Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 31

ORIN 12 Jèhófà, Ọlọ́run Atóbilọ́lá

Ohun Tí Jèhófà Ṣe Ká Lè Bọ́ Lọ́wọ́ Ẹ̀ṣẹ̀ àti Ikú

Ohun Tí Jèhófà Ṣe Ká Lè Bọ́ Lọ́wọ́ Ẹ̀ṣẹ̀ àti Ikú

“Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé gan-an débi pé ó fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni.”JÒH. 3:16.

OHUN TÁ A MÁA KỌ́

A máa rí ohun tí Jèhófà ṣe láti ràn wá lọ́wọ́ ká lè bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀. A tún máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tó ṣe fún wa ká lè wà láàyè títí láé, ká má sì dẹ́ṣẹ̀ mọ́.

1-2. (a) Kí ni ẹ̀ṣẹ̀, báwo la sì ṣe lè bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀? (Tún wo “Àlàyé Ọ̀rọ̀.”) (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí àtàwọn àpilẹ̀kọ míì nínú Ilé Ìṣọ́ yìí? (Tún wo “Ohun Tá A Fẹ́ Kẹ́yin Òǹkàwé Wa Mọ̀” nínú Ilé Ìṣọ́ yìí.)

 ṢÉ O mọ bí Jèhófà ṣe nífẹ̀ẹ́ ẹ tó? Kó o lè rí ìdáhùn ìbéèrè yìí, á dáa kó o kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tí Jèhófà ṣe kó o lè bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Ọ̀tá wa ni ẹ̀ṣẹ̀, a ó sì burú débi pé a ò lè dá borí ẹ̀. Ojoojúmọ́ la máa ń dẹ́ṣẹ̀, a sì ń kú torí pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni wá. (Róòmù 5:12) Àmọ́ ìròyìn ayọ̀ kan wà. Ìròyìn ayọ̀ náà ni pé lọ́jọ́ iwájú, Jèhófà máa mú ká bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ pátápátá. Ó dá wa lójú pé ohun tí Jèhófà máa ṣe nìyẹn!

2 Ó ti tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́fà (6,000) ọdún tí Jèhófà ti ń ran àwa èèyàn lọ́wọ́ ká lè bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Kí nìdí tó fi ń ṣe bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé ó nífẹ̀ẹ́ wa gan-an. Látìgbà tí Jèhófà ti dá àwa èèyàn ló ti nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì ti ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan tó ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀. Ọlọ́run mọ̀ pé ẹ̀ṣẹ̀ ló ń fa ikú, torí náà kò fẹ́ ká kú. Ó fẹ́ ká wà láàyè títí láé. (Róòmù 6:23) Ohun tí Ọlọ́run fẹ́ fún ẹ nìyẹn. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò ìbéèrè mẹ́ta: (1) Báwo ni Jèhófà ṣe jẹ́ káwa èèyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ nírètí pé a máa bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú? (2) Kí làwọn èèyàn aláìpé ṣe nígbà àtijọ́ kí wọ́n lè múnú Jèhófà dùn? (3) Kí ni Jésù ṣe kó lè gba aráyé sílẹ̀ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú?

BÁWO NI JÈHÓFÀ ṢE JẸ́ KÁWA ÈÈYÀN ẸLẸ́ṢẸ̀ NÍRÈTÍ?

3. Báwo ni Ádámù àti Éfà ṣe di ẹlẹ́ṣẹ̀?

3 Nígbà tí Jèhófà dá Ádámù àti Éfà, ó fẹ́ kí wọ́n máa láyọ̀. Ó fún wọn nílé tó rẹwà, ó ní kí wọ́n máa bímọ, ó sì fún wọn níṣẹ́ aláyọ̀. Ó fẹ́ kí àwọn àtọmọdọ́mọ wọn kún ayé, kí wọ́n sì sọ ayé di Párádísè bíi ti ọgbà Édẹ́nì. Àmọ́ ohun kan wà tí Jèhófà sọ pé wọn ò gbọ́dọ̀ ṣe. Ó kìlọ̀ fún wọn pé tí wọ́n bá rú òfin náà, tí wọ́n sì mọ̀ọ́mọ̀ ṣọ̀tẹ̀ sí òun, wọ́n máa kú. Àwa náà mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìgbà yẹn. Áńgẹ́lì burúkú kan tí kò nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, tí kò sì nífẹ̀ẹ́ wọn tàn wọ́n jẹ, kí wọ́n lè ṣọ̀tẹ̀. Ádámù àti Éfà gbà kí Sátánì tó jẹ́ áńgẹ́lì burúkú yẹn tàn wọ́n jẹ. Torí pé wọn ò gbẹ́kẹ̀ lé Bàbá wọn ọ̀run tó nífẹ̀ẹ́ wọn, wọ́n ṣàìgbọràn sí Jèhófà. Bá a sì ṣe mọ̀, Jèhófà ti sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí wọn tí wọ́n bá ṣàìgbọràn, ó sì rí bẹ́ẹ̀. Àtìgbà yẹn ni wọ́n ti ń jìyà ohun tí wọ́n ṣe. Wọ́n darúgbó, wọ́n sì kú níkẹyìn.—Jẹ́n. 1:28, 29; 2:8, 9, 16-18; 3:1-6, 17-19, 24; 5:5.

