Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 50

Ẹ Máa Fetí sí Ohùn Olùṣọ́ Àgùntàn Rere

Ẹ Máa Fetí sí Ohùn Olùṣọ́ Àgùntàn Rere

“Wọ́n á fetí sí ohùn mi.”​—JÒH. 10:16.

ORIN 3 Agbára Wa, Ìrètí Wa, Ìgbọ́kànlé Wa

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1. Kí nìdí tí Jésù ṣe fi àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ wé àgùntàn?

 JÉSÙ fi àjọṣe tó wà láàárín òun àtàwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ wé àjọṣe tó máa ń wà láàárín olùṣọ́ àgùntàn kan àtàwọn àgùntàn ẹ̀. (Jòh. 10:14) Àfiwé yẹn bá a mu wẹ́kú torí pé àwọn àgùntàn máa ń dá ohùn olùṣọ́ wọn mọ̀, wọ́n sì máa ń fetí sí i. Ọkùnrin kan tó rìnrìn àjò afẹ́ rí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí. Ó sọ pé: “Nígbà témi àtàwọn tá a jọ rìnrìn àjò fẹ́ ya fọ́tò àwọn àgùntàn kan, a gbìyànjú láti bá wọn sọ̀rọ̀ kí wọ́n lè sún mọ́ wa. Àmọ́ wọn ò sún mọ́ wa torí pé wọn ò dá ohùn wa mọ̀. Kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn ni ọmọkùnrin kan tó ń da àwọn àgùntàn náà dé. Bó ṣe ń pè wọ́n báyìí, ni wọ́n ń gbá tẹ̀ lé e.”

2-3. (a) Báwo làwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ṣe ń fi hàn pé àwọn ń fetí sí ohùn rẹ̀? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí àtèyí tó tẹ̀ lé e?

2 Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọkùnrin arìnrìn-àjò yẹn rán wa létí ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nípa àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé: “Wọ́n á fetí sí ohùn mi.” (Jòh. 10:16) Àmọ́ ọ̀run ni Jésù ń gbé. Torí náà, báwo la ṣe lè fetí sí ohùn rẹ̀? Ọ̀nà pàtàkì kan tá a lè gbà fi hàn pé à ń fetí sí ohùn Ọ̀gá wa ni pé ká máa fi àwọn ohun tó ń kọ́ wa ṣèwàhù.​—Mát. 7:24, 25.

3 Nínú àpilẹ̀kọ yìí àtèyí tó tẹ̀ lé e, a máa jíròrò àwọn ẹ̀kọ́ kan tí Jésù fi kọ́ni. Bá a ṣe máa rí i, Jésù kọ́ wa pé àwọn nǹkan kan wà tí ò yẹ ká ṣe mọ́ àti pé àwọn nǹkan míì wà tó yẹ ká máa ṣe. Ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ jíròrò àwọn nǹkan méjì tí olùṣọ́ àgùntàn rere sọ pé ká má ṣe mọ́.

‘Ẹ MÁ ṢE JẸ́ KÍ ÀNÍYÀN KÓ YÍN LỌ́KÀN SÓKÈ MỌ́’

4.Lúùkù 12:29 ṣe sọ, kí ló lè mú kí ‘àníyàn máa kóni lọ́kàn sókè’?

4 Ka Lúùkù 12:29. Jésù rọ àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé kí wọ́n ‘má ṣe jẹ́ kí àníyàn’ nǹkan ti ara ‘kó wọn lọ́kàn sókè mọ́.’ A mọ̀ pé ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n ni ìmọ̀ràn Jésù, ó sì máa ń tọ̀nà. Ó máa ń wù wá láti tẹ̀ lé àwọn ìmọ̀ràn Jésù. Àmọ́ láwọn ìgbà míì, kì í rọrùn láti ṣe bẹ́ẹ̀. Kí nìdí?

