Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Máa Rí Àrídájú Ọ̀rọ̀

Máa Rí Àrídájú Ọ̀rọ̀

“Nígbà tí ẹnì kan bá ń fèsì ọ̀ràn kí ó tó gbọ́ ọ, èyíinì jẹ́ ìwà òmùgọ̀ níhà ọ̀dọ̀ rẹ̀ àti ìtẹ́lógo.”​—ÒWE 18:13.

ORIN: 126, 95

1, 2. (a) Kí ló yẹ káwa Kristẹni máa ṣe, kí sì nìdí? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

Ó YẸ káwa Kristẹni tòótọ́ mọ bá a ṣe ń gbé ọ̀rọ̀ yẹ̀ wò dáadáa ká lè dórí ìpinnu tó tọ́. (Òwe 3:21-23; 8:4, 5) Ìdí ni pé, Sátánì àti ayé burúkú yìí lè gbin èrò òdì sí wa lọ́kàn tá ò bá ṣọ́ra. (Éfé. 5:6; Kól. 2:8) Torí náà, ká tó lè ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání lórí ọ̀rọ̀ kan, ó yẹ ká rí òkodoro òtítọ́ nípa ọ̀rọ̀ náà. Abájọ tí Òwe 18:13 fi sọ pé, “nígbà tí ẹnì kan bá ń fèsì ọ̀ràn kí ó tó gbọ́ ọ, èyíinì jẹ́ ìwà òmùgọ̀ níhà ọ̀dọ̀ rẹ̀ àti ìtẹ́lógo.”

2 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò àwọn ohun tó máa ń jẹ́ kó ṣòro láti rí òkodoro òtítọ́ nípa ọ̀rọ̀ kan. A tún máa ṣàyẹ̀wò àwọn ìlànà Bíbélì tó máa ràn wá lọ́wọ́ lórí ọ̀rọ̀ yìí, a sì máa rí àwọn àpẹẹrẹ tó máa jẹ́ ká mọ béèyàn ṣe ń yiiri ọ̀rọ̀ wò dáadáa.

MÁ ṢE GBA “GBOGBO Ọ̀RỌ̀” GBỌ́

3. Kí nìdí tó fi yẹ ká fi ìmọ̀ràn tó wà nínú Òwe 14:15 sọ́kàn? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

3 Yaágbó-yaájù ìsọfúnni ló wà lónìí. Ṣé ti orí íńtánẹ́ẹ̀tì la fẹ́ sọ ni àbí ti tẹlifíṣọ̀n àtàwọn ìwé ìròyìn lónírúurú? Kì í ṣèyẹn nìkan, ọ̀pọ̀ ìsọfúnni làwọn ọ̀rẹ́ wa máa ń fi ránṣẹ́ sí wa lórí fóònú àti kọ̀ǹpútà. Ó yẹ ká kíyè sára gan-an torí pé lónìí, ó wọ́pọ̀ káwọn èèyàn máa fi ìsọfúnni tí kì í ṣòótọ́ ránṣẹ́, ìdí nìyẹn tó fi yẹ ká gbé ọ̀rọ̀ èyíkéyìí tá a bá gbọ́ yẹ̀ wò dáadáa. Ìlànà Bíbélì wo la lè ronú lé? Òwe 14:15 sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ aláìní ìrírí ń ní ìgbàgbọ́ nínú gbogbo ọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n afọgbọ́nhùwà máa ń ronú nípa àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.”

4. Báwo lohun tó wà nínú Fílípì 4:​8, 9 ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ tá a bá fẹ́ yan ohun tá a máa kà? Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká ní ìsọfúnni tó péye? (Tún wo àpótí náà “ Díẹ̀ Lára Àwọn Ibi Tá A Ti Lè Rí Ìsọfúnni Tó Ṣeé Gbára Lé.”)

