ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 35
ORIN 123 Máa Ṣègbọràn sí Ètò Ọlọ́run
Báwọn Alàgbà Ṣe Lè Ṣèrànwọ́ Fáwọn Tí Wọ́n Mú Kúrò Nínú Ìjọ
“Inú àwọn tó wà ní ọ̀run máa dùn gan-an torí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tó ronú pìwà dà ju olódodo mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún (99) tí kò nílò ìrònúpìwàdà.”—LÚÙKÙ 15:7.
OHUN TÁ A MÁA KỌ́
A máa mọ ìdí to fi yẹ ká mú àwọn kan kúrò nínú ìjọ àti báwọn alàgbà ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ronú pìwà dà, kí wọ́n sì pa dà di ọ̀rẹ́ Jèhófà.
1-2. (a) Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo àwọn tó dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì tí wọn ò sì ronú pìwà dà? (b) Kí ni Jèhófà fẹ́ káwọn tó dẹ́ṣẹ̀ ṣe?
JÈHÓFÀ kì í gba ohun tí ò dáa láyè, ó sì kórìíra ẹ̀ṣẹ̀. (Sm. 5:4-6) Ó fẹ́ ká máa tẹ̀ lé ìlànà òdodo ẹ̀ tó wà nínú Bíbélì. Àmọ́ Jèhófà mọ̀ pé aláìpé ni wá, a ò sì lè pa gbogbo àṣẹ ẹ̀ mọ́ láìkù síbì kan. (Sm. 130:3, 4) Síbẹ̀, kò fàyè gba ‘àwọn tí ò ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, tí wọ́n ń fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run wa ṣe àwáwí láti máa hu ìwà àìnítìjú.’ (Júùdù 4) Torí náà, Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa “ìparun àwọn èèyàn tí kò ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run” tó máa wáyé ní ogun Amágẹ́dọ́nì.—2 Pét. 3:7; Ìfi. 16:16.
2 Àmọ́, Jèhófà ò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run. Bá a ṣe sọ nínú àwọn àpilẹ̀kọ́ tó ṣáájú, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà “fẹ́ kí gbogbo èèyàn ronú pìwà dà.” (2 Pét. 3:9) Àwọn alàgbà máa fara wé Jèhófà tí wọ́n bá fi sùúrù ran ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́ kó lè ronú pìwà dà kó sì pa dà di ọ̀rẹ́ Jèhófà. Àmọ́, kì í ṣe gbogbo ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ ló máa ń ronú pìwà dà. (Àìsá. 6:9) Àwọn kan kì í yí ìwà wọn pa dà báwọn alàgbà tiẹ̀ sapá gan-an láti mú kí wọ́n ronú pìwà dà. Tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, kí làwọn alàgbà lè ṣe?
“Ẹ MÚ ẸNI BURÚKÚ NÁÀ KÚRÒ”
3. (a) Kí ni Bíbélì sọ pé ká ṣe fún ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ tí ò ronú pìwà dà? (b) Tí ẹnì kan ò bá ronú pìwà dà, kí nìdí tá a fi lè sọ pé òun ló fẹ́ mú ara ẹ̀ kúrò nínú ìjọ?
3 Tẹ́ni tó dẹ́ṣẹ ò bá ronú pìwà dà, àwọn alàgbà gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé ohun tí 1 Kọ́ríńtì 5:13 sọ, ó ní: “Ẹ mú ẹni burúkú náà kúrò láàárín yín.” Ká sòóótọ́, ohun tẹ́ni tó dẹ́ṣẹ̀ náà fẹ́ nìyẹn, ó sì máa kórè ohun tó gbìn. (Gál. 6:7) Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé ẹni náà ò yí ìwà ẹ̀ pa dà báwọn alàgbà tiẹ̀ ti sapá léraléra láti ràn án lọ́wọ́. (2 Ọba 17:12-15) Ohun tó ń ṣe fi hàn pé kò fẹ́ tẹ̀ lé ìlànà Jèhófà mọ́.—Diu. 30:19, 20.
