Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Máa Bá Jèhófà Ṣiṣẹ́ Lójoojúmọ́

Máa Bá Jèhófà Ṣiṣẹ́ Lójoojúmọ́

“Àwa jẹ́ alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run.”​—1 KỌ́R. 3:9.

ORIN: 64, 111

1. Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà bá Jèhófà ṣiṣẹ́?

ẸLẸ́DÀÁ wa fẹ́ kí àwọn èèyàn pípé fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ kí ohun tó ní lọ́kàn lè ṣẹ. Láìka àìpé táwa èèyàn ti jogún sí, àwọn tó bá jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà lè bá Jèhófà ṣiṣẹ́ lójoojúmọ́. Bí àpẹẹrẹ, “alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run” ni wá bá a ṣe ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, tá a sì ń sọni di ọmọ ẹ̀yìn. (1 Kọ́r. 3:5-9) Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá gbáà ló jẹ́ pé Ẹlẹ́dàá ayé àtọ̀run kà wá yẹ láti jọ ṣe iṣẹ́ pàtàkì yìí! Ṣùgbọ́n, iṣẹ́ ìwàásù àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn nìkan kọ́ ni àwọn ọ̀nà tá a lè gbà bá Jèhófà ṣiṣẹ́. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò àwọn ọ̀nà míì tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀. A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń ran ìdílé wa àtàwọn ará lọ́wọ́, tá a lẹ́mìí aájò àlejò, tá à ń yọ̀ǹda ara wa fún àwọn iṣẹ́ nínú ètò Ọlọ́run, tá a sì ń mú iṣẹ́ ìsìn wa gbòòrò sí i.​—Kól. 3:23.

2. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa fi ohun tá a lè ṣe fún Jèhófà wé tàwọn míì?

2 Bá a ṣe ń jíròrò àpilẹ̀kọ yìí, ká má ṣe fi ohun tá a lè ṣe fún Jèhófà wé tàwọn míì. Ìdí ni pé ọjọ́ orí wa, ìlera wa, ipò tí kálukú wà àtohun tá a lè ṣe yàtọ̀ síra. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Kí olúkúlùkù máa wádìí ohun tí iṣẹ́ tirẹ̀ jẹ́, nígbà náà ni yóò ní ìdí fún ayọ̀ ńláǹlà ní ti ara rẹ̀ nìkan, kì í sì í ṣe ní ìfiwéra pẹ̀lú ẹlòmíràn.”​—Gál. 6:4.

Ẹ MÁA RAN ÌDÍLÉ YÍN ÀTÀWỌN ARÁ LỌ́WỌ́

3. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé gbogbo àwọn tó bá ń bójú tó ìdílé wọn ń bá Ọlọ́run ṣiṣẹ́?

3 Jèhófà ń fẹ́ káwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ bójú tó ìdílé wọn. Bí àpẹẹrẹ, ó yẹ ká ṣiṣẹ́ ká lè pèsè fún ìdílé wa. Ọ̀pọ̀ àwọn ìyá máa ń wà nílé kí wọ́n lè bójú tó àwọn ọmọ wọn jòjòló. Àwọn ọmọ kan sì ń tọ́jú àwọn obí wọn tó ti dàgbà. Ká sòótọ́, àwọn ojúṣe yìí ò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Bí ẹnì kan kò bá pèsè fún àwọn tí í ṣe tirẹ̀, àti ní pàtàkì fún àwọn tí í ṣe mẹ́ńbà agbo ilé rẹ̀, ó ti sẹ́ ìgbàgbọ́, ó sì burú ju ẹni tí kò ní ìgbàgbọ́.” (1 Tím. 5:8) Tó bá jẹ́ pé bọ́rọ̀ tiẹ̀ náà ṣe rí nìyẹn, o lè má fi bẹ́ẹ̀ ráyè ṣe tó bó o ṣe fẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, àmọ́ má bọkàn jẹ́! Inú Jèhófà máa ń dùn tó bá rí i pé à ń pèsè fún ìdílé wa.​—1 Kọ́r. 10:31.