4 Ká tó lè ṣèpinnu tó dáa nípa ọ̀rọ̀ kan, a gbọ́dọ̀ ní ìsọfúnni tó péye nípa ọ̀rọ̀ náà. Torí náà, ó yẹ ká fọgbọ́n yan irú àwọn ìsọfúnni tá a máa yẹ̀ wò àtàwọn ìròyìn tá a máa kà. (Ka Fílípì 4:8, 9.) Kò yẹ ká máa fàkókò wa ṣòfò lórí àwọn ìkànnì tó ń gbé ìròyìn èké jáde, kò sì yẹ ká máa ka àwọn ìsọfúnni tí kì í ṣòótọ́ táwọn èèyàn fi ń ránṣẹ́ kiri. Ní pàtàkì jù lọ, a gbọ́dọ̀ yẹra fáwọn ìkànnì táwọn apẹ̀yìndà fi ń tan irọ́ kálẹ̀. Ohun táwọn apẹ̀yìndà yìí ń wá ni bí wọ́n á ṣe tú wa ká, tí wọ́n á sì bomi la òtítọ́ tá a mọ̀. Yàtọ̀ síyẹn, kò yẹ ká fojú kéré àkóbá tí ìsọfúnni tí kò péye lè ṣe fún wa. Lára ẹ̀ ni pé ó lè ṣì wá lọ́nà, kó sì mú ká ṣèpinnu tí kò bọ́gbọ́n mu.​—1 Tím. 6:20, 21.

5. Ìròyìn tí kì í ṣòótọ́ wo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọ́, kí nìyẹn sì mú kí wọ́n ṣe?

5 Tá a bá gba ọ̀rọ̀ tí kì í ṣòótọ́ gbọ́, ìgbẹ̀yìn rẹ̀ kì í dáa. Àpẹẹrẹ kan lohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà ayé Mósè. Mẹ́wàá nínú àwọn méjìlá tó lọ ṣe amí Ilẹ̀ Ìlérí ló mú ìròyìn tí kò dáa wálé. (Núm. 13:25-33) Àwọn ìròyìn tó ń mọ́kàn ẹni pami tó sì kún fún àbùmọ́ tó fa kíki ni wọ́n ń sọ, èyí wá mú kí àyà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí í já. (Núm. 14:1-4) Kí ló mú káwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbà wọ́n gbọ́? Nígbà tó jẹ́ pé ọ̀pọ̀ nínú àwọn amí yẹn ló mú ìròyìn burúkú wálé, wọ́n lè máa ronú pé òótọ́ ni wọ́n ń sọ. Ni wọ́n bá kọtí ikún sí ìròyìn tó dáa táwọn ọkùnrin tó ṣeé fọkàn tán, ìyẹn Jóṣúà àti Kálébù mú wá. (Núm. 14:6-10) Dípò káwọn èèyàn náà wádìí ọ̀rọ̀ náà dáadáa kí wọ́n sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ṣe ni wọ́n gba ìròyìn burúkú náà gbọ́. Ẹ ò rí i pé ìwà òmùgọ̀ gbáà nìyẹn!

6. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká bínú tá a bá gbọ́ ohun tí kò dáa nípa àwa èèyàn Jèhófà?

6 Ó yẹ ká ṣọ́ra gan-an tá a bá gbọ́ ìròyìn èyíkéyìí nípa àwa èèyàn Jèhófà. Bíbélì sọ pé gbogbo ìgbà ni Sátánì ń fẹ̀sùn kan àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run. (Ìṣí. 12:10) Jésù tiẹ̀ kìlọ̀ fún wa pé àwọn alátakò máa fi “irọ́ pípa sọ gbogbo onírúurú ohun burúkú” nípa wa. (Mát. 5:11) Tá a bá fi ìkìlọ̀ yìí sọ́kàn, inú ò ní bí wa tá a bá gbọ́ táwọn èèyàn ń sọ ohun tí kò dáa nípa àwa èèyàn Jèhófà.

7. Kí làwọn ìbéèrè tó yẹ ká bi ara wa ká tó fi ìsọfúnni kan ránṣẹ́ sáwọn míì?

7 Ǹjẹ́ o máa ń ṣe ẹ́ bíi pé kó o fi gbogbo ìsọfúnni tó o bá ti rí ránṣẹ́ sáwọn ọ̀rẹ́ rẹ? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé ọ̀rọ̀ rẹ dà bíi ti oníròyìn kan tó máa ń fẹ́ jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ tó máa gbé ìròyìn tuntun kan sáfẹ́fẹ́. Àmọ́, kó o tó fi ìsọfúnni kan ránṣẹ́ lórí fóònù, bi ara rẹ pé: ‘Ṣé ó dá mi lójú pé òótọ́ pọ́ńbélé ni ìsọfúnni tí mo fẹ́ fi ránṣẹ́ yìí? Ṣé mo tiẹ̀ ti rí àrídájú ẹ̀?’ Tí kò bá dá ẹ lójú àmọ́ tó o fi ránṣẹ́ sáwọn ará, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìròyìn èké lò ń tàn kálẹ̀ láìmọ̀. Torí náà, tí ìsọfúnni kan kò bá dá ẹ lójú, á dáa kó o pa á rẹ́ kúrò lórí fóònù rẹ dípò kó o fi ránṣẹ́ sáwọn míì.