4. Kí nìdí tí wọ́n fi máa ń ṣèfilọ̀ tí wọ́n bá mú ẹlẹ́ṣẹ̀ tí ò ronú pìwà dà kúrò nínú ìjọ?
4 Tí wọ́n bá mú ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ tí ò ronú pìwà dà kúrò nínú ìjọ, wọ́n máa ń ṣèfilọ̀ fún ìjọ pé ẹni náà kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́. a Wọn ò ṣèfilọ̀ yẹn kí wọ́n lè dójú tì ẹni náà. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ṣèfilọ̀ náà kí ìjọ lè tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì tó sọ pé “ẹ jáwọ́ nínú kíkẹ́gbẹ́” pẹ̀lú ẹni náà, “kí ẹ má tiẹ̀ bá irú ẹni bẹ́ẹ̀ jẹun.” (1 Kọ́r. 5:9-11) Kí nìdí tí Jèhófà fi sọ bẹ́ẹ̀ fún wa? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ ìdí náà, ó ní: “Ìwúkàrà díẹ̀ ló ń mú gbogbo ìṣùpọ̀ wú.” (1 Kọ́r. 5:6) Tí wọn ò bá mú ẹni tí ò ronú pìwà dà náà kúrò nínú ìjọ, ó lè ṣàkóbá fáwọn ará, wọ́n sì lè má ṣègbọ́ràn sí Jèhófà mọ́.—Òwe 13:20; 1 Kọ́r. 15:33.
5. Báwo ló ṣe yẹ ká ṣe sẹ́ni tí wọ́n mú kúrò nínú ìjọ, kí sì nìdí?
5 Báwo ló ṣe yẹ ká ṣe sẹ́ni tí wọ́n mú kúrò nínú ìjọ? Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ò ní máa bá a kẹ́gbẹ́, ó yẹ ká máa rántí pé ọ̀rọ̀ ẹni náà ò kọjá àtúnṣe, ó kàn ṣìnà ni. Ọ̀rọ̀ ẹ̀ dà bí àgùntàn tó ṣìnà, ó ṣì lè pa dà wálé. Rántí pé ẹni náà ti ya ara ẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà. Àmọ́, ó ṣeni láàánú pé kò ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́ mọ́, ìyẹn sì lè mú kó pàdánù ìyè àìnípẹ̀kún. (Ìsík. 18:31) Síbẹ̀, Jèhófà lè ṣàánú ẹ̀, torí náa a retí pé ẹni náà ṣì lè yí pa dà. Báwo làwọn alàgbà ṣe máa ṣèrànwọ́ fẹ́ni tó dẹ́ṣẹ̀ tí wọ́n mú kúrò nínú ìjọ?
BÁWỌN ALÀGBÀ ṢE MÁA RAN ÀWỌN TÍ WỌ́N MÚ KÚRÒ NÍNÚ ÌJỌ LỌ́WỌ́
6. Kí làwọn alàgbà máa ṣe láti ran ẹni tí wọ́n mú kúrò nínú ìjọ lọ́wọ́?
6 Tí wọ́n bá mú ẹnì kan kúrò nínú ìjọ, ṣé àwọn alàgbà máa pa ẹni náà tì, pé kóun fúnra ẹ̀ wá bó ṣe máa pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà? Rárá o! Tí wọ́n bá sọ fún ẹni tí ò ronú pìwà dà pé wọ́n máa mú un kúrò nínú ìjọ, ìgbìmọ̀ tó bójú tó ọ̀rọ̀ ẹ̀ máa ṣàlàyé ohun tó máa ṣe kó lè pa dà sínú ìjọ. Àmọ́ àwọn alàgbà náà máa ṣe àwọn nǹkan míì. Lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n máa sọ fún ẹni náà pé àwọn tún máa pàdé pẹ̀lú ẹ̀ tí oṣù díẹ̀ bá ti kọjá, kí wọ́n lè mọ̀ bóyá ó ti yí iwà ẹ̀ pa dà. Tó bá wu ẹni náà láti tún pàdé pẹ̀lú wọn, àwọn alàgbà máa rọ̀ ọ́ pé kó ronú pìwà dà, kó sì pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà. Kódà tí ò bá ronú pìwà dà, àwọn alàgbà tún máa sapá láti pàdé pẹ̀lú ẹ̀ nígbà míì kó lè ronú pìwà dà.
7. Tí wọ́n bá mú ẹnì kan kúrò nínú ìjọ, báwo làwọn alàgbà ṣe lè fara wé Jèhófà kí wọ́n sì fàánú hàn sí ẹni náà? (Jeremáyà 3:12)
7 Àwọn alàgbà máa ń fara wé Jèhófà bí wọ́n ṣe ń fàánú hàn sí ẹni tí wọ́n mú kúrò nínú ìjọ. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà ò dúró kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rónú pìwà dà kó tó ràn wọ́n lọ́wọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó rán àwọn wòlíì ẹ̀ sí wọn nígbà tí wọn ò tíì ronú pìwà dà. Nínú àpilẹ̀kọ kejì, a rí bí Jèhófà ṣe fàánú hàn nígbà tó sọ fún Hósíà pé kó dárí ji ìyàwó ẹ̀ kó sì gbà á pa dà nígbà tó ṣì ń dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì. (Hós. 3:1; Mál. 3:7) Àwọn alàgbà ń fara wé Jèhófà, wọ́n ń fẹ́ kí ẹlẹ́ṣẹ̀ náà ronú pìwà dà kó lè pa dà sínú ìjọ, wọ́n sì ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti ràn án lọ́wọ́.—Ka Jeremáyà 3:12.