5. Kí nìdí táwọn kan fi máa ń ṣàníyàn nípa nǹkan tara?

 5 Àwọn kan lè máa ṣàníyàn nípa ohun tí wọ́n máa jẹ, aṣọ tí wọ́n máa wọ̀ àti ibi tí wọ́n máa gbé. Wọ́n lè máa gbé lórílẹ̀-èdè tí ọrọ̀ ajé wọn ti dẹnu kọlẹ̀, tí ò sì rọrùn láti ríṣẹ́. Ó lè ṣòro fún wọn láti rí owó tí wọ́n á máa fi gbọ́ bùkátà ìdílé wọn. Tàbí kó jẹ́ pé ẹni tó lè máa gbọ́ bùkátà ìdílé wọn ti kú, tí ò sì sẹ́ni tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́ mọ́. Yàtọ̀ síyẹn, àjàkálẹ̀ àrùn Kòrónà ti lè jẹ́ kí iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ àwọn kan, tówó ò sì wọlé fún wọn mọ́. (Oníw. 9:11) Tó bá jẹ́ pé àwọn nǹkan tá a mẹ́nu kàn yìí tàbí àwọn nǹkan míì ti ṣẹlẹ̀ sí wa, báwo la ṣe lè tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Jésù tó sọ pé ká má ṣàníyàn mọ́?

Dípò tí wàá fi jẹ́ kí àníyàn bó o ṣe máa pèsè fún ìdílé rẹ bò ẹ́ mọ́lẹ̀, ṣe ló yẹ kó o gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà (Wo ìpínrọ̀ 6-8) *

6. Ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àpọ́sítélì Pétérù nígbà kan.

6 Ìgbà kan wà tí àpọ́sítélì Pétérù àtàwọn àpọ́sítélì yòókù wà nínú ọkọ̀ lórí Òkun Gálílì nígbà tí ìjì bẹ̀rẹ̀ sí í jà. Wọ́n wá rí Jésù tó ń rìn lórí omi. Ni Pétérù bá sọ pé: “Olúwa, tó bá jẹ́ ìwọ ni, pàṣẹ fún mi pé kí n wá bá ọ lórí omi.” Ni Jésù bá ní kó “máa bọ̀,” Pétérù jáde nínú ọkọ̀ ojú omi, “ó rìn lórí omi, ó sì ń lọ sọ́dọ̀ Jésù.” Lẹ́yìn náà, kí ló ṣẹlẹ̀? “Nígbà tó wo ìjì tó ń jà, ẹ̀rù bà á. Nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí í rì, ó ké jáde pé: ‘Olúwa, gbà mí là!’” Bí Jésù ṣe na ọwọ́ rẹ̀ nìyẹn, tó sì fà á jáde. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé Pétérù lè rìn lórí omi torí pé Jésù ló ń wò. Àmọ́ nígbà tí Pétérù wo ìjì náà, ẹ̀rù bà á, ó sì ṣiyèméjì. Bó ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í rì nìyẹn.​—Mát. 14:24-31.

7. Kí la rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ Pétérù?

7 A lè rí nǹkan kọ́ nínú àpẹẹrẹ Pétérù. Nígbà tí Pétérù jáde kúrò nínú ọkọ̀ tó sì bọ́ sórí omi, kò mọ̀ pé ẹ̀rù máa ba òun débi pé òun máa bẹ̀rẹ̀ sí í rì. Ó wù ú kó máa rìn lórí omi títí tá á fi dé ọ̀dọ̀ Ọ̀gá rẹ̀. Àmọ́ dípò kó máa wo Jésù, ó jẹ́ kí ìjì yẹn dẹ́rù ba òun. Òótọ́ ni pé àwa ò lè rìn lórí omi lónìí, àmọ́ a máa ń kojú àwọn ìṣòro kan tó máa ń dán ìgbàgbọ́ wa wò. Tá ò bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà mọ́ pé ó máa mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ, ìgbàgbọ́ wa ò ní lágbára mọ́. Ìṣòro yòówù ká dojú kọ nígbèésí ayé wa tó dà bí ìjì, Jèhófà ló yẹ ká máa wò, ká sì gbẹ́kẹ̀ lé e pé á ràn wá lọ́wọ́. Báwo la ṣe lè ṣe é?

8. Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ tá ò fi ní máa ṣàníyàn nípa nǹkan tara ju bó ṣe yẹ lọ?

8 Tá ò bá ṣàníyàn nípa àwọn ìṣòro wa, àmọ́ tá a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ó máa ṣe wá láǹfààní. Ẹ rántí pé Jèhófà Bàbá wa onífẹ̀ẹ́ fi dá wa lójú pé òun máa bójú tó wa tá a bá fi Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́. (Mát. 6:32, 33) Àwọn ẹ̀rí wà nínú Bíbélì tó fi hàn pé ó máa ń bójú tó àwọn èèyàn rẹ̀. (Diu. 8:4, 15, 16; Sm. 37:25) Tí Jèhófà bá lè máa pèsè fáwọn ẹyẹ àtàwọn ewéko tó ń yọ òdòdó, ó dájú pé ó máa pèsè fáwa náà. Torí náà, kò yẹ ká máa ṣàníyàn nípa ohun tá a máa jẹ tàbí ohun tá a máa wọ̀! (Mát. 6:26-30; Fílí. 4:6, 7) Ìfẹ́ táwọn òbí ní sáwọn ọmọ wọn ló ń jẹ́ kí wọ́n pèsè nǹkan tara fún wọn. Bákan náà, ìfẹ́ tí Bàbá wa ọ̀run ní sáwa ìránṣẹ́ ẹ̀ ló ń jẹ́ kó pèsè àwọn nǹkan tara fún wa. Torí náà, ó dájú pé Jèhófà máa bójú tó wa!

9. Kí lo rí kọ́ nínú ohun tí tọkọtaya kan ṣe?

9 Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ kan yẹ̀ wò tó fi hàn pé Jèhófà máa ń pèsè àwọn nǹkan tá a nílò fún wa. Tọkọtaya kan tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà gbé mọ́tò wọn rìnrìn àjò tó lé ní wákàtí kan lọ sí ibùdó àwọn tó ń gbé ibi ààbò. Wọ́n lọ gbé àwọn arábìnrin tó wà níbẹ̀ wá sípàdé. Ọkọ sọ pé: “Lẹ́yìn ìpàdé, a pe àwọn arábìnrin náà pé kí wọ́n wá bá wa jẹun nílé, àmọ́ a wá rántí pé kò sí oúnjẹ kankan nílé.” Kí ni tọkọtaya yìí máa ṣe? Ọkọ ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó ní: “Nígbà tá a délé, a rí báàgì ńlá méjì kan tí oúnjẹ kún inú wọn lẹ́nu ọ̀nà wa. Àmọ́, a ò mọ ẹni tó gbé e síbẹ̀. Ẹ ò rí i pé Jèhófà pèsè ohun tá a nílò.” Nígbà tó yá, mọ́tò tọkọtaya náà bà jẹ́. Mọ́tò yìí ni wọ́n máa ń gbé lọ wàásù, àmọ́ kò sí owó tí wọ́n máa fi tún un ṣe. Wọ́n gbé mọ́tò náà lọ síbi tí wọ́n ti máa tún un ṣe kí wọ́n lè mọ iye tó máa ná wọn. Ọkùnrin kan wá síbẹ̀, ó sì béèrè pé: “Ta ló ni mọ́tò yìí?” Arákùnrin náà sọ pé èmi ni mo ni ín, a fẹ́ tún un ṣe ni. Ọkùnrin náà wá sọ pé: “Ìyẹn ò ṣe nǹkan kan, torí irú mọ́tò yìí àti àwọ̀ ẹ̀ gẹ́lẹ́ ni ìyàwó mi ń fẹ́. Èló lẹ fẹ́ tà á?” Bí arákùnrin náà ṣe ta mọ́tò ẹ̀ nìyẹn. Iye tó ta mọ́tò náà sì tó láti ra mọ́tò míì. Ohun tó fi parí ọ̀rọ̀ ẹ̀ ni pé: “Inú wa dùn gan-an, ayọ̀ wa sì kọjá àfẹnusọ. A mọ̀ pé kò ṣàdédé ṣẹlẹ̀. Jèhófà ló ṣe é.”

10. Kí ni Sáàmù 37:5 sọ tó jẹ́ ká rí i pé kò yẹ ká máa ṣàníyàn nípa nǹkan tara?

10 Tá a bá fetí sí ohun tí olùṣọ́ àgùntàn rere sọ pé ká má ṣàníyàn ju bó ṣe yẹ lọ, ó dájú pé Jèhófà máa pèsè fún wa. (Ka Sáàmù 37:5; 1 Pét. 5:7) Ẹ jẹ́ ká ronú nípa àwọn ìṣòro tá a mẹ́nu kàn ní  ìpínrọ̀ karùn-ún. Jèhófà máa ń bá wa yanjú àwọn ìṣòro yẹn. Ó lè jẹ́ olórí ìdílé wa tàbí ẹni tó gbà wá síṣẹ́ ni Jèhófà lò láti pèsè àwọn nǹkan tá a nílò. Tí olórí ìdílé wa ò bá lè pèsè ohun tá a nílò tàbí tí iṣẹ́ bọ́ mọ́ wa lọ́wọ́, Jèhófà máa pèsè àwọn nǹkan tá a nílò fún wa láwọn ọ̀nà míì. Ó sì dá wa lójú pé ó máa ṣe bẹ́ẹ̀. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa nǹkan míì tí olùṣọ́ àgùntàn rere rọ̀ wá pé ká má ṣe mọ́.