8. Kí làwọn alátakò kan ti ṣe làwọn ilẹ̀ kan, báwo la ṣe lè máa ti àwọn alátakò yìí lẹ́yìn láìmọ̀?

8 Ewu míì tún wà níbẹ̀ tá a bá ń tètè fi àwọn ìsọfúnni tí kò dá wa lójú ránṣẹ́ sáwọn míì. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ilẹ̀ kan wà tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ ìwàásù wa. Àwọn alátakò wa láwọn ilẹ̀ bẹ́ẹ̀ lè mọ̀ọ́mọ̀ gbé àwọn ìsọfúnni kan sáfẹ́fẹ́ kí wọ́n lè dẹ́rù bà wá, ká má sì fọkàn tán àwọn ará wa mọ́. Àpẹẹrẹ kan lohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn ará wa nígbà ìjọba Soviet Union. Àwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ KGB bẹ̀rẹ̀ sí í tan irọ́ kálẹ̀, wọ́n sọ pé àwọn arákùnrin tó ń múpò iwájú ti fi ètò Ọlọ́run sílẹ̀, wọ́n sì ti dalẹ̀ àwọn èèyàn Ọlọ́run. * Ó bani nínú jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ló gba ìròyìn èké yìí gbọ́, èyí sì mú kí wọ́n fi ètò Ọlọ́run sílẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ wọn pa dà sínú ètò Ọlọ́run nígbà tó yá, àmọ́ àwọn kan ò pa dà torí wọ́n ti jẹ́ kí ọkọ̀ ìgbàgbọ́ wọn rì. (1 Tím. 1:19) Kí ló yẹ ká ṣe tá ò bá fẹ́ kí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí wa? Tó o bá gbọ́ ọ̀rọ̀ kan tí kò dáa nípa àwọn ará wa tàbí ọ̀rọ̀ kan tí kò dá ẹ lójú, má ṣe tan irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ kálẹ̀. Àwọn tí kò gbọ́n ló máa ń gba gbogbo ọ̀rọ̀ gbọ́, torí náà, rí i dájú pé ó rí àrídájú ọ̀rọ̀ èyíkéyìí tó o bá gbọ́.

ÌSỌFÚNNI TÍ KÌ Í ṢE ÒÓTỌ́ DÉLẸ̀DÉLẸ̀

9. Kí lohun míì tó máa ń jẹ́ kó ṣòro láti rí ìsọfúnni tó péye?

9 Àwọn ìròyìn kan wà tí wọ́n máa ń gbé jáde àmọ́ kì í ṣòótọ́ délẹ̀délẹ̀. Irú àwọn ìsọfúnni bẹ́ẹ̀ máa ń jẹ́ kó ṣòro láti rí òkodoro òtítọ́. Ká má gbàgbé pé kò sì irọ́ kékeré, tí ìsọfúnni kan kò bá ti jẹ́ òótọ́ délẹ̀délẹ̀, irọ́ ni, ó sì lè ṣini lọ́nà. Tá ò bá fẹ́ kírú àwọn ìròyìn bẹ́ẹ̀ ṣì wá lọ́nà, kí ló yẹ ká ṣe?​—Éfé. 4:14.

