Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 30

Mọyì Àǹfààní Tó O Ní Pé O Wà Nínú Ìdílé Jèhófà

Mọyì Àǹfààní Tó O Ní Pé O Wà Nínú Ìdílé Jèhófà

“O mú kó rẹlẹ̀ díẹ̀ ju àwọn áńgẹ́lì, o sì fi ògo àti ọlá ńlá dé e ládé.”​—SM. 8:5, àlàyé ìsàlẹ̀.

ORIN 123 Máa Ṣègbọràn sí Ètò Ọlọ́run

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1. Tá a bá ronú jinlẹ̀ lórí gbogbo ohun tí Jèhófà dá, ìbéèrè wo ló lè wá sí wa lọ́kàn?

TÁ A bá ń ronú jinlẹ̀ lórí gbogbo ohun tí Jèhófà dá lọ́run àti láyé, ó lè ṣe wá bíi ti Ọba Dáfídì tó sọ pé: “Nígbà tí mo rí ọ̀run rẹ, àwọn iṣẹ́ ìka rẹ, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ tí o ti ṣètò sílẹ̀, kí ni ẹni kíkú jẹ́ tí o fi ń fi í sọ́kàn àti ọmọ aráyé tí o fi ń tọ́jú rẹ̀?” (Sm. 8:3, 4) Bíi ti Dáfídì, tá a bá ronú nípa bá a ṣe kéré tó ní ìfiwéra pẹ̀lú àgbáálá ayé yìí àtọ̀run tó lọ salalu, ó lè yà wá lẹ́nu pé Jèhófà ń fi wá sọ́kàn. Síbẹ̀, bá a ṣe máa rí i nínú àpilẹ̀kọ yìí, kì í ṣe pé Jèhófà fi Ádámù àti Éfà sọ́kàn nìkan ni, ó tún mú kí wọ́n wà lára ìdílé òun.

2. Kí ni Jèhófà fẹ́ kí Ádámù àti Éfà ṣe?

2 Ádámù àti Éfà ni àkọ́kọ́ lára àwọn ọmọ Jèhófà láyé, Jèhófà sì nífẹ̀ẹ́ wọn gan-an. Ọlọ́run fẹ́ kí tọkọtaya yìí fi ọmọ kún ayé, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ máa bímọ, kí ẹ sì pọ̀, kí ẹ kún ayé, kí ẹ sì ṣèkáwọ́ rẹ̀.” (Jẹ́n. 1:28) Ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ni pé kí wọ́n bímọ, kí wọ́n sì máa bójú tó ilẹ̀ ayé. Ká ní Ádámù àti Éfà ṣègbọràn sí Jèhófà, wọ́n sì ṣe ohun tó fẹ́, àwọn àtàwọn ọmọ wọn ò bá wà nínú ìdílé Ọlọ́run títí láé.

3. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ipò pàtàkì ni Ádámù àti Éfà wà nínú ìdílé Ọlọ́run?

3 Ipò pàtàkì ni Ádámù àti Éfà wà nínú ìdílé Jèhófà, ó sì buyì kún wọn gan-an. Bó ṣe wà nínú Sáàmù 8:5 àti àlàyé ìsàlẹ̀, Dáfídì sọ nípa àwa èèyàn pé: “O mú kó rẹlẹ̀ díẹ̀ ju àwọn áńgẹ́lì, o sì fi ògo àti ọlá ńlá dé e ládé.” Òótọ́ ni pé àwa èèyàn ò ní okun àti agbára bíi tàwọn áńgẹ́lì, ọgbọ́n wa ò sì tó tiwọn. (Sm. 103:20) Síbẹ̀, ẹsẹ Bíbélì yẹn jẹ́ kó hàn kedere pé ìwọ̀nba “díẹ̀” làwa èèyàn fi rẹlẹ̀ sí àwọn áńgẹ́lì. Ǹjẹ́ ìyẹn ò yani lẹ́nu? Kò sí àní-àní pé Jèhófà pọ́n Ádámù àti Éfà lé gan-an.

4. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Ádámù àti Éfà nígbà tó yá, kí la sì máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

 4 Ó bani nínú jẹ́ pé Ádámù àti Éfà ṣàìgbọràn sí Jèhófà, Jèhófà sì kọ̀ wọ́n lọ́mọ. Bá a ṣe máa rí i nínú àpilẹ̀kọ yìí, ohun tí wọ́n ṣe yẹn ṣàkóbá gan-an fáwọn àtọmọdọ́mọ wọn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ṣàìgbọràn, ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn fáráyé ò yí pa dà. Bópẹ́ bóyá, àwọn onígbọràn máa di ọmọ ẹ̀ títí láé. Ní báyìí, a máa jíròrò bí Jèhófà ṣe buyì kún wa tó sì dá wa lọ́lá. Lẹ́yìn náà, a máa jíròrò ohun tá a lè máa ṣe táá fi hàn pé a fẹ́ di ara ìdílé Ọlọ́run. Paríparí ẹ̀, a máa jíròrò àwọn ìbùkún tí àwọn ọmọ Jèhófà lórí ilẹ̀ ayé máa gbádùn títí láé.

BÍ JÈHÓFÀ ṢE DÁ ÀWA ÈÈYÀN LỌ́LÁ

Àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà dá wa lọ́lá? (Wo ìpínrọ̀ 5-11) *

5. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì bí Jèhófà ṣe dá wa ní àwòrán ara ẹ̀?

5 Jèhófà dá wa lọ́lá ní ti pé ó dá wa ní àwòrán rẹ̀. (Jẹ́n. 1:26, 27) Torí pé a jẹ́ àwòrán Ọlọ́run, a lè fìwà jọ ọ́. Nípa bẹ́ẹ̀, a lè fìfẹ́ hàn, a lè ṣàánú, a lè jẹ́ adúróṣinṣin, a sì lè jẹ́ olódodo. (Sm. 86:15; 145:17) Bá a ṣe túbọ̀ ń fìwà jọ Jèhófà, ṣe là ń bọlá fún un, tá a sì ń jẹ́ kó mọ̀ pé a mọyì ohun tó ṣe fún wa. (1 Pét. 1:14-16) Bákan náà, tá a bá fìwà jọ Jèhófà, inú wa á dùn, àá sì di ọ̀kan lára irú àwọn tó fẹ́ nínú ìdílé rẹ̀.

6. Báwo ni Jèhófà ṣe dá àwa èèyàn lọ́lá nígbà tó dá ayé?

6 Jèhófà dá ayé lọ́nà tó fi máa dùn ún gbé. Kí Jèhófà tó dá Ádámù, ó ti ṣètò gbogbo ohun táwa èèyàn máa nílò sínú ayé. (Jóòbù 38:4-6; Jer. 10:12) Torí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì lawọ́, ó pèsè gbogbo ohun táá mú ká gbádùn ìgbésí ayé wa. (Sm. 104:14, 15, 24) Bí Jèhófà ṣe ń dá àwọn nǹkan, bẹ́ẹ̀ náà ló ń yẹ̀ ẹ́ wò, ó sì “rí i pé ó dára.” (Jẹ́n. 1:10, 12, 31) Jèhófà tún dá wa lọ́lá ní ti pé ó fún wa “ní àṣẹ lórí” gbogbo nǹkan tó dá sáyé. (Sm. 8:6) Ohun tí Jèhófà fẹ́ ni pé kí àwọn èèyàn pípé wà láàyè títí láé, kí wọ́n sì máa láyọ̀ bí wọ́n ṣe ń bójú tó àwọn nǹkan tó dá sáyé. Ṣé o máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà déédéé fáwọn nǹkan tó ti ṣe àtèyí tó máa ṣe lọ́jọ́ iwájú?

7. Kí ni Jóṣúà 24:15 sọ tó jẹ́ ká mọ̀ pé a lómìnira láti yan ohun tá a fẹ́?

7 Jèhófà fún wa lómìnira láti yan ohun tá a fẹ́. A lè pinnu bóyá a máa ṣèfẹ́ Jèhófà àbí a ò ní ṣe bẹ́ẹ̀. (Ka Jóṣúà 24:15.) Inú Jèhófà máa ń dùn tá a bá pinnu pé òun la máa sìn. (Sm. 84:11; Òwe 27:11) Yàtọ̀ sí ọ̀rọ̀ ìjọsìn, a tún lè pinnu láti ṣe àwọn nǹkan tó dáa. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Jésù.

