ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 36
Gbé Ẹrù Tó Yẹ Kó O Gbé, Kó O sì Ju Èyí Tí Ò Yẹ Nù
“Ẹ jẹ́ kí àwa náà ju gbogbo ẹrù tó wúwo nù . . . , ká sì máa fi ìfaradà sá eré ìje tó wà níwájú wa.”—HÉB. 12:1.
ORIN 33 Ju Ẹrù Rẹ Sọ́dọ̀ Jèhófà
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ a
1. Kí ni Hébérù 12:1 sọ pé ó yẹ ká ṣe ká lè sáré ìyè náà parí?
BÍBÉLÌ fi ìgbésí ayé àwa Kristẹni wé eré sísá. Àwọn tó bá sá eré náà parí máa gba èrè ìyè àìnípẹ̀kun. (2 Tím. 4:7, 8) Ó yẹ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká lè sá eré náà parí torí a ti sún mọ́ òpin eré náà. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó ti sá eré ìyè náà parí sọ àwọn nǹkan tá a lè ṣe káwa náà lè sá eré náà parí ká sì gba èrè. Ó sọ pé ká “ju gbogbo ẹrù tó wúwo nù . . . ká sì máa fi ìfaradà sá eré ìje tó wà níwájú wa.”—Ka Hébérù 12:1.
2. Kí la lè ṣe ká lè “ju gbogbo ẹrù tó wúwo nù”?
2 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù sọ pé a gbọ́dọ̀ “ju gbogbo ẹrù tó wúwo nù,” ṣé ohun tó ń sọ ni pé àwa Kristẹni ò ní gbé ẹrù kankan? Rárá, ohun tó ń sọ kọ́ nìyẹn. Ohun tó ń sọ ni pé ká ju àwọn ẹrù tí ò yẹ nù. Àwọn ẹrù tí ò yẹ yẹn lè dí wa lọ́wọ́, wọn ò sì ní jẹ́ ká sáré náà parí. Ká bàa lè sá eré náà parí, a gbọ́dọ̀ mọ àwọn ẹrù náà, ká lè sọ wọ́n nù. Bákan náà, àwọn ẹrù kan wà tó yẹ ká gbé dání, kò sì yẹ ká jù wọ́n dà nù. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, a ò ní lè sá eré náà parí. (2 Tím. 2:5) Torí náà, àwọn ẹrù wo ló yẹ ká gbé?
3. (a) Ẹrù wo ni Gálátíà 6:5 sọ pé a gbọ́dọ̀ gbé? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí, kí sì nìdí?
3 Ka Gálátíà 6:5. Pọ́ọ̀lù sọ ẹrù kan tá a gbọ́dọ̀ gbé. Ó ní, “kálukú ló máa ru ẹrù ara rẹ̀.” Ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ níbí ni ohun tí Ọlọ́run fẹ́ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ṣe, tí ẹlòmíì ò lè bá wa ṣe. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tó wà nínú ‘ẹrù wa’ àti bá a ṣe lè gbé e. Bákan náà, a máa mọ àwọn ẹrù tí ò yẹ ká gbé àti bá a ṣe máa jù wọ́n nù. Tá a bá ń gbé àwọn ẹrù tó yẹ ká gbé, tá a sì ju àwọn tí ò yẹ ká gbé nù, àá lè sá eré ìyè náà parí.
ÀWỌN ẸRÙ TÓ YẸ KÁ GBÉ
4. Kí nìdí tí ẹ̀jẹ́ tá a jẹ́ fún Jèhófà ò fi ṣòro láti mú ṣẹ? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
4 Ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ tá a jẹ́. Nígbà tá a ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà, a ṣèlérí pé òun làá máa jọ́sìn, ìfẹ́ ẹ̀ làá sì máa ṣe. Ó yẹ ká mú ẹ̀jẹ́ wa ṣẹ. Ojúṣe ńlá ni ẹ̀jẹ́ tá a jẹ́ pé Jèhófà la máa sìn, àmọ́ kì í ṣe nǹkan tó nira láti ṣe. Kí nìdí? Ìdí ni pé Jèhófà dá wa ká lè máa ṣe ìfẹ́ ẹ̀. (Ìfi. 4:11) Ó dá wa ní àwòrán ara ẹ̀ kó lè máa wù wá láti jọ́sìn ẹ̀. Ìyẹn jẹ́ ká lè sún mọ́ ọn, kí inú wa sì máa dùn bá a ṣe ń ṣe ìfẹ́ ẹ̀. (Sm. 40:8) Bákan náà, tá a bá ń ṣèfẹ́ Ọlọ́run, tá a sì ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Ọmọ ẹ̀, “ara” máa “tù” wá.—Mát. 11:28-30.
