Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 32

Ẹ̀yin Ọ̀dọ́, Ẹ Máa Tẹ̀ Síwájú Lẹ́yìn Tẹ́ Ẹ Ti Ṣèrìbọmi

Ẹ̀yin Ọ̀dọ́, Ẹ Máa Tẹ̀ Síwájú Lẹ́yìn Tẹ́ Ẹ Ti Ṣèrìbọmi

“Ẹ jẹ́ kí ìfẹ́ máa mú ká dàgbà sókè nínú ohun gbogbo.”—ÉFÉ. 4:15.

ORIN 56 Sọ Òtítọ́ Di Tìrẹ

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1. Àwọn ohun rere wo ni ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ti ṣe?

 LỌ́DỌỌDÚN, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ Kristẹni ló ń ṣèrìbọmi. Ṣé ìwọ náà ti ṣèrìbọmi? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin ẹ bá ẹ yọ̀, inú Jèhófà náà sì dùn sí ẹ! (Òwe 27:11) Ronú nípa àwọn nǹkan tó o ti ṣe kó o tó ṣèrìbọmi. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọdún mélòó kan lo fi kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì dáadáa. Àwọn nǹkan tó o kọ́ ti jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, o ti wá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tó ni Bíbélì. Ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà wá lágbára gan-an débi tó o fi ya ayé ẹ sí mímọ́ fún un tó o sì ṣèrìbọmi. Ìyẹn mà dáa gan-an o!

2. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

 2 Bó o ṣe ń tẹ̀ síwájú, ó dájú pé ọ̀pọ̀ nǹkan ló ti dán ìgbàgbọ́ ẹ wò kó o tó ṣèrìbọmi. Àmọ́ bó o ṣe ń dàgbà sí i, àwọn àdánwò míì á máa yọjú. Sátánì á máa ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe kí ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà má bàa lágbára mọ́, kó o má sì sìn ín mọ́. (Éfé. 4:14) O ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kíyẹn ṣẹlẹ̀ sí ẹ. Kí ló máa jẹ́ kó o jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, kó o sì mú ìlérí ẹ ṣẹ pé òun ni wàá máa sìn? Ohun tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ ni pé kó o máa “tẹ̀ síwájú” kó o lè di Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀. (Héb. 6:1) Àmọ́, báwo lo ṣe máa ṣe é? Nǹkan tá a máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí nìyẹn.

KÍ LÓ MÁA JẸ́ KÓ O DI KRISTẸNI TÍ ÒTÍTỌ́ JINLẸ̀ NÍNÚ Ẹ̀?

3. Kí ló yẹ kí gbogbo àwa Kristẹni máa ṣe lẹ́yìn tá a ti ṣèrìbọmi?

3 Lẹ́yìn tá a ti ṣèrìbọmi, ó yẹ kí gbogbo wa máa tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fún àwọn Kristẹni tó wà ní Éfésù. Ó gba àwọn Kristẹni yẹn níyànjú pé kí wọ́n “di géńdé.” (Éfé. 4:13) Lédè míì, ohun tó ń sọ ni pé, ‘Kí wọ́n máa tẹ̀ síwájú.’ Ó dájú pé ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ yé wa dáadáa nígbà tó fi bí èèyàn ṣe ń tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn Ọlọ́run wé bí ọmọdé ṣe ń dàgbà. Tí wọ́n bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bí ọmọ kan, inú àwọn òbí ẹ̀ máa ń dùn, wọ́n sì máa ń fi yangàn. Àmọ́, ọmọ náà ò lè wà lọ́mọdé títí lọ. Tó bá yá, ó máa fi “àwọn ìwà ọmọdé” sílẹ̀. (1 Kọ́r. 13:11) Bó ṣe rí fáwa Kristẹni náà nìyẹn. Lẹ́yìn tá a ti ṣèrìbọmi, a gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Ẹ jẹ́ ká gbé àwọn àbá tó máa jẹ́ ká lè ṣe bẹ́ẹ̀ yẹ̀ wò.

4. Kí ni nǹkan tó máa jẹ́ kó o tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn Ọlọ́run? Ṣàlàyé. (Fílípì 1:9)

4 Jẹ́ kí ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà máa lágbára sí i. O ti ṣe ohun tó fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an. Àmọ́, o ṣì lè jẹ́ kí ìfẹ́ náà máa lágbára sí i. Báwo lo ṣe máa ṣe é? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ ọ̀nà kan tó o lè gbà ṣe é nínú Fílípì 1:9. (Kà á.) Pọ́ọ̀lù gbàdúrà pé kí ìfẹ́ táwọn ará Fílípì ní fún Jèhófà “túbọ̀ pọ̀ gidigidi.” Torí náà, a lè jẹ́ kí ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà máa pọ̀ sí i. Ọ̀nà tá a lè gbà ṣe é ni pé ká ní “ìmọ̀ tó péye àti òye tó kún rẹ́rẹ́.” Bá a bá ṣe ń mọ Jèhófà sí i, bẹ́ẹ̀ làá túbọ̀ máa nífẹ̀ẹ́ ẹ̀, tí àá sì mọyì àwọn ànímọ́ tó ní àti ọ̀nà tó ń gbà ṣe nǹkan. Ó yẹ kó túbọ̀ máa wù wá láti ṣe ohun táá múnú Jèhófà dùn, ká má sì ṣe ohun tó máa bà á nínú jẹ́. Ó tún yẹ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti mọ ohun tí Jèhófà fẹ́, ká sì máa ṣe é.

5-6. Kí la lè ṣe kí ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà lè máa lágbára sí i? Ṣàlàyé.

5 Jésù fìwà jọ Bàbá ẹ̀ gan-an. Torí náà, tá a bá túbọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jésù, àá túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. (Héb. 1:3) Ọ̀nà tó dáa jù tá a lè gbà mọ Jésù ni pé ká kẹ́kọ̀ọ́ ìwé Ìhìn Rere mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tó wà nínú Bíbélì. Tó bá jẹ́ pé o ò tíì bẹ̀rẹ̀ sí í ka Bíbélì lójoojúmọ́, o ò ṣe bẹ̀rẹ̀ báyìí? Bó o ṣe ń ka ìtàn ìgbésí ayé Jésù, máa kíyè sí ìwà àti ìṣe ẹ̀. Wàá rí i pé ẹni tó ṣeé sún mọ́ ni, ó nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọdé kódà ó gbé wọn sí apá rẹ̀. (Máàkù 10:13-16) Ọkàn àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ máa ń balẹ̀ tí wọ́n bá wà lọ́dọ̀ ẹ̀, wọ́n sì máa ń sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn fún un. (Mát. 16:22) Àwọn nǹkan yìí ló jẹ́ ká rí i pé Jésù fìwà jọ Bàbá ẹ̀ gan-an. Jèhófà náà sì jẹ́ ẹni tó ṣeé sún mọ́, ìdí ni pé a lè gbàdúrà sí i. Kódà, kò sí nǹkan tó wà lọ́kàn wa tá ò lè sọ fún un torí ó dá wa lójú pé kò ní dá wa lẹ́bi. Ó ṣe tán, ó nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, ó sì ń bójú tó wa.​—1 Pét. 5:7.

6 Àánú àwọn èèyàn máa ń ṣe Jésù. Àpọ́sítélì Mátíù sọ pé: “Nígbà tó rí àwọn èrò, àánú wọn ṣe é, torí wọ́n dà bí àgùntàn tí a bó láwọ, tí a sì fọ́n ká láìní olùṣọ́ àgùntàn.” (Mát. 9:36) Àmọ́ báwo lọ̀rọ̀ yìí ṣe rí lára Jèhófà? Jésù sọ pé: “Kò wu Baba mi tó wà ní ọ̀run pé kí ọ̀kan péré nínú àwọn ẹni kékeré yìí ṣègbé.” (Mát. 18:14) Ẹ ò rí i pé èyí fi wá lọ́kàn balẹ̀ gan-an! Bá a ṣe túbọ̀ ń mọ Jésù, ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà á máa lágbára sí i.

7. Àǹfààní wo la máa rí tá a bá mú àwọn tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn lọ́rẹ̀ẹ́?

7 Tó o bá ń bá àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn ṣọ̀rẹ́, wàá mọ bó o ṣe lè túbọ̀ máa fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn, òtítọ́ á sì jinlẹ̀ nínú ìwọ náà. Máa kíyè sí ayọ̀ tí wọ́n ní. Wọn ò kábàámọ̀ ìpinnu tí wọ́n ṣe láti sin Jèhófà. O lè ní kí wọ́n sọ díẹ̀ fún ẹ lára ìrírí tí wọ́n ní lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. O lè lọ gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ wọn tó o bá fẹ́ ṣe ìpinnu pàtàkì kan. Ó ṣe tán, Bíbélì sọ pé: “Nípasẹ̀ ọ̀pọ̀ agbani-nímọ̀ràn, àṣeyọrí á wà.”​—Òwe 11:14.

