ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 33
ORIN 130 Ẹ Máa Dárí Jini
Báwo Ni Jèhófà Ṣe Fẹ́ Kí Ìjọ Máa Ṣe Sáwọn Tó Dẹ́ṣẹ̀ Tó Burú Jáì?
“Tí ẹnikẹ́ni bá dẹ́ṣẹ̀, a ní olùrànlọ́wọ́.” —1 JÒH. 2:1.
OHUN TÁ A MÁA KỌ́
A máa kọ́ nípa bí wọ́n ṣe bójú tó ọ̀rọ̀ ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì nínú ìjọ Kọ́ríńtì nígbà ayé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀.
1. Kí ni Jèhófà fẹ́ kí gbogbo èèyàn ṣe?
JÈHÓFÀ fún wa ní òmìnira láti yan ohun tó wù wá. A máa ń lo òmìnira yìí ní gbogbo ìgbà tá a bá fẹ́ ṣèpinnu. Ìpinnu tó ṣe pàtàkì jù téèyàn lè ṣe ni pé kó ya ara ẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà, kó sì wà lára àwọn tó ń jọ́sìn ẹ̀. Ohun tí Jèhófà fẹ́ kí gbogbo èèyàn ṣe nìyẹn. Kí nìdí? Ìdí ni pé ó nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì fẹ́ káyé wa dáa. Ó fẹ́ ká jẹ́ ọ̀rẹ́ òun, ká sì wà láàyè títí láé.—Diu. 30:19, 20; Gál. 6:7, 8.
2. Kí ni Jèhófà fẹ́ káwọn tó dẹ́ṣẹ̀ ńlá tí wọn ò sì ronú pìwà dà ṣe? (1 Jòhánù 2:1)
2 Jèhófà kì í fipá mú ẹnikẹ́ni láti sin òun. Ó gba kálukú wa láyè láti pinnu ohun tá a máa ṣe. Àmọ́, tí Kristẹni kan tó ti ṣèrìbọmi bá rú òfin Ọlọ́run, tó sì dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì ńkọ́? Tẹ́ni náà ò bá ronú pìwà dà, a gbọ́dọ̀ mú un kúrò nínú ìjọ. (1 Kọ́r. 5:13) Síbẹ̀, Jèhófà retí pé kí ẹlẹ́ṣẹ̀ náà ronú pìwà dà kó sì pa dà sọ́dọ̀ òun. Ìdí pàtàkì tí Jèhófà fi pèsè ìràpadà nìyẹn, kí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó ronú pìwà dà lè rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà. (Ka 1 Jòhánù 2:1.) Torí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa, ó ń fìfẹ́ rọ àwọn tó dẹ́ṣẹ̀ pé kí wọ́n ronú pìwà dà.—Sek. 1:3; Róòmù 2:4; Jém. 4:8.
3. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
3 Jèhófà ti jẹ́ ká mọ bí ẹ̀ṣẹ̀ ṣe burú tó àtohun tó máa ń ṣe tá a bá dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì. Ohun kan náà ló fẹ́ káwa náà ṣe. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa bá a ṣe lè ṣe é. Bó o ṣe ń ka àpilẹ̀kọ yìí, wo (1) bí wọ́n ṣe bójú tó ọ̀rọ̀ ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì nínú ìjọ Kọ́ríńtì nígbà ayé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀, (2) ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní kí wọ́n ṣe tí ẹlẹ́ṣẹ̀ náà bá ronú pìwà dà àti (3) bí ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ìjọ Kọ́ríńtì ṣe jẹ́ ká mọ ohun tí Jèhófà máa ń ṣe tí Kristẹni kan bá dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì.
BÁWO NI ÌJỌ KỌ́RÍŃTÌ ṢE BÓJÚ TÓ Ọ̀RỌ̀ ẸNI TÓ DẸ́ṢẸ̀ TÓ BURÚ JÁÌ?