4. Kí nìdí tí Jèhófà fi kórìíra ẹ̀ṣẹ̀, báwo ló sì ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀? (Róòmù 8:20, 21)

4 Jèhófà jẹ́ kí wọ́n kọ ìṣẹ̀lẹ̀ tó bani nínú jẹ́ yìí sínú Bíbélì ká lè kẹ́kọ̀ọ́ nínú ẹ̀. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí jẹ́ ká rí i pé ó kórìíra ẹ̀ṣẹ̀ gan-an. Ẹ̀ṣẹ̀ máa ń ba àjọṣe àwa àti Jèhófà jẹ́, ìdí nìyẹn tá a fi ń kú. (Àìsá. 59:2) Abájọ tí Sátánì tó dá gbogbo wàhálà náà sílẹ̀ fi nífẹ̀ẹ́ ẹ̀ṣẹ̀, tó sì fẹ́ káwọn míì náà máa dẹ́ṣẹ̀. Nígbà tí Ádámù àti Éfà dẹ́ṣẹ̀, ó ṣeé ṣe kí Sátánì rò pé Jèhófà ò ní ṣe ohun tó fẹ́ ṣe fún aráyé mọ́. Àmọ́, ohun tí Sátánì ò mọ̀ ni pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn gan-an. Ọlọ́run ò ní yí ohun tó fẹ́ ṣe fáwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù àti Éfà pa dà láé. Torí pé ó nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn gan-an, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló ṣohun tó jẹ́ ká nírètí pé a máa bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. (Ka Róòmù 8:20, 21.) Jèhófà mọ̀ pé àwọn kan lára àwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù àti Éfà máa nífẹ̀ẹ́ òun, wọ́n á sì ṣègbọràn sóun. Torí pé òun ni Bàbá àti Ẹlẹ́dàá wa, ó máa ṣe ọ̀nà àbáyọ ká lè bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀, ká sì ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú ẹ̀. Àmọ́, báwo ni Jèhófà ṣe máa ṣe é?

5. Ìgbà wo ni Jèhófà jẹ́ ká kọ́kọ́ mọ̀ pé ìrètí ṣì wà fáwa èèyàn ẹlẹ́ṣẹ̀? Ṣàlàyé. (Jẹ́nẹ́sísì 3:15)

5 Ka Jẹ́nẹ́sísì 3:15. Ìgbà tí Jèhófà sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí Sátánì ni ìgbà àkọ́kọ́ tó jẹ́ ká mọ̀ pé ìrètí ṣì wà fáwa èèyàn ẹlẹ́ṣẹ̀. Ọlọ́run sọ tẹ́lẹ̀ pé “ọmọ” kan máa gbà wá sílẹ̀. Ọmọ yìí máa pa Sátánì run, á sì tún gbogbo ohun tó ti bà jẹ́ ṣe. (1 Jòh. 3:8) Àmọ́ ṣá o, ọmọ náà máa jìyà kó tó lè gbà wá sílẹ̀. Sátánì máa ṣe é léṣe, ìyẹn ni pé ó máa jẹ́ kí wọ́n pa á. Ohun tó máa ṣe yìí máa ba Jèhófà nínú jẹ́ gan-an. Àmọ́ Jèhófà ṣe tán láti fara da ohun tó máa ṣẹlẹ̀ yìí torí pé ikú Ọmọ ẹ̀ ló máa jẹ́ káwa èèyàn bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú.

KÍ LÀWỌN ÈÈYÀN ALÁÌPÉ ṢE NÍGBÀ ÀTIJỌ́ KÍ WỌ́N LÈ MÚNÚ JÈHÓFÀ DÙN?