Báwo lo ṣe lè múra sílẹ̀ kó lè dá ẹ lójú pé Ẹlẹ́dàá wà tí wọ́n bá tiẹ̀ kọ́ ẹ nílé ìwé pé kò sí Ẹlẹ́dàá? (Wo ìpínrọ̀ 8-9)

8. Kí lo lè ṣe tó o bá ń ṣiyèméjì nípa ohun tí Bíbélì sọ?

8 O gbọ́dọ̀ borí iyèméjì tó o ní. Bá a ṣe sọ ní  ìpínrọ̀ kejì, Sátánì á máa ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe kí ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà má bàa lágbára mọ́. Ọ̀nà kan tí Sátánì lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé kó jẹ́ kó o máa ṣiyèméjì nípa àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì kan. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan lè fẹ́ kó o gbà pé Ọlọ́run kọ́ ló dá wa àti pé àwọn nǹkan tó wà láyé yìí kàn ṣàdédé wà ni. O lè má nírú èrò yẹn nígbà tó o wà lọ́mọdé, àmọ́ ní báyìí tó o ti dàgbà, wọ́n á fẹ́ fi ẹ̀kọ́ yìí kọ́ ẹ nílé ìwé. Àlàyé tí olùkọ́ ẹ máa ṣe nípa ẹ̀kọ́ yìí lè fẹ́ bọ́gbọ́n mu lóòótọ́, ó sì lè mú kó o fẹ́ gba ẹ̀kọ́ náà gbọ́. Àmọ́, àwọn olùkọ́ ẹ lè má tíì gbé ẹ̀rí tó fi hàn pé Ẹlẹ́dàá wà yẹ̀ wò. Rántí ìlànà tó wà ní Òwe 18:17 tó sọ pé: “Ẹni tó bá kọ́kọ́ ro ẹjọ́ rẹ̀ ló ń dà bíi pé ó jàre, títí ẹnì kejì fi wá, tó sì bi í ní ìbéèrè.” Dípò tí wàá kàn gba ohun tí wọ́n sọ fún ẹ nílé ìwé gbọ́, ńṣe ló yẹ kó o fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ kó o lè mọ òótọ́. Ṣèwádìí nínú àwọn ìwé ètò Ọlọ́run. Bá àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tí wọ́n ti fìgbà kan rí gbà pé kò sí Ọlọ́run sọ̀rọ̀. Bi wọ́n pé kí ló yí èrò wọn pa dà tí wọ́n fi gbà pé Ẹlẹ́dàá kan wà tó nífẹ̀ẹ́ wa. Àwọn ọ̀rọ̀ tẹ́ ẹ bá jọ sọ máa gbé ẹ ró, á sì jẹ́ kó o gbà pé Ẹlẹ́dàá wà lóòótọ́.

9. Kí lo rí kọ́ lára Melissa?

9 Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Melissa jàǹfààní gan-an nígbà tó ṣèwádìí nípa àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá. * Ó sọ pé: “Táwọn olùkọ́ wa bá ń kọ́ wa nílé ìwé pé kò sí Ẹlẹ́dàá àti pé ohun gbogbo kàn ṣàdédé wà ni, ó máa ń jọ pé òótọ́ lohun tí wọ́n ń kọ́ wa. Mi ò kọ́kọ́ fẹ́ ṣèwádìí torí ẹ̀rù ń bà mí kó má lọ jẹ́ pé ohun táwọn olùkọ́ wa ń kọ́ wa ló jóòótọ́. Àmọ́ mo sọ lọ́kàn mi pé Jèhófà ò fẹ́ ká gba òun gbọ́ láìsí ẹ̀rí. Torí náà, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣèwádìí. Mo ka ìwé náà, Is There a Creator Who Cares About You? àtàwọn ìwé pẹlẹbẹ náà Was Life Created? àti The Origin of Life​—Five Questions Worth Asking. Ni mo bá sọ pé, ohun tí mò ń wá gan-an nìyí, ó yẹ kí n ti ṣèwádìí yìí tipẹ́tipẹ́.”

10-11. Kí ni ò ní jẹ́ kó o ṣèṣekúṣe? (1 Tẹsalóníkà 4:3, 4)

10 Má fàyè gba ìṣekúṣe. Tí ọ̀dọ́ kan bá ti ń dàgbà, ìfẹ́ láti ní ìbálòpọ̀ á máa lágbára lọ́kàn ẹ̀, àwọn ẹlòmíì sì lè máa yọ ọ́ lẹ́nu pé kó ṣèṣekúṣe. Ohun tí Sátánì sì fẹ́ kó o ṣe nìyẹn. Kí ni ò ní jẹ́ kó o ṣèṣekúṣe? (Ka 1 Tẹsalóníkà 4:3, 4.) Sọ bó ṣe ń ṣe ẹ́ fún Jèhófà tó o bá ń gbàdúrà, kó o sì bẹ̀ ẹ́ pé kó fún ẹ lókun. (Mát. 6:13) Rántí pé Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́, kì í ṣe pé ó máa fìyà jẹ ẹ́. (Sm. 103:13, 14) O tún lè ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kó o lè mọ ohun tó o máa ṣe. Melissa tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan ṣiṣẹ́ kára kó lè borí èrò ìṣekúṣe. Ó sọ pé: “Bíbélì tí mo máa ń kà lójoojúmọ́ ló jẹ́ kí n borí èrò ìṣekúṣe. Tí mo bá ti ń kà á, mo máa ń rántí pé Jèhófà ni mo ya ara mi sí mímọ́ fún àti pé òun ni màá máa sìn.”​—Sm. 119:9.

11 Má ṣe rò pé o lè dá yanjú ìṣòro ẹ. Sọ ìṣòro tó o ní fáwọn òbí ẹ. Ó lè má rọrùn láti sọ ọ̀rọ̀ ara ẹ fún ẹlòmíì, àmọ́ ó ṣe pàtàkì pé kó o ṣe bẹ́ẹ̀. Melissa sọ pé: “Mo gbàdúrà pé kí Jèhófà fún mi nígboyà, lẹ́yìn náà mo lọ sọ ìṣòro mi fún dádì mi. Lẹ́yìn tí mo sọ ohun tó wà lọ́kàn mi, ṣe lọkàn mi balẹ̀ pẹ̀sẹ̀. Mo mọ̀ pé inú Jèhófà máa dùn sí mi.”

12. Kí lo lè ṣe táá jẹ́ kó o ṣèpinnu tó dáa?

12 Jẹ́ kí ìlànà Bíbélì máa tọ́ ẹ sọ́nà. Bó o ṣe ń dàgbà, ìwọ náà á lómìnira láti ṣèpinnu fúnra ẹ. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ nǹkan ló wà tó ò tíì mọ̀. Àmọ́, báwo lo ṣe lè yẹra fún ohun tó lè ba àjọṣe ẹ pẹ̀lú Jèhófà jẹ́? (Òwe 22:3) Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Kari ṣàlàyé ohun tó ràn án lọ́wọ́ láti máa ṣèpinnu tó dáa. Ó mọ̀ pé àwọn Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn ò gbé òfin kan kalẹ̀ táá máa darí gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe. Ó sọ pé: “Kì í ṣe òfin Jèhófà nìkan ló yẹ kí n mọ̀, ó tún yẹ kí n mọ àwọn ìlànà ẹ̀.” Tó o bá ń ka Bíbélì, bi ara ẹ pé: ‘Kí ni ohun tí ẹsẹ Bíbélì yìí kọ́ mi nípa ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà ṣe nǹkan? Ṣé mo rí àwọn ìlànà kan níbẹ̀ tí mo lè lò láyé mi? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, àǹfààní wo ni mo máa rí tí mo bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà náà?’ (Sm. 19:7; Àìsá. 48:17, 18) Tó o bá ń ka Bíbélì tó o sì ń ronú lórí àwọn ìlànà tó wà níbẹ̀, wàá lè ṣèpinnu tó máa múnú Jèhófà dùn. Bí ìmọ̀ tó o ní nípa Ọlọ́run ṣe túbọ̀ ń pọ̀ sí i, wàá rí i pé kò dìgbà tó o bá rí òfin pàtó kan kó o tó ṣèpinnu torí pé wàá ti mọ ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà ṣe nǹkan.