10. Kí ló mú káwọn ọmọ Ísírẹ́lì kan pinnu láti lọ bá àwọn arákùnrin wọn jagun, kí ni wọ́n ṣe tógun yìí ò fi wáyé?

10 Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ń gbé lápá ìwọ̀ oòrùn Odò Jọ́dánì nígbà ayé Jóṣúà. (Jóṣ. 22:9-34) Wọ́n gbọ́ pé àwọn ẹ̀yà Rúbẹ́nì àti Gádì àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè tó ń gbé ní apá ìlà oòrùn Jọ́dánì mọ pẹpẹ ràgàjì kan sítòsí Odò Jọ́dánì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé òótọ́ ni pé wọ́n mọ pẹpẹ kan, síbẹ̀ wọn ò mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ìdí tí wọ́n fi mọ pẹpẹ náà. Ohun táwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wà lápá ìwọ̀ oòrùn rò ni pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ń gbé lápá ìlà oòrùn ti ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà, wọ́n sì fẹ́ máa bọ̀rìṣà. Ni wọ́n bá múra láti lọ bá wọn jagun. (Ka Jóṣúà 22:9-12.) Àmọ́ kí wọ́n tó kógun lọ, wọ́n ṣe ohun kan tó dáa. Wọ́n rán àwọn ọkùnrin tó ṣeé fọkàn tán pé kí wọ́n lọ wádìí ọ̀rọ̀ náà wò. Kí wá ni wọ́n bá bọ̀? Wọ́n rí i pé kì í ṣe torí káwọn ẹ̀yà tó ń gbé lápá ìlà oòrùn lè máa bọ̀rìṣà ni wọ́n ṣe mọ pẹpẹ yẹn, àmọ́ wọ́n mọ ọ́n kó lè wà fún ìrántí. Èyí á jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ lẹ́yìnwá ọ̀la pé ìránṣẹ́ Jèhófà ni wọ́n. Ó dájú pé inú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yẹn máa dùn pé àwọn wádìí ọ̀rọ̀ náà dáadáa kí wọ́n tó gbé ìgbésẹ̀. Ká sọ pé wọ́n ti kógun ja àwọn arákùnrin wọn ni, ìpakúpa tó máa wáyé ò bá bùáyà!

11. (a) Kí nìdí tí Dáfídì fi gba ilẹ̀ tó fún Mefibóṣẹ́tì pa dà? (b) Kí ló yẹ kí Dáfídì ti kọ́kọ́ ṣe?

11 Nígbà míì, àwọn èèyàn lè máa sọ ohun tí kì í ṣòótọ́ nípa wa. Àwọn tó bá gba irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ gbọ́ lè bẹ̀rẹ̀ sí í fi ohun tí wọ́n gbọ́ hùwà sí wa. Ẹ wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Ọba Dáfídì àti Mefibóṣẹ́tì. Dáfídì fi inúure àti àánú hàn sí Mefibóṣẹ́tì, ó sì fún un ní gbogbo ilẹ̀ Sọ́ọ̀lù bàbá-bàbá rẹ̀. (2 Sám. 9:6, 7) Kò pẹ́ sígbà yẹn lẹnì kan sọ̀rọ̀ Mefibóṣẹ́tì láìdáa lójú Dáfídì. Kàkà kí Dáfídì wádìí ọ̀rọ̀ náà wò, ó gba ọ̀rọ̀ náà gbọ́, ó sì gba gbogbo ilẹ̀ tó fún Mefibóṣẹ́tì pa dà. (2 Sám. 16:1-4) Nígbà tó yá, Dáfídì àti Mefibóṣẹ́tì jọ sọ̀rọ̀, Dáfídì wá rí i pé àṣìṣe lòun ṣe, ló bá dá díẹ̀ pa dà nínú ogún Mefibóṣẹ́tì. (2 Sám. 19:24-29) Ká sọ pé Dáfídì ti fara balẹ̀ wádìí ọ̀rọ̀ náà kó tó ṣèpinnu lórí ààbọ̀ ọ̀rọ̀ tó gbọ́ ni, ọ̀rọ̀ ò ní rí báyìí fún Mefibóṣẹ́tì.

12, 13. (a) Kí ni Jésù ṣe nígbà táwọn èèyàn sọ̀rọ̀ rẹ̀ láìdáa? (b) Kí la lè ṣe tẹ́nì kan bá parọ́ mọ́ wa?

12 Kí ló máa ṣe tó o bá gbọ́ táwọn èèyàn sọ̀rọ̀ rẹ láìdáa? Rántí pé wọ́n sọ̀rọ̀ Jésù àti Jòhánù Oníbatisí náà láìdáa. (Ka Mátíù 11:18, 19.) Kí wá ni Jésù ṣe? Dípò kó máa wá bó ṣe máa gbèjà ara rẹ̀, ńṣe ló rọ àwọn èèyàn náà pé kí wọ́n fara balẹ̀ kíyè sí ìwà òun àti ẹ̀kọ́ tóun fi ń kọ́ni. Jésù sọ pé, “a fi ọgbọ́n hàn ní olódodo nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ rẹ̀.”​—Mát. 11:19.