8. Sọ àpẹẹrẹ ìpinnu kan tí Jésù ṣe.

8 Bíi ti Jésù, àwa náà lè fi ire àwọn míì ṣáájú tiwa. Ìgbà kan wà tó rẹ Jésù àtàwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀, wọ́n wá rìnrìn àjò lọ síbì kan tó dá kí wọ́n lè sinmi. Àmọ́ àyè ìyẹn ò yọ fún wọn. Ìdí ni pé nígbà tí wọ́n fi máa dé ibi tí wọ́n ń lọ, wọ́n bá èrò rẹpẹtẹ níbẹ̀, àwọn èrò náà sì fẹ́ kí Jésù kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́. Síbẹ̀, Jésù ò kanra mọ́ wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló káàánú wọn. Kí ni Jésù wá ṣe? Bíbélì sọ pé: “Ó . . . bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn ní ọ̀pọ̀ nǹkan.” (Máàkù 6:30-34) Bíi ti Jésù, táwa náà bá ń lo àkókò àti okun wa láti ran àwọn míì lọ́wọ́, ṣe là ń fògo fún Jèhófà. (Mát. 5:14-16) A sì ń tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé a fẹ́ jẹ́ ara ìdílé rẹ̀.

9. Kí ló yẹ káwọn òbí fi sọ́kàn?

9 Jèhófà dá wa lọ́nà tá a fi lè bímọ, ó sì fẹ́ ká kọ́ àwọn ọmọ náà kí wọ́n lè nífẹ̀ẹ́ òun, kí wọ́n sì sin òun. Tó o bá jẹ́ òbí, ṣé o mọyì ẹ̀bùn iyebíye tí Jèhófà fún ẹ yìí? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà dá àwọn áńgẹ́lì lọ́lá gan-an, wọ́n sì lè ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan, síbẹ̀ wọn ò láǹfààní láti bímọ. Torí náà, ó yẹ kẹ́yin òbí mọyì àǹfààní tẹ́ ẹ ní láti bímọ. Ojúṣe ńlá lẹ̀yin òbí ní láti tọ́ àwọn ọmọ yín dàgbà nínú “ìbáwí àti ìmọ̀ràn Jèhófà.” (Éfé. 6:4; Diu. 6:5-7; Sm. 127:3) Kí àwọn òbí lè ṣe iṣẹ́ yìí láṣeyanjú, ètò Ọlọ́run ti pèsè ìwé lóríṣiríṣi, fídíò, orin àtàwọn ìtẹ̀jáde orí ìkànnì. Kò sí àní-àní pé Baba wa ọ̀run àti Ọmọ rẹ̀ mọyì àwọn ọmọdé gan-an. (Lúùkù 18:15-17) Inú Jèhófà máa ń dùn táwọn òbí bá gbára lé e, tí wọ́n sì ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti bójú tó àwọn ọmọ wọn. Ńṣe ni irú àwọn òbí bẹ́ẹ̀ mú kó ṣeé ṣe fáwọn ọmọ wọn láti di ara ìdílé Jèhófà títí láé.

10-11. Kí ni ìràpadà tí Jèhófà pèsè mú kó ṣeé ṣe?

10 Jèhófà fún wa ní Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n ká lè pa dà di ara ìdílé Rẹ̀. Bá a ṣe sọ ní  ìpínrọ̀ 4, Ádámù àti Éfà ṣe ohun tó mú kí Jèhófà kọ̀ wọ́n lọ́mọ, ìyẹn sì ṣàkóbá fáwọn ọmọ wọn náà. (Róòmù 5:12) Ádámù àti Éfà mọ̀ọ́mọ̀ ṣàìgbọràn sí Jèhófà, ìdí nìyẹn tó fi kọ̀ wọ́n lọ́mọ. Kí ló máa wá ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọ wọn? Torí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, ó ṣètò bí àwọn tó bá jẹ́ onígbọràn ṣe máa pa dà di ara ìdílé òun. Ètò tó ṣe ni pé ó fi Jésù Kristi Ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo rà wá pa dà. (Jòh. 3:16; Róòmù 5:19) Ìràpadà yìí ló mú kó ṣeé ṣe fáwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) tí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin láti di ọmọ Ọlọ́run.​—Róòmù 8:15-17; Ìfi. 14:1.