5. Kí ló máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti mú ẹ̀jẹ́ ẹ ṣẹ pé Jèhófà ni wàá máa sìn? (1 Jòhánù 5:3)
5 Bó o ṣe lè gbé ẹrù náà. Nǹkan méjì ló máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. Àkọ́kọ́, túbọ̀ máa nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Ọ̀nà tó o lè gbà ṣe é ni pé kó o máa ronú nípa àwọn nǹkan tí Jèhófà ti ṣe fún ẹ àtàwọn ohun rere tó máa ṣe fún ẹ lọ́jọ́ iwájú. Bó o bá ṣe ń nífẹ̀ẹ́ Jèhófà sí i, bẹ́ẹ̀ lá máa rọrùn fún ẹ láti pa àwọn àṣẹ ẹ̀ mọ́. (Ka 1 Jòhánù 5:3.) Ìkejì, máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù. Ohun tó jẹ́ kó ṣèfẹ́ Ọlọ́run láṣeyọrí ni pé ó máa ń gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ran òun lọ́wọ́, ó sì gbájú mọ́ èrè tó máa gbà lọ́jọ́ iwájú. (Héb. 5:7; 12:2) Bíi ti Jésù, bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ lókun, kó lè túbọ̀ dá ẹ lójú pé wàá rí ìyè àìnípẹ̀kun gbà lọ́jọ́ iwájú. Torí náà, bó o ṣe túbọ̀ ń nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, tó o sì ń fara wé Ọmọ ẹ̀, wàá mú ẹ̀jẹ́ ẹ ṣẹ pé Jèhófà ni wàá máa sìn.
6. Kí nìdí tí ò fi yẹ ká pa ojúṣe wa nínú ìdílé tì? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
6 Ojúṣe wa nínú ìdílé. Bá a ṣe ń sáré ìyè, a gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti Jésù ju àwọn mọ̀lẹ́bí wa lọ. (Mát. 10:37) Àmọ́, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé ká pa ojúṣe wa nínú ìdílé tì torí ojúṣe ìdílé wa ò sọ pé ká má ṣohun tí Ọlọ́run àti Kristi fẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, tá a bá fẹ́ ṣe ohun tí Ọlọ́run àti Kristi fẹ́, a gbọ́dọ̀ ṣe ojúṣe wa nínú ìdílé. (1 Tím. 5:4, 8) Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a máa láyọ̀. Jèhófà mọ̀ pé ìdílé máa láyọ̀ tí ọkọ àti ìyàwó bá nífẹ̀ẹ́ ara wọn, tí wọ́n sì ń bọ̀wọ̀ fún ara wọn. Bákan náà, ìdílé á láyọ̀ táwọn òbí bá nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wọn, tí wọ́n tọ́ wọn lọ́nà tó tọ́, táwọn ọmọ náà sì ń gbọ́ràn sí wọn lẹ́nu.—Éfé. 5:33; 6:1, 4.
