Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

Mo Fi Àwọn Nǹkan Sílẹ̀ Kí N Lè Tẹ̀ Lé Jésù

Mo Fi Àwọn Nǹkan Sílẹ̀ Kí N Lè Tẹ̀ Lé Jésù

Lọ́jọ́ kan, bàbá mi halẹ̀ mọ́ mi pé: “Tó o bá lọ wàásù pẹ́nrẹ́n, o ò gbọ́dọ̀ pa dà sílé yìí, tó o bá pa dà wá, màá kán ẹ lẹ́sẹ̀.” Láìfi ìyẹn pè, mo lọ. Ìgbà àkọ́kọ́ nìyẹn tí n máa fi àwọn nǹkan sílẹ̀ kí n lè tọ Jésù, Ọ̀gá náà lẹ́yìn. Ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16] péré ni mí nígbà yẹn.

KÍ NÌDÍ tí bàbá mi fi halẹ̀ mọ́ mi? Ẹ jẹ́ kí n ṣàlàyé. Abúlé kan nílùú Bulacan, lórílẹ̀-èdè Philippines ni wọ́n bí mi sí ní July 29, 1929, ibẹ̀ náà sì ni mo dàgbà sí. Ìgbà tí mo wà lọ́dọ̀ọ́, orílẹ̀-èdè Japan wá gbógun ja orílẹ̀-èdè Philippines, torí náà ọrọ̀ ajé dẹnu kọlẹ̀, nǹkan ò sì rọrùn. Àmọ́ torí pé abúlé àdádó kan là ń gbé, ogun náà ò dé ìlú wa, bá a ṣe rọra ń gbé ìgbésí ayé wa lọ nìyẹn. A ò ní rédíò, tẹlifíṣọ̀n tàbí ìwé ìròyìn èyíkéyìí, ẹnu àwọn èèyàn la ti ń gbọ́ bí nǹkan ṣe ń lọ.

Èmi ni ọmọ kejì nínú ọmọ mẹ́jọ táwọn òbí wa bí, ìgbà tí mo sì wà lọ́mọ ọdún mẹ́jọ làwọn òbí mi àgbà ti wá mú mi. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹlẹ́sìn Kátólíìkì ni wá, bàbá mi àgbà fẹ́ràn ẹ̀sìn gan-an. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tí wọ́n gba àwọn ìwé kan lọ́wọ́ àwọn ọ̀rẹ́ wọn. Mo rántí pé wọ́n fi àwọn ìwé Protection, Safety, àti ìwé Uncovered hàn mí lédè Tagalog, * wọ́n sì tún fi Bíbélì hàn mí. Mo gbádùn kí n máa ka Bíbélì, pàápàá àwọn ìwé Ìhìn Rere mẹ́rẹ̀ẹ̀rin. Bó ṣe di pé èmi náà fẹ́ máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù nìyẹn.​—Jòh. 10:27.

MO SÌNRÚ FÚN Ọ̀GÁ NÁÀ

Ọdún 1945 ni ogun náà parí. Àsìkò yẹn sì làwọn òbí mi ní kí n máa pa dà bọ̀ nílé. Bàbá mi àgbà rọ̀ mí pé kí n lọ, mo sì lọ.

Kò pẹ́ lẹ́yìn ìgbà yẹn ní December 1945, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan láti ìlú Angat wá wàásù ní abúlé wa. Arákùnrin àgbàlagbà kan ló wá wàásù nílé wa, ó sì ṣàlàyé ohun tí Bíbélì sọ nípa “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.” (2 Tím. 3:​1-5) Arákùnrin náà ní ká wá síbi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan tí wọ́n fẹ́ ṣe lábúlé kan tí ò jìnnà sí wa. Èmi nìkan ni mo lọ, àwọn òbí mi ò lọ. Àwa èèyàn bí ogún [20] la pésẹ̀ síbẹ̀, àwọn kan sì béèrè àwọn ìbéèrè tó dá lórí Bíbélì.

Mi ò fi bẹ́ẹ̀ lóye ohun tí wọ́n ń sọ níbẹ̀, torí náà mi ò rídìí tó fi yẹ kí n ṣì jókòó pa síbẹ̀. Àmọ́ bí mo ṣe fẹ́ dìde ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kọrin Ìjọba Ọlọ́run, mo gbádùn orin náà gan-an débi pé mo pinnu pé mi ò ní lọ mọ́. Lẹ́yìn tá a kọrin tá a sì gbàdúrà tán, wọ́n ní kí gbogbo wa wá sí ìpàdé tí wọ́n máa ṣe nílùú Angat lọ́jọ́ Sunday tó tẹ̀ lé e.