“Ẹ YÉÉ DÁNI LẸ́JỌ́”

Tó bá jẹ́ pé ibi táwọn èèyàn dáa sí là ń wò, ìyẹn ò ní jẹ́ ká máa dá wọn lẹ́jọ́ (Wo ìpínrọ̀ 11, 14-16) *

11.Mátíù 7:1, 2 ṣe sọ, kí ni Jésù sọ pé ká má ṣe mọ́, kí sì nìdí tí ò fi rọrùn?

11 Ka Mátíù 7:1, 2. Jésù mọ̀ pé aláìpé làwọn tó ń gbọ́rọ̀ òun, wọ́n sì sábà máa ń wo ohun tó kù díẹ̀ káàtó táwọn èèyàn bá ṣe. Ìdí nìyẹn tí Jésù fi sọ pé: “Ẹ yéé dáni lẹ́jọ́.” Kì í wù wá ká máa dá àwọn tá a jọ ń sin Jèhófà lẹ́jọ́, àmọ́ àìpé máa ń jẹ́ ká ṣe bẹ́ẹ̀. Tá a bá rí i pé a máa ń dá àwọn èèyàn lẹ́jọ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, kí ló yẹ ká ṣe? Ó yẹ ká sa gbogbo ipá wa láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Jésù, ká sì yéé dá àwọn èèyàn lẹ́jọ́.

12-13. Tá a bá ronú lórí ojú tí Jèhófà fi wo Ọba Dáfídì, báwo nìyẹn ò ṣe ní jẹ́ ká dá àwọn èèyàn lẹ́jọ́ mọ́?

12 Tá a bá ń ronú lórí àpẹẹrẹ tí Jèhófà fi lélẹ̀, á ṣe wá láǹfààní. Ibi táwa èèyàn dáa sí ni Jèhófà máa ń wò. Ohun tí Jèhófà ṣe nígbà tí Ọba Dáfídì dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá jẹ́ ká mọ̀ pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí. Bí àpẹẹrẹ, ó ṣe àgbèrè pẹ̀lú Bátí-ṣébà, ó sì tún ní kí wọ́n pa ọkọ ẹ̀. (2 Sám. 11:2-4, 14, 15, 24) Ohun tí Dáfídì ṣe yìí fìyà jẹ òun àti ìdílé ẹ̀ títí kan àwọn ìyàwó ẹ̀ tó kù. (2 Sám. 12:10, 11) Ìgbà kan tún wà tí Dáfídì ò gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá. Ó pàṣẹ pé kí wọ́n ka àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì, kò sì yẹ kó ṣe bẹ́ẹ̀. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìgbéraga ló sún Dáfídì ṣe ohun tó ṣe yìí. Torí ó fẹ́ káwọn èèyàn mọ bí ọmọ ogun òun ṣe pọ̀ tó, ó sì gbẹ́kẹ̀ lé wọn pé wọ́n á dáàbò bo òun. Àmọ́ kí ló wá ṣẹlẹ̀? Àjàkálẹ̀ àrùn pa nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́rin (70,000) lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì!​—2 Sám. 24:1-4, 10-15.

13 Tó o bá wà lórílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì nígbà yẹn, irú ojú wo lo máa fi wo Dáfídì? Ṣé o máa dá Dáfídì lẹ́jọ́ pé kò yẹ kí Jèhófà dárí jì í? Àmọ́ Jèhófà ò ronú lọ́nà yẹn. Ohun tí Jèhófà wò ni bí Dáfídì ṣe ń fi òótọ́ sin òun bọ̀ látẹ̀yìn wá àti bó ṣe ronú pìwà dà tọkàntọkàn. Torí náà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀ṣẹ̀ ńlá ni Dáfídì dá, Jèhófà dárí jì í. Jèhófà mọ̀ pé Dáfídì nífẹ̀ẹ́ òun gan-an àti pé ó fẹ́ ṣe ohun tó tọ́. A dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run pé ibi tá a dáa sí ló máa ń wò.​—1 Ọba 9:4; 1 Kíró. 29:10, 17.

14. Kí ló mú káwa Kristẹni má máa dá àwọn èèyàn lẹ́jọ́ mọ́?

14 Tí Jèhófà bá ń gbójú fo àwọn àṣìṣe wa torí pé a jẹ́ aláìpé, ó yẹ káwa náà máa gbójú fo àṣìṣe àwọn èèyàn, ká sì máa wo ibi tí wọ́n dáa sí. Ó máa ń rọrùn fún wa láti rí àṣìṣe àwọn èèyàn ká sì fi dá wọn lẹ́jọ́. Àmọ́, àwọn tó ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà kì í wo àṣìṣe táwọn ẹlòmíì bá ṣe, ńṣe ni wọ́n máa ń fìfẹ́ hàn sí wọn. Bí àpẹẹrẹ, tí wọ́n bá ṣẹ̀ṣẹ̀ rí dáyámọ́ǹdì kan, ara ẹ̀ kì í dán, àmọ́ ẹni tó mọ ìwúlò ẹ̀ mọ̀ pé lẹ́yìn tí wọ́n bá dán an tán, ẹwà ẹ̀ máa jáde. Bíi ti Jèhófà àti Jésù, a ò ní máa wo àṣìṣe àwọn èèyàn, ibi tí wọ́n dáa sí ló yẹ ká máa wò.

15. Tá a bá ń ronú nípa ipò táwọn èèyàn wà, báwo nìyẹn ò ṣe ní jẹ́ ká máa dá wọn lẹ́jọ́ lọ́nà tó le?

15 Yàtọ̀ sí pé ibi táwọn èèyàn dáa sí ló yẹ ká máa wò, kí ni ò ní jẹ́ ká dá wọn lẹ́jọ́ lọ́nà tó le? Ó yẹ ká wo ohun tí wọ́n ń fara dà nígbèésí ayé wọn. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kan. Lọ́jọ́ kan, Jésù rí opó kan tó jẹ́ aláìní nínú tẹ́ńpìlì tó ń fi owó kéékèèké méjì tí ìníyelórí ẹ̀ kéré gan-an sínú àpótí ìṣúra. Kò béèrè pé: “Kí ló dé tí ò fi owó tó jù bẹ́ẹ̀ lọ síbẹ̀?” Jésù ò wo bí owó tí obìnrin náà mú wá ṣe kéré tó, ohun tí Jésù wò ni ipò obìnrin náà àtohun tó jẹ́ kó mú ọrẹ náà wá. Torí náà, Jésù yìn ín torí pé ó ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe.​—Lúùkù 21:1-4.

16. Kí la rí kọ́ nínú ohun tí Veronica ṣe?

16 Ohun tí Arábìnrin Veronica ṣe jẹ́ ká rí ìdí tó fi yẹ ká máa ronú nípa ipò táwọn èèyàn wà. Inú ìjọ kan náà ni arábìnrin kan tó ń dá tọ́ ọmọ ẹ̀ ọkùnrin àti Veronica wà. Veronica sọ pé: “Lójú tèmi, wọn kì í wá sípàdé, wọn kì í sì í lọ sóde ẹ̀rí déédéé, ìyẹn jẹ́ kí n máa fojú tí ò dáa wò wọ́n. Àmọ́ nígbà tó yá, èmi àti arábìnrin náà jọ lọ sóde ẹ̀rí. Ó ṣàlàyé ohun tóun ń fara dà fún mi. Ó ní ọmọ òun ní àìsàn kan tí kì í jẹ́ kí ọpọlọ ṣiṣẹ́ dáadáa. Ó ń sapá gan-an láti pèsè ohun táwọn méjèèjì nílò àti bí àjọṣe wọn pẹ̀lú Jèhófà ṣe máa dáa. Nígbà míì tí àìlera ọmọ ẹ̀ ò bá jẹ́ kó lè wá sípàdé, ó máa ń rí i pé òun lọ ṣèpàdé níjọ míì.” Ohun tí Veronica fi parí ọ̀rọ̀ ẹ̀ ni pé: “Mi ò mọ̀ pé irú ìṣòro yìí ni arábìnrin yìí ń fara dà. Mo wá mọyì arábìnrin náà gan-an, mo sì ń bọ̀wọ̀ fún un torí ó ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti sin Jèhófà.”

17. Kí ni Jémíìsì 2:8 sọ pé ká máa ṣe, báwo la sì ṣe máa ṣe é?

17 Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá rí i pé a ti ń dá ẹnì kan tá a jọ ń sin Jèhófà lẹ́jọ́? Ó yẹ ká rántí ohun tí Bíbélì sọ pé ká nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa. (Ka Jémíìsì 2:8.) Bákan náà, ó yẹ ká gbàdúrà sí Jèhófà látọkàn wá, ká bẹ̀ ẹ́ pé kó ràn wá lọ́wọ́ ká má dáni lẹ́jọ́ mọ́. Ó yẹ ká ṣiṣẹ́ lórí àdúrà tá a gbà, ká wá àyè láti wà pẹ̀lú ẹni náà ká lè túbọ̀ mọ irú ẹni tó jẹ́. A lè sọ fún un pé kó jẹ́ ká jọ ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí tàbí ká pè é wá jẹun nílé wa. Bá a bá ṣe ń mọ ẹni náà sí i, tá a sì ń wo ibi tó dáa sí, ńṣe là ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà àti Jésù. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn fi hàn pé à ń tẹ̀ lé àṣẹ olùṣọ́ àgùntàn rere tó sọ pé ká yéé dáni lẹ́jọ́.

18. Kí ló yẹ ká ṣe táá fi hàn pé à ń fetí sí ohùn olùṣọ́ àgùntàn rere?

18 Bí àwọn àgùntàn ṣe máa ń fetí sí ohùn olùṣọ́ àgùntàn, bẹ́ẹ̀ náà làwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ṣe máa ń fetí sí ohùn rẹ̀. Tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe, tá ò ṣàníyàn nípa nǹkan tara mọ́, tá ò sì dá àwọn èèyàn lẹ́jọ́ mọ́, Jèhófà àti Jésù máa bù kún wa. Bóyá a wà lára “agbo kékeré” tàbí lára “àwọn àgùntàn mìíràn,” ẹ jẹ́ ká máa fetí sí ohùn olùṣọ́ àgùntàn rere, ká sì máa ṣègbọràn sí i. (Lúùkù 12:32; Jòh. 10:11, 14, 16) Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa jíròrò ohun méjì tí Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé kí wọ́n máa ṣe.

ORIN 101 À Ń Ṣiṣẹ́ Níṣọ̀kan

^ Nígbà tí Jésù sọ pé àwọn àgùntàn òun máa fetí sí ohùn òun, ohun tó ń sọ ni pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun máa fetí sí ẹ̀kọ́ òun, wọ́n á sì máa fi ṣèwà hù nígbèésí ayé wọn. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa gbé méjì lára ẹ̀kọ́ pàtàkì tí Jésù kọ́ wa yẹ̀ wò. Àkọ́kọ́, ká má ṣe máa ṣàníyàn nípa àwọn nǹkan tara àti ìkejì, ká má máa dá àwọn èèyàn lẹ́jọ́. Ẹ jẹ́ ká jíròrò bá a ṣe lè lo àwọn ìmọ̀ràn yẹn nígbèésí ayé wa.

^ ÀWÒRÁN: Iṣẹ́ bọ́ mọ́ arákùnrin kan lọ́wọ́, kò fi bẹ́ẹ̀ sówó lọ́wọ́ ẹ̀ mọ́ láti gbọ́ bùkátà ìdílé ẹ̀, wọ́n sì tún fẹ́ gba ilé míì. Àwọn ìṣòro yẹn lè gbà á lọ́kàn débi pé tí ò bá ṣọ́ra, ó lè má ráyè fún ìjọsìn Ọlọ́run mọ́.

^ ÀWÒRÁN: Arákùnrin kan pẹ́ kó tó dé ìpàdé, àmọ́ ó máa ń ṣe àwọn nǹkan rere míì. Bí àpẹẹrẹ, ó máa ń wàásù lọ́nà àìjẹ́ bí àṣà, ó máa ń ran àwọn àgbàlagbà lọ́wọ́, ó sì máa ń ṣiṣẹ́ ìmọ́tótó ní Gbọ̀ngàn Ìjọba.