ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 32
ORIN 44 Àdúrà Ẹni Tó Ní Ẹ̀dùn Ọkàn
Jèhófà Fẹ́ Kí Gbogbo Èèyàn Ronú Pìwà Dà
“Jèhófà . . . kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run ṣùgbọ́n ó fẹ́ kí gbogbo èèyàn ronú pìwà dà.”—2 PÉT. 3:9.
OHUN TÁ A MÁA KỌ́
A máa mọ ohun tí ìrònúpìwàdà jẹ́, ìdí tí ìrònúpìwàdà fi ṣe pàtàkì àti bí Jèhófà ṣe ń ran àwọn tó dẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè ronú pìwà dà.
1. Kí ni ẹni tó ronú pìwà dà máa ń ṣe?
TÁ A bá ṣohun tí ò dáa, ó yẹ ká ronú pìwà dà. Bíbélì sọ pé tẹ́nì kan bá ronú pìwà dà, ó máa kábàámọ̀ ohun tó ṣe, á sì pinnu pé òun ò ní hùwà yẹn mọ́.—Wo “Ìrònúpìwàdà” nínú Àlàyé Ọ̀rọ̀ inú Bíbélì.
2. Kí nìdí tó fi yẹ ká mọ ohun tí ìrònúpìwàdà jẹ́? (Nehemáyà 8:9-11)
2 Gbogbo èèyàn ló yẹ kó mọ ohun tí ìrònúpìwàdà jẹ́. Kí nìdí? Ìdí ni pé ojoojúmọ́ là ń dẹ́ṣẹ̀, a sì ti jogún ẹ̀ṣẹ̀ torí pé a jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ádámù àti Éfà. (Róòmù 3:23; 5:12) Bẹ́ẹ̀ ni o, gbogbo wa ni ẹlẹ́ṣẹ̀. Kódà àwọn ẹni ìgbàgbọ́ bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà láwọn kùdìẹ̀-kudiẹ tí wọ́n bá yí. (Róòmù 7:21-24) Ṣéyẹn wá túmọ̀ sí pé gbogbo ìgbà la gbọ́dọ̀ máa banú jẹ́ torí a jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀? Rárá o, aláàánú ni Jèhófà, ó sì fẹ́ ká láyọ̀. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn Júù nígbà ayé Nehemáyà. (Ka Nehemáyà 8:9-11.) Jèhófà ò fẹ́ kí ẹ̀dùn ọkàn bò wọ́n mọ́lẹ̀ torí ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá sẹ́yìn, àmọ́ ó fẹ́ kí wọ́n máa láyọ̀ bí wọ́n ṣe ń sin òun. Jèhófà mọ̀ pé tá a bá ronú pìwà dà, a máa láyọ̀. Ìdí nìyẹn tó fi ń kọ́ wa pé ká ronú pìwà dà. Tá a bá ronú pìwà dà ẹ̀ṣẹ̀ wa, ó dájú pé Bàbá wa aláàánú máa dárí jì wá.
3. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
3 Ó máa dáa ká túbọ̀ mọ ohun tí ìrònúpìwàdà jẹ́. Torí náà nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò ohun pàtàkì mẹ́ta. Àkọ́kọ́, a máa sọ̀rọ̀ nípa bí Jèhófà ṣe jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ ohun tí ìrònúpìwàdà jẹ́. Ìkejì, a máa sọ̀rọ̀ nípa bí Jèhófà ṣe ran àwọn tó dẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè ronú pìwà dà. Ìkẹta, a máa jíròrò ohun tí Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé ìrònúpìwàdà jẹ́.