11 Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn olóòótọ́ míì ló ń ṣèfẹ́ Ọlọ́run. Wọ́n máa ní àǹfààní láti di ara ìdílé Ọlọ́run lẹ́yìn tí wọ́n bá yege ìdánwò ìkẹyìn tó máa wáyé níparí Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi. (Sm. 25:14; Róòmù 8:20, 21) Ìrètí tí wọ́n ní yìí ló mú kí wọ́n lè máa pe Jèhófà Ẹlẹ́dàá wọn ní “Baba.” (Mát. 6:9) Bákan náà, àwọn tó bá jíǹde máa láǹfààní láti mọ ohun tí Jèhófà fẹ́ kí wọ́n ṣe. Àwọn tó bá sì ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́ máa di ara ìdílé rẹ̀.

12. Ìbéèrè wo la máa dáhùn báyìí?

12 Níbi tá a bọ́rọ̀ dé yìí, a ti rí i pé Jèhófà dá àwa èèyàn lọ́lá lónírúurú ọ̀nà. Bí àpẹẹrẹ, ó ti gba àwọn ẹni àmì òróró ṣọmọ, ó sì ti fún àwọn “ogunlọ́gọ̀ èèyàn” nírètí láti di ọmọ ẹ̀ nínú ayé tuntun. (Ìfi. 7:9) Ìbéèrè náà ni pé, kí la lè máa ṣe báyìí táá fi hàn pé a fẹ́ di ara ìdílé Jèhófà títí láé?

JẸ́ KÍ JÈHÓFÀ MỌ̀ PÉ O FẸ́ DI ARA ÌDÍLÉ ÒUN

13. Sọ ohun tá a lè ṣe táá jẹ́ ká wà lára ìdílé Jèhófà. (Máàkù 12:30)

13 Fi gbogbo ọkàn ẹ sin Jèhófà kó o lè fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. (Ka Máàkù 12:30.) Nínú gbogbo nǹkan rere tí Jèhófà fún wa, ọ̀kan lára èyí tó ga jù ni àǹfààní tá a ní láti máa sìn ín. A lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tá a bá ń “pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.” (1 Jòh. 5:3) Ọ̀kan lára àwọn àṣẹ Jèhófà tó yẹ ká pa mọ́ lèyí tí Jésù sọ pé ká sọ àwọn èèyàn dọmọ ẹ̀yìn, ká sì máa batisí wọn. (Mát. 28:19) Ó tún pàṣẹ pé ká nífẹ̀ẹ́ ara wa. (Jòh. 13:35) Jèhófà máa mú káwọn tó bá ṣègbọràn di ara ìdílé ẹ̀ kárí ayé.​—Sm. 15:1, 2.

14. Kí la lè ṣe láti fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn míì? (Mátíù 9:36-38; Róòmù 12:10)

14 Fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ àwọn míì. Ìfẹ́ ló gbawájú nínú àwọn ànímọ́ tí Jèhófà ní. (1 Jòh. 4:8) Ká tó mọ Jèhófà rárá ló ti ń fìfẹ́ hàn sí wa. (1 Jòh. 4:9, 10) Tá a bá ń fìfẹ́ hàn sáwọn míì, ṣe là ń fi hàn pé a fìwà jọ Jèhófà. (Éfé. 5:1) Ọ̀kan lára ọ̀nà tó dáa jù tá a lè gbà fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn ni pé ká kọ́ wọn nípa Jèhófà nígbà tí àkókò ṣì wà. (Ka Mátíù 9:36-38.) Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe là ń fún wọn láǹfààní láti di ara ìdílé Ọlọ́run. Kódà lẹ́yìn tẹ́nì kan bá ṣèrìbọmi, ó yẹ ká ṣì máa fìfẹ́ hàn sí i, ká sì máa bọ̀wọ̀ fún un. (1 Jòh. 4:20, 21) Báwo la ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀? Ọ̀nà kan tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká fọkàn tán an. Bí àpẹẹrẹ, a ò ní máa fura òdì sí i. Kàkà bẹ́ẹ̀, àá máa bọlá fún un, àá sì gbà pé ó sàn jù wá lọ.​—Ka Róòmù 12:10; Fílí. 2:3.

15. Àwọn wo ló yẹ ká máa fàánú hàn sí, ká sì máa ṣe lóore?

