Ǹjẹ́ O Rántí?
Ṣó o gbádùn kíka àwọn Ilé Ìṣọ́ tó jáde lọ́dún yìí? Wò ó bóyá wàá lè dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Ojú wo ló yẹ kó o máa fi wo àwọn ẹni àmì òróró?
A mọyì ìgbàgbọ́ wọn; àmọ́ a kì í fún wọn láfiyèsí àrà ọ̀tọ̀. A kì í “kan sáárá” sí wọn. (Júùdù 16, àlàyé ìsàlẹ̀) A kì í béèrè lọ́wọ́ wọn nípa bí wọ́n ṣe di ẹni àmì òróró torí a mọ̀ pé ọ̀rọ̀ àárín àwọn àti Jèhófà nìyẹn.—w20.01, ojú ìwé 29.
Kí làwọn nǹkan tó lè mú kó o gbà pé Jèhófà ń kíyè sí ẹ?
Bíbélì sọ pé Jèhófà ti kíyè sí ẹ kí wọ́n tó bí ẹ. Yàtọ̀ síyẹn, ó ń gbọ́ àdúrà tó ò ń gbà. Jèhófà mọ ohun tó wà lọ́kàn ẹ, ó sì mọ ohun tó ò ń rò. Bákan náà, àwọn nǹkan tó ò ń ṣe lè múnú Jèhófà dùn, ó sì lè bà á nínú jẹ́. (1 Kíró. 28:9; Òwe 27:11) Òun fúnra ẹ̀ ló fà ẹ́ wá sọ́dọ̀ ara ẹ̀.—w20.02, ojú ìwé 12.
Àwọn ìgbà wo ló yẹ ká sọ̀rọ̀, ìgbà wo ló sì yẹ ká dákẹ́?
Inú wa máa ń dùn láti sọ̀rọ̀ Jèhófà fáwọn èèyàn. A máa ń sọ̀rọ̀ tá a bá kíyè sí i pé ẹnì kan fẹ́ ṣi ẹsẹ̀ gbé. Àwọn alàgbà máa ń gba àwọn ará nímọ̀ràn nígbà tó bá yẹ bẹ́ẹ̀. A kì í béèrè (bẹ́ẹ̀ la ò kì í ṣàlàyé) nípa bá a ṣe ń ṣèpàdé àti bá a ṣe ń wàásù nílẹ̀ tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ wa. A kì í sọ̀rọ̀ tó bá kan ọ̀rọ̀ ìjọ tó jẹ́ àṣírí tàbí àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ míì nípa àwọn ará.—w20.03, ojú ìwé 20-21.
Ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín eéṣú inú àsọtẹ́lẹ̀ Jóẹ́lì orí 2 àtèyí tó wà nínú Ìfihàn orí 9?
Jóẹ́lì 2:20-29 sọ pé Ọlọ́run máa lé àwọn eéṣú náà jìnnà, ó sì máa san àsanpadà ohun tí wọ́n jẹ run. Ẹ̀yìn náà ni Ọlọ́run tú ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ sára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Apá kan lára àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣẹ nígbà táwọn ọmọ ogun Bábílónì gbéjà ko ilẹ̀ Ísírẹ́lì, apá tó kù sì ṣẹ nígbà tó yá. Ìfihàn 9:1-11 sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹni àmì òróró tó dà bí eéṣú tí wọ́n ń fìgboyà kéde ìdájọ́ Jèhófà sórí ayé èṣù yìí, ìyẹn ò sì bá àwọn èèyàn ayé lára mu.—w20.04, ojú ìwé 3-6.
Ta ni ọba àríwá lónìí?
Rọ́ṣíà àtàwọn alátìlẹyìn rẹ̀ ni. Wọ́n ń fòfin de iṣẹ́ ìwàásù wa, wọ́n sì ń ṣenúnibíni sí àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa. Ọba àríwá ń bá ọba gúúsù jà.—w20.05, ojú ìwé 13.
Ṣé àwọn ànímọ́ mẹ́sàn-án tó wà nínú Gálátíà 5:22, 23 nìkan ni “èso ti ẹ̀mí”?
Rárá. Ìdí sì ni pé ẹ̀mí Ọlọ́run lè ràn wá lọ́wọ́ láti ní àwọn ànímọ́ míì, bí òdodo. (Éfé. 5:8, 9)—w20.06, ojú ìwé 17.
Ewu wo ló wà nínú kó o máa gbé fọ́tò ẹ àtàwọn nǹkan míì nípa ara ẹ sórí ìkànnì?
Àwọn nǹkan tó ò ń gbé sórí ìkànnì lè fi hàn pé ò ń gbéra ga bó o tiẹ̀ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀.—w20.07, ojú ìwé 6-7.
Kí làwa tá à ń sọni dọmọ ẹ̀yìn lè kọ́ lára àwọn apẹja tó mọṣẹ́ wọn níṣẹ́?
Àwọn apẹja tó mọṣẹ́ wọn níṣẹ́ máa ń lọ síbi tí wọ́n ti lè rẹ́ja pa àti lásìkò tí wọ́n lè rí i pa. Wọ́n máa ń lo irinṣẹ́ tó yẹ. Wọ́n máa ń lo ìgboyà, wọ́n sì máa ń fara da ojú ọjọ́ tí kò bára dé. A lè ṣe bíi tiwọn lẹ́nu iṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn tá à ń ṣe.—w20.09, ojú ìwé 5.
Báwo la ṣe lè mú káwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà?
A lè gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n máa ka Bíbélì lójoojúmọ́ kí wọ́n sì máa ṣàṣàrò lórí ohun tí wọ́n kà. Bákan náà, ká kọ́ wọn bí wọ́n á ṣe máa gbàdúrà.—w20.11, ojú ìwé 4.
Àwọn wo ló wà lára “gbogbo èèyàn” tí Bíbélì sọ pé Ọlọ́run máa sọ “di ààyè nínú Kristi”?—1 Kọ́r. 15:22.
Kì í ṣe gbogbo èèyàn tó ti kú ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń sọ pé Ọlọ́run máa jí dìde. Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ló ń tọ́ka sí, ìyẹn àwọn tí Ọlọ́run ti “sọ di mímọ́ nínú Kristi Jésù.” (1 Kọ́r. 1:2; 15:18)—w20.12, ojú ìwé 5-6.
Iṣẹ́ wo làwọn ẹni àmì òróró tó máa ‘yí pa dà ní ìpajúpẹ́, nígbà kàkàkí ìkẹyìn’ máa ṣe?—1 Kọ́r. 15:51-53.
Wọ́n máa dara pọ̀ mọ́ Jésù, wọ́n á sì jọ fi ọ̀pá irin ṣe olùṣọ́ àgùntàn àwọn èèyàn. (Ìfi. 2:26, 27)—w20.12, ojú ìwé 12-13.