Irú àwọn ọ̀rẹ́ wo ni ọ̀dọ́bìnrin yìí yàn? (Wo ìpínrọ̀ 13)

13. Báwo làwọn ọ̀rẹ́ rere ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́? (Òwe 13:20)

13 Yan àwọn ọ̀rẹ́ tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Bá a ṣe sọ tẹ́lẹ̀, àwọn ọ̀rẹ́ tó o bá yàn ló máa jẹ́ kó o mọ̀ bóyá wàá di Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀. (Ka Òwe 13:20.) Ohun kan ṣẹlẹ̀ tó mú kí arábìnrin kan tó ń jẹ́ Sara má láyọ̀ mọ́, àmọ́ nígbà tó yá ó pa dà bẹ̀rẹ̀ sí í láyọ̀. Sara sọ pé: “Mo yan àwọn ọ̀rẹ́ gidi lásìkò yẹn. Èmi àti arábìnrin ọ̀dọ́ kan jọ máa ń múra ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ sílẹ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Ọ̀rẹ́ mi kan tún ràn mí lọ́wọ́ kí n lè máa dáhùn nípàdé. Torí pé àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ni mo mú lọ́rẹ̀ẹ́, ìyẹn ti jẹ́ kí n máa dá kẹ́kọ̀ọ́ déédéé kí n sì máa gbàdúrà déédéé. Ìfẹ́ tí mo ní fún Jèhófà wá túbọ̀ lágbára sí i, mo sì pa dà bẹ̀rẹ̀ sí í láyọ̀.”

14. Báwo ni Julien ṣe yan àwọn ọ̀rẹ́ tó dáa?

14 Báwo lo ṣe lè yan àwọn ọ̀rẹ́ tó máa jẹ́ kó o túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà? Julien tó ti wá di alàgbà báyìí sọ pé: “Nígbà tí mo ṣì wà lọ́dọ̀ọ́, mo ní àwọn ọ̀rẹ́ tá a jọ máa ń lọ wàásù. Wọ́n nítara, wọ́n sì jẹ́ kí n rí i pé iṣẹ́ aláyọ̀ niṣẹ́ ìwàásù. Mo wá pinnu pé iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún ni màá fi ayé mi ṣe. Mo tún rí i pé ìdí tí mi ò fi láwọn ọ̀rẹ́ gidi tẹ́lẹ̀ ni pé àwọn ojúgbà mi nìkan ni mo yàn lọ́rẹ̀ẹ́. Nígbà tó yá, mo tún ní àwọn ọ̀rẹ́ gidi ní Bẹ́tẹ́lì tí mo wà. Àpẹẹrẹ tó dáa tí wọ́n fi lélẹ̀ jẹ́ kí n yan àwọn eré ìnàjú tó dáa, ìyẹn sì ti jẹ́ kí n túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà.”

15. Ìkìlọ̀ wo ni Pọ́ọ̀lù fún Tímótì nípa ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́? (2 Tímótì 2:20-22)

15 Kí lo máa ṣe tó o bá rí i pé ẹni tó ò ń bá kẹ́gbẹ́ nínú ìjọ lè ba ìwà ẹ jẹ́? Pọ́ọ̀lù mọ àwọn kan nínú ìjọ nígbà ayé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ tí wọn kì í hùwà bíi Kristẹni, torí náà ó sọ fún Tímótì pé kó yẹra fún wọn. (Ka 2 Tímótì 2:20-22.) A ti ṣiṣẹ́ kára ká lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. Torí náà, kò yẹ ká jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ba àjọṣe wa pẹ̀lú Bàbá wa ọ̀run jẹ́.​—Sm. 26:4.

ÀWỌN NǸKAN WO LO LÈ ṢE TÁÁ MÚ KÓ O TẸ̀ SÍWÁJÚ NÍNÚ ÌJỌSÌN ỌLỌ́RUN?

16. Àwọn nǹkan wo lo lè ṣe táá mú kó o tẹ̀ síwájú?

16 Àwọn nǹkan tó máa mú kó o tẹ̀ síwájú ni kó o máa ṣe. Yan àwọn nǹkan tó máa mú kí ìgbàgbọ́ ẹ lágbára, táá sì mú kó o di Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀. (Éfé. 3:16) Bí àpẹẹrẹ, o lè mú kí ọ̀nà tó ò ń gbà ka Bíbélì tó o sì ń gbà kẹ́kọ̀ọ́ túbọ̀ dáa sí i. (Sm. 1:2, 3) O sì lè rí i pé á dáa kó o máa gbàdúrà déédéé, dípò ní ìdákúrekú, kó sì jẹ́ látọkàn wá. Yàtọ̀ síyẹn, á dáa kó o yan eré ìnàjú tó dáa, kó o sì kíyè sí iye àkókò tó ò ń lò nídìí ẹ̀. (Éfé. 5:15, 16) Tí Jèhófà bá rí ẹ bó o ṣe ń ṣiṣẹ́ kára kó o lè tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn ẹ̀, inú ẹ̀ á dùn sí ẹ.