JÈHÓFÀ KỌ́ ÀWỌN ỌMỌ ÍSÍRẸ́LÌ NÍ OHUN TÍ ÌRÒNÚPÌWÀDÀ JẸ́
4. Kí ni Jèhófà kọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípa ìrònúpìwàdà?
4 Nígbà tí Jèhófà sọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì di orílẹ̀-èdè ẹ̀, ó bá wọn dá májẹ̀mú, wọ́n sì ṣèlérí pé àwọn máa pa májẹ̀mú náà mọ́. Tí wọ́n bá pa òfin ẹ̀ mọ́, á dáàbò bò wọ́n, á sì bù kún wọn. Nígbà tó ń sọ nípa òfin náà fún wọn, ó fi dá wọn lójú pé: “Àṣẹ tí mò ń pa fún ọ lónìí yìí kò nira jù fún ọ, kì í sì í ṣe ohun tí kò sí lárọ̀ọ́wọ́tó rẹ.” (Diu. 30:11, 16) Àmọ́ tí wọ́n bá ṣàìgbọràn, bí àpẹẹrẹ tí wọ́n bá sin ọlọ́run míì, Jèhófà ò ní dáàbò bò wọ́n mọ́, ìyà á sì jẹ wọ́n. Síbẹ̀, wọ́n ṣì lè rójúure Jèhófà. Wọ́n lè ‘pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run wọn, kí wọ́n sì fetí sí ohùn rẹ̀.’ (Diu. 30:1-3, 17-20) Ìyẹn ni pé, wọ́n lè ronú pìwà dà. Tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà máa sún mọ́ wọn, á sì pa dà bù kún wọn.
5. Báwo ni Jèhófà ò ṣe jẹ́ kọ́rọ̀ àwọn èèyàn ẹ̀ sú òun? (2 Àwọn Ọba 17:13, 14)
5 Léraléra làwọn èèyàn Jèhófà ṣọ̀tẹ̀. Yàtọ̀ sí pé wọ́n ń bọ̀rìṣà, wọ́n tún ń ṣe àwọn nǹkan míì tó burú gan-an. Torí náà, wọ́n jẹ palaba ìyà. Àmọ́, Jèhófà ò jẹ́ kọ́rọ̀ àwọn aláìgbọràn yìí sú òun. Léraléra ló rán àwọn wòlíì ẹ̀ sí wọn, tó ń rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n ronú pìwà dà, kí wọ́n sì pa dà sọ́dọ̀ òun.—Ka 2 Àwọn Ọba 17:13, 14.
6. Kí ni Jèhófà ní káwọn wòlíì ẹ̀ sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípa ìdí tó fi yẹ kí wọ́n ronú pìwà dà? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
6 Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jèhófà ní káwọn wòlíì ẹ̀ kìlọ̀ fáwọn èèyàn ẹ̀, kí wọ́n sì tọ́ wọn sọ́nà. Bí àpẹẹrẹ, Ọlọ́run ní kí Jeremáyà sọ fún wọn pé: “Pa dà, ìwọ Ísírẹ́lì ọ̀dàlẹ̀ . . . Mi ò ní wò ọ́ tìbínútìbínú, nítorí adúróṣinṣin ni mí . . . Mi ò sì ní máa bínú títí láé. Kìkì pé kí o mọ ẹ̀bi rẹ lẹ́bi, nítorí o ti ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà.” (Jer. 3:12, 13) Jèhófà ní kí Jóẹ́lì sọ fún wọn pé: “Ẹ fi gbogbo ọkàn yín pa dà sọ́dọ̀ mi.” (Jóẹ́lì 2:12, 13) Ó tún ní kí Àìsáyà sọ fún wọn pé: “Ẹ jẹ́ kí ara yín mọ́; ẹ mú ìwà ibi yín kúrò níwájú mi; ẹ jáwọ́ nínú ìwà burúkú.” (Àìsá. 1:16-19) Bákan náà, Jèhófà ní kí Ìsíkíẹ́lì sọ fún wọn pé: “Ǹjẹ́ inú mi máa ń dùn sí ikú ẹni burúkú? . . . Ṣebí ohun tí mo fẹ́ ni pé kó yí ìwà rẹ̀ pa dà kó sì máa wà láàyè? Inú mi ò dùn sí ikú ẹnikẹ́ni, . . . torí náà, ẹ yí pa dà, kí ẹ sì máa wà láàyè.” (Ìsík. 18:23, 32) Ẹ ò rí i pé inú Jèhófà máa ń dùn táwọn èèyàn bá ronú pìwà dà torí ó fẹ́ kí wọ́n wà láàyè títí láé! Àmọ́, Jèhófà kì í dúró dìgbà tí àwọn tó dẹ́ṣẹ̀ máa yí pa dà kó tó ràn wọ́n lọ́wọ́. Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àwọn àpẹẹrẹ míì.