4. Báwo làwọn òbí ṣe lè fi ire Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́, àǹfààní wo sì ni wọ́n máa rí?

4 Àwọn òbí Kristẹni lè bá Jèhófà ṣiṣẹ́ tí wọ́n bá ń gbin iṣẹ́ ìsìn Jèhófà sọ́kàn àwọn ọmọ wọn. Àwọn òbí kan ti ṣe bẹ́ẹ̀, èyí sì ti mú káwọn ọmọ wọn bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ alákòókò kíkún, kódà níbi tó jìnnà sílé. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan ti di míṣọ́nnárì, àwọn míì ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà níbi tí àìní gbé pọ́, àwọn míì sì ń ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àárò lè máa sọ àwọn òbí yìí torí ọ̀nà àwọn ọmọ wọn tó jìn sílé, síbẹ̀ àwọn òbí tó lẹ́mìí ìfara-ẹni-rúbọ máa ń fún àwọn ọmọ wọn níṣìírí láti máa bá iṣẹ́ ìsìn náà nìṣó. Kí nìdí? Ìdí ni pé wọ́n ń láyọ̀ bí wọ́n ṣe ń rí i táwọn ọmọ wọn ń fi ire Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́, èyí sì ń fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀. (3 Jòh. 4) Ọ̀pọ̀ àwọn òbí yìí ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Hánà tó sọ pé òun fún Jèhófà ní Sámúẹ́lì ọmọ òun. Kò sí àní-àní pé àwọn òbí yìí kà á sì àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ láti bá Jèhófà ṣiṣẹ́ lọ́nà yìí.​—1 Sám. 1:28.

5. Báwo lo ṣe lè ran àwọn míì lọ́wọ́ nínú ìjọ rẹ? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

5 Tó bá jẹ́ pé àwọn ojúṣe ìdílé tó ò ń bójú tó kò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀, ǹjẹ́ o lè ran àwọn míì lọ́wọ́? Bí àpẹẹrẹ, o lè ṣèrànwọ́ fáwọn tó ń tọ́jú àwọn aláìlera, àwọn aláìsàn, àwọn àgbàlagbà tàbí àwọn míì. O lè kíyè sí àwọn tó wà nínú ìjọ rẹ kó o lè mọ àwọn tó nílò ìrànlọ́wọ́. O lè lọ sọ́dọ̀ arábìnrin kan tó ń tọ́jú òbí rẹ̀ tó ti dàgbà, kó o bá a dúró ti òbí rẹ̀, kí arábìnrin náà lè ráyè bójú tó àwọn nǹkan míì. Yàtọ̀ síyẹn, o lè ṣèrànwọ́ láti gbé àwọn míì wá sípàdé tàbí kó o lọ bá wọn ra nǹkan lọ́jà tàbí kó o bá wọn bójú tó àwọn nǹkan míì tí wọ́n fẹ́ ṣe. O tún lè yọ̀ǹda láti gbé wọn lọ sọ́dọ̀ ẹnì kan tó wà nílé ìwòsàn. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ò ń bá Jèhófà ṣiṣẹ́ nìyẹn, ó sì lè jẹ́ pé Jèhófà ń lò ẹ́ láti dáhùn àdúrà ẹni náà.​—Ka 1 Kọ́ríńtì 10:24.

MÁA GBA ÀWỌN ÈÈYÀN LÁLEJÒ

6. Kí ló túmọ̀ sí láti fi ẹ̀mí aájò àlejò hàn?

6 Àwọn tó ń bá Ọlọ́run ṣiṣẹ́ máa ń lẹ́mìí aájò àlejò. Nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, ọ̀rọ̀ tí wọ́n lò fún “aájò àlejò” túmọ̀ sí “ṣíṣe inúure sí àwọn tá ò mọ̀ rí.” (Héb. 13:2) Bíbélì mẹ́nu kan àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó ṣe bẹ́ẹ̀ láyé àtijọ́ tá a lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn. (Jẹ́n. 18:1-5) Ó yẹ káwa náà máa wá ọ̀nà tá a lè gbà ran àwọn míì lọ́wọ́ yálà wọ́n “bá wa tan nínú ìgbàgbọ́” tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́.​—Gál. 6:10.

7. Àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń gba àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún lálejò?