13 A lè kẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì nínú ohun tí Jésù sọ. Ìdí ni pé àwọn èèyàn lè sọ̀rọ̀ wa láìdáa tàbí kí wọ́n ṣàríwísí wa nígbà míì. Ó lè máa ṣe wá bíi pé ká gbèjà ara wa káwọn èèyàn lè mọ̀ pé irọ́ ni wọ́n pa mọ́ wa. Àmọ́, nǹkan kan wà tá a lè ṣe. A lè gbé ìgbé ayé wa lọ́nà tó máa jẹ́ kó hàn kedere sáwọn èèyàn pé irọ́ lẹni náà pa mọ́ wa. Láìsí àní-àní, àpẹẹrẹ Jésù jẹ́ ká rí i pé tá a bá ń hùwà tó yẹ Kristẹni, kò sẹ́ni tó máa gba irọ́ èyíkéyìí táwọn èèyàn bá pa mọ́ wa gbọ́.

MÁ ṢE DÁ ARA RẸ LÓJÚ JÙ

14, 15. Kí ló lè ṣẹlẹ̀ tá a bá ń gbára lé òye tara wa?

14 Kì í rọrùn kéèyàn tó rí òkodoro òtítọ́ nípa ọ̀rọ̀ kan. Àìpé tiwa náà sì lè mú kó ṣòro láti dórí ìpinnu tó tọ́ nípa ọ̀rọ̀ náà. A lè ti máa sin Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún, ká ti nírìírí, ká sì mọ béèyàn ṣe ń gbé ọ̀rọ̀ yẹ̀ wò dáadáa. Àwọn èèyàn tiẹ̀ lè máa bọ̀wọ̀ fún wa torí pé a mọ bí wọ́n ṣe ń fọgbọ́n yanjú ọ̀rọ̀. Síbẹ̀ tá ò bá ṣọ́ra, àwọn ànímọ́ yìí lè kó wa síṣòro. Lọ́nà wo?

15 A lè bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé a ti gbọ́n tán àti pé kò sọ́rọ̀ tá ò lè yanjú. Ìyẹn lè mú ká máa lo ọgbọ́n orí wa àti bí nǹkan ṣe máa ń rí lára wa nígbà tá a bá ń gbé ọ̀rọ̀ kan yẹ̀ wò. A lè máa ronú pé kò sọ́rọ̀ tá ò lè yanjú kódà tá ò bá mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀rọ̀ náà. Ẹ ò rí i pé ìyẹn máa léwu gan-an! Abájọ tí Bíbélì fi kìlọ̀ fún wa pé ká má ṣe gbẹ́kẹ̀ lé òye tara wa.​—Òwe 3:5, 6; 28:26.

16. Kí ló ṣẹlẹ̀ nílé oúnjẹ kan, ibo sì ni Arákùnrin Tom parí èrò sí?

16 Ẹ jẹ́ ká fọkàn yàwòrán ìṣẹ̀lẹ̀ yìí. Lọ́jọ́ kan, alàgbà kan tó nírìírí tó ń jẹ́ Tom lọ jẹun nílé oúnjẹ kan, àmọ́ ó yà á lẹ́nu nígbà tó rí Arákùnrin John tí wọ́n jọ jẹ́ alàgbà pẹ̀lú obìnrin míì tí kì í ṣe ìyàwó rẹ̀. Tom rí i pé àwọn méjèèjì ń rẹ́rìn-ín, wọ́n ń ṣeré, kódà wọ́n tiẹ̀ ń gbá ara wọn mọ́ra. Ohun tó rí yìí rú u lójú. Arákùnrin Tom wá bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé, ṣé kì í ṣe pé arákùnrin John máa kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀? Kí ló máa wá ṣẹlẹ̀ sí ìyàwó ẹ̀? Ṣé ìyà ò ní jẹ àwọn ọmọ wọn? Ohun kan ni pé Arákùnrin Tom ti rí àwọn tí irú ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí rí. Tó bá jẹ́ pé ìwọ náà wà níbẹ̀, báwo lohun tó o rí ṣe máa rí lára ẹ?