7. Báwo ni Jèhófà ṣe fi ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Hósíà àti ìyàwó ẹ̀ kọ́ àwọn èèyàn ẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́?
7 Ẹ jẹ́ ká wo bí Jèhófà ṣe fi ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Gómérì ìyàwó Hósíà kọ́ àwọn èèyàn ẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́. Lẹ́yìn tó ṣàgbèrè, ó fi Hósíà ọkọ ẹ̀ sílẹ̀, ó sì bá ọkùnrin míì lọ. Ṣé ọ̀rọ̀ ẹ̀ ti kọjá àtúnṣe? Jèhófà tó mọ ohun tó wà lọ́kàn èèyàn sọ fún Hósíà pé: “Lọ lẹ́ẹ̀kan sí i, nífẹ̀ẹ́ ìyàwó rẹ tí ọkùnrin míì ti fẹ́, tó sì ń ṣe àgbèrè, bí Jèhófà ṣe nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn Ísírẹ́lì bí wọ́n tilẹ̀ lọ sọ́dọ̀ àwọn ọlọ́run míì.” (Hós. 3:1; Òwe 16:2) Ẹ kíyè sí pé ìyàwó Hósíà ò tíì jáwọ́ nínú ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì yẹn nígbà tí Jèhófà sọ fún Hósíà pé kó wá a lọ, kó dárí jì í, kó sì gbà á pa dà. a Lọ́nà kan náà, Jèhófà kì í jẹ́ kọ́rọ̀ àwọn èèyàn ẹ̀ aláìgbọràn sú òun. Kódà nígbà tí wọn ò tíì jáwọ́ nínú ẹ̀ṣẹ̀ burúkú wọn, Jèhófà ṣì nífẹ̀ẹ́ wọn, ó sì ń rán àwọn wòlíì ẹ̀ sí wọn kí wọ́n lè ronú pìwà dà, kí wọ́n sì yí ìwà wọn pa dà. Ṣé àpẹẹrẹ yìí fi hàn pé tẹ́nì kan bá ṣì ń dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì, ‘Jèhófà tó ń yẹ ọkàn wò’ lè ran ẹni náà lọ́wọ́, kó sì ronú pìwà dà? (Òwe 17:3) Ẹ jẹ́ ká wo bí Jèhófà ṣe ń ṣe é.
BÍ JÈHÓFÀ ṢE Ń RAN ÀWỌN TÓ DẸ́ṢẸ̀ LỌ́WỌ́ KÍ WỌ́N LÈ RONÚ PÌWÀ DÀ
8. Báwo ni Jèhófà ṣe ran Kéènì lọ́wọ́ kó lè ronú pìwà dà? (Jẹ́nẹ́sísì 4:3-7) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
8 Kéènì ni àkọ́bí Ádámù àti Éfà. Ó jogún ẹ̀ṣẹ̀ látọ̀dọ̀ àwọn òbí ẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, Bíbélì sọ nípa Kéènì pé: “Àwọn iṣẹ́ rẹ̀ burú.” (1 Jòh. 3:12) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìdí nìyẹn tí Jèhófà ò fi “ṣojúure sí Kéènì rárá, [tí] kò sì gba ọrẹ rẹ̀.” Dípò kí Kéènì yí ìwà ẹ̀ pa dà, ńṣe ló “bínú gan-an, inú rẹ̀ ò sì dùn.” Kí ni Jèhófà ṣe? Ó bá Kéènì sọ̀rọ̀. (Ka Jẹ́nẹ́sísì 4:3-7.) Ẹ kíyè sí i pé Jèhófà fìfẹ́ rọ Kéènì pé tó bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe rere, nǹkan ṣì máa dáa fún un. Ó sì kìlọ̀ fún un pé kó sá fún ẹ̀ṣẹ̀. Àmọ́, ó ṣeni láàánú pé Kéènì ya aláìgbọràn. Kò jẹ́ kí Jèhófà ran òun lọ́wọ́ láti ronú pìwà dà. Lẹ́yìn tí Kéènì yarí kanlẹ̀, ṣé Jèhófà wá sọ pé òun ò ní ran àwọn míì lọ́wọ́ mọ́ kí wọ́n lè ronú pìwà dà? Rárá o!
