Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Báwo ni a ṣe gba Pọ́ọ̀lù ‘lọ sí ọ̀run kẹta’ àti “sínú párádísè”?​—2 Kọ́r. 12:​2-4.

Nínú 2 Kọ́ríńtì 12:​2, 3, Pọ́ọ̀lù sọ pé òun mọ ọkùnrin kan ‘tí a gbà lọ sí ọ̀run kẹta.’ Ta ni ọkùnrin náà? Nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará ní Kọ́ríńtì, ó tẹnu mọ́ ọn pé Ọlọ́run ló yan òun láti jẹ́ àpọ́sítélì. (2 Kọ́r. 11:​5, 23) Ẹ̀yìn ìyẹn ló wá mẹ́nu kan ‘àwọn ìran àti àwọn ìṣípayá ti Olúwa.’ Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí kókó yìí, kò mẹ́nu kan àwọn arákùnrin míì. Torí náà, ó bọ́gbọ́n mu láti gbà pé òun gangan ni ọkùnrin náà.​—2 Kọ́r. 12:​1, 5.

Kò sí àní-àní nígbà náà pé Pọ́ọ̀lù lẹni ‘tí a gbà lọ sí ọ̀run kẹta,’ òun náà la sì ‘gbà lọ sínú párádísè.’ (2 Kọ́r. 12:​2-4) Bó ṣe lo ọ̀rọ̀ náà “ìṣípayá” mú ká gbà pé àwọn nǹkan táá ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú ló rí nínú ìran.

Kí ni “ọ̀run kẹta” tí Pọ́ọ̀lù rí?

Nínú Bíbélì, “ọ̀run” lè tọ́ka sí ojú ọ̀run. (Jẹ́n. 11:4; 27:28; Mát. 6:26) Àmọ́ “ọ̀run” tún lè tọ́ka sáwọn nǹkan míì. Ó lè tọ́ka sí ìṣàkóso èèyàn. (Dán. 4:​20-22) Yàtọ̀ síyẹn, ó tún lè tọ́ka sí ìṣàkóso Ọlọ́run, ìyẹn Ìjọba Ọlọ́run.​—Ìṣí. 21:1.

Pọ́ọ̀lù rí “ọ̀run kẹta.” Kí nìdí tó fi pè é ní ọ̀run kẹta? Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, Bíbélì máa ń sọ̀rọ̀ kan náà lẹ́ẹ̀mẹta fún ìtẹnumọ́, ìró gbọnmọ-gbọnmọ tàbí láti túbọ̀ jẹ́ ká mọ bí ọ̀rọ̀ kan ṣe lágbára tó. (Aísá. 6:3; Ìsík. 21:27; Ìṣí. 4:8) Ó jọ pé ìdí tí Pọ́ọ̀lù fi lo ọ̀rọ̀ náà, “ọ̀run kẹta” ni pé ó fẹ́ ká mọ̀ pé ìṣàkóso tóun ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ ga lọ́lá, kò sì láfiwé, ìyẹn sì ni Ìjọba Mèsáyà tí Jésù àtàwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) máa ṣàkóso. (Wo ìwé Insight on the Scriptures, Ìdìpọ̀ 1, ojú ìwé 1059 àti 1062.) Nígbà tí àpọ́sítélì Pétérù ń kọ̀wé sáwọn ará, ó sọ pé à ń retí “ọ̀run tuntun” tí Ọlọ́run ṣèlérí.​—2 Pét. 3:13.

“Párádísè” wo ni Pọ́ọ̀lù sọ pé òun rí?

Ọ̀rọ̀ náà “Párádísè” ní ìtúmọ̀ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀: (1) Ó lè tọ́ka sí ìgbà tí ayé wa yìí máa di Párádísè bíi ti ọgbà Édẹ́nì. (2) Ó lè túmọ̀ sí Párádísè tẹ̀mí táwa èèyàn Ọlọ́run máa gbádùn nínú ayé tuntun. (3) Bákan náà, ó lè túmọ̀ sí àwọn àǹfààní àgbàyanu tó wà lọ́run, ìyẹn “párádísè Ọlọ́run” bó ṣe wà nínú Ìṣípayá 2:7.​—Wo Ilé Ìṣọ́, July 15, 2015, ojú ìwé 8, ìpínrọ̀ 8.

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìtumọ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí ni ìran tí Pọ́ọ̀lù rí ń tọ́ka sí, bó ṣe ròyìn rẹ̀ nínú 2 Kọ́ríńtì 12:4.

Ẹ jẹ́ ká ṣàkópọ̀ ohun tá à ń sọ:

Ó ṣeé ṣe kí “ọ̀run kẹta” tí Pọ́ọ̀lù sọ nínú 2 Kọ́ríńtì 12:2 tọ́ka sí Ìjọba Mèsáyà tí Jésù àtàwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) máa ṣàkóso, ìyẹn sì ni Bíbélì pè ní “ọ̀run tuntun.”​—2 Pét. 3:13.

Ó tún jẹ́ “ọ̀run kẹta” torí pé Ìjọba náà ga lọ́lá kò sì láfiwé.

“Párádísè” tí Pọ́ọ̀lù rí nínú ìran náà ṣeé ṣe kó jẹ́ (1) Párádísè tá à ń retí lórí ilẹ̀ ayé, (2) Párádísè tẹ̀mí tá a máa gbádùn nígbà yẹn, èyí táá gbòòrò ju Párádísè tẹ̀mí tá à ń gbádùn báyìí lọ àti (3) “párádísè Ọlọ́run” tó wà lọ́run lásìkò kan náà pẹ̀lú Párádísè orí ilẹ̀ ayé.

Pẹ̀lú àlàyé yìí, tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ètò tuntun, ó túmọ̀ sí àpapọ̀ ọ̀run tuntun àti ayé tuntun. Ìṣètò tuntun lèyí máa jẹ́, tó ní nínú Ìjọba Ọlọ́run tó wà lọ́run àtàwa tá à ń sin Jèhófà nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé.