Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ṣé ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nínú 1 Kọ́ríńtì 15:29 ni pé àwọn Kristẹni kan ṣèrìbọmi nítorí àwọn òkú?
Rárá, kò sí ibì kankan nínú Bíbélì tàbí nínú ìwé ìtàn èyíkéyìí tó fi hàn pé wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀.
Bí àwọn Bíbélì kan ṣe túmọ̀ ẹsẹ yìí ti mú káwọn kan ronú pé nígbà ayé Pọ́ọ̀lù, àwọn kan ṣèrìbọmi nítorí àwọn òkú. Bí àpẹẹrẹ, Bibeli Ìròyìn Ayọ̀ kà pé: “Nítorí kí ni àwọn kan ṣe ń ṣe ìrìbọmi nítorí àwọn tí ó kú? Bí a kò bá ní jí àwọn òkú dìde, kí ni ìdí rẹ̀ tí wọ́n fi ń ṣe ìrìbọmi nítorí wọn?”
Àmọ́ ẹ gbọ́ ohun táwọn ọ̀mọ̀wé Bíbélì méjì kan sọ. Bí àpẹẹrẹ, Ọ̀mọ̀wé Gregory Lockwood sọ pé “kò sí ẹ̀rí kankan nínú Bíbélì tàbí nínú ìtàn tó fi hàn pé ẹnikẹ́ni ṣèrìbọmi nítorí òkú.” Bákan náà, Ọ̀jọ̀gbọ́n Gordon D. Fee sọ pé: “Kò sí àkọsílẹ̀ kankan nínú Bíbélì tàbí nínú ìtàn tó fi hàn pé wọ́n ṣe irú ìrìbọmi bẹ́ẹ̀. Kò sí ohun tó jọ bẹ́ẹ̀ nínú Májẹ̀mú Tuntun, bẹ́ẹ̀ sì ni kò sí ẹ̀rí pé àwọn Kristẹni ìgbàanì ṣe é. Bákan náà, àwọn ṣọ́ọ̀ṣì tí wọ́n dá sílẹ̀ kété lẹ́yìn ikú àwọn àpọ́sítélì kò ṣe bẹ́ẹ̀.”
Nínú Bíbélì, Jésù sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n ‘máa sọ àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, kí wọ́n máa batisí wọn, kí wọ́n sì máa kọ́ wọn pé kí wọ́n máa pa gbogbo ohun’ tóun pa láṣẹ mọ́. (Mát. 28:19, 20) Kẹ́nì kan tó lè ṣèrìbọmi, ó gbọ́dọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀, kó gbà wọ́n gbọ́, kó sì máa ṣègbọràn sí wọn. Ẹni tó ti kú ò lè ṣe àwọn nǹkan yìí, bẹ́ẹ̀ sì ni Kristẹni kan tó wà láàyè kò lè ṣe é fún ẹni tó ti kú.—Oníw. 9:5, 10; Jòh. 4:1; 1 Kọ́r. 1:14-16.
Kí wá ni Pọ́ọ̀lù ń sọ gan-an?
Àwọn kan ní Kọ́ríńtì sọ pé kò sí àjíǹde àwọn òkú. (1 Kọ́r. 15:12) Àmọ́ Pọ́ọ̀lù jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé àwọn òkú máa jíǹde. Ó sọ pé ‘ojoojúmọ́ ni òun ń dojú kọ ikú’ bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó wà láàyè. Láìka ti pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni ẹ̀mí ẹ̀ wà nínú ewu, ó dá a lójú pé tóun bá kú, Jèhófà máa jí òun dìde, òun á sì di ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára bíi ti Jésù.—1 Kọ́r. 15:30-32, 42-44.
Ó yẹ kí àwọn ará tó wà ní Kọ́ríńtì mọ̀ pé torí pé àwọn jẹ́ ẹni àmì òróró, onírúurú àdánwò làwọn máa kojú, àwọn sì máa kú kí Jèhófà tó jí àwọn dìde. Torí náà, níwọ̀n bí a ti “batisí [wọn] sínú Kristi Jésù” ó túmọ̀ sí pé a “batisí [wọn] sínú ikú rẹ̀.” (Róòmù 6:3) Èyí túmọ̀ sí pé bíi ti Jésù, àwọn náà máa dojú kọ onírúurú àdánwò, wọ́n á sì kú kí Jèhófà tó jí wọn dìde sí ọ̀run.
Lẹ́yìn ohun tó lé ní ọdún méjì tí Jésù ṣèrìbọmi, ó sọ fún méjì lára àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé, a “máa batisí yín bí a ṣe ń batisí mi.” (Máàkù 10:38, 39) Kì í ṣe ìrìbọmi inú omi ni Jésù ń sọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó ní lọ́kàn ni pé bí òun ṣe ń fòótọ́ ọkàn sin Jèhófà máa yọrí sí ikú. Pọ́ọ̀lù sọ pé àwọn ẹni àmì òróró máa jìyà pẹ̀lú Jésù “kí a lè ṣe [wọ́n] lógo pẹ̀lú rẹ̀.” (Róòmù 8:16, 17; 2 Kọ́r. 4:17) Torí náà, àwọn náà gbọ́dọ̀ kú kí Ọlọ́run tó jí wọn dìde sí ọ̀run.
Nípa bẹ́ẹ̀, ọ̀nà tó péye tá a lè gbà túmọ̀ ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù nínú 1 Kọ́ríńtì 15:29 ni: “Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, kí ni àwọn tí à ń batisí kí wọ́n lè jẹ́ òkú máa ṣe? Tí a ò bá ní gbé àwọn òkú dìde rárá, kí nìdí tí a fi ń batisí wọn kí wọ́n lè jíǹde?”