17. Kí ni Tom pa dà wá mọ̀, ẹ̀kọ́ wo lèyí sì kọ́ wa?

17 Àmọ́ ẹ dúró ná o. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Tom ronú pé Arákùnrin John ti dalẹ̀ ìyàwó rẹ̀, ṣé ó mọ bọ́rọ̀ ṣe jẹ́ gan-an? Nígbà tó dọwọ́ ìrọ̀lẹ́, Tom pe John lórí fóònù. John wá ṣàlàyé fún Tom pé àbúrò òun ni obìnrin náà àti pé ó ti tọ́jọ́ mẹ́ta táwọn ti ríra. Torí pé kò ní pẹ́ pa dà lòun ṣe lọ pàdé rẹ̀ nílé oúnjẹ yẹn. Ó sọ pé ìyàwó òun fẹ́ wá bá àwọn níbẹ̀, àmọ́ ohun tó ń ṣe ò jẹ́ kó lè ráyè wá. Ẹ fojú inú wo bọ́rọ̀ yẹn ṣe máa rí lára Tom, ó dájú pé inú rẹ̀ máa dùn pé òun ò tíì sọ ohun tóun rò fáwọn míì. Kí ni èyí kọ́ wa? Ó yẹ ká fi sọ́kàn pé kò sí bá a ṣe nírìírí tó, tá ò bá rí àrídájú ọ̀rọ̀ kan, a lè ṣèpinnu tí kò tọ́.

18. Kí ló lè ṣẹlẹ̀ tá a bá ń di àwọn ará wa sínú?

18 Tí èdèkòyédè bá wà láàárín àwa àtẹnì kan nínú ìjọ, ó rọrùn láti dórí ìpinnu tí kò tọ́ tá a bá gbọ́ nǹkan kan nípa ẹni náà. Tó bá jẹ́ pé ibi tẹ́ni yẹn kù sí là ń wò ṣáà, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í fura sí i. Tá a bá wá gbọ́ nǹkan tí kò dáa nípa ẹni yẹn pẹ́nrẹ́n, a lè tètè gbà pé òótọ́ ni. Kí nìyẹn kọ́ wa? Tá a bá ń di àwọn ará wa sínú, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í fojú tí kò dáa wò wọ́n torí àwọn ọ̀rọ̀ tí kì í ṣòótọ́ tá a gbọ́ nípa wọn. (1 Tím. 6:4, 5) Kò yẹ ká máa jowú àwọn ará wa tàbí ká máa ṣe ìlara wọn, torí tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í ní èrò tí kò dáa nípa wọn. Dípò ká máa ro èrò tí kò dáa nípa àwọn ará wa, a gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ wọn ká sì máa dárí jì wọ́n látọkàn.​—Ka Kólósè 3:12-14.

ÀWỌN ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ MÁA DÁÀBÒ BÒ WÁ

19, 20. (a) Àwọn ìlànà Bíbélì wo la lè ronú lé tá a bá fẹ́ mọ béèyàn ṣe ń wádìí ọ̀rọ̀ wò dáadáa? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?

19 Lónìí, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ìsọfúnni tó wà ló kún fún irọ́, àwọn míì sì wà tí kì í ṣe òótọ́ délẹ̀délẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀tọ̀ ni kéèyàn rídìí ọ̀rọ̀ kan, ọ̀tọ̀ sì ni kéèyàn ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání. Bákan náà, àìpé tiwa fúnra wa náà lè jẹ́ ká dórí èrò tí kò tọ́. Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́? Àwọn ìlànà Bíbélì kan wà tá a lè ronú lé. Bí àpẹẹrẹ, ìlànà Bíbélì kan sọ pé ìwà òmùgọ̀ ni téèyàn bá ń fèsì ọ̀rọ̀ kó tó wádìí rẹ̀, èyí sì máa kó ìtìjú bá a. (Òwe 18:13) Ìlànà Bíbélì míì sọ pé ká wádìí ọ̀rọ̀ wò dáadáa ká tó gbà á gbọ́. (Òwe 14:15) Paríparí ẹ̀, láìka iye ọdún tá a ti wà nínú òtítọ́, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kó má lọ di pé àá máa gbẹ́kẹ̀ lé òye tara wa. (Òwe 3:5, 6) Kò sí àní-àní pé àwọn ìlànà Bíbélì máa ń dáàbò bò wá torí pé ó máa ń jẹ́ ká wádìí ọ̀rọ̀ wò dáadáa, ká ní èrò tó tọ́, ká sì ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání.

20 Àmọ́, ohun míì wà tó yẹ ká fún láfiyèsí, ìyẹn ni pé kéèyàn máa fi ìrísí dáni lẹ́jọ́. Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa rí àwọn nǹkan tó máa ń fà á àtàwọn ohun tá a lè ṣe láti yẹra fún irú ìwà bẹ́ẹ̀.

^ ìpínrọ̀ 8 Wo Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti Ọdún 2004, ojú ìwé 111 sí 112 lédè Gẹ̀ẹ́sì àti Ìwé Ọdọọdún 2008, ojú ìwé 133 sí 135 lédè Gẹ̀ẹ́sì.