9. Báwo ni Jèhófà ṣe ran Dáfídì lọ́wọ́ kó lè ronú pìwà dà?
9 Jèhófà nífẹ̀ẹ́ Ọba Dáfídì gan-an. Ó tiẹ̀ pè é ní “ẹni tí ọkàn mi fẹ́.” (Ìṣe 13:22) Àmọ́ Dáfídì dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì, ó ṣàgbèrè, ó sì pààyàn. Bí Òfin Mósè ṣe sọ, ó yẹ kí wọ́n pa Dáfídì ni. (Léf. 20:10; Nọ́ń. 35:31) Síbẹ̀, Jèhófà fìfẹ́ dá sọ́rọ̀ náà. b Ó rán wòlíì Nátánì pé kó lọ bá Dáfídì, bẹ́ẹ̀ sì rèé Dáfídì ò tíì ṣe ohun tó fi hàn pé òun ronú pìwà dà. Nátánì lo àpèjúwe tó jẹ́ kí Dáfídì mọ̀ pé òun ti dẹ́ṣẹ̀ ńlá. Dáfídì wá mọ̀ pé òun ti ṣẹ Jèhófà gan-an, ó sì ronú pìwà dà. (2 Sám. 12:1-14) Ó kọ sáàmù kan tó fi hàn pé òun ti ronú pìwà dà tọkàntọkàn. (Sm. 51, àkọlé) Sáàmù yẹn ti ran ọ̀pọ̀ èèyàn tó dẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́, ó sì ti mú kí wọ́n ronú pìwà dà. Ṣé inú wa ò dùn pé Jèhófà fìfẹ́ ran Dáfídì ìránṣẹ́ ẹ̀ lọ́wọ́ kó lè ronú pìwà dà?
10. Báwo ló ṣe rí lára ẹ nígbà tó o rí i pé Jèhófà mú sùúrù fáwọn tó dẹ́ṣẹ̀, tó sì dárí jì wọ́n?
10 Jèhófà kórìíra ẹ̀ṣẹ̀, kò sì fàyè gbà á. (Sm. 5:4, 5) Síbẹ̀ torí ó mọ̀ pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni gbogbo wa, ó ṣe tán láti ràn wá lọ́wọ́ ká lè bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ torí ó nífẹ̀ẹ́ wa. Kódà, ó máa ń ran àwọn tó dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì lọ́wọ́ kí wọ́n lè ronú pìwà dà, kí wọ́n sì pa dà di ọ̀rẹ́ ẹ̀. Ẹ ò rí i pé ìyẹn mára tù wá gan-an! Tá a bá ń ronú lórí bí Jèhófà ṣe mú sùúrù fáwọn tó dẹ́ṣẹ̀ tó sì dárí jì wọ́n, a máa jẹ́ olóòótọ́, àá sì tètè ronú pìwà dà tá a bá dẹ́ṣẹ̀. Torí náà, ẹ jẹ́ ká jíròrò ohun tí Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé ìrònúpìwàdà jẹ́.
JÉSÙ KỌ́ ÀWỌN ỌMỌLẸ́YÌN Ẹ̀ NÍ OHUN TÍ ÌRÒNÚPÌWÀDÀ JẸ́
11-12. Kí ni Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ nípa bí Jèhófà ṣe ń dárí jini? (Wo àwòrán.)
11 Nígbà tó tó àsìkò, Mèsáyà dé. Bá a ṣe sọ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, Jèhófà jẹ́ kí Jòhánù Arinibọmi àti Jésù Kristi wàásù fáwọn èèyàn, wọ́n sì rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n ronú pìwà dà. Nígbà tí Jésù náà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ẹ̀, ó kọ́ àwọn èèyàn pé ó ṣe pàtàkì kí wọ́n ronú pìwà dà.—Mát. 3:1, 2; 4:17.
12 Nígbà tí Jésù wà láyé, ó jẹ́ káwọn èèyàn mọ bó ṣe máa ń wu Jèhófà tó láti dárí jini. Ọ̀nà tó dáa tí Jésù gbà ṣe é ni pé ó sọ àpèjúwe ọmọkùnrin kan tó sọ nù. Ọ̀dọ́kùnrin náà kúrò nílé, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ìgbésí ayé burúkú. Àmọ́ nígbà tí “orí rẹ̀ wálé,” ó pinnu láti pa dà sílé. Kí ni bàbá ẹ̀ ṣe? Jésù sọ pé nígbà tí ọmọ náà “ń bọ̀ ní òkèèrè ni bàbá rẹ̀ tajú kán rí i, àánú rẹ̀ ṣe é, ó wá sáré lọ dì mọ́ ọn, ó sì rọra fi ẹnu kò ó lẹ́nu.” Ohun tó wà lọ́kàn ọmọ náà ni pé kí bàbá ẹ̀ sọ ọ́ di ìránṣẹ́. Àmọ́ bàbá ẹ̀ pè é ní “ọmọ mi,” ó sì gbà á pa dà sílé. Kódà, ó sọ pé: “Ó sọ nù, a sì rí i.” (Lúùkù 15:11-32) Nígbà tí Jésù wà lọ́run, ọ̀pọ̀ ìgbà ló rí bí Bàbá ẹ̀ ṣe fàánú hàn sáwọn tó dẹ́ṣẹ̀, tí wọ́n sì ronú pìwà dà. Ẹ ò rí i pé àpèjúwe tí Jésù lò yìí múnú wa dùn, ó sì jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú pé aláàánú ni Jèhófà Baba wa ọ̀run!
13-14. Kí ni Pétérù kọ́ nípa ìrònúpìwàdà, kí ló sì fi kọ́ àwọn èèyàn? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
13 Àpọ́sítélì Pétérù kọ́ ẹ̀kọ́ pàtàkì lọ́dọ̀ Jésù nípa bí Jèhófà ṣe máa ń dárí ji àwọn tó dẹ́ṣẹ̀ tí wọ́n sì ronú pìwà dà. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Pétérù ṣàṣìṣe, àmọ́ Jésù dárí jì í. Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tí Pétérù sọ pé òun ò mọ Jésù lẹ́ẹ̀mẹ́ta, inú ẹ̀ bà jẹ́ gan-an. (Mát. 26:34, 35, 69-75) Àmọ́ lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ó fara han Pétérù nígbà tí ò sẹ́nì kankan lọ́dọ̀ ẹ̀. (Lúùkù 24:33, 34; 1 Kọ́r. 15:3-5) Ó dájú pé Jésù mọ̀ pé Pétérù ti ronú pìwà dà, ó sì fẹ́ kó mọ̀ pé òun ti dárí jì í.—Wo àlàyé ọ̀rọ̀ “and Peter” tó wà ní Máàkù 16:7 nínú nwtsty-E.
14 Pétérù mọ bó ṣe máa ń rí téèyàn bá ronú pìwà dà tó sì rí ìdáríjì gbà, torí náà, ó lè kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ ohun tí ìrònúpìwàdà jẹ́. Kò pẹ́ lẹ́yìn tí wọ́n ṣe àjọyọ̀ Pẹ́ńtíkọ́sì, Pétérù bá àwọn Júù aláìgbàgbọ́ sọ̀rọ̀. Ó ṣàlàyé fún wọn pé àwọn ni wọ́n pa Mèsáyà. Àmọ́, ó fìfẹ́ rọ̀ wọ́n pé: “Nítorí náà, ẹ ronú pìwà dà, kí ẹ sì yí pa dà, kí Ọlọ́run lè pa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín rẹ́, kí àwọn àsìkò ìtura lè wá látọ̀dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀.” (Ìṣe 3:14, 15, 17, 19) Pétérù jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ìrònúpìwàdà máa ń mú kí ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ yí ìwà ẹ̀ pa dà, kó sì máa ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́. Ó tún jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé Jèhófà máa pa ẹ̀ṣẹ̀ wọn rẹ́. Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, Pétérù sọ fáwọn Kristẹni pé: “Jèhófà . . . ń mú sùúrù fún yín torí kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run ṣùgbọ́n ó fẹ́ kí gbogbo èèyàn ronú pìwà dà.” (2 Pét. 3:9) Ẹ wo bó ṣe tù wá lára tó pé tá a bá dẹ́ṣẹ̀, Jèhófà máa dárí jì wá, ì báà jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì pàápàá!