8. Báwo ni àpèjúwe tí Jésù sọ nípa ọmọkùnrin tó sọ nù ṣe jẹ́ ká mọ bí Jèhófà ṣe máa ń fàánú hàn sí wa? (Lúùkù 15:7)
8 Ṣé ẹ rántí pé nínú àpilẹ̀kọ kejì, a sọ̀rọ̀ nípa àpèjúwe tí Jésù sọ nípa ọmọkùnrin tó sọ nù. Nígbà tí bàbá ẹ̀ tajú kán rí i, “ó wá sáré lọ dì mọ́ ọn, ó sì rọra fi ẹnu kò ó lẹ́nu.” (Lúùkù 15:20) Ṣé ẹ rí i pé bàbá ẹ̀ ò dúró kí ọmọ yẹn kọ́kọ́ wá tọrọ àforíjì. Kàkà bẹ́ẹ̀, òun ló kọ́kọ́ lọ bá a torí pé ó nífẹ̀ẹ́ ẹ̀. Ohun kan náà làwọn alàgbà máa ṣe fún ẹni tó fi Jèhófà sílẹ̀. Wọ́n fẹ́ káwọn tó ti sọ nù pa dà wálé. (Lúùkù 15:22-24, 32) Inú àwọn tó wà lọ́run máa ń dùn gan-an tẹ́ni tó dẹ́ṣẹ̀ bá pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà, inú àwọn ará ìjọ náà sì máa ń dùn!—Ka Lúùkù 15:7.
9. Kí ni Jèhófà fẹ́ káwọn tó dẹ́ṣẹ̀ ṣe?
9 Nínú ohun tá a ti ń sọ bọ̀, a ti rí i pé Jèhófà ò fàyè gba àwọn tí ò ronú pìwà dà kí wọ́n wà nínú ìjọ. Síbẹ̀, ó fẹ́ ràn wọ́n lọ́wọ́. Ó fẹ́ kí wọ́n pa dà sọ́dọ̀ òun. Hósíà 14:4 sọ bó ṣe máa ń rí lára Jèhófà táwọ́n ẹlẹ́ṣẹ̀ bá ronú pìwà dà, ó ní: “Màá wo àìṣòótọ́ wọn sàn. Màá nífẹ̀ẹ́ wọn láti ọkàn mi wá, torí pé mi ò bínú sí wọn mọ́.” Ohun tí Jèhófà sọ yìí á jẹ́ káwọn alàgbà máa kíyè sí ohun tó fi hàn pé ẹnì náà ti bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pìwà dà. Ó tún jẹ́ kó dá àwọn tó ti fi Jèhófà sílẹ̀ lójú pé ó nífẹ̀ẹ́ wọn, ó sì fẹ́ kí wọ́n pa dà sọ́dọ̀ òun láìjáfara.
10-11. Báwo làwọn alàgbà ṣe máa ṣèrànwọ́ fáwọn tí wọ́n mú kúrò nínú ìjọ tipẹ́tipẹ́?
10 Báwo làwọn alàgbà ṣe máa ṣèrànwọ́ fáwọn tí wọ́n mú kúrò nínú ìjọ tipẹ́tipẹ́, bóyá lọ́pọ̀ ọdún sẹ́yìn? Irú awọn ẹni bẹ́ẹ̀ lè má dá ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n torí ẹ̀ mú wọn kúrò nínú ìjọ mọ́. Àwọn míì tiẹ̀ lè má rántí ìdí tí wọ́n fi mú wọn kúrò nínú ìjọ. Bó ti wù kó pẹ́ tó tí wọ́n ti kúrò, àwọn alàgbà máa wá wọn kàn, wọ́n á sì bá wọn sọ̀rọ̀. Nígbà táwọn alàgbà bá lọ sọ́dọ̀ wọn, wọ́n máa sọ pé káwọn gbàdúrà pẹ̀lú wọn, wọ́n á sì rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n pa dà sínú ìjọ. Àmọ́ tó bá ti pẹ́ gan-an tí wọ́n ti kúrò nínú ìjọ, ó máa gba pé kí wọ́n tún pa dà kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà. Torí náà, tẹ́ni náà bá sọ pé òun fẹ́ pa dà sínú ìjọ, àwọn alàgbà lè ṣètò kí ẹnì kan máa kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọn ò bá tiẹ̀ tíì gbà á pa dà. Bó ti wù kó rí, àwọn alàgbà ló máa ṣètò ẹni tó máa kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
11 Àwọn alàgbà máa ń fara wé Jèhófà bó ṣe ń fàánú hàn, wọ́n máa ń wá àwọn tó ti fi Jèhófà sílẹ̀, wọ́n sì máa ń rọ̀ wọn pé kí wọ́n pa dà sọ́dọ̀ rẹ̀. Tí àwọn tó dẹ́ṣẹ̀ bá ti ronú pìwa dà tí wọ́n ò sì hùwà burúkú náà mọ́, wọ́n á gbà wọ́n pa dà láìjáfara.—2 Kọ́r. 2:6-8.
