Ohun Tá A Fẹ́ Kẹ́yin Òǹkàwé Wa Mọ̀
Ẹ̀yin Òǹkàwé Wa Ọ̀wọ́n
Nínú Ilé Ìṣọ́ yìí, a máa jíròrò àpilẹ̀kọ márùn-ún tó máa dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e yìí:
Àkọ́kọ́, ètò wo ni Jèhófà ṣe kí àwa ọmọ ẹ̀ lè máa sá fún ẹ̀ṣẹ̀, ká sì máa ṣohun tó fẹ́?
Ìkejì, kí lẹni tó dẹ́ṣẹ̀ máa ṣe kó lè ronú pìwà dà tọkàntọkàn, báwo sì ni Jèhófà ṣe máa ràn án lọ́wọ́?
Ìkẹta, báwo ni Jèhófà ṣe ní kí ìjọ tó wà ní Kọ́ríńtì bójú tó ọ̀rọ̀ ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ tí ò ronú pìwà dà?
Ìkẹrin, báwo làwọn alàgbà ṣe máa ran àwọn tó dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì lọ́wọ́ lásìkò wa yìí?
Ìkarùn-ún, lẹ́yìn tí wọ́n bá mú ẹni tí ò ronú pìwà dà kúrò nínú ìjọ, báwo làwọn ará ṣe lè máa fìfẹ́ àti àánú hàn sí ẹni náà?