7. Báwo lo ṣe lè máa ṣe ojúṣe ẹ nínú ìdílé?
7 Bó o ṣe lè gbé ẹrù náà. Bóyá ọkọ, aya tàbí ọmọ ni ẹ́, ọgbọ́n Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì ni kó o máa lò, dípò tí wàá fi gbára lé èrò tara ẹ, àṣà ìbílẹ̀ ẹ tàbí ohun táwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ agbaninímọ̀ràn sọ. (Òwe 24:3, 4) Máa kẹ́kọ̀ọ́ àwọn ìwé ètò Ọlọ́run. Nínú àwọn ìwé náà, wàá rí àwọn àbá tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ táá jẹ́ kó o máa fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò. Bí àpẹẹrẹ, a dìídì kọ ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ́ náà “Ìrànlọ́wọ́ fún Ìdílé” fáwọn tọkọtaya, àwọn òbí àtàwọn ọ̀dọ́, kí wọ́n lè yanjú ìṣòro tí wọ́n ní báyìí. b Pinnu pé wàá máa ṣe ohun tí Bíbélì sọ, kódà táwọn yòókù nínú ìdílé ẹ ò bá ṣe bẹ́ẹ̀. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, gbogbo ìdílé ẹ máa jàǹfààní ẹ̀, wàá sì rí ìbùkún Jèhófà gbà.—1 Pét. 3:1, 2.
8. Báwo làwọn ìpinnu wa ṣe lè pa wá lára?
8 Àbájáde ìpinnu tá a bá ṣe. Jèhófà ti fún wa lómìnira láti yan ohun tá a fẹ́, ó sì fẹ́ ká ṣe ìpinnu tó tọ́ kí inú wa lè máa dùn. Àmọ́ tá a bá ṣe ìpinnu tí ò dáa, ó máa ń fàyè gbà á kí ìyà ẹ̀ jẹ wá. (Gál. 6:7, 8) Torí náà, a máa fara mọ́ àbájáde ìpinnu tí ò tọ́ tá a ṣe, ọ̀rọ̀ tí ò dáa tá a sọ àtàwọn nǹkan tá a kánjú ṣe. Ẹ̀rí ọkàn lè máa dà wá láàmú tó bá jẹ́ pé ohun tó burú jáì la ṣe. Àmọ́, tá a bá gbà pé a máa jìyà àbájáde ẹ̀ṣẹ̀ wa, ìyẹn á jẹ́ ká jẹ́wọ́ ẹ̀sẹ̀ náà, ká ṣàtúnṣe, ká má sì dá ẹ̀ṣẹ̀ náà mọ́. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, á jẹ́ ká lè máa sá eré ìyè nìṣó.
9. Kí lo lè ṣe tó o bá ti ṣe ìpinnu tí ò tọ́? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
9 Bó o ṣe lè gbé ẹrù náà. Tó o bá ti ṣe ìpinnu tí ò tọ́, kí lo lè ṣe? Gbà pé ohun tó ṣelẹ̀ ti ṣẹlẹ̀. Má fi àkókò ẹ ṣòfò, kó o wá máa sọ pé ohun tó o ṣe ò burú tàbí kó o wá máa dá ara ẹ àtàwọn ẹlòmíì lẹ́bi nítorí àṣìṣe tó o ṣe. Kàkà bẹ́ẹ̀, gbà pé o ti ṣàṣìṣe, kó o sì máa ṣe gbogbo ohun tó o bá lè ṣe láti ṣàtúnṣe. Tí ẹ̀rí ọkàn ẹ bá ń dà ẹ́ láàmú nítorí àṣìṣe tó o ṣe, rẹ ara ẹ sílẹ̀, gbàdúrà sí Jèhófà, jẹ́ kó mọ̀ pé o ṣàṣìṣe, kó o sì ní kó dárí jì ẹ́. (Sm. 25:11; 51:3, 4) Lọ bẹ àwọn tó o ṣẹ̀, tó bá pọn dandan, lọ bá àwọn alàgbà pé kí wọ́n ràn ẹ́ lọ́wọ́. (Jém. 5:14, 15) Kẹ́kọ̀ọ́ látinú àwọn àṣìṣe tó o ṣe, kó o má sì dá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ náà mọ́. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó dájú pé Jèhófà máa fàánú hàn sí ẹ, ó sì máa ràn ẹ́ lọ́wọ́.—Sm. 103:8-13.
