Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Rántí?

Ǹjẹ́ O Rántí?

Ṣó o gbádùn kíka àwọn Ilé Ìṣọ́ tó jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí? Wò ó bóyá wàá lè dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

Báwo ni Bíbélì ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run mọ bí nǹkan ṣe rí lára wa?

Nígbà tí àwọn ará Íjíbítì sọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dẹrú, Ọlọ́run mọ ìyà tó ń jẹ wọ́n, ó sì mọ bí nǹkan ṣe rí lára wọn. (Ẹ́kís. 3:7; Aísá. 63:⁠9) Torí pé Ọlọ́run dá wa ní àwòrán ara rẹ̀, ó máa ń dùn wá tá a bá rí i táwọn míì ń jìyà. Ẹ jẹ́ ká máa rántí pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì mọ bí nǹkan ṣe rí lára wa kódà nígbà tá a bá ro ara wa pin.​—⁠wp18.3, ojú ìwé 8 àti 9.

Báwo ni ẹ̀kọ́ Jésù ṣe mú káwọn èèyàn borí ẹ̀tanú?

Nígbà ayé Jésù, ọ̀pọ̀ àwọn Júù ló máa ń ṣe ẹ̀tanú sáwọn tó wá láti ẹ̀yà míì. Jésù tẹnu mọ́ ọn pé a gbọ́dọ̀ lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ ká má sì fàyè gba ẹ̀tanú nínú ọkàn wa. Ó wá rọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n má ṣe gbé ara wọn ga ju àwọn arákùnrin wọn lọ.​—⁠w18.06, ojú ìwé 9 àti 10.

Kí la rí kọ́ látinú bí Jèhófà ò ṣe jẹ́ kí Mósè wọ Ilẹ̀ Ìlérí?

Mósè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. (Diu. 34:10) Àmọ́, nígbà tó ku díẹ̀ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ Ilẹ̀ Ìlérí, wọ́n tún bẹ̀rẹ̀ sí í ráhùn pé àwọn ò rómi mu. Ọlọ́run wá pàṣẹ fún Mósè pé kó bá àpáta náà sọ̀rọ̀. Àmọ́ kàkà kó ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe ló lu àpáta náà. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ torí pé Mósè ò tẹ̀ lé ìtọ́ni ni Jèhófà fi bínú sí i tàbí kó jẹ́ torí pé kò fògo fún Jèhófà. (Núm. 20:​6-12) Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí jẹ́ ká rí ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa ṣègbọràn sí Jèhófà, ká sì máa fògo fún un.​—⁠w18.07, ojú ìwé 13 àti 14.

Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa fi ìrísí dáni lẹ́jọ́?

Ohun mẹ́ta kan wà táwọn èèyàn sábà máa ń wò tí wọ́n bá fẹ́ pinnu irú ẹni tẹ́nì kan jẹ́, ìyẹn ni ẹ̀yà tàbí ìlú tẹ́nì kan ti wá, bó ṣe lówó tó àti ọjọ́ orí rẹ̀. Ó ṣe pàtàkì pé ká máa fojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn èèyàn wò wọ́n, ká má sì ṣe ojúsàájú. (Ìṣe 10:​34, 35)​—⁠w18.08, ojú ìwé 8 sí 12.

Ọ̀nà wo làwọn Kristẹni tó ti dàgbà lè gbà ran àwọn míì lọ́wọ́?

Àwọn Kristẹni tó ti dàgbà lè má lè bójú tó àwọn iṣẹ́ kan mọ́ nínú ìjọ, síbẹ̀ Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wọn, ọ̀pọ̀ nǹkan sì ni wọ́n lè ṣe láti ran àwọn míì lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè kàn sí ọkọ tàbí ìyàwó tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà tàbí kí wọ́n ran àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ lọ́wọ́. Wọ́n lè máa darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kí wọ́n sì máa ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.​—⁠w18.09, ojú ìwé 8 sí 11.

Kí lohun tó wà nínú Àwọn Ohun Tá A Fi Ń Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́?

Lára ẹ̀ ni káàdì ìkànnì JW àtàwọn ìwé ìkésíni. Àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú mẹ́jọ àti ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ìwé pẹlẹbẹ mélòó kan àti ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ méjì tún wà níbẹ̀. A tún láwọn fídíò mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, lára ẹ̀ ni Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?​—⁠w18.10, ojú ìwé 16.

Òwe 23:23 ṣe sọ, báwo làwa Kristẹni ṣe lè “ra òtítọ́”?

A kì í fowó ra òtítọ́. Síbẹ̀ a gbọ́dọ̀ sapá, ká sì lo àkókò wa ká lè rí òtítọ́.​—⁠w18.11, ojú ìwé 4.

Kí la rí kọ́ látinú bí Hóséà ṣe dárí ji Gómérì ìyàwó rẹ̀?

Láìka iye ìgbà tí Gómérì ṣe àgbèrè sí, Hóséà dárí jì í, kò sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Tí Kristẹni kan bá ṣe àgbèrè, ọkọ tàbí ìyàwó rẹ̀ lè pinnu láti dárí jì í. Tí irú ọkọ tàbí aya bẹ́ẹ̀ bá wá ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹni tó ṣe ìṣekúṣe náà lẹ́yìn ìgbà yẹn, ó ti dárí jì í nìyẹn, kò sì lè kọ̀ ọ́ sílẹ̀ mọ́. Tó bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìkọ̀sílẹ̀ yẹn kò bá Ìwé Mímọ́ mu.​—⁠w18.12, ojú ìwé 13.