4. Kí ló ṣẹlẹ̀ nínú ìjọ Kọ́ríńtì nígbà ayé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀? (1 Kọ́ríńtì 5:1, 2)
4 Ka 1 Kọ́ríńtì 5:1, 2. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù wà lẹ́nu ìrìn àjò míṣọ́nnárì ẹlẹ́ẹ̀kẹta, ó gbọ́ ìròyìn tí ò dáa nípa ìjọ tuntun tó wà ní Kọ́ríńtì. Arákùnrin kan nínú ìjọ yẹn ń bá ìyàwó bàbá ẹ̀ ṣèṣekúṣe. Ìwà náà burú gan-an, kódà ‘kò sírú ẹ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè!’ Kì í ṣe pé ìjọ náà fàyè gba ìwà burúkú nìkan ni, wọn ò tún rí ohun tó burú nínú ẹ̀. Ó ṣeé ṣe káwọn kan nínú ìjọ náà máa rò pé àwọn ń fara wé Ọlọ́run aláàánú tó mọ àwa èèyàn aláìpé dáadáa, tó sì máa ń fàánú hàn. Àmọ́ Jèhófà ò fàyè gba ìwà burúkú kankan láàárín àwọn èèyàn ẹ̀. Torí ìwà burúkú tí ọkùnrin náà hù, àwọn tí ò sin Jèhófà á máa fojú tí ò dáa wo ìjọ Ọlọ́run, ó sì tún lè jẹ́ káwọn Kristẹni míì nínú ìjọ máa hùwà burúkú yẹn. Torí náà, kí ni Pọ́ọ̀lù ní kí ìjọ ṣe?
5. Kí ni Pọ́ọ̀lù ní kí ìjọ ṣe, kí ló sì ń sọ gan-an? (1 Kọ́ríńtì 5:13) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
5 Ka 1 Kọ́ríńtì 5:13. Ọlọ́run fẹ̀mí ẹ̀ darí Pọ́ọ̀lù láti kọ lẹ́tà síjọ yẹn pé kí wọ́n mú ẹlẹ́ṣẹ̀ tí ò ronú pìwà dà náà kúrò nínú ìjọ. Báwo làwọn ará ìjọ ṣe máa ṣe sí ẹni yẹn? Pọ́ọ̀lù sọ pé kí wọ́n “jáwọ́ nínú kíkẹ́gbẹ́” pẹ̀lú ẹ̀. Kí ni Pọ́ọ̀lù ń sọ? Àlàyé tí Pọ́ọ̀lù ṣe ni pé kò tiẹ̀ yẹ kí wọ́n “bá irú ẹni bẹ́ẹ̀ jẹun.” (1 Kọ́r. 5:11) Téèyàn bá ń bá ẹnì kan jẹun, á rọrùn fáwọn méjèèjì láti máa sọ̀rọ̀ fàlàlà. Torí náà, ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ ni pé ìjọ ò gbọ́dọ̀ máa bá ẹni náà gbafẹ́ tàbí kí wọ́n máa bá a ṣe wọléwọ̀de. Èyí ò ní jẹ́ káwọn tó kù nínú ìjọ bẹ̀rẹ̀ sí í hùwà burúkú bíi tiẹ̀. (1 Kọ́r. 5:5-7) Yàtọ̀ síyẹn, tí wọn ò bá bá ọkùnrin náà da nǹkan pọ̀ mọ́, ó máa mọ̀ pé ohun tóun ṣe burú gan-an, á kábàámọ̀, á sì ronú pìwà dà.