ÀWỌN ẸRÙ TÓ YẸ KÓ O ‘JÙ NÙ’
10. Tá a bá ń retí ohun tọ́wọ́ wa ò lè tẹ̀, báwo nìyẹn ṣe lè dẹrù pa wá? (Gálátíà 6:4)
10 Ohun tọ́wọ́ wa ò lè tẹ̀. Tá a bá ń fi ara wa wé àwọn ẹlòmíì, a lè dẹrù pa ara wa. (Ka Gálátíà 6:4.) Tá a bá ń fi ara wa wé àwọn ẹlòmíì ní gbogbo ìgbà, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìlara wọn, ká sì máa bá wọn díje. (Gál. 5:26) Tá a bá ń ṣiṣẹ́ kára torí ká lè ní nǹkan táwọn ẹlòmíì ní, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ohun tágbára wa ò ká. Kẹ́ ẹ sì máa wò ó o, “ìrètí pípẹ́ máa ń mú ọkàn ṣàìsàn.” Tá a bá wá ń retí ohun tọ́wọ́ wa ò lè tẹ̀ láé, ẹ ò rí i pé ìbànújẹ́ yẹn máa pọ̀ gan-an! (Òwe 13:12) Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ó máa rẹ̀ wá gan-an, a ò sì ní lè sáré ìyè náà dáadáa.—Òwe 24:10.
11. Kí ni ò ní jẹ́ kó o máa lé ohun tó ju agbára ẹ lọ?
11 Bó o ṣe lè ju ẹrù náà nù. Má rò pé o ò ṣe tó ohun tí Jèhófà retí pé kó o ṣe. Kò retí pé kó o ṣe ohun tó ju agbára ẹ lọ. (2 Kọ́r. 8:12) Mọ̀ dájú pé Jèhófà kì í fi ohun tó o ṣe wé ohun táwọn ẹlòmíì ṣe. (Mát. 25:20-23) Ó mọyì bó o ṣe ń sin òun tọkàntọkàn, bó o ṣe jẹ́ olóòótọ́ àti bó o ṣe ń fara dà á. Ó yẹ kó o mọ̀wọ̀n ara ẹ, kó o sì gbà pé ọjọ́ orí ẹ, àìsàn àtàwọn nǹkan míì lè má jẹ́ kó o ṣe tó bó o ṣe fẹ́. Ìwọ náà lè ṣe bíi ti Básíláì. Tó o bá rí i pé àìsàn tàbí ọjọ́ orí ẹ ò ní lè jẹ́ kó o ṣe iṣẹ́ kan, o lè ní kí wọ́n gbé e fún ẹlòmíì. (2 Sám. 19:35, 36) Bíi ti Mósè, jẹ́ káwọn míì ràn ẹ́ lọ́wọ́, kó o sì gbéṣẹ́ fún wọn. (Ẹ́kís. 18:21, 22) Tó o bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, kò ní jẹ́ kó o máa lé àwọn nǹkan tó ju agbára ẹ lọ débi pé o ò ní lè sá eré ìyè náà mọ́.
12. Ṣé ẹ̀bi wa ni táwọn ẹlòmíì bá ṣe ìpinnu tí ò dáa? Ṣàlàyé.
12 Tó o bá ń dá ara ẹ lẹ́bi nítorí ìpinnu táwọn ẹlòmíì ṣe. A ò lè ṣèpinnu fáwọn ẹlòmíì, a ò sì lè dáàbò bò wọ́n kí wọ́n má jìyà ìpinnu tí ò dáa tí wọ́n ṣe. Bí àpẹẹrẹ, ọmọ kan lè sọ pé òun ò sin Jèhófà mọ́. Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè kó ẹ̀dùn ọkàn tó pọ̀ bá àwọn òbí ọmọ náà. Àmọ́, tírú àwọn òbí bẹ́ẹ̀ bá ń dá ara wọn lẹ́bi nítorí ìpinnu tí ò dáa tọ́mọ wọn ṣe, ńṣe lẹ̀dùn ọkàn wọn á máa pọ̀ sí i. Ìyẹn ò sí lára ẹrù tí Jèhófà retí pé kí wọ́n gbé.—Róòmù 14:12.