6. Kí làwọn ọkùnrin olóòótọ́ bí Ébẹ́lì àti Nóà ṣe kí wọ́n lè sún mọ́ Jèhófà?

6 Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, díẹ̀díẹ̀ ni Jèhófà ń jẹ́ káwa èèyàn aláìpé mọ bá a ṣe lè sún mọ́ òun. Ébẹ́lì ni ọmọ kejì tí Ádámù àti Éfà bí, òun sì lẹni àkọ́kọ́ tó jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà lẹ́yìn ọ̀tẹ̀ tó wáyé ní Édẹ́nì. Torí náà, Ébẹ́lì rúbọ sí Jèhófà torí pé ó nífẹ̀ẹ́ ẹ̀, ó fẹ́ múnú ẹ̀ dùn, ó sì fẹ́ sún mọ́ ọn. Olùṣọ́ àgùntàn ni Ébẹ́lì, torí náà ó mú lára àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn ẹ̀, ó sì fi rúbọ sí Jèhófà. Báwo lohun tí Ébẹ́lì ṣe yìí ṣe rí lára Jèhófà? Jèhófà “ṣojúure sí Ébẹ́lì, ó sì gba ọrẹ rẹ̀.” (Jẹ́n. 4:4) Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà míì wà tí wọ́n rúbọ sí i, tí Jèhófà sì gba ẹbọ wọn torí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ ẹ̀ wọ́n sì gbẹ́kẹ̀ lé e, irú bíi Nóà. (Jẹ́n. 8:20, 21) Bí Jèhófà ṣe gba ẹbọ wọn jẹ́ ká mọ̀ pé àwa èèyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ lè rí ojúure ẹ̀, ká sì sún mọ́ ọn. b

7. Kí la kọ́ lára Ábúráhámù nípa bó ṣe gbà láti fi ọmọ ẹ̀ rúbọ?

7 Ọkùnrin tó nígbàgbọ́ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ ni Ábúráhámù. Lọ́jọ́ kan, Jèhófà ní kó fi Ísákì ọmọ kan ṣoṣo tó bí rúbọ. Ó dájú pé ohun tí Jèhófà ní kí Ábúráhámù ṣe yìí ò ní rọrùn fún un rárá. Síbẹ̀, ó gbà láti ṣe ohun tí Jèhófà sọ. Àmọ́ bó ṣe fẹ́ pa ọmọ ẹ̀ báyìí ni Ọlọ́run sọ pé kó má ṣe bẹ́ẹ̀. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn jẹ́ ká rí ohun tí Jèhófà máa ṣe fáwa èèyàn lọ́jọ́ iwájú, ó máa fi Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n rúbọ torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa gan-an.—Jẹ́n. 22:1-18.

8. Kí làwọn ẹbọ tí Òfin Mósè sọ pé káwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa rú ṣàpẹẹrẹ? (Léfítíkù 4:27-29; 17:11)

8 Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, Òfin Mósè sọ pé káwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa rú àwọn ẹbọ kan láti fi ṣètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn. (Ka Léfítíkù 4:27-29; 17:11.) Àwọn ẹbọ tí wọ́n ń rú yẹn ṣàpẹẹrẹ ẹbọ kan tó ṣe pàtàkì tó máa gba aráyé sílẹ̀ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀. Ẹ̀mí Ọlọ́run darí àwọn wòlíì ẹ̀ láti sọ tẹ́lẹ̀ pé Ọmọ tá a ṣèlérí náà, ìyẹn àyànfẹ́ Ọmọ Ọlọ́run máa jìyà, ó sì máa kú. Wọ́n máa pa á bí ìgbà tí wọ́n pa àgùntàn tí wọ́n fi rúbọ. (Àìsá. 53:1-12) Ẹ ò rí i pé nǹkan ńlá ni Jèhófà ṣe fún wa bó ṣe yọ̀ǹda Ọmọ ẹ̀ ọ̀wọ́n pé kó kú, kó lè gba ìwọ àti aráyé sílẹ̀ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú!

KÍ NI JÉSÙ ṢE KÓ LÈ GBA ARÁYÉ SÍLẸ̀?

9. Kí ni Jòhánù Arinibọmi sọ nípa Jésù? (Hébérù 9:22; 10:1-4, 12)

9 Lọ́dún 29 S. K., Jòhánù Arinibọmi sọ ohun kan nípa Jésù ará Násárẹ́tì, ó ní: “Wò ó, Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run tó kó ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ!” (Jòh. 1:29) Ọ̀rọ̀ inú ẹsẹ Bíbélì yìí jẹ́ ká mọ̀ pé Jésù ni ọmọ tí Jèhófà ṣèlérí tipẹ́tipẹ́ pé ó máa gba aráyé sílẹ̀. Torí náà, ó máa fi ara ẹ̀ rúbọ nítorí wa. Ó wá hàn kedere báyìí pé ọmọ tí Jèhófà ṣèlérí pé ó máa gba aráyé sílẹ̀ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ ti dé.—Ka Hébérù 9:22; 10:1-4, 12.