6. Kí ni ìjọ àtẹni tó dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì náà ṣe nígbà tí wọ́n gba lẹ́tà Pọ́ọ̀lù?
6 Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù fi lẹ́tà tó kọ ránṣẹ́ sí ìjọ Kọ́ríńtì, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa ohun tí ìjọ náà máa ṣe. Nígbà tó yá, Títù mú ìròyìn ayọ̀ nípa ìjọ náà wá fún Pọ́ọ̀lù. Àwọn ará ìjọ yẹn ṣe ohun tí lẹ́tà Pọ́ọ̀lù sọ, wọ́n mú ọkùnrin náà kúrò nínú ìjọ. (2 Kọ́r. 7:6, 7) Lẹ́yìn oṣù díẹ̀ tí Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà sí wọn, ọkùnrin náà ronú pìwà dà! Ó ti yí ìwà ẹ̀ pa dà, ó sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ̀ lé ìlànà òdodo Jèhófà. (2 Kọ́r. 7:8-11) Kí ni Pọ́ọ̀lù wá ní kí ìjọ ṣe?
BÁWO LÓ ṢE YẸ KÍ ÌJỌ ṢE SÍ ỌKÙNRIN TÓ RONÚ PÌWÀ DÀ?
7. Kí ni ọkùnrin yẹn ṣe nígbà tí wọ́n mú un kúrò nínú ìjọ? (2 Kọ́ríńtì 2:5-8)
7 Ka 2 Kọ́ríńtì 2:5-8. Pọ́ọ̀lù sọ pé “ìbáwí tó múná tí èyí tó pọ̀ jù lára yín ti fún irú ẹni bẹ́ẹ̀ ti tó.” Ohun tó ń sọ ni pé ìbáwí náà ti ṣiṣẹ́ lára ẹ̀. Lọ́nà wo? Ó ti mú kó ronú pìwà dà.—Héb. 12:11.
8. Kí ni Pọ́ọ̀lù tún sọ fún ìjọ pé kí wọ́n ṣe?
8 Pọ́ọ̀lù sọ fún ìjọ pé: “Kí ẹ dárí jì í tinútinú, kí ẹ sì tù ú nínú” àti pé “kí ẹ jẹ́ kó mọ̀ pé ẹ nífẹ̀ẹ́ òun.” Kíyè sí pé Pọ́ọ̀lù ò ní kí wọ́n gbà á pa dà sínú ìjọ nìkan, ó tún sọ pé kí wọ́n dárí jì í, kí wọ́n sì tù ú nínú. Pọ́ọ̀lù fẹ́ kí wọ́n fi hàn nínú ìwà àti ọ̀rọ̀ wọn pé àwọn ti dárí jì í, àwọn sì nífẹ̀ẹ́ ẹ̀ lóòótọ́. Tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, á mú kó dá arákùnrin náà lójú pé inú ìjọ dùn láti gba òun pa dà.
9. Kí nìdí tó fi ṣòro fáwọn kan nínú ìjọ yẹn láti dárí ji ọkùnrin tó ronú pìwà dà náà?
9 Ṣé ó ṣòro fáwọn kan nínú ìjọ yẹn láti fìdùnnú gba ọkùnrin tó ronú pìwà dà náà pa dà sínú ìjọ? Bíbélì ò sọ, àmọ́ ó ṣeé ṣe kó rí bẹ́ẹ̀. Ìdí ni pé ìwà tó hù yẹn dá wàhálà sílẹ̀ nínú ìjọ, ó sì ti kó ìtìjú bá àwọn kan. Àwọn ará ìjọ yẹn ti ṣiṣẹ́ kára láti jẹ́ oníwà mímọ́, torí náà, àwọn kan lè rò pé kò dáa kí wọ́n gba ẹni tó dá irú ẹ̀ṣẹ̀ burúkú yẹn pa dà sínú ìjọ. (Fi wé Lúùkù 15:28-30.) Síbẹ̀, kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì káwọn ará ìjọ fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ arákùnrin náà dénúdénú?
10-11. Kí ló lè ṣẹlẹ̀ táwọn alàgbà ò bá dárí ji ẹlẹ́ṣẹ̀ tó ronú pìwà dà?
10 Kí ló lè ṣẹlẹ̀ táwọn alàgbà ò bá jẹ́ kí ẹni tó ronú pìwà dà tọkàntọkàn pa dà sínú ìjọ tàbí báwo lẹ ṣe rò pé ó máa rí lára ẹni náà lẹ́yìn tó bá pa dà, táwọn ará ìjọ ò sì fìfẹ́ hàn sí i? Ó ṣeé ṣe kí “ìbànújẹ́ tó pọ̀ lápọ̀jù” dorí ẹ̀ kodò. Ó lè rò pé òun ò lè pa dà wá sínú ìjọ mọ́. Ó tiẹ̀ lè rò pé Jèhófà ò lè dárí ji òun, kó má sì sapá láti yí pa dà mọ́.
11 Èyí tó burú jù ni pé táwọn ará ìjọ ò bá dárí ji ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ tó sì ti ronú pìwà dà, àwọn náà lè má jẹ́ ọ̀rẹ́ Jèhófà mọ́. Kí nìdí? Ìdí ni pé wọn ò fara wé Jèhófà tó máa ń dárí ji àwọn tó dẹ́ṣẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, Sátánì tó burú, tí kì í ṣàánú ẹnikẹ́ni ni wọ́n ń fara wé. Ká sòótọ́, wọ́n lè jẹ́ kí Èṣù lò wọ́n láti mú kí ọkùnrin náà má sin Jèhófà mọ́.—2 Kọ́r. 2:10, 11; Éfé. 4:27.
12. Báwo ni ìjọ ṣe lè fara wé Jèhófà?
12 Báwo ni ìjọ tó wà ní Kọ́ríńtì ṣe lè fara wé Jèhófà, tí wọn ò sì ní fara wé Sátánì? Bíi ti Jèhófà, ó yẹ káwọn náà dárí ji àwọn tó dẹ́ṣẹ̀, tí wọ́n sì ti ronú pìwà dà. Kíyè sí ohun tí àwọn tó kọ Bíbélì sọ nípa Jèhófà. Dáfídì sọ pé “ẹni rere” ni Jèhófà, ó sì “ṣe tán láti dárí jini.” (Sm. 86:5) Míkà sọ pé: “Ta ló dà bí rẹ, Ọlọ́run, tó ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ jini, tó sì ń gbójú fo ìṣìnà?” (Míkà 7:18) Àìsáyà náà sọ pé: “Kí èèyàn burúkú fi ọ̀nà rẹ̀ sílẹ̀, kí ẹni ibi sì yí èrò rẹ̀ pa dà; kó pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà, ẹni tó máa ṣàánú rẹ̀, sọ́dọ̀ Ọlọ́run wa, torí ó máa dárí jini fàlàlà.”—Àìsá. 55:7.
13. Kí nìdí tó fi yẹ kí wọ́n gba ọkùnrin tó ronú pìwà dà yẹn pa dà sínú ìjọ? (Wo àpótí náà, “ Ìgbà Wo Ni Wọ́n Gba Ọkùnrin inú Ìjọ Kọ́ríńtì Yẹn Pa Dà?”)
13 Tí ìjọ tó wà ní Kọ́ríńtì bá fẹ́ fara wé Jèhófà, wọ́n gbọ́dọ̀ gba ọkùnrin tí wọ́n mú kúrò nínú ìjọ pa dà, kí wọ́n sì jẹ́ kó mọ̀ pé àwọn nífẹ̀ẹ́ ẹ̀. Tí ìjọ Kọ́ríńtì bá ṣe ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ, pé kí wọ́n gba ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ tó ti ronú pìwà dà náà pa dà, wọ́n máa fi hàn pé àwọn “jẹ́ onígbọràn nínú ohun gbogbo.” (2 Kọ́r. 2:9) Òótọ́ ni pé ẹ̀yìn oṣù díẹ̀ tí wọ́n mú un kúrò nínú ìjọ ló ronú pìwà dà, àmọ́ ìbáwí tí wọ́n fún un ti jẹ́ kó ronú pìwà dà tọkàntọkàn. Torí náà, kò sídìí tó fi yẹ kí wọ́n fi nǹkan falẹ̀ kí wọ́n tó gbà á pa dà.