12. (a) Àwọn nǹkan wo ló yẹ káwọn alàgbà kíyè sí? (b) Kí nìdí tí ò fi yẹ ká máa rò pé àwọn tó bá dá irú ẹ̀ṣẹ̀ kan ò lè rí àánú Jèhófà gbà? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
12 Àwọn nǹkan kan wà tó yẹ káwọn alàgbà kíyè sí kí wọ́n tó gba ẹnì kan pa dà sínú ìjọ. Bí àpẹẹrẹ, tí ẹnì kan bá hùwà ìkà sọ́mọdé tàbí tó bá a ṣèṣekúṣe, tẹ́nì kan bá jẹ́ apẹ̀yìndà tàbí tẹ́nì kan dá ọgbọ́nkọ́gbọ́n kó lè kọ ẹnì kejì ẹ̀ sílẹ̀, àwọn alàgbà gbọ́dọ̀ rí i dájú pé ó ronú piwà dà tọkàntọkàn kí wọ́n tó gbà á pa dà. (Mál. 2:14; 2 Tím. 3:6) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn alàgbà gbọ́dọ̀ dáàbò bo ìjọ, wọ́n tún gbọ́dọ̀ máa rántí pé Jèhófà máa tẹ́wọ́ gba ẹni tó ronú pìwà dà látọkànwá, tó sì jáwọ́ nínú ìwà burúkú tó ń hù. Òótọ́ ni pé àwọn alàgbà gbọ́dọ̀ rí i dájú pé ẹni tó hùwà àìṣòótọ́ sáwọn ẹlòmíì ronú pìwà dà, àmọ́ kò yẹ kí wọ́n rò pé irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ kò lè rí àánú Jèhófà gbà. b—1 Pét. 2:10.
OHUN TÍ ÌJỌ LÈ ṢE
13. Ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín bá a ṣe ń ṣe sẹ́ni táwọn alàgbà bá wí àtẹni tí wọ́n mú kúrò nínú ìjọ?
13 Bá a ṣe jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, nígbà míì wọ́n máa ń ṣèfilọ̀ pé a ti bá ẹnì kan wí. Tó bá ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀, àá ṣì máa bá a kẹ́gbẹ́ torí pé ó ti ronú pìwà dà, ó sì ti jáwọ́ nínú ìwà burúkú tó ń hù. (1 Tím. 5:20) Ó yẹ káwọn ará fìfẹ́ hàn sí i torí pé ara ìjọ ṣì ni. (Héb. 10:24, 25) Àmọ́, ọ̀rọ̀ ẹni tí wọ́n mú kúrò nínú ìjọ yàtọ̀ sí ti ẹni tí wọ́n bá wí. A máa “jáwọ́ nínú kíkẹ́gbẹ́” pẹ̀lú ẹni tí wọ́n mú kúrò nínú ìjọ, ‘a ò tiẹ̀ ní bá irú ẹni bẹ́ẹ̀ jẹun.’—1 Kọ́r. 5:11.
14. Báwo làwọn ará ṣe lè lo ẹ̀rí ọkàn wọn tí wọ́n bá rí ẹni tí wọ́n mú kúrò nínú ìjọ? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
14 Ṣé ohun tá à ń sọ ni pé ká má pe ẹni náà wá sípàdé tàbí ká má kí i nípàdé? Rárá o. Ó dájú pé a ò ní bá ẹni náà kẹ́gbẹ́. Àmọ́ tẹ́ni náà bá jẹ́ mọ̀lẹ́bí tàbí ọ̀rẹ́ wa kí wọ́n tó mú un kúrò nínú ìjọ, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ló máa pinnu bóyá kóun pè é wá sìpàdé. Tó bá wá sípàdé, báwo ló ṣe yẹ ká ṣe sí i? Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, a ò ní kí i. Àmọ́ ní báyìí, ẹnì kọ̀ọ̀kan ló máa pinnu ohun tó máa ṣe bí ẹ̀rí ọkàn ẹ̀ bá ṣe gbà á láyè. Àwọn kan lè pinnu pé àwọn máa kí i lásán, àwọn míì sì lè pinnu pé àwọn máa ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ. Àmọ́, a ò ní bá a sọ̀rọ̀ púpọ̀ tàbí ká máa bá a ṣe wọléwọ̀de.