13. Kí ló yẹ kí òbí kan ṣe tọ́mọ ẹ̀ bá ṣe ìpinnu tí ò dáa?
13 Bó o ṣe lè ju ẹrù náà nù. Ó yẹ kẹ́yin òbí mọ̀ pé gbogbo wa ni Jèhófà fún lómìnira láti ṣe ohun tá a fẹ́. Ó sì máa ń jẹ́ kẹ́nì kọ̀ọ̀kan wa ṣe ìpinnu tó bá wù wá. Ọ̀kan lára ìpinnu náà ni bóyá Jèhófà la máa sìn àbí òun kọ́. Jèhófà mọ̀ pé o kì í ṣe ẹni pípé, àmọ́ ó fẹ́ kó o ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe. Ọmọ ẹ ló máa jíhìn fún ìpinnu tí ò dáa tó ṣe, kì í ṣe ìwọ. (Òwe 20:11) Síbẹ̀, o lè máa ronú pé ìwọ lo fà á tọ́mọ ẹ fi ṣe irú ìpinnu tó ṣe yẹn. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, sọ bó ṣe ń ṣe ẹ́ fún Jèhófà, kó o sì ní kó dárí jì ẹ́. Ó mọ̀ pé ohun tó ṣẹlẹ̀ ti ṣẹlẹ̀, o ò sì lè yí i pa dà. Síbẹ̀, kò retí pé kó o dáàbò bo ọmọ ẹ kó má bàa jìyà ohun tó ṣe. Torí náà, máa rántí pé tọ́mọ ẹ bá pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà, inú ẹ̀ máa dùn gan-an láti gbà á pa dà.—Lúùkù 15:18-20.
14. Kí nìdí tí ò fi yẹ ká máa dá ara wa lẹ́bi ṣáá?
14 Má ṣe máa dá ara ẹ lẹ́bi ṣáá. Tá a bá dẹ́ṣẹ̀, kò burú tá a bá kábàámọ̀ ohun tá a ṣe. Àmọ́, Jèhófà ò retí pé ká máa dá ara wa lẹ́bi ṣáá torí ohun tá a ṣe. Ẹrù tó yẹ ká jù nù ni. Tá a bá jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa, tá a ronú pìwà dà, tá a sì ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká má bàa dá ẹ̀ṣẹ̀ náà mọ́, kò yẹ ká máa dá ara wa lẹ́bi mọ́. Ó yẹ kó dá wa lójú pé Jèhófà ti dárí jì wá. (Ìṣe 3:19) Tá a bá ti ṣe àwọn nǹkan yìí, Jèhófà ò fẹ́ ká máa dá ara wa lẹ́bi mọ́. Ó mọ̀ pé ó lè pa wá lára tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀. (Sm. 31:10) Tá a bá jẹ́ kí ẹ̀dùn ọkàn bò wá mọ́lẹ̀, ó lè má jẹ́ ká sáré ìyè náà mọ́.—2 Kọ́r. 2:7.
15. Kí ni ò ní jẹ́ kó o máa dá ara ẹ lẹ́bi ṣáá? (1 Jòhánù 3:19, 20) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
15 Bó o ṣe lè ju ẹrù náà nù. Tó o bá ń dá ara ẹ lẹ́bi ṣáá, máa rántí pé tí Ọlọ́run bá ti dárí ẹ̀ṣẹ̀ ẹ jì ẹ́, kò ní rántí ẹ̀ mọ́. (Sm. ) Ó ṣèlérí pé tóun bá ti dárí ji àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó ronú pìwà dà tọkàntọkàn, òun ò “ní rántí ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́.” ( 130:4Jer. 31:34) Ìyẹn ni pé lẹ́yìn tí Jèhófà bá ti dárí jì ẹ́, kò tún ní rántí ẹ̀ mọ́. Torí náà, tó o bá ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ ẹ, má rò pé Jèhófà ò tíì dárí jì ẹ́ lo ṣe ń jìyà. Tó o bá ti pàdánù àwọn iṣẹ́ tó ò ń ṣe nínú ètò Ọlọ́run nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tó o dá, má banú jẹ́ ju bó ṣe yẹ lọ. Jèhófà ti gbàgbé àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ẹ, ó sì yẹ kíwọ náà gbàgbé ẹ̀.—Ka 1 Jòhánù 3:19, 20.
