ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 33
Jèhófà Máa Ń Bójú Tó Àwọn Èèyàn Rẹ̀
“Ojú Jèhófà ń ṣọ́ àwọn tó bẹ̀rù rẹ̀.”—SM. 33:18.
ORIN 4 “Jèhófà Ni Olùṣọ́ Àgùntàn Mi”
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *
1. Kí nìdí tí Jésù fi bẹ Jèhófà pé kó máa ṣọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun?
NÍ ALẸ́ tó ṣáájú ikú Jésù, ó gbàdúrà sí Bàbá rẹ̀ ọ̀run pé kó ṣohun kan fún òun. Ó bẹ Jèhófà pé kó máa ṣọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn òun. (Jòh. 17:15, 20) Ó ṣe tán, gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀, ó sì máa ń bójú tó wọn. Àmọ́, Jésù mọ̀ pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun máa dojú kọ àtakò tó le gan-an látọ̀dọ̀ Sátánì. Jésù tún mọ̀ pé kí wọ́n tó lè borí àtakò látọ̀dọ̀ Èṣù, àfi kí Jèhófà ràn wọ́n lọ́wọ́.
2. Kí ni Sáàmù 33:18-20 sọ tó jẹ́ ká mọ̀ pé kò yẹ ká máa bẹ̀rù tí àdánwò bá dé bá wa?
2 Ọ̀pọ̀ ìṣòro làwa Kristẹni tòótọ́ ń dojú kọ lónìí torí inú ayé burúkú tí Sátánì ń darí là ń gbé. A máa ń láwọn ìṣòro tó lè mú ká rẹ̀wẹ̀sì, tó sì máa ń dán ìgbàgbọ́ wa wò. Àmọ́, àwọn ohun tá a máa kọ́ nínú àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká rí i pé kò yẹ ká bẹ̀rù rárá. Jèhófà ń rí gbogbo ìṣòro tá à ń dojú kọ, ó sì ṣe tán láti ràn wá lọ́wọ́ ká lè borí àwọn ìṣòro náà. Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ méjì yẹ̀ wò nínú Bíbélì tó jẹ́ ká rí i pé Jèhófà máa “ń ṣọ́ àwọn tó bẹ̀rù rẹ̀.”—Ka Sáàmù 33:18-20.
TÓ BÁ Ń ṢE WÁ BÍI PÉ A DÁ WÀ
3. Àwọn ìgbà wo ló máa ń ṣe wá bíi pé a dá wà?
3 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a láwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tá a jọ ń sin Jèhófà, ó ṣì máa ń ṣe wá bíi pé a dá wà lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Bí àpẹẹrẹ, ó máa ń ṣe àwọn ọ̀dọ́ kan bíi pé kò sẹ́ni tó máa tì wọ́n lẹ́yìn tí wọ́n bá ń ṣàlàyé ohun tí wọ́n gbà gbọ́ nílé ìwé, tí wọ́n bá sì kó lọ síjọ tuntun, ó máa ń ṣe wọ́n bíi pé wọn ò rẹ́ni fojú jọ. Yàtọ̀ síyẹn, inú àwọn kan lára wa lè má dùn, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í rẹ̀wẹ̀sì, ká sì rò pé a lè yanjú ìṣòro náà fúnra wa. A lè má fẹ́ sọ bó ṣe ń ṣe wá fáwọn míì torí a rò pé ọ̀rọ̀ wa lè má yé wọn. Nígbà míì, ó lè máa ṣe wá bíi pé kò sẹ́ni tó rí tiwa rò. Tá a bá ń ronú pé a dá wà, ó lè kó ìdààmú bá wa, ká sì gbà pé kò sọ́nà àbáyọ. Àmọ́, Jèhófà ò fẹ́ ká máa ronú bẹ́ẹ̀. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀?
4. Kí nìdí tí wòlíì Èlíjà fi sọ pé: ‘Èmi nìkan ló ṣẹ́ kù’?
4 Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọkùnrin olóòótọ́ kan tó ń jẹ́ Èlíjà. Ó lé lógójì (40) ọjọ́ tó fi ń sá kiri torí Jésíbẹ́lì lérí pé òun máa pa á. (1 Ọba 19:1-9) Nígbà tó yá, ó ké pe Jèhófà látinú ihò tó wà pé: ‘Èmi nìkan ni wòlíì tó ṣẹ́ kù.’ (1 Ọba 19:10) Bẹ́ẹ̀ sì rèé, àwọn wòlíì míì ṣì ṣẹ́ kù sílùú yẹn torí Ọbadáyà ti gba ọgọ́rùn-ún (100) wòlíì sílẹ̀ lọ́wọ́ Jésíbẹ́lì tó fẹ́ pa wọ́n. (1 Ọba 18:7, 13) Kí wá nìdí tí Èlíjà fi rò pé òun nìkan lòun ṣẹ́ kù? Ṣé ó rò pé gbogbo àwọn wòlíì tí Ọbadáyà gbà sílẹ̀ ti kú ni? Àbí ìdí tó fi rò pé òun dá wà ni pé kò sẹ́ni tó wá sin Jèhófà pẹ̀lú ẹ̀ lẹ́yìn ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn olùjọsìn Báálì lórí Òkè Kámẹ́lì? Ṣé ó ṣeé ṣe kó máa rò pé kò sẹ́ni tó mọ inú ewu tóun wà tàbí kó máa rò pé kò sẹ́ni tó rí tòun rò? Bíbélì ò sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára Èlíjà. Àmọ́ ó dá wa lójú pé Jèhófà mọ ìdí tó fi ń ṣe Èlíjà bíi pé òun dá wà, ó sì mọ bóun ṣe máa ràn án lọ́wọ́.
5. Báwo ni Jèhófà ṣe fi dá Èlíjà lójú pé òun nìkan kọ́ ló ṣẹ́ kù?
5 Onírúurú ọ̀nà ni Jèhófà gbà ran Èlíjà lọ́wọ́. Ó jẹ́ kí Èlíjà sọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára ẹ̀. Ẹ̀ẹ̀mejì ni Jèhófà béèrè lọ́wọ́ ẹ̀ pé: “Kí lò ń ṣe níbí?” (1 Ọba 19:9, 13) Jèhófà fara balẹ̀ tẹ́tí sí Èlíjà láwọn ìgbà tó ń sọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára ẹ̀. Jèhófà jẹ́ kó mọ̀ pé òun wà pẹ̀lú ẹ̀, ó sì tún jẹ́ kó mọ bí agbára òun ṣe pọ̀ tó. Ó tún fi dá Èlíjà lójú pé òun nìkan kọ́ ló ṣẹ́ kù tó ń sin òun. (1 Ọba 19:11, 12, 18) Kò sí àní-àní pé nígbà tí Èlíjà sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ̀, tí Jèhófà sì jẹ́ kó mọ̀ pé àwọn míì ṣì wà tó ń jọ́sìn òun, ara tù ú. Jèhófà wá gbé àwọn iṣẹ́ kan tó ṣe pàtàkì fún Èlíjà. Ó ní kó yan Hásáẹ́lì láti di ọba Síríà, kó yan Jéhù ṣe ọba Ísírẹ́lì, kó sì sọ Èlíṣà di wòlíì. (1 Ọba ) Àwọn iṣẹ́ tí Jèhófà gbé fún Èlíjà yìí ò ní jẹ́ kó máa rò pé òun dá wà mọ́. Jèhófà tún ní kí òun àti Èlíṣà jọ máa ṣiṣẹ́, wọ́n sì di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́. Torí náà, kí lo lè ṣe táá jẹ́ kí Jèhófà ran ìwọ náà lọ́wọ́ tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé o dá wà? 19:15, 16
6. Tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé o dá wà, kí lo lè sọ nínú àdúrà ẹ? (Sáàmù 62:8)
6 Jèhófà fẹ́ kó o máa gbàdúrà sóun. Ó mọ àwọn ìṣòro tó ò ń dojú kọ, ó sì fi dá ẹ lójú pé gbogbo ìgbà lòun ṣe tán láti gbọ́ àdúrà ẹ. (1 Tẹs. 5:17) Inú Jèhófà máa ń dùn láti gbọ́ àdúrà táwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ ń gbà sí i. (Òwe 15:8) Tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé o dá wà, kí lo lè sọ nínú àdúrà ẹ? Bíi ti Èlíjà, sọ gbogbo bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára ẹ fún Jèhófà. (Ka Sáàmù 62:8.) Sọ gbogbo ìṣòro ẹ fún un àti báwọn ìṣòro náà ṣe ń kó ẹ lọ́kàn sókè. Bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè fara da àwọn ìṣòro tó ò ń bá yí. Bí àpẹẹrẹ, tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé kò sẹ́ni tó máa tì ẹ́ lẹ́yìn, tẹ́rù sì ń bà ẹ́ láti ṣàlàyé ohun tó o gbà gbọ́ nílé ìwé, bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kó o lè fìgboyà sọ̀rọ̀. O lè bẹ̀ ẹ́ pé kó fún ẹ lọ́gbọ́n tí wàá fi ṣàlàyé ohun tó o gbà gbọ́ lọ́nà tó máa wọ̀ wọ́n lọ́kàn. (Lúùkù 21:14, 15) Tó o bá rẹ̀wẹ̀sì tàbí tí nǹkan tojú sú ẹ, bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kó o lè sọ̀rọ̀ náà fún Kristẹni kan tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀. O tún lè bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kí ẹni tó o fẹ́ sọ̀rọ̀ náà fún fara balẹ̀ gbọ́ ẹ dáadáa kó lè mọ bí nǹkan ṣe rí lára ẹ. Torí náà, tó o bá sọ bí nǹkan ṣe rí lára ẹ fún Jèhófà, tó ò ń kíyè sí bó ṣe ń dáhùn àwọn àdúrà ẹ, tó o sì jẹ́ káwọn ará tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn ràn ẹ́ lọ́wọ́, wàá rí i pé kò ní ṣe ẹ́ bíi pé o dá wà mọ́.
7. Kí lo rí kọ́ lára Mauricio?
7 Jèhófà gbé iṣẹ́ pàtàkì kan fún gbogbo wa. Torí náà, ó dájú pé ó rí gbogbo ohun tó ò ń ṣe, ó sì mọyì bó o ṣe ń ṣiṣẹ́ kára nínú ìjọ àti lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. (Sm. 110:3) Tó o bá ń ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, báwo nìyẹn ò ṣe ní jẹ́ kó o dá wà mọ́? Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí arákùnrin ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Mauricio. * Kò pẹ́ lẹ́yìn tí Mauricio ṣèrìbọmi, ọ̀kan lára àwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ tímọ́tímọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í fi Jèhófà sílẹ̀. Mauricio sọ pé: “Nígbà tí mo rí i pé ọ̀rẹ́ mi ti fi Jèhófà sílẹ̀, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiyèméjì pé bóyá lèmi náà máa lè sin Jèhófà. Mo wá ń ronú pé bóyá ni màá lè mú ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ mi ṣẹ, kí n sì máa sin Jèhófà nìṣó. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í rẹ̀wẹ̀sì, mo sì rò pé kò sẹ́ni tó lè mọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára mi.” Kí ni Mauricio wá ṣe tó ràn án lọ́wọ́? Ó sọ pé: “Mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, ìyẹn jẹ́ kí n gbé ọ̀rọ̀ náà kúrò lọ́kàn, kí n má sì ronú nípa ẹ̀ mọ́. Nígbà témi àtàwọn ará bá jọ lọ wàásù, inú mi máa ń dùn, kò sì ṣe mí bíi pé mo dá wà mọ́.” Kódà, láwọn ìgbà tá ò láǹfààní láti wàásù láti ilé dé ilé pẹ̀lú àwọn ará, bá a ṣe jọ máa ń wàásù nípasẹ̀ lẹ́tà àti lórí fóònù máa ń fún ìgbàgbọ́ wa lókun. Nǹkan míì wo ni Mauricio ṣe tó ràn án lọ́wọ́? Ó sọ pé: “Mo tún máa ń ṣiṣẹ́ tí wọ́n bá fún mi nínú ìjọ. Mo máa ń múra àwọn iṣẹ́ náà sílẹ̀ dáadáa, àwọn ará sì máa ń gbádùn ẹ̀. Àwọn iṣẹ́ tí mò ń ṣe yìí jẹ́ kí n rí i pé Jèhófà àtàwọn ará nífẹ̀ẹ́ mi, wọ́n sì mọyì mi.”
TÍ ÌṢÒRO TÓ LE GAN-AN BÁ MÚ KÁ RẸ̀WẸ̀SÌ
8. Báwo ló ṣe máa ń rí lára wa tá a bá dojú kọ ìṣòro tó le gan-an?
8 Láwọn ọjọ́ ìkẹyìn tá à ń gbé yìí, ohun tó dájú ni pé ìṣòro á máa bá wa fínra. (2 Tím. 3:1) Síbẹ̀, ìṣòro kan lè dé bá wa lójijì, ó sì lè yà wá lẹ́nu pé àwa nirú ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí. Bí àpẹẹrẹ, ìṣòro àìlówó lọ́wọ́ lè dé bá wa lójijì, dókítà lè sọ fún wa pé a ti ní àìsàn kan tó le gan-an tàbí kí ẹnì kan tá a fẹ́ràn kú. Nírú àkókò yẹn, nǹkan lè tojú sú wa ká sì rẹ̀wẹ̀sì, pàápàá tó bá jẹ́ pé bí ìṣòro kan ṣe ń lọ ni òmíì ń tẹ̀ lé e tàbí táwọn ìṣòro náà dé sígbà kan náà. Ẹ rántí pé Jèhófà ń rí gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí wa, ó sì máa jẹ́ ká lè fìgboyà kojú ìṣòro èyíkéyìí tó bá dé bá wa.
9. Sọ díẹ̀ lára àwọn àdánwò tó dé bá Jóòbù.
9 Ẹ jẹ́ ká wo bí Jèhófà ṣe ran ọkùnrin olóòótọ́ kan tó ń jẹ́ Jóòbù lọ́wọ́. Oríṣiríṣi ìṣòro tó ń tánni lókun ló dé bá Jóòbù láàárín àkókò díẹ̀. Ní ọjọ́ kan péré, wọ́n mú ìròyìn burúkú wá fún Jóòbù pé gbogbo ẹran ọ̀sìn ẹ̀ ló ti kú, wọ́n tún sọ fún un pé àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ àtàwọn ọmọ ẹ̀ ti kú. (Jóòbù 1:13-19) Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jóòbù yìí ṣì ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá a nígbà tí àìsàn kan tún kọ lù ú. Àìsàn náà ń ríni lára, ó sì ń jẹ́ kára ro ó gan-an. (Jóòbù 2:7) Àìsàn náà le débi tí Jóòbù fi sọ pé: “Mo kórìíra ayé mi gidigidi; mi ò fẹ́ wà láàyè mọ́.”—Jóòbù 7:16.
10. Kí làwọn nǹkan tí Jèhófà ṣe fún Jóòbù tó jẹ́ kó lè fara da àwọn àdánwò tó dé bá a? (Wo àwòrán iwájú ìwé.)
10 Jèhófà rí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jóòbù. Torí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ Jóòbù, ó ràn án lọ́wọ́ láti fara da àwọn àdánwò tó dé bá a kó lè jẹ́ olóòótọ́. Jèhófà rán Jóòbù létí bí ọgbọ́n òun ṣe pọ̀ tó àti bóun ṣe ń fìfẹ́ bójú tó àwọn nǹkan tóun dá. Ó tún sọ fún un nípa bí agbára àwọn ẹranko tóun dá ṣe pọ̀ tó àti oríṣiríṣi nǹkan táwọn ẹranko náà máa ń ṣe. (Jóòbù 38:1, 2; 39:9, 13, 19, 27; 40:15; 41:1, 2) Jèhófà tún lo ọkùnrin olóòótọ́ kan tó ń jẹ́ Élíhù láti tu Jóòbù nínú kó sì fún un lókun. Élíhù fi dá Jóòbù lójú pé Jèhófà máa ń san àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lẹ́san tí wọ́n bá fara da àdánwò. Àmọ́ Jèhófà tún mú kí Élíhù fìfẹ́ bá Jóòbù wí. Élíhù jẹ́ kí Jóòbù rí i pé kò yẹ kó máa ro ara ẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ, ó sì jẹ́ kó mọ̀ pé kò já mọ́ nǹkan kan tó bá fi ara ẹ̀ wé Jèhófà tó dá ayé àtọ̀run. (Jóòbù 37:14) Jèhófà tún gbé iṣẹ́ kan fún Jóòbù pé kó gbàdúrà fún àwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. (Jóòbù 42:8-10) Báwo ni Jèhófà ṣe ń ran àwa náà lọ́wọ́ lónìí tá a bá dojú kọ àdánwò tó le gan-an?
11. Àwọn nǹkan wo ni Bíbélì sọ tó lè tù wá nínú tá a bá ń dojú kọ àdánwò?