10. Kí ni Jésù ṣe tó fi hàn pé àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ló “wá pè”?

10 Àwọn èèyàn tínú wọn bà jẹ́ torí pé wọ́n dẹ́ṣẹ̀ ni Jésù fẹ́ ràn lọ́wọ́ kí wọ́n lè di ọmọlẹ́yìn ẹ̀. Ó mọ̀ pé ẹ̀ṣẹ̀ ló fà á tí aráyé fi ń jìyà. Ìdí nìyẹn tó fi ran àwọn tó ti dẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́. Ó wá sọ àpèjúwe kan, ó ní: “Àwọn tí ara wọn le kò nílò oníṣègùn, àmọ́ àwọn tó ń ṣàìsàn nílò rẹ̀.” Ó tún sọ pé: “Kì í ṣe àwọn olódodo ni mo wá pè, àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni.” (Mát. 9:12, 13) Ohun tí Jésù sì ṣe nìyẹn. Bí àpẹẹrẹ, ó bá obìnrin tó fi omijé fọ ẹsẹ̀ rẹ̀ sọ̀rọ̀ lọ́nà pẹ̀lẹ́, ó sì dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀ jì í. (Lúùkù 7:37-50) Nígbà tí Jésù bá obìnrin ará Samáríà kan pàdé nídìí kànga, ó kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, bó tiẹ̀ mọ̀ pé ọkùnrin tó ń bá gbé kì í ṣe ọkọ ẹ̀. (Jòh. 4:7, 17-19, 25, 26) Yàtọ̀ síyẹn, àwa èèyàn ń kú torí pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni wá. Àmọ́, Ọlọ́run fún Jésù lágbára kó lè jí àwọn òkú dìde, àtọmọdé, àtàgbà, àtọkùnrin, àtobìnrin.—Mát. 11:5.

11. Kí nìdí táwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ fi sún mọ́ Jésù?

11 Kò yà wá lẹ́nu pé àwọn tó sọ ẹ̀ṣẹ̀ dàṣà sún mọ́ Jésù. Ìdí sì ni pé ó gba tiwọn rò, ó sì fàánú hàn sí wọn. Ara máa ń tù wọ́n tí wọ́n bá wà lọ́dọ̀ ẹ̀. (Lúùkù 15:1, 2) Torí náà, Jésù gbóríyìn fún wọn torí pé wọ́n nígbàgbọ́, ó sì san wọ́n lérè. (Lúùkù 19:1-10) Ó máa ń ṣàánú àwọn èèyàn bíi ti Bàbá ẹ̀. (Jòh. 14:9) Àwọn nǹkan tí Jésù ṣe àtàwọn nǹkan tó sọ jẹ́ ká rí i pé Bàbá ẹ̀ máa ń gba tèèyàn rò, ó máa ń ṣàánú, ó nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, ó sì fẹ́ ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀. Ìdí nìyẹn tí Jésù fi ran àwọn tó dẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè yí pa dà, kí wọ́n sì di ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀.—Lúùkù 5:27, 28.

12. Kí ni Jésù sọ nípa ikú ẹ̀?

12 Jésù mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sóun láìpẹ́. Léraléra ló sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ pé ẹnì kan máa da òun, wọ́n sì máa kan òun mọ́gi. (Mát. 17:22; 20:18, 19) Ó mọ̀ pé ikú òun máa jẹ́ kí aráyé bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀, bí Jòhánù Arinibọmi àtàwọn wòlíì ṣe sọ tẹ́lẹ̀. Jésù tún kọ́ni pé lẹ́yìn tóun bá kú, òun máa “fa onírúurú èèyàn” sọ́dọ̀ ara òun. (Jòh. 12:32) Táwa èèyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ bá fẹ́ múnú Jèhófà dùn, a gbọ́dọ̀ nígbàgbọ́ nínú Jésù, ká sì máa ṣe ohun tó sọ. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, a máa “dá [wa] sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀.” (Róòmù 6:14, 18, 22; Jòh. 8:32) Torí náà, Jésù ṣe tán láti kú ikú oró kó lè gbà wá là, ó sì fìgboyà ṣe bẹ́ẹ̀.—Jòh. 10:17, 18.