Àwa bíi mélòó kan fẹsẹ̀ rin nǹkan bíi máìlì márùn-ún (8 km) lọ sílé Arákùnrin  tí wọ́n ti fẹ́ ṣe ìpàdé náà. Àwa àádọ́ta [50] la pé jọ síbẹ̀, àmọ́ ṣe lorí mi ń wú bí mo ṣe ń rí àwọn ọmọdé tó ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tó jinlẹ̀ gan-an. Lára àwọn tá a jọ máa ń wà nípàdé yẹn ni arákùnrin àgbàlagbà kan tó ń jẹ́ Damian Santos. Olórí ìlú ni wọ́n tẹ́lẹ̀ kí wọ́n tó di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, aṣáájú-ọ̀nà sì ni wọ́n. Lẹ́yìn ìgbà bíi mélòó kan tí mo lọ sípàdé, wọ́n ní kí n sùn sọ́dọ̀ àwọn, ọ̀rọ̀ Bíbélì la sì jọ sọ mọ́jú.

Nígbà yẹn, ọ̀pọ̀ wa ló jẹ́ pé lẹ́yìn tá a ti kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ Bíbélì la ti pinnu pé Jèhófà la máa sìn. Lẹ́yìn ìpàdé mélòó kan tí mo lọ, àwọn arákùnrin tó wà níbẹ̀ bi èmi àtàwọn míì pé, “Ṣé ẹ fẹ́ ṣèrìbọmi?” Mo dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, mo fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀.” Ó dá mi lójú pé mo ti ṣe tán láti “sìnrú fún Ọ̀gá náà, Kristi.” (Kól. 3:24) Torí náà ní February 15, 1946, méjì lára wa ṣèrìbọmi nínú odò kan tó wà nítòsí.

A mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì pé káwa Kristẹni máa wàásù nígbà gbogbo bíi ti Jésù. Àmọ́, iṣẹ́ ìwàásù yìí kò dùn mọ́ bàbá mi nínú. Lọ́jọ́ kan, wọ́n sọ pé, “O ti kéré jù átimáa wàásù kiri. Yàtọ̀ síyẹn, ti pé wọ́n rì ẹ́ bọmi ò sọ ẹ́ di oníwàásù.” Mo ṣàlàyé fún wọn pé ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ni pé ká máa wàásù ìhìn rere Ìjọba rẹ̀. (Mát. 24:14) Mo tún wá sọ pé, “Mo gbọ́dọ̀ san ẹ̀jẹ́ tí mo jẹ́ fún Ọlọ́run.” Ìgbà yẹn ni bàbá mi wá sọ ohun tí mo sọ lókè yẹn. Wọn ò fẹ́ kí n máa wàásù rárá, ìyẹn ló sì jẹ́ kí n fi ilé sílẹ̀ kí n lè tara bọ iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.

Ìdílé Cruz sọ pé kí n wá máa gbé lọ́dọ̀ àwọn nílùú Angat. Wọ́n tún rọ èmi àti àbígbẹ̀yìn wọn obìnrin tó ń jẹ́ Nora pé ká bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Àwa méjèèjì di aṣáájú-ọ̀nà ní November 1, 1947. Nora lọ sìn nílùú míì, èmi náà sì ń bá iṣẹ́ lọ nílùú Angat.

MO TÚN FI ÀWỌN NǸKAN SÍLẸ̀ LỌ SÌN NÍ BẸ́TẸ́LÌ

Lẹ́yìn ọdún mẹ́ta tí mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, Arákùnrin Earl Stewart wá láti ẹ̀ka ọ́fíìsì láti wá sọ àsọyé. Iwájú ilé ìtajà ńlá kan nílùú Angat ló ti sọ àsọyé náà, ọgọ́rùn-ún márùn-ún èèyàn [500] ló sì péjọ síbẹ̀. Èdè Gẹ̀ẹ́sì ló fi sọ àsọyé náà, mo wá ṣe àkópọ̀ rẹ̀ lédè Tagalog. Ọdún méje péré ni mo fi lọ sílé ìwé, èdè Gẹ̀ẹ́sì sì làwọn tíṣà wa sábà máa ń sọ, torí náà mo gbọ́ èdè náà níwọ̀nba. Ohun míì tó ràn mí lọ́wọ́ ni pé kò fi bẹ́ẹ̀ sáwọn ìtẹ̀jáde Bíbélì lédè Tagalog, torí náà, èdè Gẹ̀ẹ́sì ni mo sábà máa ń fi kẹ́kọ̀ọ́. Ohun tó jẹ́ kí n rí àsọyé yẹn tú sédè Tagalog nìyẹn, mo sì tún ṣe bẹ́ẹ̀ láwọn ìgbà míì.

Lọ́jọ́ tí Arákùnrin Stewart wá sọ àsọyé yẹn, ó sọ fáwọn ará ìjọ tó wà níbẹ̀ pé ẹ̀ka ọ́fíìsì nílò arákùnrin aṣáájú-ọ̀nà kan tàbí méjì ní Bẹ́tẹ́lì. Ìdí sì ni pé àwọn míṣọ́nnárì fẹ́ lọ sí àpéjọ Theocracy’s Increase Assembly nílùú New York lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà lọ́dún 1950, wọ́n sì nílò àwọn tó máa ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì láàárín àsìkò yẹn. Mo wà lára àwọn tí wọ́n pè, bó ṣe di pé mo tún fi ibi tó ti mọ́ mi lára sílẹ̀ nìyẹn, tí mo sì gba Bẹ́tẹ́lì lọ.

June 19, 1950 ni mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì. Wọ́n ti kọ́ ilé Bẹ́tẹ́lì náà tipẹ́, ó tóbi gan-an, igi sì pọ̀ níbẹ̀. Éékà méjì àti ààbọ̀ ni ọgbà ilé náà. Àwọn arákùnrin méjìlá tí kò tíì gbéyàwó ló ń sìn níbẹ̀. Ilé ìdáná ni mo ti kọ́kọ́ máa ń ṣiṣẹ́ láàárọ̀, àmọ́ tó bá di nǹkan bí aago mẹ́sàn-án, aṣọ ni mo máa ń lọ̀. Ohun tí mo máa ń ṣe lọ́sàn-án náà nìyẹn. Kódà lẹ́yìn táwọn míṣọ́nnárì pa dà dé, mo ṣì ń báṣẹ́ mi lọ níbẹ̀. Mo máa ń ṣiṣẹ́ níbi tí wọ́n ti ń dìwé pọ̀ àti níbi tí wọ́n ti ń ṣètò ìwé ìròyìn fáwọn tó san àsansílẹ̀. Mo tún máa ń ṣiṣẹ́ níbi tí wọ́n ti ń gbàlejò, ohunkóhun tí wọ́n bá ní kí n ṣe ni mo máa ń ṣe.

MO KÚRÒ LÓRÍLẸ̀-ÈDÈ PHILIPPINES LỌ SÍLÉ Ẹ̀KỌ́ GÍLÍÁDÌ

Lọ́dún 1952, wọ́n pe àwa mẹ́fà láti Philippines wá sí kíláàsì ogún ti ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Inú mi sì dùn gan-an nígbà tí mo gba lẹ́tà tí wọ́n fi pè mí. Ọ̀pọ̀ lára àwọn nǹkan tá a rí ní Amẹ́ríkà ló ṣàjèjì sí wa. Gbogbo nǹkan tó wà níbẹ̀ ló yàtọ̀ pátápátá sáwọn nǹkan tó wà lábúlé wa.

Èmi àtàwọn akẹ́kọ̀ọ́ míì nílé Ẹ̀kọ́ Gílíádì

Bí àpẹẹrẹ, a ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ bí wọ́n ṣe ń lo àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé àtàwọn nǹkan míì tá ò mọ̀ tẹ́lẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, ojú ọjọ́ ibẹ̀ yàtọ̀ gan-an sí ti ìlú wa. Láàárọ̀ ọjọ́ kan, bí mo ṣe bọ́ síta báyìí, inú yìnyín ni mo bára mi, ṣe ni gbogbo ẹ̀ funfun báláú. Ìgbà àkọ́kọ́ tí mo máa rí yìnyín nìyẹn, òtútù sì mú mi torí ibẹ̀ tutù gan-an.

Síbẹ̀, gbogbo nǹkan yẹn ò jẹ́ nǹkan kan lójú mi tí n bá fi wéra pẹ̀lú ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí mo gbà nílé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Àwọn olùkọ́ wa máa ń kọ́ wa lọ́nà tí nǹkan á fi tètè yé wa. A kọ́ bá a ṣe lè máa ṣe ìwádìí àti ìdákẹ́kọ̀ọ́ tó nítumọ̀. Kò sí àní-àní pé ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí mo gbà yìí jẹ́ kí n túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà.

Lẹ́yìn tí mo kẹ́kọ̀ọ́ yege níbẹ̀, wọ́n ní kí n lọ ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe fúngbà díẹ̀ ní Bronx, nílùú New York City. Torí náà, ní July 1953, mo lọ sí àpéjọ New World Society Assembly tí wọ́n ṣe nílùú yẹn. Lẹ́yìn àpéjọ náà, wọ́n ní kí n lọ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ míì ní Philippines.