7 Tá a bá ń fi ẹ̀mí aájò àlejò hàn sáwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, à ń bá Ọlọ́run ṣiṣẹ́ nìyẹn. (Ka 3 Jòhánù 5, 8.) Nírú àwọn àsìkò bẹ́ẹ̀, a máa ń láǹfààní láti fún ara wa ní “pàṣípààrọ̀ ìṣírí.” (Róòmù 1:11, 12) Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Olaf. Lọ́pọ̀ ọdún sẹ́yìn, alábòójútó àyíká kan tí kò tíì níyàwó wá bẹ ìjọ wọn wò, àmọ́ kò sí ẹni tó lè gba alábòójútó àyíká náà sílé. Olaf wá béèrè lọ́wọ́ àwọn òbí rẹ̀ tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí bóyá alábòójútó àyíká náà lè dé sílé àwọn. Àwọn òbí rẹ̀ gbà, ṣùgbọ́n wọ́n sọ pé orí àga ni Olaf máa sùn. Èyí ò rọrùn, àmọ́ àǹfààní tí Olaf rí tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Olaf sọ pé: “Ọ̀sẹ̀ yẹn lárinrin gan-an ni! Èmi àti alábòójútó àyíká máa jí láàárọ̀ kùtùkùtù, a sì jọ máa ń sọ̀rọ̀ bá a ṣe ń jẹun àárọ̀. Ìṣírí tí alábòójútó àyíká fún mi ló jẹ́ ki ń gba iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà.” Ní báyìí, ó ti lé lógójì [40] ọdún tí Olaf ti ń ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì, ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ló sì ti sìn.

8. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ṣe inúure sáwọn èèyàn kódà tó bá kọ́kọ́ dà bíi pé wọn ò mọyì ohun tá a ṣe? Sọ àpẹẹrẹ kan.

8 Onírúurú ọ̀nà la lè gbà ṣe inúure sáwọn tá ò mọ̀ rí kódà tí wọn ò bá kọ́kọ́ mọrírì ohun tá a ṣe. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ yìí. Arábìnrin kan lórílẹ̀-èdè Sípéènì ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú obìnrin kan tó ń jẹ́ Yesica tó wá láti orílẹ̀-èdè Ecuador. Lọ́jọ́ kan tí wọ́n ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́, ṣe ni Yesica bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún pẹ̀rẹ̀pẹ̀rẹ̀. Arábìnrin náà bi í pé kí ló ṣẹlẹ̀. Yesica wá ṣàlàyé fún un pé kóun tó kó wá sórílẹ̀-èdè Sípéènì, àtijẹ-àtimu nira gan-an fún òun. Lọ́jọ́ kan, nǹkan burú débi pé omi lásán lòun fún ọmọ òun mu torí pé òun ò ní oúnjẹ kankan rárá. Yesica sọ pé òun ṣáà ń gbé ọmọ náà jó kó lè sùn, òun sì ń gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ran òun lọ́wọ́. Kò pẹ́ sígbà yẹn làwọn obìnrin méjì tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí wá sílé rẹ̀, àmọ́ ṣe ni Yesica kanra mọ́ wọn, tó sì fa ìwé ìròyìn tí wọ́n fún un ya. Ó wá pariwo mọ́ wọn pé: “Ṣé oúnjẹ tẹ́ ẹ fẹ́ kí n fún ọmọ mi jẹ rèé?” Àwọn arábìnrin náà gbìyànjú láti pẹ̀tù sí i lọ́kàn, àmọ́ pàbó ni gbogbo ìsapá wọn já sí. Nígbà tó yá, àwọn arábìnrin náà gbé apẹ̀rẹ̀ oúnjẹ kan sẹ́nu ọ̀nà ilé rẹ̀. Inúure táwọn arábìnrin yìí ṣe wú Yesica lórí gan-an, ó sì dùn ún pé òun ò moore bí Ọlọ́run ṣe dáhùn àdúrà òun lọ́jọ́ yẹn. Yesica wá pinnu pé Jèhófà lòun máa fayé òun sìn. Ẹ ò rí i pé inúure tá a bá ṣe sáwọn èèyàn máa ń sèso rere!​—Oníw. 11:1, 6.