11 Lónìí, Jèhófà kì í bá wa sọ̀rọ̀ bó ṣe bá Jóòbù sọ̀rọ̀, àmọ́ ó máa ń fi Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ bá wa sọ̀rọ̀. (Róòmù 15:4) Ó ń fi Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tù wá nínú, ó sì jẹ́ ká nírètí pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa. Ẹ jẹ́ ká gbé kókó díẹ̀ yẹ̀ wò nínú Bíbélì tó lè tù wá nínú nígbà àdánwò. Nínú Bíbélì, Jèhófà fi dá wa lójú pé kò sí ohunkóhun títí kan àdánwò tó le gan-an tó “máa lè yà wá kúrò nínú ìfẹ́” rẹ̀. (Róòmù 8:38, 39) Ó tún fi dá wa lójú pé òun ‘wà nítòsí gbogbo àwọn tó ń gbàdúrà sí òun.’ (Sm. 145:18) Jèhófà jẹ́ ká mọ̀ pé tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé òun, àá lè fara da àdánwò èyíkéyìí tó bá dé bá wa. Kódà, àá máa láyọ̀ tí ìṣòro bá tiẹ̀ ń bá wa fínra. (1 Kọ́r. 10:13; Jém. 1:2, 12) Bíbélì tún jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn àdánwò tá à ń dojú kọ báyìí jẹ́ fún ìgbà díẹ̀, àkókò náà ò sì tó nǹkan kan tá a bá fi wé ìyè àìnípẹ̀kun tí Ọlọ́run máa fún wa lọ́jọ́ iwájú. (2 Kọ́r. 4:16-18) Bákan náà, Jèhófà fi dá wa lójú pé òun máa pa gbogbo àwọn tó ń fa àdánwò tó ń ṣẹlẹ̀ sí wa run, ìyẹn Sátánì Èṣù àtàwọn ẹni burúkú tí wọ́n ń hùwà bíi tiẹ̀. (Sm. 37:10) Àmọ́, ṣé o ti mọ àwọn ẹsẹ Bíbélì kan sórí tó máa jẹ́ kó o lè fara da àwọn àdánwò tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú?
12. Kí ni Jèhófà fẹ́ ká máa ṣe kí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ lè ṣe wá láǹfààní?
12 Jèhófà fẹ́ ká ní àkókò kan tá a yà sọ́tọ̀ láti máa fi kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé, ká sì máa ronú lórí ohun tá a kà. Tá a bá ń fi àwọn ohun tá à ń kọ́ sílò, ìgbàgbọ́ wa máa lágbára, àá sì túbọ̀ sún mọ́ Bàbá wa ọ̀run. Ìyẹn lá sì jẹ́ ká fara da àwọn àdánwò tó lè dé bá wa. Jèhófà tún máa ń fi ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀ ran àwọn tó bá ń ka Ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ́wọ́. Ẹ̀mí mímọ́ yìí sì máa ń jẹ́ ká ní “agbára tó kọjá ti ẹ̀dá,” ká lè fara da àdánwò èyíkéyìí.—2 Kọ́r. 4:7-10.
13. Báwo ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” fi ń bọ́ wa ṣe ń jẹ́ ká máa fara da àdánwò?
13 Jèhófà ń ran “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” lọ́wọ́ láti máa ṣe ìwé, fídíò àtàwọn orin tó ń jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa lágbára, tí kò sì jẹ́ ká fi Jèhófà sílẹ̀. (Mát. 24:45) Ó yẹ ká máa lo àwọn nǹkan tí Jèhófà ń pèsè fún wa yìí dáadáa. Arábìnrin kan tó wá láti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé òun mọyì gbogbo nǹkan tí Jèhófà ń pèsè fún wa yìí. Ó ní: “Láti ogójì (40) ọdún tí mo ti ń sin Jèhófà, oríṣiríṣi nǹkan ló ti dán ìgbàgbọ́ mi wò.” Àwọn àdánwò tó dé bá arábìnrin yìí lágbára gan-an. Ọkùnrin kan tó ti mutí yó, tó sì ń wakọ̀ kọ lu bàbá ẹ̀ àgbà, ó sì kú. Àìsàn kan tó le gan-an pa àwọn òbí ẹ̀, òun náà sì ní àìsàn jẹjẹrẹ lẹ́ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Kí ló jẹ́ kó lè fara dà á? Ó sọ pé: “Kò sígbà kan tí Jèhófà fi mí sílẹ̀. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí ẹrú olóòótọ́ àti olóye fi ń bọ́ wa ti jẹ́ kí n lè fara dà á. Ìyẹn ló jẹ́ kí n lè sọ bíi ti Jóòbù pé: ‘Títí màá fi kú, mi ò ní fi ìwà títọ́ mi sílẹ̀!’”—Jóòbù 27:5.
