká fara wé àpẹẹrẹ pípé tí Jésù fi lélẹ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tẹnu mọ́ kókó yìí nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa “àkópọ̀ ìwà tuntun.” Ó jẹ́ kó ṣe kedere pé “ìpamọ́ra” tàbí sùúrù wà lára àkópọ̀ ìwà tuntun, ó sì gbà wá níyànjú pé ká “jẹ́ kí àlàáfíà Kristi máa ṣàkóso nínú ọkàn-àyà [wa].” (Kól. 3:10, 12, 15) A lè jẹ́ kí àlàáfíà yìí máa “ṣàkóso” ọkàn wa tá a bá nígbàgbọ́ bíi ti Jésù, tá a sì gbà pé Ọlọ́run máa mú nǹkan tọ́ lásìkò tó yẹ. Tá a bá ń fara wé Jésù, kò sóhun tó máa ṣẹlẹ̀ táá mú ká bínú kọjá àyè.​—Jòh. 14:27; 16:33.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti ń ṣe wá bíi pé kí ayé tuntun tí Jèhófà ṣèlérí ti dé, síbẹ̀ tá a bá ń ronú lórí ìdí tí Jèhófà fi ń mú sùúrù, á jẹ́ káwa náà túbọ̀ máa mú sùúrù. Bíbélì jẹ́ kó dá wa lójú pé: “Jèhófà kò fi nǹkan falẹ̀ ní ti ìlérí rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn kan ti ka ìfi-nǹkan-falẹ̀ sí, ṣùgbọ́n ó ń mú sùúrù fún yín nítorí pé kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run ṣùgbọ́n ó fẹ́ kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà.” (2 Pét. 3:9) Tá a bá ń ronú lórí bí Jèhófà ṣe ń mú sùúrù fún wa, ó yẹ káwa náà máa ṣe sùúrù pẹ̀lú àwọn míì. (Róòmù 2:4) Àmọ́, àwọn nǹkan wo ló lè ṣẹlẹ̀ tó máa gba pé ká mú sùúrù?

ÀWỌN ÌGBÀ TÓ YẸ KÁ NÍ SÙÚRÙ

Ọ̀pọ̀ nǹkan ló máa ń ṣẹlẹ̀ sí wa lójoojúmọ́ tó máa gba pé ká mú sùúrù. Bí àpẹẹrẹ, o lè fẹ́ bá ẹnì kan sọ̀rọ̀ pàtàkì kan, ìyẹn lè gba pé kó o fara balẹ̀ kẹ́ni náà sọ̀rọ̀ tán tàbí kó o ṣe sùúrù kó o má bàa já lu ọ̀rọ̀ rẹ̀. (Ják. 1:19) Tó bá jẹ́ pé ìwà Kristẹni kan máa ń bí wa nínú, ó lè gba pé ká ṣe sùúrù pẹ̀lú irú ẹni bẹ́ẹ̀. Dípò tá a fi máa bínú sí ẹni náà, á dáa ká ronú lórí bí Jèhófà àti Jésù ṣe ń mú sùúrù fún wa láìka àìpé wa sí. Wọn kì í rin kinkin mọ́ àwọn àṣìṣe pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ tá a bá ṣe, kàkà bẹ́ẹ̀ ibi tá a dáa sí ni wọ́n máa ń wò, wọ́n sì máa ń mú sùúrù fún wa bá a ṣe ń sapá láti ṣàtúnṣe.​—1 Tím. 1:16; 1 Pét. 3:12.

Ohun míì tó lè mú kó ṣòro fún wa láti mú sùúrù ni tẹ́nì kan bá sọ pé a ṣe ohun kan tí kò dáa. Irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ lè kọ́kọ́ bí wa nínú, ká sì fẹ́ gbèjà ara wa. Àmọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ ohun tó yẹ ká ṣe nírú ipò bẹ́ẹ̀. Ó sọ pé: “Onísùúrù sàn ju onírera ní ẹ̀mí. Má ṣe kánjú nínú ẹ̀mí rẹ láti fara ya, nítorí pé fífara ya sinmi ní oókan àyà àwọn arìndìn.” (Oníw. 7:8, 9) Torí náà, tó bá tiẹ̀ jẹ́ pé irọ́ lẹni náà pa mọ́ wa, ó ṣì yẹ ká ṣe sùúrù ká tó fèsì. Ohun tí Jésù náà ṣe nìyẹn nígbà táwọn kan sọ ohun tí kò dáa nípa rẹ̀.​—Mát. 11:19.