MÁA YỌ̀ǸDA ARA RẸ FÚN IṢẸ́ ÈTÒ ỌLỌ́RUN

9, 10. (a) Nínú Bíbélì, àwọn ìgbà wo làwọn èèyàn yọ̀ǹda ara wọn fún iṣẹ́ Jèhófà? (b) Àwọn iṣẹ́ wo làwọn arákùnrin tó ń yọ̀ǹda ara wọn sábà máa ń ṣe nínú ìjọ lónìí?

9 Ní Ísírẹ́lì ìgbàanì, ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn èèyàn máa ń yọ̀ǹda ara wọn fún iṣẹ́ Jèhófà. (Ẹ́kís. 36:2; 1 Kíró. 29:5; Neh. 11:2) Bákan náà lónìí, ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ló wà tá a lè yọ̀ǹda ara wa fún. A lè yọ̀ǹda àkókò wa àtàwọn nǹkan tá a ní, kódà a lè fi àwọn iṣẹ́ tá a mọ̀ ọ́n ṣe ran àwọn ará wa lọ́wọ́. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá láyọ̀, Jèhófà sì máa bù kún ẹ lọ́pọ̀ yanturu.

10 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gba àwọn arákùnrin níyànjú pé kí wọ́n ṣiṣẹ́ kára kí wọ́n lè di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti alàgbà, nípa bẹ́ẹ̀, àwọn náà á lè máa bá Jèhófà ṣiṣẹ́. (1 Tím. 3:1, 8, 9; 1 Pét. 5:2, 3) Téèyàn bá ń nàgà fún àǹfààní yìí, ohun tó ń jẹ irú ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́kàn ni báá ṣe máa ran àwọn míì lọ́wọ́ nípa tara àti nípa tẹ̀mí. (Ìṣe 6:1-4) Ǹjẹ́ àwọn alàgbà ti bi ẹ́ rí bóyá wàá lè ṣe alábòójútó èrò tàbí kó o máa ṣèrànwọ́ nídìí ìwé, kó o máa bójú tó ìpínlẹ̀ ìwàásù ìjọ tàbí kó o lọ́wọ́ sí àtúnṣe Gbọ̀ngàn Ìjọba? Àwọn tó ń yọ̀ǹda ara wọn fún irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ gbà pé ayọ̀ wà nínú kéèyàn máa ran àwọn míì lọ́wọ́.

Àwọn tó bá yọ̀ǹda ara wọn fún iṣẹ́ nínú ètò Ọlọ́run máa ń láwọn ọ̀rẹ́ tuntun(Wo ìpínrọ̀ 11)

11. Báwo làwọn ọ̀rẹ́ tí arábìnrin kan ní nígbà tó ń ṣiṣẹ́ ìkọ́lé ṣe ràn án lọ́wọ́?

11 Àwọn tó bá yọ̀ǹda ara wọn fún iṣẹ́ nínú ètò Ọlọ́run máa ń ní àwọn ọ̀rẹ́ tuntun. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Arábìnrin Margie. Ọdún méjìdínlógún [18] ló fi bá àwọn tó ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba ṣiṣẹ́. Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́bìnrin ló ti ràn lọ́wọ́, tó sì ti dá lẹ́kọ̀ọ́ lẹ́nu iṣẹ́ yìí. Arábìnrin Margie gbà pé iṣẹ́ yìí ti fún òun láǹfààní láti fún àwọn ará níṣìírí kóun náà sì rí ìṣírí gbà. (Róòmù 1:12) Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó kojú ìṣòro, àwọn ọ̀rẹ́ tó ní lẹ́nu iṣẹ́ ìkọ́lé ló fún un níṣìírí. Ǹjẹ́ ìwọ náà ti fìgbà kan rí yọ̀ǹda ara rẹ fún irú iṣẹ́ ìkọ́lé bẹ́ẹ̀? Bóyá o mọ̀ nípa iṣẹ́ ìkọ́lé tàbí bẹ́ẹ̀ kọ, ǹjẹ́ o lè yọ̀ǹda ara rẹ?