15-16. (a) Kí ló jẹ́ kí Jèhófà dárí ji Pọ́ọ̀lù? (1 Tímótì 1:12-15) (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e?
15 Àwọn èèyàn tó dá irú ẹ̀ṣẹ̀ tí Sọ́ọ̀lù ará Tásù dá kò tó nǹkan, àmọ́ ó ronú pìwà dà tọkàntọkàn, ó sì rí ìdáríjì gbà. Ó ṣenúnibíni tó le gan-an sáwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi. Ó ṣeé ṣe kí ọ̀pọ̀ Kristẹni máa wo Sọ́ọ̀lù bí ẹni tí ọ̀rọ̀ ẹ̀ ò látùnṣe, tí ò sì lè ronú pìwà dà. Àmọ́, Jésù mọ̀ pé ó lè yí ìwà ẹ̀ pa dà, kó sì ronú pìwà dà. Òun àti Bàbá ẹ̀ rí ohun tó dáa lára Sọ́ọ̀lù. Jésù sọ pé: “Ohun èlò tí a ti yàn ni ọkùnrin yìí jẹ́ fún mi.” (Ìṣe 9:15) Kódà Jésù ṣe iṣẹ́ ìyanu tó jẹ́ kí Sọ́ọ̀lù lè ronú pìwà dà. (Ìṣe 7:58–8:3; 9:1-9, 17-20) Lẹ́yìn tí Sọ́ọ̀lù di Kristẹni, a wá mọ̀ ọ́n sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń sọ bóun ṣe mọyì inúure àtàánú tí Jèhófà àti Jésù fi hàn sóun. (Ka 1 Tímótì 1:12-15.) Torí Pọ́ọ̀lù mọyì ohun tí Jèhófà ṣe fún un, ó sọ pé: “Ọlọ́run, nínú inú rere rẹ̀, fẹ́ darí rẹ sí ìrònúpìwàdà.”—Róòmù 2:4.
16 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù gbọ́ nípa ìṣekúṣe nínú ìjọ Kọ́ríńtì, báwo ló ṣe bójú tó o? Ohun tó ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà máa ń fìfẹ́ bá àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ wí, ó sì máa ń fàánú hàn sí wọn tí wọ́n bá ronú pìwà dà. A tún máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa bá a ṣe lè máa fàánú hàn bíi ti Jèhófà. A máa jíròrò ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ìjọ Kọ́ríńtì nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e.
ORIN 33 Ju Ẹrù Rẹ Sọ́dọ̀ Jèhófà
a Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣàrà ọ̀tọ̀. Lónìí, Jèhófà ò sọ pé kí ẹni tí ọkọ ẹ̀ tàbí ẹni tí aya ẹ̀ ṣàgbèrè máa fẹ́ ẹ nìṣó. Ẹ̀mí Ọlọ́run darí Jésù láti jẹ́ ká mọ̀ pé ẹni tí ọkọ ẹ̀ tàbí ẹni tí aya ẹ̀ ṣàgbèrè lè kọ̀ ọ́ sílẹ̀ tó bá fẹ́ bẹ́ẹ̀.—Mát. 5:32; 19:9.
b Wo àpilẹ̀kọ náà, “Kí Lo Gbọ́dọ̀ Ṣe Tó O Bá Fẹ́ Kí Jèhófà Dárí Jì Ẹ́?” nínú Ilé Ìṣọ́ November 15, 2012, ojú ìwé 21-23, ìpínrọ̀ 3-10.