MÁA SÁRÉ KÓ O LÈ YEGE
16. Bá a ṣe ń sá eré ìyè, kí ló yẹ ká mọ̀?
16 Bá a ṣe ń sáré ìyè nìṣó, ó yẹ ká ‘sáré lọ́nà tí àá fi lè gba èrè.’ (1 Kọ́r. 9:24) Ohun tó máa ràn wá lọ́wọ́ ni tá a bá mọ ẹrù tó yẹ ká gbé àtèyí tó yẹ ká jù nù. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a ti sọ̀rọ̀ nípa díẹ̀ lára ẹrù tó yẹ ká gbé àtèyí tó yẹ ká jù nù. Àmọ́, àwọn kan ṣì wà tó yẹ ká sọ̀rọ̀ nípa wọn. Bí àpẹẹrẹ, Jésù sọ pé tá ò bá ṣọ́ra, ‘àjẹjù, ọtí àmujù àti àníyàn ìgbésí ayé lè di ẹrù pa ọkàn wa.’ (Lúùkù 21:34) Ẹsẹ Bíbélì yìí àtàwọn míì lè jẹ́ kó o rí àwọn ibi tó yẹ kó o ti ṣàtúnṣe bó o ṣe ń sá eré ìyè nìṣó.
17. Kí nìdí tó fi dá wa lójú pé a máa yege bá a ṣe ń sá eré ìyè?
17 Ó yẹ kó dá wa lójú pé a máa yege bá a ṣe ń sáré ìyè torí Jèhófà máa fún wa lókun tá a máa fi sáré náà. (Àìsá. 40:29-31) Torí náà, má jẹ́ kó rẹ̀ ẹ́! Tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó fi gbogbo okun ẹ̀ sáré kó lè gba èrè tí Jèhófà fẹ́ fún un. (Fílí. 3:13, 14) Ìwọ fúnra ẹ lo máa sá eré yìí torí wọn kì í báàyàn sá a, àmọ́ Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè sáré náà dópin. Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti gbé àwọn ẹrù tó yẹ, kó o sì ju àwọn tí ò yẹ nù. (Sm. 68:19) Torí náà, mọ̀ pé Jèhófà máa dúró tì ẹ́, á sì jẹ́ kó o fi ìfaradà sá eré ìyè náà parí!
ORIN 65 Ẹ Tẹ̀ Síwájú!
a Àpilẹ̀kọ yìí máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa bá eré ìyè tá à ń sá nìṣó. Bá a ṣe ń sáré, àwọn ojúṣe kan wà tá a gbọ́dọ̀ ṣe. Ara àwọn ojúṣe náà ni bá a ṣe máa mú ẹ̀jẹ́ wa ṣẹ pé Jèhófà la máa sìn, ojúṣe wa nínú ìdílé àti àbájáde ìpinnu tá a bá ṣe. Àmọ́, a gbọ́dọ̀ ju àwọn ẹrù tí ò yẹ, tí ò sì ní jẹ́ ká sáré náà parí dà nù. Àwọn ẹrù wo nìyẹn? A máa dáhùn ìbéèrè yẹn nínú àpilẹ̀kọ yìí.
b Wàá rí ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ náà “Ìrànlọ́wọ́ fún Ìdílé” lórí jw.org. Díẹ̀ lára àpilẹ̀kọ tó wà fáwọn tọkọtaya nìyí “Bó O Ṣe Lè Fi Ọ̀wọ̀ Hàn” àti “Bó O Ṣe Lè Mọyì Ẹnì Kejì Rẹ.” Èyí tó wà fáwọn òbí ni: “Kọ́ Àwọn Ọmọdé Bí Wọ́n Ṣe Lè Máa Fọgbọ́n Lo Fóònù” àti “Bó O Ṣe Lè Máa Bá Ọmọ Rẹ Tó Ti Ń Bàlágà Sọ̀rọ̀.” Èyí tó wà fáwọn ọ̀dọ́ ni: “Bó Ò Ṣe Ní Jẹ́ Káwọn Ojúgbà Ẹ Máa Darí Ẹ” àti “Ohun Tó O Lè Ṣe Tó Bá Ń Ṣe Ẹ́ Bíi Pé O Kò Ní Ọ̀rẹ́.”