12. Báwo la ṣe lè ṣèrànwọ́ fáwọn tí àjálù bá?

12 Ọ̀nà míì táwa èèyàn Ọlọ́run ń gbà bá Ọlọ́run ṣiṣẹ́ ni pé, a máa ń ran àwọn ará wa lọ́wọ́ nígbà àjálù. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ará máa ń fi owó ṣètìlẹyìn fáwọn tí àjálù bá. (Jòh. 13:34, 35; Ìṣe 11:27-30) Ohun míì tá a lè ṣe ni pé ká yọ̀ǹda ara wa fún iṣẹ́ ìmọ́tótó níbi tí àjálù náà ti ṣẹlẹ̀ tàbí ká bá wọn tún àwọn ibi tó bà jẹ́ ṣe. Bí àpẹẹrẹ, omíyalé ba ilé Arábìnrin Gabriela tó wá láti orílẹ̀-èdè Poland jẹ́. Àmọ́ inú rẹ̀ dùn nígbà táwọn ará tó wà láwọn ìjọ ìtòsí wá ràn án lọ́wọ́. Ó sọ pé: “Mi ò fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa ohun tí mo pàdánù, ó ṣe tán, àwọn nǹkan tara ni. Àmọ́, ẹ jẹ́ kí n sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí mo jèrè. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí mi ti jẹ́ kó túbọ̀ dá mi lójú pé kò síbòmíì tó dà bí ètò Ọlọ́run tá a wà yìí, èyí sì máa ń fún mi láyọ̀ gan-an.” Ọ̀pọ̀ àwọn tírú ẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ sí náà gbà pẹ̀lú ohun tí arábìnrin yìí sọ. Àwọn tó ń yọ̀ǹda ara wọn fún iṣẹ́ Jèhófà lọ́nà yìí máa ń ní ìbàlẹ̀ ọkàn, wọ́n sì máa ń láyọ̀.​—Ka Ìṣe 20:35; 2 Kọ́ríńtì 9:6, 7.

13. Tá a bá ń yọ̀ǹda ara wa, báwo nìyẹn ṣe máa mú kí àjọṣe àwa àti Jèhófà túbọ̀ lágbára? Sọ àpẹẹrẹ kan.

13 Arábìnrin Stephanie àtàwọn akéde míì ń láyọ̀ bí wọ́n ṣe ń bá Jèhófà ṣiṣẹ́ lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Wọ́n máa ń ṣèrànwọ́ fáwọn ìdílé tí ogún lé kúrò nílùú wọn tí wọ́n sì kó wá sórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Wọ́n máa ń bá wọn wá ilé, wọ́n á sì kó àwọn ohun tí wọ́n nílò sínú rẹ̀. Stephanie sọ pé: “Inú wọn dùn gan-an bí wọ́n ṣe fojú ara wọn rí ìfẹ́ tó so ẹgbẹ́ ará pọ̀, ayọ̀ tí èyí sì fún wa kọjá àfẹnusọ. Àwọn ìdílé yẹn máa ń rò pé àwa là ń ran àwọn lọ́wọ́, àmọ́ òótọ́ ibẹ̀ ni pé ohun tí wọ́n ṣe fún wa ju ohun táwa ṣe fún wọn lọ. Ìdí ni pé, wọ́n ti jẹ́ ká rí bí ìfẹ́ àti ìṣọ̀kan ṣe so wá pọ̀. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n nígbàgbọ́, wọ́n sì tún gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, èyí wá jẹ́ ká túbọ̀ mọyì gbogbo nǹkan tí ètò Ọlọ́run ń pèsè fún wa, ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà sì túbọ̀ lágbára sí i.”

O LÈ ṢE PÚPỌ̀ SÍ I LẸ́NU IṢẸ́ ÌSÌN JÈHÓFÀ

14, 15. (a) Irú ẹ̀mí wo ni wòlíì Aísáyà fi hàn? (b) Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wòlíì Aísáyà lónìí?