15 Máa fàánú hàn sí gbogbo èèyàn, kó o sì máa ṣoore fún wọn. Tá a bá fẹ́ wà lára ìdílé Ọlọ́run títí láé, ó ṣe pàtàkì ká máa fi ìlànà Bíbélì sílò láyé wa. Bí àpẹẹrẹ, Jésù kọ́ wa pé ká máa fàánú hàn sí gbogbo èèyàn títí kan àwọn ọ̀tá wa, ká sì máa ṣoore fún wọn. (Lúùkù 6:32-36) Ìyẹn lè má fi bẹ́ẹ̀ rọrùn nígbà míì. Tó bá ṣòro fún ẹ, sapá láti máa ronú, kó o sì máa hùwà bíi ti Jésù. Tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti máa ṣègbọràn sí Jèhófà tá a sì ń fara wé Jésù, ṣe là ń fi han Jèhófà pé a fẹ́ jẹ́ ara ìdílé ẹ̀ títí láé.

16. Kí la lè ṣe tá ò fi ní ba orúkọ ìdílé Jèhófà jẹ́?

16 Má ṣe ohun tó máa ba orúkọ ìdílé Jèhófà jẹ́. Nínú ìdílé, àbúrò sábà máa ń fara wé ẹ̀gbọ́n. Ó ṣe tán, wọ́n máa ń sọ pé, ẹṣin iwájú ni tẹ̀yìn ń wò sáré. Tí ẹ̀gbọ́n náà bá ń fi ìlànà Bíbélì sílò nígbèésí ayé ẹ̀, àpẹẹrẹ tó dáa ló máa jẹ́ fún àbúrò ẹ̀. Àmọ́ tó bá jẹ́ pé ohun tí ò dáa ni ẹ̀gbọ́n náà ń ṣe, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ohun tí àbúrò ẹ̀ náà máa ṣe nìyẹn. Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè ṣẹlẹ̀ nínú ìdílé Jèhófà. Tí Kristẹni kan tó ti fìgbà kan rí jẹ́ olóòótọ́ bá di apẹ̀yìndà tàbí tó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣèṣekúṣe, àwọn míì náà lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ẹ̀. Ṣe làwọn tó bá ṣe bẹ́ẹ̀ ń ba orúkọ ìdílé Jèhófà jẹ́. (1 Tẹs. 4:3-8) Torí náà, ká má ṣe jẹ́ káwọn tó ń hùwà burúkú kéèràn ràn wá, ká má sì ṣe ohunkóhun tó máa mú ká jìnnà sí Baba wa ọ̀run.

17. Èrò wo ni kò yẹ ká ní, kí sì nìdí?

17 Jèhófà ni kó o gbẹ́kẹ̀ lé dípò àwọn nǹkan tara. Jèhófà ṣèlérí pé òun máa fún wa ní gbogbo ohun tá a nílò bí oúnjẹ, aṣọ àti ibùgbé tá a bá fi Ìjọba rẹ̀ sípò àkọ́kọ́, tá a sì ń fi ìlànà rẹ̀ sílò. (Sm. 55:22; Mát. 6:33) Tá a bá fìyẹn sọ́kàn, a ò ní máa ronú pé àwọn nǹkan tara tó wà láyé yìí ló máa fún wa láyọ̀, táá sì fi wá lọ́kàn balẹ̀. A mọ̀ pé ohun kan ṣoṣo tó lè fún wa ní ìbàlẹ̀ ọkàn ni pé ká máa ṣèfẹ́ Jèhófà. (Fílí. 4:6, 7) Kódà tá a bá tiẹ̀ lówó láti ra ọ̀pọ̀ nǹkan, ó yẹ ká bi ara wa pé ṣé a nílò wọn lóòótọ́, ṣé a sì máa ráyè bójú tó wọn? Ṣé ó ṣeé ṣe káwọn nǹkan yẹn gbà wá lọ́kàn ju bó ṣe yẹ lọ? Ká rántí pé Jèhófà fẹ́ kọ́wọ́ wa dí lẹ́nu iṣẹ́ tó gbé fún wa. Torí náà, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí nǹkan míì dí wa lọ́wọ́ iṣẹ́ náà. Ó dájú pé a ò ní fẹ́ dà bí ọ̀dọ́kùnrin tí Jésù fún láǹfààní láti di ọmọlẹ́yìn òun kó sì di ara ìdílé Jèhófà, àmọ́ tó kọ̀ nítorí àwọn nǹkan tí kò tó nǹkan tó kó jọ!​—Máàkù 10:17-22.