MO KÚRÒ NÍ ÌGBOORO LỌ SÍ ABÚLÉ

Àwọn arákùnrin tó wà ní ẹ̀ka ọ́fíìsì sọ fún mi pé: “Ní báyìí, iṣẹ́ alábòójútó àyíká ni wàá máa ṣe.” Mo fẹ́ràn iṣẹ́ yẹn torí pé ó ń jẹ́ kí n lè máa ṣe bíi ti Jésù tó ń lọ láti ìlú kan sí òmíì láti ran àwọn àgùntàn Jèhófà lọ́wọ́. (1 Pét. 2:21) Àyíká kan tó wà ní gbùngbùn Luzon ni wọ́n ní kí n lọ, òun sì ni erékùṣù tó tóbi jù ní Philippines. Àwọn ìlú míì náà wà níbẹ̀, bí ìlú Bulacan, Nueva Ecija, Tarlac àti ìlú Zambales. Kí n tó lè dé àwọn ìlú kan, àfi kí n gorí àwọn òkè gbágungbàgun Sierra Madre Mountains. Kò sí ọkọ̀ èrò tó ń lọ sáwọn ìlú yìí, torí náà mo máa ń bẹ àwọn tó ń wa ọkọ̀ agbégilódò pé kí wọ́n jẹ́ kí n jókòó sórí àwọn igi tí wọ́n kó. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n máa ń gbà bó tiẹ̀ jẹ́ pé kì í rọrùn.

Ìjọ tuntun ló pọ̀ jù ní àyíká yẹn, wọn ò sì fi bẹ́ẹ̀ tóbi. Torí náà, àwọn arákùnrin tó wà níbẹ̀ mọrírì bí mo ṣe bá wọn ṣètò ìpàdé àti òde ẹ̀rí lọ́nà tó túbọ̀ nítumọ̀.

Nígbà tó yá, wọ́n gbé mi lọ sí àyíká míì, mo sì ń bẹ gbogbo ìjọ tó wà ní àgbègbè Bicol wò. Àwùjọ àdádó táwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ ló pọ̀ jù ní àyíká yìí. Ní ilé kan, ṣáláńgá ni wọ́n ti máa ń gbọnsẹ̀, igi méjì ni wọ́n sì gbé sórí rẹ̀. Lọ́jọ́ kan, bí mo ṣe gorí àwọn igi yẹn báyìí, àfi wìì, àtèmi àti igi ó dinú ṣáláńgá. Ó pẹ́ kí n tó lè fọ gbogbo ìdọ̀tí yẹn kúrò, ẹ̀yin náà ni mo wá jẹun àárọ̀.

Àyíká yìí ni mo wà nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa Nora tó ṣe aṣáájú-ọ̀nà nílùú Bulacan. Lásìkò tí mò ń sọ yìí, ó ti di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe nílùú Dumaguete City, mo sì lọ kí i. Lẹ́yìn ìyẹn, a bẹ̀rẹ̀ sí í kọ lẹ́tà síra wa, nígbà tó sì di ọdún 1956, a ṣègbéyàwó. Lẹ́yìn tá a ṣègbéyàwó, ìjọ kan tó wà ní erékùṣù Rapu Rapu Island la kọ́kọ́ bẹ̀ wò. Bá a ṣe ń rìn ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ là ń gun àwọn òkè, àmọ́ gbogbo ìyẹn ò ṣe mí ní nǹkan kan torí èmi àtìyàwó mi la jọ ń ṣèbẹ̀wò sáwọn ará tó wà láwọn ibi àdádó yẹn.

WỌ́N TÚN PÈ MÍ SÍ BẸ́TẸ́LÌ LẸ́Ẹ̀KAN SÍ I

Lẹ́yìn nǹkan bí ọdún mẹ́rin tá a ti ń ṣiṣẹ́ alábòójútó àyíká, wọ́n ní ká máa bọ̀ ní Bẹ́tẹ́lì. Torí náà, ní January 1960 a bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì, ibẹ̀ la sì wà títí dòní. Láàárín àwọn ọdún yìí, mo ti kẹ́kọ̀ọ́ gan-an lára àwọn arákùnrin tó ń bójú tó àwọn ojúṣe pàtàkì nínú ètò Ọlọ́run. Oríṣiríṣi iṣẹ́ ni Nora náà sì ti ṣe ní Bẹ́tẹ́lì.