14 Ṣé wàá fẹ́ túbọ̀ bá Jèhófà ṣiṣẹ́? Ṣé o lè lọ sìn níbi tí àìní gbé pọ̀? Òótọ́ ni pé kò pọndandan ka kó lọ síbi tó jìnnà ká tó lè ṣiṣẹ́ Jèhófà. Àmọ́, àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin kan ti yọ̀ǹda ara wọn láti lọ sìn níbi tó jìnnà sí àdúgbò wọn. Irú ẹ̀mí tí wòlíì Aísáyà ní làwọn náà ní. Nígbà tí Jèhófà béèrè lọ́wọ́ Aísáyà pé: “Ta ni èmi yóò rán, ta sì ni yóò lọ fún wa?” Aísáyà dáhùn pé: “Èmi nìyí! Rán mi!” (Aísá. 6:8) Ṣé ìwọ náà lè yọ̀ǹda ara rẹ láti lọ sìn níbi tí àìní wà? Àwọn ọ̀nà wo lo lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀?

15 Nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ ìwàásù àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn, ó sọ pé: “Ìkórè pọ̀, ṣùgbọ́n díẹ̀ ni àwọn òṣìṣẹ́. Nítorí náà, ẹ bẹ Ọ̀gá ìkórè láti rán àwọn òṣìṣẹ́ jáde sínú ìkórè rẹ̀.” (Mát. 9:37, 38) Ǹjẹ́ o lè lọ ṣe aṣáájú-ọ̀nà níbi tí àìní gbé pọ̀ tàbí kó o ran ẹlòmíì lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀? Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin kan gbà pé ọ̀nà tó dáa jù táwọn lè gbà fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àtàwọn èèyàn ni pé káwọn ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà níbi tí àìní gbé pọ̀. Ǹjẹ́ àwọn ọ̀nà míì wà tó o lè gbà ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà? Kò sí àní-àní pé wà á láyọ̀ tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀.

16, 17. Àwọn ọ̀nà wo lo lè gbà ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà?

16 Ṣé o lè sìn ní Bẹ́tẹ́lì tàbí kó o ṣèrànwọ́ fáwọn tó ń ṣiṣẹ́ ìkọ́lé nínú ètò Ọlọ́run? O lè yọ̀ǹda ara rẹ fúngbà díẹ̀ tàbí kó o máa tilé wá sìn. Gbogbo ìgbà ni ètò Ọlọ́run máa ń nílò àwọn tó lè ṣiṣẹ́ níbikíbi tá a bá ti nílò wọn, tí wọ́n sì lè ṣiṣẹ́ èyíkéyìí tá a bá fún wọn. Nígbà míì, ètò Ọlọ́run lè ní kẹ́nì kan lọ ṣiṣẹ́ níbi kan tí wọ́n ti nílò àwọn èèyàn, kó sì jẹ́ pé ẹni náà ò nírìírí kankan nípa iṣẹ́ ọ̀hún. Síbẹ̀, Jèhófà mọrírì ẹ̀mí ìfara-ẹni-jìn tí wọ́n ní bí wọ́n ṣe ń sìn níbikíbi tí àìní bá wà.​—Sm. 110:⁠3.

17 Ǹjẹ́ wàá fẹ gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ kó o lè túbọ̀ já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, o lè gba fọ́ọ̀mù Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run. Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn, tí wọ́n sì wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún ló máa ń gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ yìí, èyí sì máa ń jẹ́ kí wọ́n lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Àwọn tó bá fẹ́ lọ sílé ẹ̀kọ́ yìí gbọ́dọ̀ múra tán láti ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí tí wọ́n bá fún wọn lẹ́yìn ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà. Ǹjẹ́ ìwọ náà lè lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere kó o lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà?​—1 Kọ́r. 9:23.

18. Àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń bá Jèhófà ṣiṣẹ́ lójoojúmọ́?

18 Torí pé a jẹ́ èèyàn Jèhófà, ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn jẹ wá lógún. Ìdí nìyẹn tá a fi máa ń lawọ́ sáwọn èèyàn, a sì máa ń ṣe inúure sí wọn torí pé a nífẹ̀ẹ́ wọn. Bá a ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀, à ń láyọ̀, ọkàn wa sì balẹ̀. (Gál. 5:22, 23) Ipò yòówù ká wà, tá a bá jẹ́ ọ̀làwọ́ bíi ti Jèhófà, ó dájú pé a máa láyọ̀, àá sì jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n lójú rẹ̀!​—Òwe 3:9, 10.