Ó yẹ káwọn òbí máa mú sùúrù tí wọ́n bá fẹ́ gba àwọn ọmọ wọn nímọ̀ràn tàbí tí wọ́n bá fẹ́ ràn wọ́n lọ́wọ́ láti jáwọ́ nínú ìwà kan. Àpẹẹrẹ kan ni ti Mattias tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Scandinavia. Nígbà tí Mattias wà ní kékeré, àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ máa ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ torí ohun tó gbà gbọ́. Àwọn òbí rẹ̀ ò kọ́kọ́ mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀, wọ́n kàn rí i pé Mattias máa ń kanra tó bá ti dé ilé, ó sì ń ṣiyèméjì nípa ohun tó gbà gbọ́. Gillis bàbá Mattias sọ pé: “Ọ̀rọ̀ yẹn gba sùúrù gan-an. Nígbà míì, Mattias máa béèrè pé: “Ta tiẹ̀ ni Ọlọ́run? Tó bá jẹ́ pé Bíbélì kì í ṣe Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ńkọ́? Báwo tiẹ̀ la ṣe mọ̀ pé Ọlọ́run ló ní ká ṣe gbogbo nǹkan tá à ń ṣe yìí?” Kódà, ó máa ń sọ fún bàbá rẹ̀ pé: “Ṣé dandan ni kí n gba ẹ̀sìn tẹ́yin náà gbà ni?”

Bàbá Mattias sọ pé: “Nígbà míì, ìbínú lọmọ wa fi máa ń bi wá ní ìbéèrè, àmọ́ kì í ṣe èmi tàbí ìyá rẹ̀ ló ń bínú sí, ṣe ló ń bínú torí ó gbà pé ẹ̀kọ́ òtítọ́ ló mú kí nǹkan ṣòro fún òun.” Báwo ni bàbá Mattias ṣe bójú tó ọ̀rọ̀ yìí? Ó sọ pé: “Èmi àti ọmọ mi jọ máa ń jókòó sọ̀rọ̀ fún ọ̀pọ̀ wákàtí nígbà míì. Lọ́pọ̀ ìgbà, màá bi í ní ìbéèrè díẹ̀, màá wá fara balẹ̀ gbọ́ tiẹ̀ kí n lè mọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ̀ gan-an. Nígbà míì, mo lè sọ ọ̀rọ̀ kan fún un, kí n sì ní kó lọ ronú lórí ẹ̀ fún bí ọjọ́ kan, lẹ́yìn náà àá wá jọ jíròrò ẹ̀. Ìgbà míì sì rèé, màá ní kó fún mi lọ́jọ́ díẹ̀ kémi náà lè lọ ronú lórí ohun kan tó sọ. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, àwọn ọ̀rọ̀ tá a jọ ń sọ bẹ̀rẹ̀ sí í wọ Mattias lọ́kàn, ó wá lóye àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì bí ìràpadà, ó sì gbà pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa àti pé òun ni Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run. Kí n sòótọ́, kò rọrùn, àmọ́ díẹ̀díẹ̀ ni ìfẹ́ Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í gbilẹ̀ lọ́kàn rẹ̀. Ó gba àkókò àti sùúrù, ṣùgbọ́n inú èmi àtìyàwó mi dùn gan-an lónìí pé gbogbo ìsapá wa lórí Mattias nígbà yẹn ò já sásán.”