15. Irú àwọn wo ni 2 Jòhánù 9-11 ń sọ? (Tún wo àpótí náà, “ Ṣé Ẹ̀ṣẹ̀ Kan Náà Ni Jòhánù àti Pọ́ọ̀lù Ń Sọ̀rọ̀ Nípa Ẹ̀?”)
15 Àwọn kan lè béèrè pé, ‘Ṣebí Bíbélì sọ pé ẹni tó bá kí ẹni náà ti lọ́wọ́ nínú àwọn iṣẹ́ burúkú rẹ̀?’ (Ka 2 Jòhánù 9-11.) Ohun tí ẹsẹ Bíbélì yìí ń sọ jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn apẹ̀yìndà àtàwọn míì tó ń gbé ìwà burúkú lárugẹ ló ń bá wí. (Ìfi. 2:20) Torí náà, tẹ́nì kan bá ń kọ́ àwọn èèyàn ní ẹ̀kọ́ àwọn apẹ̀yìndà tàbí tó ń kọ́ àwọn èèyàn níwà burúkú, àwọn alàgbà ò ní lọ́ sọ́dọ̀ ẹ̀. Òótọ́ ni pé ẹni náà ṣì lè ronú pìwà dà, àmọ́ ní báyìí, a ò ní kí i, a ò sì ní pè é wá sípàdé.
MÁA FARA WÉ JÈHÓFÀ TÓ MÁA Ń FÀÁNÚ HÀN
16-17. (a) Kí ni Jèhófà fẹ́ kí àwọn tó dẹ́ṣẹ̀ ṣe? (Ìsíkíẹ́lì 18:32) (b) Báwo làwọn alàgbà ṣe ń bá Jèhófà ṣíṣẹ?
16 Kí la kọ́ nínú àpilẹ̀kọ márùn-ún tá a ti jíròrò yìí? Ohun tá a kọ́ ni pé Jèhófà ò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run! (Ka Ìsíkíẹ́lì 18:32.) Ó fẹ́ káwọn tó dẹ́ṣẹ̀ pa dà di ọ̀rẹ́ òun. (2 Kọ́r. 5:20) Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi máa ń rọ àwọn èèyàn ẹ̀ tó ya aláìgbọràn láyé àtijọ́ pé kí wọ́n ronú pìwà dà, kí wọ́n sì pa dà sọ́dọ̀ òun. Àwọn alàgbà láǹfààní láti máa bá Jèhófà ṣiṣẹ́ bí wọ́n ṣe ń ran àwọn tó dẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè ronú pìwà dà.—Róòmù 2:4; 1 Kọ́r. 3:9.
17 Ẹ wo bí ayọ̀ ṣe máa ń pọ̀ lọ́run nígbà táwọn tó dẹ́ṣẹ̀ bá ronú pìwà dà! Inú Jèhófà Baba wa ọ̀run máa ń dùn nígbà tí ìránṣẹ́ ẹ̀ kan tó sọ nù bá pa dà sínú ìjọ. Tá a bá ń ronú nípa àánú àti inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí Jèhófà fi hàn sí wa, àá túbọ̀ máa nífẹ̀ẹ́ ẹ̀.—Lúùkù 1:78.
ORIN 111 Ohun Tó Ń Fún Wa Láyọ̀
a A ò ní sọ pé a yọ ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ lẹ́gbẹ́ mọ́. Bí Pọ́ọ̀lù ṣe sọ ní 1 Kọ́ríńtì 5:13, ọ̀rọ̀ tí àá máa lò báyìí ni mú kúrò nínú ìjọ.
b Bí Bíbélì ṣe sọ, ẹ̀ṣẹ̀ tí ò ní ìdáríjì kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀ kan pàtó, àmọ́ ó jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ téèyàn mọ̀ọ́mọ̀ dá torí pé ó fẹ́ ta ko Ọlọ́run. Jèhófà àti Jésù ló lè mọ̀ bóyá ẹnì kan ti dá ẹ̀ṣẹ̀ tí ò ní ìdáríjì.—Máàkù 3:29; Héb. 10:26, 27.