Mò ń sọ àsọyé ní àpéjọ àgbègbè kan, ẹnì kan sì ń túmọ̀ rẹ̀ sí èdè Cebuano

Tí mo bá ronú sẹ́yìn, inú mi máa ń dùn pé àwọn ìbísí tó wáyé ní Philippines ṣojú mi. Nígbà tí mo kọ́kọ́ sìn ní Bẹ́tẹ́lì, mi ò tíì fẹ́ ìyàwó nígbà yẹn, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá [10,000] akéde ló wà ní gbogbo Philippines. Àmọ́ ní báyìí, a ti lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún méjì [200,000]. Láti mú kí iṣẹ́ ìwàásù náà tẹ̀ síwájú, àwa ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé márùndínlógójì [435] ló ń ṣiṣẹ́ sìn ní Bẹ́tẹ́lì báyìí.

Bí ọdún ṣe ń gorí ọdún ni iṣẹ́ Bẹ́tẹ́lì túbọ̀ ń pọ̀ sí i, nígbà tó yá ibẹ̀ ò gba gbogbo wa mọ́. Torí náà, Ìgbìmọ̀ Olùdarí sọ pé ká wá ilẹ̀ tá a lè kọ́ ilé tuntun sí, tó sì máa tóbi ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Èmi àti alábòójútó ẹ̀ka ìtẹ̀wé jọ ń lọ láti ilé kan sí òmíì ní àgbègbè yẹn, a sì ń bi wọ́n bóyá a rẹ́ni tó fẹ́ ta ilé tàbí ilẹ̀ rẹ̀. A ò rẹ́ni tó fẹ́ ta tiẹ̀, kódà ẹnì kan sọ fún wa pé: “Àwa èèyàn Ṣáínà kì í ta ilé wa. A máa ń ra tàwọn míì mọ́ tiwa ni.”

Mò ń túmọ̀ àsọyé Arákùnrin Albert Schroeder

Lọ́jọ́ kan, ọkùnrin kan ṣàdédé pè wá pé òun fẹ́ ta ilẹ̀ òun torí pé ó fẹ́ ṣí lọ sí Amẹ́ríkà. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn yà wá lẹ́nu gan-an, àmọ́ a ò tíì rí nǹkan kan. Ẹnì kan ní àdúgbò yẹn tún ní òun máa ta tòun, ó sì rọ àwọn aládùúgbò tó kù pé kí wọ́n ta tiwọn. Kódà, ọkùnrin tó ní “Àwa èèyàn Ṣáínà kì í ta ilé wa” náà ta ilé rẹ̀ fún wa. Èyí tá à ń wí yìí pẹ́, ilẹ̀ wa ti fi ìlọ́po mẹ́ta ju ohun tá a ní tẹ́lẹ̀ lọ. Ó dá mi lójú pé Jèhófà ló jẹ́ kó ṣeé ṣe.

Lọ́dún 1950, èmi ni mo kéré jù ní Bẹ́tẹ́lì, àmọ́ ní báyìí èmi àtìyàwó mi la dàgbà jù. Mi ò kábàámọ̀ bí mo ṣe tẹ̀ lé àṣẹ Jésù Ọ̀gá wa, tí mo sì lọ sí gbogbo ibi tó ní kí n lọ. Lóòótọ́, àwọn òbí mi lé mi jáde nílé, àmọ́ Jèhófà fún mi lẹ́bí àti ará láàárín àwọn èèyàn rẹ̀. Ó dá mi lójú háún-háún pé Jèhófà ń pèsè gbogbo ohun tá a nílò láìka ibi tá a ti ń sìn. Èmi àti Nora dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó ń pèsè fún wa, a sì ń rọ àwọn míì náà pé kí wọ́n dán Jèhófà wò.​—Mál. 3:10.

Nígbà kan, Jésù sọ fún agbowó orí kan tó ń jẹ́ Mátíù Léfì pé: “Di ọmọlẹ́yìn mi.” Kí ni Mátíù wá ṣe? Bíbélì sọ pé: “Ó fi ohun gbogbo sílẹ̀ sẹ́yìn, ó dìde, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí tẹ̀ lé [Jésù].” (Lúùkù 5:​27, 28) Èmi náà ti ṣe irú ohun tí Mátíù ṣe, mo sì ń rọ àwọn míì náà pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ kí wọ́n lè gba ọ̀pọ̀ ìbùkún.

Mo ṣì ń ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe nínú iṣẹ́ Ọlọ́run ní Philippines

^ ìpínrọ̀ 6 Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é, àmọ́ a ò tẹ̀ ẹ́ mọ́ báyìí..