Ohun Tó O Lè Fi Kẹ́kọ̀ọ́
Wá Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Nípa Jèhófà
Tá a bá ń ka Bíbélì, a lè lo àwọn ìwé àti fídíò wa láti ṣèwádìí, ká lè lóye ohun tá à ń kà. Àmọ́, kò yẹ ká máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ká lè ní ìmọ̀ nìkan, ó tún yẹ ká máa wá àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye nípa ìwà àti ìṣe Jèhófà táá jẹ́ ká túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ ẹ̀. Ohun tó máa jẹ́ ká ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká bi ara wa ní ìbéèrè yìí, ‘Kí ni ìtàn Bíbélì yìí kọ́ mi nípa Jèhófà?’
Bí àpẹẹrẹ, o lè ṣèwádìí sí i nípa àwọn ànímọ́ Jèhófà tó gba iwájú, ìyẹn ìfẹ́, ọgbọ́n, ìdájọ́ òdodo àti agbára, kó o sì wo bó ṣe ń fi wọ́n hàn nínú ohun tó ń ṣe. Àmọ́, Jèhófà ṣì láwọn ànímọ́ míì tó dáa. Torí náà, ibo lo ti lè ṣèwádìí kó o lè mọ púpọ̀ sí i nípa àwọn ànímọ́ náà?
Lọ wo àwọn ànímọ́ míì tí Jèhófà ní tó ju àádọ́ta (50) lọ nínú Watch Tower Publications Index. Wàá rí àkòrí náà “Jehovah” àti ìsọ̀rí tó sọ pé “Qualities by Name.” Ṣèwádìí nípa àwọn ànímọ́ Jèhófà tó wà nínú ìtàn Bíbélì tó ò ń kà. (Tó bá jẹ́ pé Ìwé Ìwádìí fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lo fi máa ń ṣèwádìí, lọ wo “Jèhófà Ọlọ́run,” lẹ́yìn náà kó o wo ìsọ̀rí tó sọ pé “Àwọn Ànímọ́ Jèhófà.”)