Àwọn nǹkan wo ni ọ̀dọ́bìnrin yìí ń ṣe tó máa jẹ́ kó tẹ̀ síwájú? (Wo ìpínrọ̀ 17)

17. Tó o bá ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, àǹfààní wo lo máa rí?

17 Tó o bá ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, wàá di Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀. Jésù sọ pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tó wà nínú rírígbà lọ.” (Ìṣe 20:35) Ọ̀pọ̀ àǹfààní lo máa rí tó o bá ń lo àkókò àti okun ẹ láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, o lè ran àwọn àgbàlagbà tó wà níjọ ẹ lọ́wọ́ tàbí kó o ran àwọn aláìlera lọ́wọ́. Ṣé o lè lọ bá wọn ra nǹkan tàbí kó o kọ́ wọn bí wọ́n á ṣe lo ẹ̀rọ ìgbàlódé wọn? Tó bá jẹ́ arákùnrin ni ẹ́, o lè di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, kó o lè máa ran àwọn ará lọ́wọ́. (Fílí. 2:4) Bákan náà, o lè fìfẹ́ hàn sáwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó o bá ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún wọn. (Mát. 9:36, 37) Tó bá ṣeé ṣe, pinnu pé iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún lo máa ṣe.

18. Báwo ni iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú?

18 Iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún máa fún ẹ ní ọ̀pọ̀ àǹfààní láti tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, iṣẹ́ ìsìn aṣáájú-ọ̀nà lè fún ẹ láǹfààní láti lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run. O lè lọ sìn ní Bẹ́tẹ́lì tàbí kó o lọ ṣe iṣẹ́ ìkọ́lé ètò Ọlọ́run. Ọ̀dọ́bìnrin aṣáájú-ọ̀nà kan tó ń jẹ́ Kaitlyn sọ pé: “Bí mo ṣe ń lo àkókò mi nínú iṣẹ́ ìwàásù pẹ̀lú àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn ti ràn mí lọ́wọ́ gan-an, ó sì ti jẹ́ kí n tẹ̀ síwájú lẹ́yìn tí mo ṣèrìbọmi. Àpẹẹrẹ rere wọn ti jẹ́ kí n lè máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀, ó sì ti jẹ́ kí n mọ̀ọ̀yàn kọ́ dáadáa.”

19. Àwọn àǹfààní wo lo máa rí tó o bá ń tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn Ọlọ́run?

19 Bó o ṣe ń tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn Ọlọ́run, ọ̀pọ̀ àǹfààní lo máa rí. Bí àpẹẹrẹ, o ò ní lo àkókò ẹ fáwọn nǹkan tí ò ṣàǹfààní. (1 Jòh. 2:17) O ò ní ṣèpinnu tó máa kó ìbànújẹ́ bá ẹ. Dípò bẹ́ẹ̀, wàá ṣàṣeyọrí, wàá sì ní ayọ̀ tòótọ́. (Òwe 16:3) Àpẹẹrẹ rere tó o bá fi lélẹ̀ máa ran àwọn tẹ́ ẹ jọ ń sin Jèhófà lọ́wọ́. (1 Tím. 4:12) Ju gbogbo ẹ̀ lọ, wàá ní àlàáfíà àti ìbàlẹ̀ ọkàn torí ò ń ṣèfẹ́ Jèhófà, o sì ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú ẹ̀.​—Òwe 23:15, 16.

ORIN 88 Mú Mi Mọ Àwọn Ọ̀nà Rẹ

^ Inú àwa èèyàn Jèhófà máa ń dùn táwọn ọ̀dọ́ bá ṣèrìbọmi. Àmọ́ lẹ́yìn táwọn ọ̀dọ́ yìí bá ti ṣèrìbọmi, wọ́n gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ síwájú kí wọ́n lè di Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn. Àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ kí àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèrìbọmi mọ ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe kí wọ́n lè di Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn.

^ A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.