Àwọn òbí Mattias gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, wọ́n sì fi sùúrù kọ́ ọmọ wọn. Bàbá Mattias rántí ohun kan tó máa ń sọ fún Mattias, ó ní: “Mo sábà máa ń sọ fún Mattias pé èmi àti ìyá rẹ̀ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an, ìyẹn sì ń jẹ́ ká túbọ̀ máa gbàdúrà pé kí Jèhófà ràn án lọ́wọ́ kó lè lóye òtítọ́.” Inú àwọn òbí Mattias dùn gan-an pé àwọn fi sùúrù ràn án lọ́wọ́.

Ó tún yẹ káwa Kristẹni máa mú sùúrù tá a bá ń ṣèrànwọ́ fún mọ̀lẹ́bí tàbí ọ̀rẹ́ wa tó ń ṣàìsàn. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Ellen, * tóun náà ń gbé ní Scandinavia.

Ní nǹkan bí ọdún mẹ́jọ sẹ́yìn, ẹ̀ẹ̀mejì ni ọkọ Ellen ní àrùn rọpárọsẹ̀, ìyẹn ò sì jẹ́ kí ọpọlọ rẹ̀ ṣiṣẹ́ dáadáa mọ́. Torí náà, kò nímọ̀lára ìfẹ́, ayọ̀ tàbí ìbànújẹ́ mọ́. Èyí mú kí nǹkan nira gan-an fún Ellen. Ellen sọ pé: “Ohun tó ṣẹlẹ̀ gba sùúrù gan-an, mi ò sì dákẹ́ àdúrà.” Ó wá fi kún un pé: “Ẹsẹ Bíbélì kan tó máa ń tù mí nínú ni Fílípì 4:13, tó sọ pé: ‘Mo ní okun fún ohun gbogbo nípasẹ̀ agbára ìtóye ẹni tí ń fi agbára fún mi.’ ” Okun tí Jèhófà ń fún Ellen ló ń jẹ́ kó lè máa mú sùúrù bó ṣe ń fara da ìṣòro náà.​—Sm. 62:5, 6.

MÁA FARA WÉ JÈHÓFÀ

Jèhófà ló fi àpẹẹrẹ tó ga jù lọ lélẹ̀ tó bá di pé ká ní sùúrù. (2 Pét. 3:15) Ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ ló wà nínú Bíbélì nípa bí Jèhófà ṣe fi sùúrù bá àwọn èèyàn lò. (Neh. 9:30; Aísá. 30:18) Bí àpẹẹrẹ, ṣé Jèhófà bínú nígbà tí Ábúráhámù bi í ní ọ̀pọ̀ ìbéèrè nípa ìdí tó fi fẹ́ pa ìlú Sódómù run? Rárá o, Jèhófà ò dá ọ̀rọ̀ mọ́ ọn lẹ́nu nígbà tó ń béèrè ìbéèrè. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló fara balẹ̀ tẹ́tí sí ọ̀kọ̀ọ̀kan ìbéèrè tí Ábúráhámù béèrè. Lẹ́yìn náà, Jèhófà tún àwọn ọ̀rọ̀ Ábúráhámù sọ kí Ábúráhámù lè mọ̀ pé òun gbọ́ gbogbo ohun tó sọ, ó sì fi dá Ábúráhámù lójú pé òun ò ní pa ìlú Sódómù run tóun bá rí olódodo mẹ́wàá péré níbẹ̀. (Jẹ́n. 18:22-33) Èyí jẹ́ ká rí i pé Jèhófà máa ń fara balẹ̀ tẹ́tí sí wa, kì í sì í fi ìwàǹwara gbé ìgbésẹ̀. Àpẹẹrẹ tó dáa nìyẹn jẹ́ fún wa.

Ànímọ́ pàtàkì ni sùúrù jẹ́ nínú àkópọ̀ ìwà tuntun tó yẹ káwa Kristẹni gbé wọ̀. Tá a bá ń sapá láti ní ànímọ́ pàtàkì yìí, ṣe là ń bọlá fún Jèhófà Baba wa ọ̀run tó nífẹ̀ẹ́ wa, tó sì ń fi sùúrù bá wa lò. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà máa kà wá mọ́ “àwọn tí wọ́n tipasẹ̀ ìgbàgbọ́ àti sùúrù jogún àwọn ìlérí náà.”​—Héb. 6:10-12.