OHUN TÁWỌN ỌMỌ JÈHÓFÀ MÁA GBÁDÙN TÍTÍ LÁÉ

18. Àǹfààní ńlá àti ìbùkún wo làwọn tó bá jẹ́ onígbọràn máa gbádùn títí láé?

18 Àǹfààní tó ga jù lọ táwọn onígbọràn máa gbádùn ni pé wọ́n á nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, wọ́n á sì máa jọ́sìn ẹ̀ títí láé. Àwọn tó máa wà lórí ilẹ̀ ayé máa láǹfààní láti bójú tó ilẹ̀ ayé tí Jèhófà ṣètò pé kó jẹ́ ilé wọn. Láìpẹ́, Ìjọba Ọlọ́run máa sọ ayé yìí àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀ dọ̀tun. Gbogbo àjálù tó ti wáyé látìgbà tí Ádámù àti Éfà ti fi ìdílé Jèhófà sílẹ̀ ni Jésù máa ṣàtúnṣe sí. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn èèyàn ni Jèhófà máa jí dìde, á fún wọn ní ìlera pípé, á sì fún wọn láǹfààní láti wà láàyè títí láé nínú ayé tó ti di Párádísè. (Lúùkù 23:42, 43) Bí àwọn tó wà nínú ìdílé Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé ṣe túbọ̀ ń di pípé, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn máa ní “ògo àti ọlá ńlá” tí Dáfídì sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀.​—Sm. 8:5.

19. Kí ló yẹ ká fi sọ́kàn?

19 Tó o bá wà lára “ogunlọ́gọ̀ èèyàn,” ìrètí àgbàyanu lo ní. Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ẹ, ó sì fẹ́ kó o wà nínú ìdílé òun títí láé. Torí náà, ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti múnú ẹ̀ dùn. Jẹ́ kí àwọn ìlérí Jèhófà máa wà lọ́kàn ẹ lójoojúmọ́. Lákòótán, mọyì àǹfààní tó o ní pé o wà lára àwọn tó ń jọ́sìn Baba wa ọ̀run kó o sì jẹ́ kí inú ẹ máa dùn pé wàá láǹfààní láti máa sìn ín títí láé àti láéláé!

ORIN 107 Ìfẹ́ Ọlọ́run Jẹ́ Àpẹẹrẹ fún Wa

^ ìpínrọ̀ 5 Kí nǹkan tó lè máa lọ dáadáa nínú ìdílé, kálukú gbọ́dọ̀ mọ ojúṣe rẹ̀, kí wọ́n sì fọwọ́ sowọ́ pọ̀. Bàbá tó jẹ́ olórí ìdílé gbọ́dọ̀ máa fìfẹ́ hàn sí ìdílé ẹ̀. Ó ṣe pàtàkì kí ìyá fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ọkọ ẹ̀, káwọn ọmọ náà sì máa ṣègbọràn sáwọn òbí wọn. Bẹ́ẹ̀ náà lọ̀rọ̀ rí nínú ìdílé Jèhófà. Jèhófà ní ohun kan lọ́kàn fún wa, tá a bá sì fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ẹ̀, àá wà lára ìdílé ẹ̀ títí láé.

^ ìpínrọ̀ 55 ÀWÒRÁN: Torí pé Jèhófà dá wa ní àwòrán rẹ̀, ó ṣeé ṣe fún tọkọtaya yìí láti fìfẹ́ hàn sí ara wọn àti sáwọn ọmọ wọn. Tọkọtaya yìí nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an, wọ́n sì mọyì àǹfààní tí wọ́n ní láti tọ́ àwọn ọmọ wọn kí wọ́n lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, kí wọ́n sì sìn ín. Àwọn òbí náà lo fídíò láti ṣàlàyé ìdí tí Jèhófà fi pèsè ìràpadà fún wa nípasẹ̀ Jésù. Wọ́n tún kọ́ àwọn ọmọ wọn pé nínú Párádísè, a máa bójú tó ayé àtàwọn ẹranko títí láé.