BÁ A ṢE LÈ FARA WÉ JÈHÓFÀ BÓ ṢE Ń FI ÌDÁJỌ́ ÒDODO ÀTI ÀÁNÚ HÀN
14-15. Kí la kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ìjọ Kọ́ríńtì? (2 Pétérù 3:9) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
14 Jèhófà jẹ́ kí wọ́n kọ bí wọ́n ṣe bójú tó ohun tó ṣẹlẹ̀ níjọ Kọ́ríńtì sínú Bíbélì ká lè “gba ẹ̀kọ́.” (Róòmù 15:4) Ohun tá a kọ́ ni pé Jèhófà kì í fàyè gba ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì láàárín àwa èèyàn ẹ̀. Kò fàyè gba àwọn tí ò ronú pìwà dà pé kí wọ́n wà nínú ìjọ. Lóòótọ́, aláàánú ni Jèhófà, àmọ́ kì í gbàgbàkugbà, kì í sì í pa ìlànà ẹ̀ tì. (Júùdù 4) Tí Jèhófà bá fàyè gba àwọn tí ò ronú pìwà dà kí wọ́n wà nínú ìjọ, ìyẹn ò ní fi hàn pé ó jẹ́ aláàánú torí ó máa pa àwọn ará ìjọ lára.—Òwe 13:20; 1 Kọ́r. 15:33.
15 Ohun míì tá a kọ́ ni pé Jèhófà ò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run. Ó fẹ́ kí gbogbo èèyàn rígbàlà. Ó máa ń fàánú hàn sáwọn tó bá yí ìwà wọn pa dà, tí wọ́n sì fẹ́ pa dà di ọ̀rẹ́ ẹ̀. (Ìsík. 33:11; ka 2 Pétérù 3:9.) Torí náà, nígbà tí ọkùnrin tó wà ní Kọ́ríńtì yẹn ronú pìwà dà tí ò sì hùwà burúkú náà mọ́, Jèhófà ní kí Pọ́ọ̀lù sọ fún ìjọ pé kí wọ́n dárí jì í, kí wọ́n sì gbà á pa dà.
16. Kí lo rí kọ́ lára Jèhófà nípa bí wọ́n ṣe bójú tó ohun tó ṣẹlẹ̀ ní Kọ́ríńtì?
16 Ohun tá a kọ́ nínú bí wọ́n ṣe bójú tó ohun tó ṣẹlẹ̀ ní Kọ́ríńtì jẹ́ ká rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, olódodo àti onídàájọ́ òdodo sì ni. (Sm. 33:5) Ẹ ò rí i pé ohun tá a mọ̀ yìí yẹ kó túbọ̀ mú ká máa yin Jèhófà. Inú wa sì dùn gan-an pé ó ṣàánú wa torí ẹlẹ́ṣẹ̀ ni gbogbo wa, a sì fẹ́ kó dárí jì wá. Ó yẹ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà torí ó pèsè ìràpadà fún wa ká lè rí ìdáríjì gbà. Ẹ ò rí i pé ara tù wá gan-an nígbà tá a mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa dénú, ó sì fẹ́ ká máa láyọ̀ títí láé!
17. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e?
17 Báwo ni wọ́n ṣe máa bójú tó ọ̀rọ̀ ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ nínú ìjọ lónìí? Báwo ni àwọn alàgbà ṣe lè fìfẹ́ hàn bíi Jèhófà, kí wọ́n sì ran ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́ kó lè ronú pìwà dà? Kí ló yẹ kí ìjọ ṣe tí wọ́n bá mú ẹnì kan kúrò nínú ìjọ tàbí tí wọ́n bá gbà á pa dà? A máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e.
ORIN 109 Ní Ìfẹ́ Tó Ti Ọkàn Wá