13. Báwo ni Jésù ṣe kú, kí ni ikú ẹ̀ sì jẹ́ ká mọ̀ nípa Jèhófà? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

13 Níkẹyìn, wọ́n da Jésù, wọ́n fàṣẹ ọba mú un, wọ́n bú u, wọ́n parọ́ mọ́ ọn, wọ́n dájọ́ ikú fún un, wọ́n sì fìyà jẹ ẹ́. Àwọn sójà mú un lọ síbi tí wọ́n ti máa pa á, wọ́n sì kàn án mọ́gi. Àmọ́ ó jẹ́ olóòótọ́, ó sì fara da ìrora yẹn. Ó dun Jèhófà gan-an bó ṣe ń wo Ọmọ ẹ̀ tó ń jẹ̀rora. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà lágbára láti gba Jésù sílẹ̀, kò ṣe bẹ́ẹ̀. Kí nìdí tí Jèhófà tó nífẹ̀ẹ́ Jésù ò fi gbà á sílẹ̀? Ìdí ni pé ó nífẹ̀ẹ́ wa. Jésù sọ pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé gan-an débi pé ó fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí gbogbo ẹni tó bá ń ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.”—Jòh. 3:16.

Ó dun Jèhófà gan-an bó ṣe gbà kí wọ́n pa Ọmọ ẹ̀, ká lè bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú (Wo ìpínrọ̀ 13)


14. Kí ni ikú Jésù jẹ́ kó o mọ̀?

14 Bí Jèhófà ṣe gbà kí Jésù fi ara ẹ̀ rúbọ nítorí wa jẹ́ ká mọ̀ pé ó nífẹ̀ẹ́ àwa àtọmọdọ́mọ Ádámù àti Éfà gan-an. Ohun tí Jèhófà ṣe yẹn fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ ẹ. Kò rọrùn fún Jèhófà láti fara dà á bó ṣe ń wo ọmọ ẹ̀ tó ń jẹ̀rora kó lè gbà ẹ́ sílẹ̀ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. (1 Jòh. 4:9, 10) Ó fẹ́ ran ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lọ́wọ́ ká lè máa sìn ín nìṣó bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni wá, ó sì fẹ́ ká bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀!

15. Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá fẹ́ jàǹfààní ìràpadà tí Ọlọ́run fi Jésù ṣe?

15 Ẹ̀bùn ni ìràpadà, torí náà ikú Jésù Ọmọ bíbí kan ṣoṣo Ọlọ́run ló jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà. Àmọ́ kí Ọlọ́run tó lè dárí jì wá, ohun kan wà tó yẹ ká ṣe. Kí ni nǹkan náà? Jòhánù Arinibọmi àti Jésù fúnra ẹ̀ sọ ohun tó yẹ ká ṣe, wọ́n ní: “Ẹ ronú pìwà dà, torí Ìjọba ọ̀run ti sún mọ́lé.” (Mát. 3:1, 2; 4:17) Torí náà, tá a bá fẹ́ bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀, ká sì sún mọ́ Bàbá wa ọ̀run tó nífẹ̀ẹ́ wa, àfi ká ronú pìwà dà. Àmọ́, kí ni ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ gbọ́dọ̀ ṣe ká tó lè sọ pé ó ti ronú pìwà dà, báwo nìyẹn sì ṣe máa ràn án lọ́wọ́ láti ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́? A máa rí ìdáhùn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e.

ORIN 18 A Mọyì Ìràpadà

a ÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀: Nínú Bíbélì, ọ̀rọ̀ náà “ẹ̀ṣẹ̀” túmọ̀ sí ohun tí Jèhófà sọ pé ká má ṣe àmọ́ tá a ṣàìgbọràn tàbí ohun tí Jèhófà sọ pé ká ṣe, tá ò sì ṣe. “Ẹ̀ṣẹ̀” tún lè jẹ́ àìpé tá a jogún látọ̀dọ̀ Ádámù. Ẹ̀ṣẹ̀ tá a jogún yìí ló fà á tá a fi ń kú.

b Ìdí tí Jèhófà fi máa ń gba ẹbọ àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ ẹ̀ kó tó di pé ẹ̀sìn Kristẹni bẹ̀rẹ̀ ni pé, ó mọ̀ pé Jésù Kristi ṣì máa fi ara ẹ̀ rúbọ, ìyẹn sì máa jẹ́ ká bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú pátápátá.—Róòmù 3:25.