Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
2 Tẹsalóníkà 3:14 sọ pé ká sàmì sí àwọn èèyàn kan. Ṣé àwọn alàgbà ló máa sàmì náà àbí Kristẹni kọ̀ọ̀kan?
Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà sáwọn Kristẹni ní Tẹsalóníkà, ó sọ pé: “Tí ẹnikẹ́ni ò bá ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ tí a sọ nínú lẹ́tà yìí, ẹ sàmì sí ẹni náà.” (2 Tẹs. 3:14) Òye wa nípa ọ̀rọ̀ yìí tẹ́lẹ̀ ni pé àwọn alàgbà ni Pọ́ọ̀lù ń darí ọ̀rọ̀ yìí sí. Tí ẹnì kan bá mọ̀ọ́mọ̀ ṣàìgbọràn sáwọn ìlànà Bíbélì láìka àwọn ìmọ̀ràn tí wọ́n fún un léraléra sí, àwọn alàgbà lè sọ àsọyé kan láti kìlọ̀ fún ìjọ. Lẹ́yìn náà, àwọn ará ò ní kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú ẹni tí wọ́n sàmì sí náà mọ́, àfi tí wọ́n bá wà nípàdé ìjọ àti lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.
Àmọ́ ní báyìí, a rí i pé ó yẹ ká ṣàtúnṣe òye tá a ní tẹ́lẹ̀. Ó hàn gbangba pé Kristẹni kọ̀ọ̀kan ló máa pinnu ohun tó máa ṣe lórí ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù gbà wá yìí. Torí náà, àwọn alàgbà ò ní sọ àsọyé láti kìlọ̀ fún ìjọ mọ́. Kí nìdí tá a fi ṣàtúnṣe yìí? Ẹ jẹ́ ká gbé ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ yẹ̀ wò nígbà tó ń fún àwọn ará nímọ̀ràn yìí.
Pọ́ọ̀lù sọ pé àwọn kan nínú ìjọ yẹn “ń rìn ségesège.” Wọn ò ṣègbọràn sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ní ìbẹ̀wò tí Pọ́ọ̀lù ṣe ṣáájú ìgbà yẹn, ó sọ fún wọn pé: “Tí ẹnikẹ́ni ò bá fẹ́ ṣiṣẹ́, kó má jẹun.” Síbẹ̀, àwọn kan lára wọn kọ̀ láti ṣiṣẹ́ tí wọ́n máa fi gbọ́ bùkátà ara wọn, bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n lágbára láti ṣe bẹ́ẹ̀. Bákan náà, wọ́n ń tojú bọ ọ̀rọ̀ ọlọ́rọ̀. Báwo ló ṣe yẹ káwọn Kristẹni ṣe sáwọn tó ń rìn ségesège yẹn?—2 Tẹs. 3:6, 10-12.
Pọ́ọ̀lù ní “ẹ sàmì sí ẹni náà.” Ohun tí ọ̀rọ̀ yìí túmọ̀ sí ní èdè Gíríìkì ni pé ká mọ irú ìwà tẹ́ni náà ń hù, ká sì ṣọ́ra fún un. Àwọn ará ìjọ ni Pọ́ọ̀lù darí ọ̀rọ̀ yìí sí, kì í ṣe àwọn alàgbà nìkan. (2 Tẹs. 1:1; 3:6) Torí náà, Kristẹni kọ̀ọ̀kan tó kíyè sí i pé arákùnrin tàbí arábìnrin kan ò ṣe ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ ló máa pinnu pé òun ò ní bá ẹni náà “kẹ́gbẹ́ mọ́.”
Ṣé ohun tá à ń sọ ni pé kí wọ́n máa hùwà sẹ́ni náà bí ẹni tí wọ́n mú kúrò nínú ìjọ? Rárá o, torí Pọ́ọ̀lù tún sọ pé: “Ẹ máa gbà á níyànjú bí arákùnrin.” Torí náà, àwọn ará ìjọ á ṣì máa bá a sọ̀rọ̀ nípàdé, wọ́n á ṣì jọ máa wàásù, àmọ́ àwọn ará lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ló máa pinnu pé àwọn ò ní ṣe wọlé-wọ̀de pẹ̀lú ẹ̀ mọ́. Kí nìdí? Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Kí ojú lè tì í.” Tá ò bá ṣe wọlé-wọ̀de pẹ̀lú Kristẹni tó ń rìn ségesège náà mọ́, ìyẹn lè jẹ́ kí ojú tì í, kó sì yíwà ẹ̀ pa dà.—2 Tẹs. 3:14, 15.
Báwo làwa Kristẹni ṣe lè mọ ìgbà tó yẹ ká sàmì sí ẹnì kan lónìí? Ó gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ dá wa lójú pé ẹni náà ń ṣe “ségesège” lóòótọ́ bí Pọ́ọ̀lù ṣe sọ. Àwọn tí Pọ́ọ̀lù ń sọ kì í ṣe àwọn tó ń ṣe nǹkan tí ẹ̀rí ọkàn wa ò gbà, àmọ́ tí nǹkan náà ò ta ko ìlànà Ìwé Mímọ́. Bákan náà, kì í ṣe ọ̀rọ̀ èyí-wù-mí-ò-wù-ọ́ ni Pọ́ọ̀lù ń sọ níbí, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe àwọn tó ṣe ohun tó dùn wá ló ń sọ nípa ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn tí Pọ́ọ̀lù ń sọ ni àwọn tó mọ̀ọ́mọ̀ ń ṣàìgbọràn sáwọn ìlànà Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì.
Lónìí, tá a bá kíyè sí pé arákùnrin tàbí arábìnrin kan ń mọ̀ọ́mọ̀ ṣàìgbọràn sí ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ, a ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ló máa pinnu pé òun ò ní bá ẹni náà lọ síbi àríyá tàbí ibi ìgbafẹ́. Torí pé kálukú wa ló máa pinnu ohun tó máa ṣe lórí ọ̀rọ̀ yìí, a ò ní sọ̀rọ̀ náà fáwọn ẹlòmíì yàtọ̀ sáwọn ará ilé wa tá a jọ ń sin Jèhófà. Àmọ́, àá ṣì máa bá ẹni náà sọ̀rọ̀ nípàdé, àá sì jọ máa wàásù. Tó bá ti ṣe àwọn àtúnṣe tó yẹ, a lè jọ lọ síbi àríyá tàbí ibi ìgbafẹ́.
a Bí àpẹẹrẹ, arákùnrin tàbí arábìnrin kan lè má fẹ́ ṣiṣẹ́ tó máa fi gbọ́ bùkátà ara ẹ̀, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó lágbára láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ó lè mọ̀ọ́mọ̀ máa fẹ́ aláìgbàgbọ́ sọ́nà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti kìlọ̀ fún un léraléra. Ẹni náà lè máa tan ọ̀rọ̀ tó lè fa ìyapa kiri tàbí kó máa ṣòfófó. (1 Kọ́r. 7:39; 2 Kọ́r. 6:14; 2 Tẹs. 3:11, 12; 1 Tím. 5:13) Àwọn tó bá ń ṣe “ségesège” ló máa ń hu irú àwọn ìwà yìí.