14. Báwo ni Jèhófà ṣe ń lo àwọn ará wa láti ràn wá lọ́wọ́ nígbà ìṣòro? (1 Tẹsalóníkà 4:9)
14 Jèhófà ti kọ́ àwọn èèyàn ẹ̀ pé kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn, kí wọ́n sì máa ran ara wọn lọ́wọ́ nígbà ìṣòro. (2 Kọ́r. 1:3, 4; ka 1 Tẹsalóníkà 4:9.) Àwọn ará wa máa ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Élíhù, wọ́n máa ń tètè ràn wá lọ́wọ́ ká lè jẹ́ olóòótọ́ nígbà ìṣòro. (Ìṣe 14:22) Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká wo bí àwọn ará ìjọ ṣe tu arábìnrin kan tó ń jẹ́ Diane nínú lẹ́yìn tí ọkọ ẹ̀ ṣàìsàn tó le gan-an, tí wọ́n sì ràn án lọ́wọ́ kí ìgbàgbọ́ ẹ̀ lè lágbára. Ó sọ pé: “Kò rọrùn rárá. Àmọ́ Jèhófà ò fi wá sílẹ̀, ó dúró tì wá gbágbáágbá ní gbogbo àkókò yẹn. Àwọn ará ìjọ wa náà ò gbẹ́yìn, ọ̀pọ̀ nǹkan ni wọ́n ṣe láti ràn wá lọ́wọ́. Wọ́n máa ń pè wá lórí fóònù, wọ́n máa ń bẹ̀ wá wò, wọ́n sì máa ń dì mọ́ wa. Ìyẹn ló jẹ́ ká lè máa fara dà á nìṣó. Torí pé mi ò mọ mọ́tò wà, àwọn ará máa ń wá fi mọ́tò wọn gbé mi lọ sípàdé àti òde ìwàásù.” Ẹ ò rí bí inú wa ṣe ń dùn pé Jèhófà fi àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin yìí jíǹkí wa nínú ìjọ!
MÁA DÚPẸ́ LỌ́WỌ́ JÈHÓFÀ PÉ Ó Ń BÓJÚ TÓ Ẹ
15. Kí nìdí tó fi dá wa lójú pé a lè fara da àdánwò?
15 Gbogbo wa pátápátá la máa dojú kọ àdánwò. Àmọ́ àwọn nǹkan tá a kọ́ nínú àpilẹ̀kọ yìí ti jẹ́ ká rí i pé Jèhófà ò ní fi wá sílẹ̀ nígbà ìṣòro. Bí bàbá kan tó nífẹ̀ẹ́ ọmọ ẹ̀ ṣe máa ń bójú tó o, bẹ́ẹ̀ náà ni Jèhófà ṣe ń bójú tó wa. Gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń wà pẹ̀lú wa, ó sì máa ń gbọ́ wa tá a bá bẹ̀ ẹ́ pé kó ràn wá lọ́wọ́. (Àìsá. 43:2) Ó dájú pé kò sí ìṣòro tó lè dé bá wa tó máa jẹ́ ká fi Jèhófà sílẹ̀ torí gbogbo nǹkan tó máa jẹ́ ká lè fara dà á ló ti pèsè fún wa. Ara àwọn nǹkan tó pèsè fún wa ni pé ó ní ká máa gbàdúrà sí òun, ó fún wa ní Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀, àwọn ìwé, fídíò àtàwọn orin tó ń jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa lágbára, ó sì tún fi àwọn ará jíǹkí wa kí wọ́n lè ràn wá lọ́wọ́ nígbà ìṣòro.
16. Kí ló yẹ ká máa ṣe tá a bá fẹ́ kí Jèhófà máa bójú tó wa?
16 A mà dúpẹ́ o pé Bàbá wa ọ̀run ń bójú tó wa! “Ọkàn wa [sì] ń yọ̀ nínú rẹ̀.” (Sm. 33:21) A lè fi hàn pé a mọyì bí Jèhófà ṣe ń bójú tó wa tá a bá ń lo àwọn nǹkan tó pèsè fún wa. Ó tún yẹ ká ṣe ipa tiwa, ìyẹn ni pé ká má fi Jèhófà sílẹ̀. Lédè míì, tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti máa ṣègbọràn sí Jèhófà tá a sì ń ṣe ohun tó fẹ́, ó dájú pé títí láé lá máa bójú tó wa!—1 Pét. 3:12.
ORIN 30 Bàbá Mi, Ọlọ́run Mi àti Ọ̀rẹ́ Mi